ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w04 1/1 ojú ìwé 22-27
  • A Bù Kún Wa Jìngbìnnì Nítorí Pé A ní Ẹ̀mí Míṣọ́nnárì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Bù Kún Wa Jìngbìnnì Nítorí Pé A ní Ẹ̀mí Míṣọ́nnárì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àpẹẹrẹ Ìgboyà Táwọn Òbí Mi Fi Lélẹ̀
  • Bí Ann Ṣe Rí Òtítọ́
  • Ohun Kan Náà Là Ń Lé, Àmọ́ Ipò Wa Yí Padà
  • Ìdílé Wa Sìn Nílẹ̀ Òkèèrè
  • Ìfòfindè—Ìdánwò Ìgbàgbọ́ àti Ọgbọ́n Tá A Dá Sí I
  • A Forí Lé New Guinea
  • Bí Ipò Nǹkan Ṣe Gbà La Ṣe Ṣe É
  • Sísìn ní “Àwọn Erékùṣù Aláyọ̀”
  • Ọ̀nà Ọpẹ́ Wa Pọ̀
  • Jèhófà ‘Mú Kí Àwọn Ọ̀nà Mi Tọ́’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Àwọn Nǹkan Díẹ̀ Tá A Yááfì Jẹ́ Ká Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • A Pinnu Láti Sin Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Dàgbà ní Alaska
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
w04 1/1 ojú ìwé 22-27

Ìtàn Ìgbésí Ayé

A Bù Kún Wa Jìngbìnnì Nítorí Pé A ní Ẹ̀mí Míṣọ́nnárì

GẸ́GẸ́ BÍ TOM COOKE ṢE SỌ Ọ́

Ìró ìbọn ṣàdédé ba ọ̀sán ọjọ́ tí gbogbo nǹkan tòrò minimini náà jẹ́. Ńṣe ni ọta ìbọn ń fò kọjá láàárín àwọn igi tó wà nínú ọgbà wa. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ gan-an? Kò pẹ́ sí àkókò yẹn la gbọ́ pé àwọn kan ti dìtẹ̀ gbàjọba, àti pé Ọ̀gágun Idi Amin ló wá ń ṣàkóso Uganda báyìí. Ọdún 1971 lèyí ṣẹlẹ̀.

KÍ NÌDÌÍ tí èmi àti Ann, ìyàwó mi, fi kó kúrò ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó lálàáfíà tá a sì kó wá sí apá ibi tó léwu nílẹ̀ Áfíríkà yìí? Lóòótọ́, ẹni tó fẹ́ràn láti máa rìnrìn àjò láti ìlú kan sí ìlú kejì ni mí, ṣùgbọ́n àpẹẹrẹ àwọn òbí mi tí wọ́n fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Ìjọba náà ló fún mi níṣìírí láti ní ẹ̀mí míṣọ́nnárì.

Mo rántí ọjọ́ kan tí oòrùn mú ganrínganrín ní August 1946, nígbà táwọn òbí mi kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀. Wọ́n dúró sí ibi ilẹ̀kùn àbáwọlé, wọ́n sì bá àwọn àlejò méjì náà sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn gan-an. Àwọn àlejò wọ̀nyí, ìyẹn Fraser Bradbury àti Mamie Shreve, tún padà wá sílé wa lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbésí ayé ìdílé wa sì yí padà lọ́nà tó gbàfiyèsí láàárín oṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn.

