ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ
Jèhófà ‘Mú Kí Àwọn Ọ̀nà Mi Tọ́’
LỌ́JỌ́ kan, arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Ẹsẹ Bíbélì wo lẹ fẹ́ràn jù?” Mi ò tiẹ̀ rò ó pé ẹ̀ẹ̀mejì tí mo fi sọ pé, “Òwe orí 3, ẹsẹ 5 àti 6 tó sọ pé: ‘Fi gbogbo ọkàn rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Máa kíyè sí i ní gbogbo ọ̀nà rẹ, á sì mú kí àwọn ọ̀nà rẹ tọ́.’” Kí n sòótọ́, Jèhófà ti mú kí àwọn ọ̀nà mi tọ́. Kí nìdí tí mo fi sọ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ kí n sọ ìtàn ìgbésí ayé mi fún yín.
ÀWỌN ÒBÍ MI MÚ KÍ N BẸ̀RẸ̀ SÍ Í RIN Ọ̀NÀ TÓ TỌ́
Káwọn òbí mi tó fẹ́ra ni wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ láwọn ọdún 1920. Orílẹ̀-èdè England ni wọ́n ń gbé, wọ́n sì bí mi lọ́dún 1939. Nígbà tí mo wà ní kékeré, àwọn òbí mi máa ń mú mi lọ sípàdé, mo sì máa ń gbádùn Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run. Títí dòní, mi ò jẹ́ gbàgbé iṣẹ́ àkọ́kọ́ tí mo ṣe nípàdé yẹn, tí mo gun àpótí kékeré kan kẹ́nu mi lè tó makirofóònù. Ọmọ ọdún mẹ́fà péré ni mí nígbà yẹn, ṣe lara mi ń gbọ̀n bí mo ṣe ń wo àwọn àgbàlagbà tó jókòó nínú àwùjọ.
Èmi àtàwọn òbí mi jọ ń wàásù ní òpópónà
Tí n bá fẹ́ lọ sóde ẹ̀rí, bàbá mi máa kọ àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ sínú káàdì kan tí màá fún onílé pé kó kà. Ọmọ ọdún mẹ́jọ péré ni mí nígbà tí mo kọ́kọ́ dá lọ kan ilẹ̀kùn onílé. Ẹ wo bí inú mi ṣe dùn tó nígbà tí onílé náà ka ohun tó wà nínú káàdì ọwọ́ mi tó sì gba ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ”! Ṣe ni mo sáré lọ síbi tí bàbá mi wà, tí mo sì sọ fún wọn. Bí mo ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí àti ìpàdé mú kí n láyọ̀, ó sì jẹ́ kó túbọ̀ wù mí láti fayé mi sin Jèhófà.
Nígbà tó yá, bàbá mi san àsansílẹ̀ Ilé Ìṣọ́ fún mi. Gbàrà tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bá ti dé ni mo máa ń fara balẹ̀ kà á. Ìyẹn mú kí òtítọ́ túbọ̀ jinlẹ̀ lọ́kàn mi, kí n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà yẹn, mo ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà.
Ìdílé wa láǹfààní láti lọ sí Àpéjọ Ìbísí Ìjọba nílùú New York lọ́dún 1950. Ẹṣin ọ̀rọ̀ Thursday, August 3 ni “Ọjọ́ Àwọn Míṣọ́nnárì.” Lọ́jọ́ yẹn, Arákùnrin Carey Barber tó pa dà wá di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìrìbọmi. Nígbà tó béèrè àwọn ìbéèrè méjì tí wọ́n máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi, ṣe ni mo dìde dúró tí mo sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mọ́kànlá (11) ni mí, mo mọ bí ìgbésẹ̀ yẹn ti ṣe pàtàkì tó. Àmọ́, ẹ̀rù bà mí láti wọnú omi torí pé mi ò mọ̀ ọ́n wẹ̀. Àbúrò bàbá mi tẹ̀ lé mi lọ síbi odò náà, ó sì fi mí lọ́kàn balẹ̀ pé kí n má bẹ̀rù, kò sóhun tó máa ṣe mí. Kí n tó mọ̀, wọ́n ti ṣèrìbọmi fún mi, bóyá lẹsẹ̀ mi tiẹ̀ kan ìsàlẹ̀ odò náà. Ṣe ni mò ń ti ọwọ́ arákùnrin kan bọ́ sí òmíì, ọ̀kan ṣèrìbọmi fún mi, èkejì sì gbé mi jáde kúrò nínú omi. Àtọjọ́ yẹn ni Jèhófà ti ń mú kí àwọn ọ̀nà mi tọ́.
