DECEMBER 8-14
ÀÌSÁYÀ 6-8
Orin 75 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Èmi Nìyí! Rán Mi!”
(10 min.)
Àìsáyà ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kó tó gbà láti ṣiṣẹ́ wòlíì fún Jèhófà (Ais 6:8; ip-1 93-94 ¶13-14)
Iṣẹ́ tí Jèhófà gbé fún Àìsáyà ò rọrùn (Ais 6:9, 10; ip-1 95 ¶15-16)
Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ò ṣe fetí sí ọ̀rọ̀ Àìsáyà, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn ò fetí sọ́rọ̀ Jésù (Mt 13:13-15; ip-1 99 ¶23)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni mo ṣe lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà bí Àìsáyà?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Ais 7:3, 4—Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo Ọba Áhásì tó jẹ́ ẹni burúkú? (w06 12/1 9 ¶4)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 8:1-13 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Pa Dà Lọ
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
Orin 83
7. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Wàásù Láti Ilé Dé Ilé
(15 min.) Ìjíròrò.
Àwọn èèyàn mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáadáa pé a máa ń wàásù láti ilé dé ilé, ohun tí Jésù àtàwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ náà sì ṣe nìyẹn.—Lk 10:5; Iṣe 5:42.
Àmọ́, a ní láti dá iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé dúró nígbà àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà. A bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láwọn ọ̀nà míì, irú bíi ká fi tẹlifóònù wàásù tàbí ká kọ lẹ́tà. A tún máa ń wàásù fáwọn èèyàn tá a bá pàdé lọ́jà, nínú mọ́tò tàbí láwọn ibòmíì. Inú wa sì dùn torí ó ti wá mọ́ wa lára láti máa wàásù láwọn ọ̀nà míì. Síbẹ̀, ìwàásù ilé-dé-ilé ni ọ̀nà tó ṣe pàtàkì jù tá à ń gbà wàásù ìhìn rere. Torí náà tó bá ṣeé ṣe fún ẹ, rí i pé ò ń lọ́wọ́ sí ìwàásù ilé-dé-ilé déédéé.
Tá a bá ń wàásù láti ilé de ilé, báwo ló ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan yìí?
Ká wàásù fún gbogbo àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa
Kí ọ̀nà tá à ń gbà kọ́ àwọn èèyàn dáa sí, ká túbọ̀ ní ìgboyà, ká má ṣojúsàájú, ká sì ṣe tán láti yááfì àwọn nǹkan fún iṣẹ́ Ọlọ́run
Ká bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ À Ń Wàásù Láìka Bójú Ọjọ́ Ṣe Rí. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí la kọ́ lára àwọn ará tó wà ní erékùṣù Faroe?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 42-43