OCTOBER 20-26
ONÍWÀÁSÙ 9-10
Orin 30 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ní Èrò Tó Dáa Tó O Bá Tiẹ̀ Níṣòro
(10 min.)
Kò yẹ ká máa rò pé torí inú Jèhófà ò dùn sí wa làwọn ìṣòro kan ṣe dé bá wa (Onw 9:11; w13 8/15 14 ¶20-21)
Torí pé ayé Sátánì là ń gbé, a ò retí pé kí nǹkan lọ bá a ṣe fẹ́, wọ́n sì lè fi ẹ̀tọ́ wa dù wá (Onw 10:7; w19.09 4 ¶10)
Tá a bá tiẹ̀ láwọn ìṣòro kan, ó yẹ ká máa wáyè ronú nípa àwọn ohun rere tí Jèhófà ti ṣe, ká sì fi hàn pé a mọyì wọn (Onw 9:7, 10; w11 10/15 8 ¶1-2)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Onw 10:12-14—Ìkìlọ̀ wo ló wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí tó jẹ́ ká mọ̀ pé òfófó kò dáa? (lv 137 ¶11, 12)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Onw 10:1-20 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Bá ẹnì kan tí inú ẹ̀ ò dùn sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ẹnì kan sọ fún ẹ pé bọ́rọ̀ ajé ṣe dẹnu kọlẹ̀ ti tojú sú òun. Jíròrò kókó kan ní apá “Ohun Tá À Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn” ní àfikún A látinú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn pẹ̀lú ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 47
7. Jèhófà Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Tó O Bá Níṣòro
(15 min.) Ìjíròrò.
Oríṣiríṣi ìṣòro la máa ń ní lójoojúmọ́. Àmọ́ nígbà míì, àwọn ìṣòro kan lè dé bá wa lójijì tó máa kà wá láyà, tó sì lè tán wa lókun. Kódà, ó lè mú ká rẹ̀wẹ̀sì débi pé a ò ní mọ ohun tó yẹ ká ṣe. Kí la lè ṣe tá a bá níṣòro tó le gan-an?
Ìṣòro yòówù kó dé bá wa, Jèhófà máa dúró tì wá, ó sì máa mú kí nǹkan tọ́ lákòókò tó yẹ. (Ais 33:6) Ká lè fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a gbọ́dọ̀ mọ̀wọ̀n ara wa. (Owe 11:2) Tá a bá bára wa nínú ìṣòro, ṣe ló yẹ ká fara balẹ̀, ìyẹn á jẹ́ ká lè ṣèpinnu tó tọ́, àá sì lè bójú tó ara wa tàbí èèyàn wa tí nǹkan ṣẹlẹ̀ sí. (Onw 4:6)
Jèhófà ti fi àwọn ará wa kẹ́ wa. Torí náà, tá a bá níṣòro, ó yẹ ká jẹ́ kí wọ́n mọ̀, ká sì gbà kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́. Rántí pé àwọn ará nífẹ̀ẹ́ ẹ gan-an, inú wọn sì máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.
Ka 2 Kọ́ríńtì 4:7-9. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Tá a bá tiẹ̀ níṣòro, kí nìdí tó fi yẹ ká ṣì máa lọ sípàdé, ká máa ka Bíbélì, ká sì máa wàásù déédéé?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Jèhófà Wà Nítòsí Àwọn Tó Ní Ọgbẹ́ Ọkàn. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni Jèhófà ṣe ran Arákùnrin àti Arábìnrin Septer lọ́wọ́?
Báwo làwọn ará ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́?
Kí la rí kọ́ lára Arákùnrin àti Arábìnrin Septer?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 28, ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 6 àti ẹ̀kọ́ 29