MO PINNU PÉ JÈHÓFÀ NI MÀÁ GBẸ́KẸ̀ LÉ
Nígbà tí mo jáde iléèwé, ó wù mí pé kí n ṣe aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ àwọn olùkọ́ mi rọ̀ mí pé kí n lọ sí yunifásítì. Mo ṣe ohun tí wọ́n sọ, mo sì lọ sí yunifásítì. Kò pẹ́ tí mo wá rí i pé mi ò lè kó irin méjì bọná. Torí pé ó ṣòro fún mi láti gbájú mọ́ ẹ̀kọ́ mi níléèwé kí n sì tún jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, mo pinnu pé màá fibẹ̀ sílẹ̀. Mo fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, lẹ́yìn náà mo kọ lẹ́tà, mo sọ fún wọn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé mi ò ṣe mọ́, mo sì fi iléèwé náà sílẹ̀ lẹ́yìn ọdún kan. Torí pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
July 1957 ni mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní ìlú Wellingborough. Mo sọ fún àwọn arákùnrin tó wà ní Bẹ́tẹ́lì pé mo fẹ́ lọ sìn, á sì wù mí kí wọ́n rán mi lọ síbi tí aṣáájú-ọ̀nà tó nírìírí wà. Wọ́n wá ní kí n lọ síbi tí Arákùnrin Bert Vaisey ti ń sìn. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ lára wọn, wọ́n nítara, wọ́n sì ràn mí lọ́wọ́ láti ní ìṣètò fún lílọ sóde ẹ̀rí. Àwa mẹ́jọ péré la wà nínú ìjọ yẹn, àwọn arábìnrin àgbàlagbà mẹ́fà, èmi àti Arákùnrin Vaisey. Bí mo ṣe máa ń múra gbogbo ìpàdé sílẹ̀, tí mo sì máa ń kópa nínú wọn mú kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà kí n sì máa kọ́ni.
Nígbà tó yá, ìjọba rán mi lọ sẹ́wọ̀n torí pé mi ò wọṣẹ́ ológún, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi mí sílẹ̀. Ẹ̀yìn náà ni mo pàdé aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan tó ń jẹ́ Barbara. A ṣègbéyàwó lọ́dún 1959, a sì pinnu pé a máa lọ síbikíbi tí ètò Ọlọ́run bá rán wa lọ. Ìlú Lancashire ni wọ́n kọ́kọ́ rán wa lọ. Nígbà tó sì di January 1961, wọ́n pè mí sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ olóṣù kan tí wọ́n ṣe ní Bẹ́tẹ́lì. Ó yà mí lẹ́nu pé lẹ́yìn tá a parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn, wọ́n sọ mí di alábòójútó àyíká. Ọ̀sẹ̀ méjì ni mo fi gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ alábòójútó àyíká kan tó nírìírí nílùú Birmingham, wọ́n sì gbà kí ìyàwó mi wà pẹ̀lú mi. Ẹ̀yìn náà ni wọ́n rán wa lọ sí àyíká tiwa ní ìlú Lancashire àti Cheshire.
KÒ SÓHUN TÓ DÀ BÍI KÉÈYÀN GBẸ́KẸ̀ LÉ JÈHÓFÀ
Àsìkò ìsinmi la wà ní August 1962, nígbà tá a gba lẹ́tà kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Nígbà tá a já àpò ìwé náà, ǹjẹ́ ẹ mọ ohun tá a bá níbẹ̀? Fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ni, níbi tá a ti máa gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún odindi oṣù mẹ́wàá! Lẹ́yìn témi àtìyàwó mi ti fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, a kọ̀rọ̀ kúnnú fọ́ọ̀mù náà, a sì tètè mú un lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì bí wọ́n ṣe sọ. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà, a tẹkọ̀ létí, ó di Brooklyn New York, fún kíláàsì kejìdínlógójì (38) ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.
Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n mú ká túbọ̀ lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì kọ́ wa nípa ètò Jèhófà àti àwọn ará tó wà kárí ayé. Torí pé a ṣì kéré, ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ lára àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì. Mo láǹfààní láti máa bá Arákùnrin Fred Rusk tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wa ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́. Ọ̀kan lára ẹ̀kọ́ tí wọ́n tẹ̀ mọ́ mi lọ́kàn ni pé tí n bá máa fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn, kí n rí i dájú pé inú Ìwé Mímọ́ ni mo ti mú un. Lára àwọn tó wá bá wa sọ̀rọ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà ni Arákùnrin Nathan Knorr, Frederick Franz àti Karl Klein, àwọn arákùnrin yìí sì ní ìrírí gan-an. A rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ lára Arákùnrin A. H. Macmillan. Mi ò lè gbàgbé àlàyé tí wọ́n ṣe nípa bí Jèhófà ṣe darí ètò rẹ̀ lásìkò ìfọ̀mọ́ tó wáyé lọ́dún 1914 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1919!
IṢẸ́ ÌSÌN WA YÍ PA DÀ
Nígbà tí ilé ẹ̀kọ́ náà ń parí lọ, Arákùnrin Knorr sọ fún èmi àti ìyàwó mi pé orílẹ̀-èdè Bùrúńdì ní Áfíríkà ni wọ́n máa rán wa lọ. Ṣe la sáré lọ wo Ìwé Ọdọọdún tó wà níbi ìkówèésí ní Bẹ́tẹ́lì ká lè mọ iye àwọn akéde tó wà ní Bùrúńdì nígbà yẹn. Àmọ́, ó yà wá lẹ́nu gan-an pé kò sí akéde kankan ní Bùrúńdì nígbà yẹn! Ìlú tíṣẹ́ ìwàásù ò tíì dé là ń lọ nílẹ̀ Áfíríkà, a ò sì débẹ̀ rí. Ìyẹn wá jẹ́ ká bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́kàn sókè! La bá fọ̀rọ̀ náà sádùúrà, Jèhófà sì mú kọ́kàn wa balẹ̀.
Nígbà tá a dé Bùrúńdì, gbogbo nǹkan ló ṣàjèjì sí wa, ojú ọjọ́ wọn gbóná, àṣà wọn sì yàtọ̀. Kódà èdè Faransé ni wọ́n ń sọ, a ò sì gbọ́ èdè náà. Torí náà, ó di dandan pé ká kọ́ èdè Faransé. Yàtọ̀ síyẹn, a ò tètè ríbi tá a máa gbé. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn tá a débẹ̀, ọ̀kan lára àwọn tá a jọ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn Harry Arnott wá sọ́dọ̀ wa nígbà tó ń pa dà lọ síbi tó ti ń sìn ní Sáńbíà, òun ló sì bá wa wá ilé tá a kọ́kọ́ gbé. Àmọ́ kò pẹ́ táwọn aláṣẹ fi bẹ̀rẹ̀ sí í ta kò wá torí pé wọn ò mọ nǹkan kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí ara wa bẹ̀rẹ̀ sí í mọlé, àwọn aláṣẹ sọ fún wa pé a ò ní lè dúró nílùú yẹn torí a ò ní ìwé àṣẹ láti ṣiṣẹ́. Ó dùn wá gan-an pé a ní láti fi ìlú yẹn sílẹ̀, a sì lọ sí orílẹ̀-èdè Uganda.
Àyà wa ń já bá a ṣe ń lọ sí Uganda torí pé a ò ní ìwé ìgbélùú, àmọ́ ọkàn wa balẹ̀ torí a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Arákùnrin kan láti Kánádà tó ń sìn níbi tí àìní gbé pọ̀ lórílẹ̀-èdè Uganda ṣàlàyé ọ̀rọ̀ wa fáwọn aláṣẹ, àwọn aláṣẹ sì fún wa lóṣù díẹ̀ láti gba ìwé ìgbélùú. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ò fi wá sílẹ̀.
