DECEMBER 15-21
ÀÌSÁYÀ 9-10
Orin 77 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa “Ìmọ́lẹ̀ Tó Mọ́lẹ̀ Yòò”
(10 min.)
Wọ́n máa rí “ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò” ní Gálílì (Ais 9:1, 2; Mt 4:12-16; ip-1 126 ¶16-17)
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa pọ̀ sí i láwọn orílẹ̀-èdè tó bá fetí sí ìwàásù Jésù, wọ́n sì máa láyọ̀ (Ais 9:3; ip-1 128 ¶18-19)
Àwọn nǹkan dáadáa tí Jésù máa ṣe máa wà títí láé (Ais 9:4, 5; ip-1 128-129 ¶20-21)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Ais 9:6—Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jésù máa jẹ́ “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn”? (ip-1 130 ¶23-24)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 10:1-14 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ẹni náà kì í ṣe Kristẹni. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Máa bá ìjíròrò ẹ lọ látinú ìwé ìléwọ́ tó o fún un nígbà tó o wá kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 49—Àkòrí: Kí Ló Fà Á Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Yí Àwọn Ohun Kan tí Wọ́n Gbà Gbọ́ Pa Dà? (th ẹ̀kọ́ 12)
Orin 95
7. Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
(5 min.) Ìjíròrò.
Ètò Ọlọ́run ò dúró sójú kan, gbogbo ìgbà ló ń tẹ̀ síwájú. Ṣé ò ń fọkàn sí àwọn àyípadà tó ń wáyé? Ẹ jẹ́ ká wo àyípadà mẹ́ta tó ti wáyé nínú ètò Ọlọ́run àtàwọn àǹfààní tá a ti rí.
Kọ òye tuntun kan tá a ní àti àǹfààní tó ṣe wá.—Owe 4:18
Kọ àyípadà kan tó ti wáyé nínú bá a ṣe ń wàásù àti bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti pa àṣẹ Jésù mọ́.—Mt 28:19, 20
Kọ àyípadà kan tó ti wáyé nínú ọ̀nà tá à ń gbà ṣe nǹkan nínú ètò Ọlọ́run àti àǹfààní tó ṣe wá.—Ais 60:17
8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù December
(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 8 àti ẹ̀kọ́ 44-45