Àpẹẹrẹ Ìgboyà Táwọn Òbí Mi Fi Lélẹ̀

Àwọn òbí mi máa ń kópa nínú ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò tó ń lọ lábúlé wa. Bí àpẹẹrẹ, kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn, ńṣe la lẹ fọ́tò Winston Churchill mọ́ gbogbo ilé wa. Kódà, ilé wa ni ẹgbẹ́ Conservative Party Committee ti ń ṣèpàdé ẹgbẹ́ wọn lákòókò tí wọ́n ń múra ìbò tí wọ́n dì lórílẹ̀-èdè wa lẹ́yìn ogun. Ìdílé wa tún mọ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì àti láwùjọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ọdún mẹ́sàn-án péré ni mí nígbà yẹn, síbẹ̀ mo mọ̀ pé ó ya àwọn mọ̀lẹ́bí wa lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí i pé a fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àpẹẹrẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tá à ń dara pọ̀ mọ́, tí wọ́n ń sìn tọkàntọkàn tí wọn kì í sì í bẹ̀rù ló mú káwọn òbí mi di ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ ìwàásù. Láìpẹ́, bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọyé táwọn èèyàn máa ń gbọ́ látorí ẹ̀rọ gbohùngbohùn kan tó wà ní àgbègbè kan táwọn ilé ìtajà pọ̀ sí ní Spondon, ìyẹn lábúlé wa, àwa ọmọ náà sì máa ń dúró sáwọn ibi táwọn èèyàn ti máa rí wa tá a ó sì kó àwọn ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ́wọ́. Kí n má parọ́, ńṣe ló máa ń dà bíi pé kí ilẹ̀ lanu gbé mi mì nígbà táwọn ọmọ tá a jọ ń lọ sílé ìwé bá bá mi níbẹ̀.

Àpẹẹrẹ àwọn òbí mi tún ran Daphne, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin lọ́wọ́, láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead lọ́dún 1955, wọ́n sì yàn án lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Japan.a Àmọ́, Zoe, àbúrò mi obìnrin, kò sin Jèhófà mọ́.

Láàárín àkókò náà, mo parí ẹ̀kọ́ tí mò ń kọ́ nípa àwòrán yíyà àti fífi àwòrán àtàwọn ọ̀rọ̀ ṣàpèjúwe ohun tó bá ṣẹlẹ̀. Ohun pàtàkì táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ mi máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ jù lọ láyé ìgbà yẹn ni iṣẹ́ àṣesin orílẹ̀-èdè ẹni tó pọndandan nígbà yẹn lọ́hùn-ún. Nígbà tí mo sọ fún wọn pé ẹ̀rí ọkàn mi kò lè jẹ́ kí n ṣe é, àwàdà ni wọ́n rò pé mò ń ṣe. Ọ̀rọ̀ yìí fún mi láǹfààní láti bá àwọn kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jíròrò Bíbélì. Láìpẹ́, wọ́n rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún kan nítorí pé mo kọ̀ láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun. Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì nígbà tá a jọ wà nílé ẹ̀kọ́ àwòrán yíyà náà ló wá di ìyàwó mi níkẹyìn. Àmọ́, màá jẹ́ kí Ann fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bó ṣe rí òtítọ́ fún yín.

Bí Ann Ṣe Rí Òtítọ́

“Ìdílé mi kì í ṣe ìdílé onísìn, mi ò sì ṣe batisí nínú ìsìn kankan. Àmọ́ ọ̀ràn nípa ohunkóhun tó jọ mọ́ ìsìn máa ń ká mi lára gan-an, ṣọ́ọ̀ṣì èyíkéyìí táwọn ọ̀rẹ́ mi bá sì ń lọ ni mo máa ń tẹ̀ lé wọn lọ. Ìfẹ́ tí mo ní sí Bíbélì túbọ̀ pọ̀ sí i nígbà tí mò gbọ́ ìjíròrò alárinrin tó wáyé lákòókò tí Tom àti Ẹlẹ́rìí kan ń bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mìíràn fèrò wérò nílé ẹ̀kọ́. Ẹ̀rù bà mí nígbà tí wọn fi Tom àti Ẹlẹ́rìí yẹn sẹ́wọ̀n nítorí pé wọn kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun.

“Mo máa ń kọ̀wé sí Tom nígbà tó wà lẹ́wọ̀n, ìfẹ́ tí mo ní sí Bíbélì sì túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i. Ìgbà tí mo lọ sí London láti lọ kàwé sí i ni mo wá gbà pé kí Muriel Albrecht máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Muriel ti sìn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Estonia, òun àti ìyá rẹ̀ sì jẹ́ orísun ìṣírí ńlá fún mi. Láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìpàdé, mo sì máa ń dúró síwájú Victoria Station tí màá máa fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn èèyàn níbẹ̀.