Nǹkan yàtọ̀ gan-an níbí sí ti Bùrúńdì. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ní Uganda bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ju méjìdínlọ́gbọ̀n (28) lọ ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, a rí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́ a rí i pé ká tó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ kí wọ́n sì tẹ̀ síwájú, a gbọ́dọ̀ kọ́ ọ̀kan lára àwọn èdè ìbílẹ̀ tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Agbègbè Kampala níbi tí wọ́n ti ń sọ èdè Luganda la ti ń wàásù, torí náà èdè yẹn la kọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó gbà wá lọ́dún mélòó kan ká tó lè sọ ọ́ dáadáa, bá a ṣe kọ́ èdè náà mú ká lè dé ọkàn àwọn èèyàn. Ìyẹn jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ká sì mọ ibi tá a ti lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Nígbà tí wọ́n rí bá a ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í sọ tinú wọn fún wa, ìyẹn sì jẹ́ ká mọ bí ohun tí wọ́n kọ́ ṣe rí lára wọn.
A RÌNRÌN ÀJÒ GAN-AN
Mọ́tò tá a fi ń rìnrìn àjò ní Uganda
Inú wa ń dùn gan-an bá a ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àmọ́, ayọ̀ wa tún légbá kan nígbà tí ètò Ọlọ́run ní ká bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ arìnrìn-àjò lórílẹ̀-èdè náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Kẹ́ńyà sọ pé ká lọ káàkiri orílẹ̀-èdè náà, ká sì wá àwọn agbègbè tí wọ́n lè rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe lọ kí wọ́n lè lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn gbà wá tọwọ́tẹsẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò pàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí. Wọ́n máa ń tọ́jú wa gan-an, kódà wọ́n máa ń se oúnjẹ fún wa.
Nígbà tó yá, mo rìnrìn àjò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Láti Kampala, mo wọkọ̀ ojú irin fún ọjọ́ méjì lọ sí Mombasa. Látibẹ̀, mo wọkọ̀ ojú omi lọ sí erékùṣù Seychelles, tó wà ní àárín agbami Indian Ocean. Àmọ́ látọdún 1965 sí 1972, ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé mi lọ sí Seychelles. Àkókò yẹn ni àwọn akéde méjì tó wà níbẹ̀ di àwùjọ, nígbà tó sì yá, wọ́n di ìjọ tó ń gbèrú gan-an. Àwọn orílẹ̀-èdè míì tí mo tún rìnrìn àjò lọ ni Eritrea, Etiópíà àti Sudan.
Àmọ́ nǹkan yí pa dà lójijì ní Uganda nígbà táwọn ológun gbàjọba. Àwọn nǹkan burúkú tó ṣẹlẹ̀ láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e jẹ́ kí n rí i pé ó bọ́gbọ́n mu ká tẹ̀ lé ìtọ́ni Jésù tó ní ká “san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì.” (Máàkù 12:17) Nígbà kan, wọ́n sọ pé kí gbogbo àwọn àjèjì tó wà lórílẹ̀-èdè Uganda lọ forúkọ sílẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá tó sún mọ́ wọn jù. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la ṣe bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn nígbà tí èmi àti míṣọ́nnárì kan ń wa mọ́tò lọ ní Kampala, àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ dá wa dúró. Ṣe lọkàn wa ń lù kì-kì. Wọ́n fẹ̀sùn kàn wá pé amí ni wá, wọ́n sì mú wa lọ sí oríléeṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá. Àmọ́, a ṣàlàyé fún wọn pé míṣọ́nnárì ni wá. Gbogbo bá a ṣe ń ṣàlàyé fún wọn pé a ti forúkọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ kò wọ̀ wọ́n létí rárá. Ni àwọn ọlọ́pàá tó dira bá fi wá sínú ọkọ̀, wọ́n sì gbé wa lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá tó sún mọ́ ilé wa. Nígbà tá a débẹ̀, ọlọ́pàá tá a bá sọ fún àwọn tó mú wa wá pé a ti forúkọ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ó sì ní kí wọ́n tú wa sílẹ̀, ṣe lara tù wá pẹ̀sẹ̀!
Lásìkò yẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọkàn wa kì í balẹ̀ pàápàá táwọn sójà tó ti mutí yó bá dá wa dúró lójú ọ̀nà. Tíyẹn bá ṣẹlẹ̀, a máa ń gbàdúrà, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ dìgbà tí wọ́n á fi jẹ́ ká kọjá. Àmọ́ ó dùn wá pé nígbà tó dọdún 1973, ìjọba lé gbogbo àwa míṣọ́nnárì kúrò ní Uganda.
