DECEMBER 22-28
ÀÌSÁYÀ 11-13
Orin 14 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Kí Ni Bíbélì Jẹ́ Ká Mọ̀ Nípa Ẹni Tó Máa Jẹ́ Mèsáyà Náà?
(10 min.)
Ó máa jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Dáfídì (Ais 11:1; ip-1 159 ¶4-5)
Ẹ̀mí Jèhófà lá máa darí ẹ̀, á sì máa ṣe nǹkan lọ́nà tí Jèhófà fẹ́ (Ais 11:2, 3a; ip-1 159 ¶6; 160 ¶8)
Ó máa ṣèdájọ́ lọ́nà tó tọ́, á sì tún fàánú hàn tó bá ń ṣèdájọ́ (Ais 11:3b-5; ip-1 160 ¶9; 161 ¶11)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Kí ló máa mú kí ìṣàkóso Jésù dáa ju tèèyàn lọ?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Ais 11:10—Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe nímùúṣẹ? (ip-1 165-166 ¶16-18)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 11:1-12 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Lo ìkànnì jw.org láti dáhùn ìbéèrè ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Ran ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe lè wàásù láti ilé dé ilé. (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 4)
Orin 57
7. Ṣé O Kì Í “Fi Ìrísí Òde Ṣe Ìdájọ́”?
(15 min.) Ìjíròrò.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tá a bá rí la fi máa ń pinnu irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ àtohun tó máa ṣe. Àmọ́ ní ti Jésù, ohun tó fojú rí kọ́ ló fi máa ń ṣèdájọ́, ó sì yẹ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀. (Ais 11:3, 4) Jésù mọ ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, bí ẹni náà ṣe ń ronú àtohun tó ń mú kó ṣe nǹkan. Àmọ́, àwa ò lè mọ àwọn nǹkan yìí. Síbẹ̀, ó yẹ ká gbìyànjú láti fara wé Jésù. Jésù sọ pé: “Ẹ yéé fi ìrísí òde ṣe ìdájọ́, àmọ́ ẹ máa dá ẹjọ́ òdodo.”—Jo 7:24.
Lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, tó bá jẹ́ pé bí ẹnì kan ṣe rí la fi ń pinnu irú ẹni tó jẹ́, a ò ní ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa dáadáa, ìtara wa sì máa dín kù. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá dé ibì kan tí àwọn tó ń gbé níbẹ̀ wá láti ẹ̀yà míì tàbí tí ẹ̀sìn wọn yàtọ̀, ṣé ó máa ń yá wa lára láti wàásù níbẹ̀? Tó bá jẹ́ àdúgbò táwọn olówó tàbí àwọn tálákà pọ̀ sí ńkọ́? Ṣé a máa ń ronú pé ẹnì kan ò ní gbọ́ ìwàásù torí bó ṣe rí? Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé “ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”—1Ti 2:4.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Àwọn Ẹ̀kọ́ Látinú Ilé Ìṣọ́—Má Ṣe Máa Fi Ìrísí Dáni Lẹ́jọ́. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Bá a ṣe rí i nínú fídíò yìí, àwọn nǹkan wo ló ń mú káwọn èèyàn máa fi ojú pa àwọn míì rẹ́?
Kí ló lè ṣẹlẹ̀ tá a bá gba ẹ̀mí burúkú yìí láyè nínú ìjọ?
Kí ló ran àwọn tá a fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò lọ́wọ́ tí wọn ò fi fi ìrísí dá àwọn míì lẹ́jọ́?
Kí lo kọ́ nínú àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ yẹn?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 46-47