“Ìjọ Southwark tó wà ní gúúsù London ni mo dara pọ̀ mọ́. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tẹ̀mí tí wọ́n wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè ló wà nínú ìjọ náà, ọ̀pọ̀ lára wọn ni kò sì fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Bo tilẹ̀ jẹ́ pé àjèjì ni mí, síbẹ̀ wọ́n ṣe mi bíi mọ̀lẹ́bí wọn. Ìfẹ́ tí mo rí nínú ìjọ yẹn gan-an ló mú un dá mi lójú pé òtítọ́ nìyí, mo sì ṣe ìrìbọmi lọ́dún 1960.”

Ohun Kan Náà Là Ń Lé, Àmọ́ Ipò Wa Yí Padà

Èmi àti Ann ṣègbéyàwó ní òpin ọdún 1960, àwa méjèèjì la sì ní in lọ́kàn pé a máa wọnú iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì. Àmọ́ ipò wa yí padà nígbà tá a rí i pé oyún ti wà níkùn. Lẹ́yìn tá a bí Sara, ọmọbìnrin wa, èmi àti Ann ṣì ní in lọ́kàn pé a máa lọ sí orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba náà gan-an. Mo kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ ní May 1966 mo rí lẹ́tà kan gbà láti Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ ní Uganda, tí wọ́n sọ pé àyè ti wà fún mi. Àmọ́ lákòókò tá à ń wí yìí, oyún ọmọ wa kejì ti wà níkùn Ann. Lílọ tá a fẹ́ lọ yẹn dà bí ohun tí kò bọ́gbọ́n mu rárá lójú àwọn kan. A lọ sọ fún dókítà wa nípa ọ̀ràn náà, ó sì sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá fẹ́ lọ, ẹ rí i pé ẹ wọ ọkọ òfuurufú lọ síbẹ̀ kí oyún ìyàwó rẹ̀ tó pé oyún oṣù méje.” Bá a ṣe forí lé Uganda lójú ẹsẹ̀ nìyẹn. Nítorí ìdí èyí, àwọn òbí wa o fojú rí Rachel, ọmọbìnrin tá a bí ṣèkejì títí tó fi pé ọmọ ọdún méjì. Ìsinsìnyí táwa náà ti di òbí àgbà la wa lóye ohun ńlá táwọn òbí wa fara dà nígbà yẹn, a sì mọrírì rẹ̀ gan-an.

Dídé tá a dé sí Uganda ní 1966 múnú wa dùn gan-an, ó sì tún ṣẹ̀rù bà wá. Bá a ṣe ń jáde nínú ọkọ̀ òfuurufú báyìí, àwọn ohun aláwọ̀ mèremère tó wà láyìíká ló kọ́kọ́ fà wá mọ́ra. Wọ́n tàn yòò gan-an ni. Ilé wa tá a kọ́kọ́ gbé wà nítòsí ìlú kékeré Iganga, tó wà ní nǹkan bí àádọ́ta kìlómítà sí Jinja, ìyẹn ìlú kan tó wà ní ibi tó jẹ́ orísun Odò Náílì. Àwùjọ àdádó kan tó wà ní Jinja ni àwọn Ẹlẹ́rìí tó sún mọ́ wa jù lọ. Gilbert òun Joan Walters àti Stephen òun Barbara Hardy tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ló ń bójú tó àwùjọ náà. Mo kọ̀wé béèrè pé kí àwọn ará ibi iṣẹ́ mi gbé mi lọ sí Jinja kí n lè túbọ̀ ṣèrànwọ́ fún àwùjọ yìí. Kété lẹ́yìn tá a bí Rachel la kó lọ sí Jinja. Inú wa dùn gan-an pé a láǹfààní láti bá àwùjọ kékeré táwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ bíi mélòó kan wà níbẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀, bí àwùjọ náà ṣe ń gbèrú sí i láti di ìjọ tí yóò ṣìkejì ní Uganda.

Ìdílé Wa Sìn Nílẹ̀ Òkèèrè

Èmi àti Ann rí i pé ibi tá a yàn yẹn ló dára jù lọ láti tọ́ àwọn ọmọ wà. A láǹfààní àtibá àwọn míṣọ́nnárì tó wá láti onírúurú orílẹ̀-èdè ṣiṣẹ́ pọ̀, a sì tún láǹfààní láti ṣèrànwọ́ fún ìjọ tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀. A fẹ́ràn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tí wọ́n jẹ́ ará Uganda gan-an, wọ́n sì máa ń wá sílé wa. Stanley àti Esinala Makumba máa ń fún wa níṣìírí gan-an.