Mò ń fi ẹ̀rọ kékeré tó máa ń da ìwé kọ tẹ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Abidjan, Côte d’Ivoire
Lẹ́yìn ìyẹn, ètò Ọlọ́run sọ pé ká lọ sórílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire, ní West Africa. Ìyípadà ńlá lèyí jẹ́ fún wa torí a ní láti kọ́ àṣà tuntun. A tún ní láti kọ́ èdè Faransé torí òun ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Yàtọ̀ síyẹn, a ní láti gbé pẹ̀lú àwọn míṣọ́nnárì tí wọ́n wá láti ilẹ̀ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́, a rí ọwọ́ Jèhófà torí kò pẹ́ táwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Èmi àtìyàwó mi gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, a sì ń rí bó ṣe ń mú àwọn ọ̀nà wa tọ́.
Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àyẹ̀wò fi hàn pé Barbara ìyàwó mi ní àrùn jẹjẹrẹ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà la rìnrìn àjò lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì ká lè gba ìtọ́jú tó yẹ, nígbà tó dọdún 1983, ó ṣe kedere pé a ò lè sìn nílẹ̀ Áfíríkà mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí dun àwa méjèèjì gan-an.
NǸKAN YÍ PA DÀ FÚN MI
Nígbà tá a dé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London, ṣe ni àìsàn ìyàwó mi túbọ̀ ń burú sí i. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó kú. Àwọn tó wà ní Bẹ́tẹ́lì dúró tì mí. Ó tiẹ̀ ní tọkọtaya kan tó ràn mí lọ́wọ́ gan-an, tí wọ́n sì jẹ́ kí n túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Arábìnrin kan wà tó ń jẹ́ Ann tó máa ń tilé wá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Ó ti ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe rí, ó sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Nígbà tó dọdún 1989, a ṣègbéyàwó, a sì jọ ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní London.
Èmi àti Ann rèé níwájú ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ sí Britain
Látọdún 1995 sí 2018, mo láǹfààní láti jẹ́ aṣojú oríléeṣẹ́, mo sì ti ṣèbẹ̀wò sí ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta (60) orílẹ̀-èdè. Ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo bẹ̀ wò, mo rí bí Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀, láìka onírúurú ìṣòro tí wọ́n ń kojú sí.
Lọ́dún 2017, ètò Ọlọ́run ní kí n ṣèbẹ̀wò sí orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà. Inú mi dùn gan-an láti mú Ann wá sí Burundi, ó sì yà wá lẹ́nu pé àwọn akéde tó wà níbẹ̀ ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ààbọ̀ (15,500) báyìí! Ìyẹn nìkan kọ́ o, ọ̀kan lára àwọn àdúgbò tí mo ti wàásù láti ilé dé ilé lọ́dún 1964 ni wọ́n kọ́ Bẹ́tẹ́lì sí báyìí.
Inú mi dùn gan-an nígbà tí ètò Ọlọ́run sọ àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tí mo máa ṣèbẹ̀wò sí lọ́dún 2018. Orílẹ̀-èdè Côte d’Ivoire wà lára àwọn ibi tí mo máa lọ. Nígbà tá a dé Abidjan tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, ṣe ló dà bí ìgbà tí mo pa dà sílé. Nígbà tí mo wo orúkọ ẹni tó wà níyàrá tó tẹ̀ lé tèmi, mo rí i pé Arákùnrin Sossou ni. Mo rántí pé òun ni alábòójútó ìlú nígbà tí mo wà ní Abidjan. Àmọ́ kì í ṣe Sossou tí mo lérò ló wà níbẹ̀, ọmọ ẹ̀ ni.
Kò sí àní-àní pé Jèhófà máa ń mú ọ̀rọ̀ ẹ̀ ṣẹ. Àwọn nǹkan tí mo kojú nígbèésí ayé ti jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé téèyàn bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó máa mú àwọn ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Ní báyìí, mo ti pinnu pé màá máa rìn lójú ọ̀nà tó túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i yìí títí wọnú ayé tuntun.—Òwe 4:18.