Àmọ́ àwọn ará nìkan kọ́ ló máa ń bá wa lálejò, àwọn ẹranko ìgbẹ́ tó dùn ún wò tó yí wa ká máa ń bá wa lálejò pẹ̀lú. Àwọn erinmi máa ń rìn jáde látinú Odò Náílì lóru, wọ́n á sì máa rìn bọ̀ nítòsí ilé wa. Mo rántí ìgbà kan tá a rí òjòlá tó gùn tó mítà mẹ́fà nínú ọgbà wa. Àwọn ìgbà mìíràn wà tá a máa ń lọ wòran làwọn ọgbà ẹranko, níbi táwọn kìnnìún àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ mìíràn tí máa ń rìn káàkiri bí wọ́n ṣe fẹ́.

Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, ìran àpéwò la máa ń jẹ́ fún àwọn ará àdúgbò náà tí wọn ò rí kẹ̀kẹ́ téèyàn fi ń ti ọmọ ọwọ́ káàkiri rí. Ńṣe làwọn ògo wẹẹrẹ máa ń wọ́ tẹ̀lé wa lẹ́yìn bá a ti ń lọ láti ilé dé ilé. Àwọn èèyàn á sún mọ́ wa, wọ́n á sì fọwọ́ kan ọmọ òyìnbó jòjòló náà. Inú wa máa ń dún gan-an láti jẹ́rìí nítorí pé àwọn èèyàn náà máa ń yẹni sí. A rò pé gbogbo wọn ló máa wá sínú òtítọ́ nítorí ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fáwọn kan láti jáwọ́ nínú àwọn àṣà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ lára wọn tẹ́wọ́ gba ìlànà ìwà rere tó wà nínú Bíbélì, iye àwọn tó wà nínú ìjọ náà sì ń pọ̀ sí i. Mánigbàgbé ni àpéjọ àyíká tá a kọ́kọ́ ṣe ní Jinja lọ́dún 1968 jẹ́ fún ìjọ náà. Ìrìbọmi táwọn tá a kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe nínú Odò Náílì sì jẹ́ ohun tá ò lè gbàgbé títí láé. Àmọ́ àlàáfíà tá a ń gbádùn yìí kò tọ́jọ́.

Ìfòfindè—Ìdánwò Ìgbàgbọ́ àti Ọgbọ́n Tá A Dá Sí I

Ọ̀gágun Idi Amin gbàjọba lọ́dún 1971. Ìyẹn sì dá wàhálà tó pọ̀ sílẹ̀ ní Jinja, tíì là ń mu lọ́wọ́ nínú ọgbà wa nígbà tí ohun tá a sọ níbẹ̀rẹ̀ yẹn ṣẹlẹ̀. Àárín ọdún méjì tó tẹ̀ lé e ni wọ́n lé gbogbo àwọn ará Éṣíà tó pọ̀ rẹpẹtẹ lórílẹ̀-èdè náà kúrò níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wà níbẹ̀ ló sá lọ, nǹkan ò sì lọ déédéé mọ́ láwọn ilé ìwé àti ilé ìwòsàn. Ẹ̀yìn ìyẹn ni ìròyìn kan tó ṣe kedere tó sì múni gbọ̀n rìrì wá dé pé wọ́n ti fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nítorí ààbò, Ẹ̀ka Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ tí mò ń bá ṣiṣẹ́ ni ká lọ sí Kampala tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè náà. Ọ̀nà méjì ni lílọ tá a lọ síbẹ̀ gbà ṣàǹfààní. Àwọn èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ wá ní Kampala, ìyẹn sì jẹ́ ká láǹfààní àtirìn káàkiri fàlàlà. Iṣẹ́ tún pọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú ìjọ tó wà níbẹ̀ àti nínú iṣẹ́ ìwàásù.

Ipò tá a wà náà ni Brian òun Marion Wallace àtàwọn ọmọ wọn méjèèjì wa, àwọn náà sì pinnu láti dúró sí Uganda. A gbádùn ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn gan-an bá a ṣe jọ ń sìn nínú Ìjọ tó wà ní Kampala láàárín àkókò tí nǹkan le koko yẹn. Àwọn ohun tá a ti kà nípa àwọn arákùnrin wa tó ń sìn lábẹ́ ìfòfindè láwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ló wá jẹ́ ìṣírí àrà ọ̀tọ̀ fún wa báyìí. Ńṣe la máa ń kóra jọ ní àwùjọ kéékèèké láti ṣe àwọn ìpàdé wa. Gbogbo wa sì máa ń pàdé ní àwùjọ ńlá nínú Ọgbà Ọ̀gbìn Entebbe lẹ́ẹ̀kan lóṣù, tá a ó díbọ́n bí ẹni pé àríyá là ń ṣe. Àwọn ọmọ wa gbà pé èyí ló dáa jù.

A ní láti ṣọ́ra gan-an nípa ọ̀nà tá a gbà ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù. Kíá làwọn èèyàn máa rí àwa aláwọ̀ funfun nígbà tá a bá ń wọlé àwọn ará Uganda. Ìdí nìyẹn tí àwọn ilé ìtajà, àwọn ilé àdágbé, àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ bíi mélòó kan fi wá di ìpínlẹ̀ wa. Ọgbọ́n kan tí mo máa ń dá láwọn ilé ìtajà ni pé máa béèrè ọjà kan tí mo mọ̀ pé kò sí lórí àtẹ mọ́, bíi ṣúgà àti ìrẹsì. Bí ẹni tó ń tajà náà bá wá bẹ̀rẹ̀ sí dárò nítorí ohun tó ń lọ lórílẹ̀-èdè náà, màá wá bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún un. Ọgbọ́n tí mò dá yìí gbéṣẹ́ gan-an. Nígbà mìíràn, kì í ṣe pé máa rí ẹni tí máa lọ padà bẹ̀ wò nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún máa ń fún mi ní díẹ̀ lára ọjà tí kò sí lórí àtẹ mọ́ yìí.

Síbẹ̀, ńṣe ni ìwà ipá gbòde kan láyìíká wa lákòókò tá à ń wí yìí. Nítorí àjọṣe àárín Uganda àti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó túbọ̀ ń bà jẹ́ sí i, àwọn aláṣẹ kọ̀ láti fọwọ́ sí ìwé tí màá fi máa bá iṣẹ́ lọ̀ níbẹ̀. Nítorí náà, pẹ̀lú ìbànújẹ́ la fi kí àwọn arákùnrin wa pé ó dìgbóṣe ní 1974, lẹ́yìn tá a ti lo ọdún mẹ́jọ gbáko ní Uganda. Síbẹ̀, ìfẹ́ tá a ní sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì ṣì wà digbí.

A Forí Lé New Guinea

Ní January 1975, a lò àǹfààní kan tá a rí láti ṣiṣẹ́ ní Papua New Guinea. Bá a ṣe bẹ̀rẹ̀ ọdún mẹ́jọ tá a fi ṣe iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ ní àgbègbè Pàsífíìkì náà nìyẹn. Bá a ṣe lo ìgbésí ayé wa láàárín àwọn arákùnrin àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nítumọ̀, ó sì mérè wá.

Àwòkẹ́kọ̀ọ́ ni ìdílé wa fi máa ń rántí àkókò tá a lo ní Papua New Guinea, nítorí pé àkókò yẹn la kópa nínú àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọdọọdún la máa ń ṣèrànwọ́ láti múra àwọn àwòkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ fún àpéjọpọ̀ àgbègbè, a sì gbádùn rẹ̀ gan-an! A gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ wa pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ìdílé tí nǹkan tẹ̀mí jẹ lọ́kàn, àwọn wọ̀nyí sì ní ipa tó dára lórí àwọn ọmọ wa. Sara, ọmọbìnrin wa àgbà fẹ́ Ray Smith, tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn méjèèjì sì ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nítòsí ẹnubodè Irian Jaya (tó ti di Papua, ìyẹn àgbègbè kan ní Indonesia nísinsìnyí). Ilé kan tí wọ́n fi koríko kọ́ lábúlé kékeré náà ni wọ́n gbé, Sara sì sọ pé ẹ̀kọ́ àrà ọ̀tọ̀ ni àkókò tí òun lò lẹ́nu iṣẹ́ yẹn jẹ́ fóun.

Bí Ipò Nǹkan Ṣe Gbà La Ṣe Ṣe É

Ní báyìí, àwọn òbí mi wá nílò àbójútó gan-an. Dípò ká padà sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn òbí mi gbà láti wá máa gbé lọ́dọ̀ wa, gbogbo wa sì kó lọ sí Australia lọ́dún 1983. Wọ́n tún lo àkókò díẹ̀ lọ́dọ̀ Daphne, ẹ̀gbọ́n mi obìnrin tó ṣì wà ní Japan lákòókò yẹn. Lẹ́yìn tí àwọn òbí mi kú, èmi àti Ann pinnu láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà déédéé, èyí sì fún wa láǹfààní àtiṣe iṣẹ́ ìsìn tó gba ìsapá gidigidi.

Kò tíì pẹ́ tá a bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà nígbà tí wọ́n pè wa pé ká wa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Àtìgbà tí mo ti wa ní kékeré ni mo ti máa ń wo ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan. Èmi náà ti wá di alábòójútó àyíká báyìí. Iṣẹ́ yìí ló wá jẹ́ iṣẹ́ tó muni lomi jù lọ tá a tíì ṣe títí di àkókò yẹn nínú ìgbésí ayé wa, àmọ́ ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà máa ń ràn wá lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tá a o rí irú rẹ̀ rí.

Nígbà tí Arákùnrin Theodore Jaracz wá ṣe ìbẹ̀wò ẹ̀ka sí Australia ní 1990, a fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láti mọ̀ bóyá a ti dàgbà jù láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ní ilẹ̀ òkèèrè. Ó ní: “Solomon Islands ńkọ́?” Nítorí náà, níkẹyìn, nígbà tí èmi àti Ann ti lé lẹ́ni àádọ́ta ọdún, a forí lé ibi tó máa jẹ́ ibi iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n kọ́kọ́ yàn wá sí.

Sísìn ní “Àwọn Erékùṣù Aláyọ̀”

Àwọn Erékùṣù Aláyọ̀ làwọn èèyàn mọ Solomon Islands sí, iṣẹ́ ìsìn tá a sì ṣe níbẹ̀ ní ọdún mẹ́wàá tó ti kọjá yìí ti jẹ́ àkókò aláyọ̀ ní ti tòótọ́. Èmi àti Ann rí i pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní Solomon Islands kóni mọ́ra nígbà tí mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè níbẹ̀. Aájò àlejò tí wọ́n fi hàn jọ wá lójú gan-an ni, olúkúlùkù wọn ló sì ń fara da ìsapá tí mò ń ṣe láti ṣàlàyé àwọn nǹkan ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tá a mú rọrùn ní Solomon Islands, èyí tí mò rò pé gbogbo èèyàn lóye, ìyẹn èdè tó jẹ́ ọ̀kan lára èyí tí àwọn ọ̀rọ̀ wọn kéré jù lọ láyé.

Kété lẹ́yìn tá a dé Solomon Islands ni àwọn alátakò gbìyànjú láti máà jẹ́ ká rí Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa lò. Ìjọ Áńgílíkà pe àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́jọ́ pé ilẹ̀ àwọn wà lára ilẹ̀ tá a kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa tó wà ní Honiara sí. Ìjọba fara mọ́ ohun tí wọ́n sọ yìí, nítorí náà á ní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Gíga. Àbájáde ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tá a pè yìí la ó fí mọ̀ bóyá wíwó la máa wó Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa tó lè gba àwọn èèyàn tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀fà [1,200].

Odindi ọ̀sẹ̀ kan ní ẹjọ́ náà fi wà nílé ẹjọ́. Gbogbo èèyàn ló rí ẹ̀mí ìgbéraga tí agbẹjọ́rò àwọn alátakò wa fi hàn bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wá náà. Àmọ́, ńṣe ni Arákùnrin Warren Cathcart, tó jẹ́ agbẹjọ́rò tiwa, tó wá láti New Zealand, túdìí ẹ̀sùn táwọn alátakò wa fi kàn wá ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, tó sì gbá gbogbo rẹ̀ dànù. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ Friday, ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ náà ti tàn dé ibi tó jìnnà, ilé ẹjọ́ náà sì kún fún àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àtàwọn Kristẹni arákùnrin wa. Mo rántí àṣìṣe tó wà nínú ìwé tí wọ́n fi ṣe ìkéde ẹjọ́ wa. Ó kà pé: “Ẹjọ́ Ìjọba Solomon Islands òun Ṣọ́ọ̀ṣì Melanesia pẹ̀lú Jèhófà.” Àwa ni wọ́n dá láre.

Àmọ́ ṣá o, àwọn Erékùṣù Aláyọ̀ tó tòrò minimini yìí kò wà bẹ́ẹ̀ títí lọ. Èmi àti Ann tún bára wa nínú pákáǹleke àti ìwà ipá àwọn ológun tí wọ́n dìtẹ̀ láti gbàjọba. Ìdíje láàárín àwọn ẹ̀yà kan wá di ogun abẹ́lé. Wọ́n gbàjọba náà ní June 5, 2000, olú ìlú náà sì wá di èyí táwọn ológun ń ṣàkóso. Gbọ̀ngàn Àpéjọ wa làwọn tó sá kúrò nílé wọn fi ṣe ibùdó fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan. Ó ya àwọn aláṣẹ lẹ́nu pé ńṣe ni àwọn Kristẹni arákùnrin tó wá látinú ẹ̀yà tó ń bára wọn jà náà jùmọ̀ ń gbé pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan tó wà ní àlàáfíà lábẹ́ òrùlé Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Èyí má jẹ́ ẹ̀rí àtàtà fún wọn o!

Kódà, àwọn tó ń jagun náà pàápàá gbóríyìn fún àìdásí-tọ̀túntòsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Èyí ló jẹ́ ká lè pàrọwà sí ọ̀kan lára àwọn ọ̀gá ológun náà pé kó jọ̀wọ́ jẹ́ ká wa ọkọ̀ kan tó kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ẹrù mìíràn kọjá lọ sọ́dọ̀ àwùjọ àwọn arákùnrin wa tí wọ́n wà lágbègbè tó jẹ́ táwọn ọ̀tá. Mi ò rò pé a rí ẹnì tí kò sunkún lára wa nígbà tá a wa fojú gán-ní àwọn ìdílé wọ̀nyí tí wọ́n ti pínyà kúrò lọ́dọ̀ wa láti oṣù bíi mélòó kan.

Ọ̀nà Ọpẹ́ Wa Pọ̀

Tá a bá ronú lórí ìgbésí ayé wa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, a ó rí i pé ọ̀nà ọpẹ́ wa pọ̀. Gẹ́gẹ́ bí òbí, inú wa dùn pé àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì àtàwọn ọkọ wọn, tórúkọ wọn ń jẹ́ Ray àti John, kò jáwọ́ nínú fífi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà. Wọ́n ti jẹ́ alátìlẹyìn gidi fún wa nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tá à ń ṣe.

Láti ọdún méjìlá sẹ́yìn ni èmi àti Ann ti làǹfààní láti sìn ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti Solomon Islands, a sì ti rí i pé iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba Ọlọ́run ní Solomon Islands ti di ìlọ́po méjì láàárín àkókò náà, wọ́n ti lé ní ẹgbẹ̀sán [1,800] báyìí. Ẹnu àìpẹ́ yìí ni mo tún ní àǹfààní láti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ fún àwọn Mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, ní Patterson, New York. Láìsí àní-àní, a ti gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀ àti ọ̀pọ̀ ìbùkún nítorí pé a ní ẹ̀mí míṣọ́nnárì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “A Ko Fi Ọrọ na Falẹ̀” nínú Ilé-Ìṣọ́ Na, July 15, 1977.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ní ọjọ́ ìgbéyàwó wa, lọ́dún 1960

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ní Uganda, Stanley àti Esinala Makumba jẹ́ orísun ìṣírí fún ìdílé wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Sara ń rìn lọ sínú ahéré aládùúgbò wa kan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Mo ya àwọn àwòrán tó ràn mi lọ́wọ́ láti kọ́ àwọn ará Solomon Islands lẹ́kọ̀ọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

A bá ìjọ kan tó wa ní àdádó ní Solomon Islands ṣèpàdé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìdílé wa lónìí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́