Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Ọlọ́run Ń Mú Kí Ó Dàgbà ní Alaska
LÁBẸ́ yìnyín àti òjò dídì tí ó bojú ilẹ̀, hóró tín-ń-tín kan ń wá àǹfààní láti dàgbà. Láàárín àkókò kúkúrú olóṣù mẹ́ta tí ó jẹ́ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ní Alaska, hóró cabbage kan tí kò wọ̀n ju mìlímítà 3 lè dàgbà di èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 40 kìlógíráàmù! Dájúdájú, orílẹ̀-èdè yìí tí ọ̀pọ̀ ti rò pé ó jẹ́ aṣálẹ̀, aláìlèméso-jáde kan tí ọ̀rinrin ibẹ̀ pọ̀ lápọ̀jù nígbà kan rí lè mú ọ̀pọ̀ yanturu èso jáde.
Ní gidi, bí ọ̀ràn ti rí gan-an ní pápá oko tẹ̀mí ní Alaska nìyẹn. Níbẹ̀, ní orílẹ̀-èdè onígbà òtútù gígùn náà, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a nìṣó ní fífún irúgbìn Ìjọba. Bí ó ti rí ní àwọn apá ibòmíràn lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run mú kí irúgbìn náà dàgbà nínú àwọn ọkàn-àyà rere.—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.
● Nígbà tí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tí ń jẹ́ Vanessa wà nínú bọ́ọ̀sì ilé ẹ̀kọ́ kan, ó ṣàkíyèsí Ann, akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan, tí ó máa ń dá nìkan jókòó. Ó dà bí ẹni pé inú Ann bà jẹ́, nítorí náà, Vanessa pe Ann láti wá jókòó ti òun. Abájọ tí inú Ann fi bà jẹ́! Àrùn ọ̀kàn-àyà ti pa ìyá rẹ̀, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà tí àrùn jẹjẹrẹ pa bàbá rẹ̀. Ìdí nìyẹn ti Ann fi ń gbé lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ní Alaska.
Vanessa yà ní ilé ojúlùmọ̀ rẹ̀ tuntun nígbà tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ Saturday kan, ó sì fi ìwé pẹlẹbẹ Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? sílẹ̀ fún un. Ní ọjọ́ Monday tí ó tẹ̀ lé e, Ann wá ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí náà rí ní ilé ẹ̀kọ́. Ann ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè Bíbélì tí Vanessa tóótun láti dáhùn. Ó béèrè pé: “Ibo ni ẹ ti ń ṣe ìjọsìn yín?” Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Ann wá sí ìpàdé rẹ̀ àkọ́kọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Kò gba àkókò púpọ̀ fún ọmọ òrukàn ọlọ́dún 17 yìí láti rí ọ̀pọ̀ ‘bàbá’ àti ‘ìyá,’ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí. (Mátíù 19:29) Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àkókò ayọ̀ tó láti rí Ann tí ó ń yọ̀ tí ó sì ń rẹ́rìn ín bí ó ti ń fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ hàn sí Jèhófà nípa ṣíṣe ìrìbọmi ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Àwọn Ońṣẹ́ Àlàáfíà Ọlọ́run”!
● Ní àwọn àgbègbè jíjìnnà réré ti Alaska Olótùútù Nini gbígbòòrò—níbi tí àwọn abúlé ti fi ọgọ́rọ̀ọ̀rún aginjù kìlómítà jìnnà sí ara wọn—a ti lo ọkọ̀ òfuurufú ẹlẹ́ńjìnnì méjì ti Watch Tower Society láti fún irúgbìn Ìjọba ní àwọn àrọko tí ó lé ní 150. Ṣùgbọ́n ìdàgbàsókè tẹ̀mí nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé sinmi lórí fífi ìwé ránṣẹ́. Níwọ̀n bí lẹ́tà kíkọ ti jẹ́ ìpèníjà kan fun ọ̀pọ̀, ẹnì kan tí ń fi Bíbélì kọ́ni gbọ́dọ̀ lo ọgbọ́n láti máà jẹ́ kí iná ìfẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ náà kú. Báwo ni a ṣe lè ṣe àṣeparí èyí?
Kathy darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ó tẹ̀ síwájú pẹ̀lú Edna, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń gbé ní ibi tí ó jìnnà tó 600 kìlómítà sí ara wọn! Dípò dída àwọn ìbéèrè tí ó wà nínú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ, Kathy ṣètò ìwé kan tí ó kọ àwọn ìbéèrè sí, ó sì fi àyè tí a lè kọ ìdáhùn sí síbẹ̀. Lẹ́yìn tí Edna bá kọ àwọn ìdáhùn kún ibẹ̀, Kathy yóò fèsì, yóò sì kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ṣe pàtàkì láti fi ṣàlàyé kókó kan sínú rẹ̀. Kathy sọ pé: “Mo ya ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Wednesday sọ́tọ̀ fun ‘ìkẹ́kọ̀ọ́’ wa, mo sì gbìyànjú láti ri pé kò yẹ̀ bí mo ti ń ṣe sí àwọn àdéhùn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mìíràn. Mo tún ń fi àpò ìwé tí a lẹ sítáǹpù mọ́ tí mo kọ àdírẹ́sì mi sí ránṣẹ́ sí Edna. Níwọ̀n bí ó ti ń gba ọ̀sẹ̀ méjì kí lẹ́tà tó tẹni lọ́wọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfìwéránṣẹ́ dà bí ẹni pé ó falẹ̀ díẹ̀.”
Finú wòye ìdùnnú náà nígbà tí Kathy àti Edna fojú rí ara wọn ní àpéjọpọ̀ àgbègbè ní Anchorage lẹ́yìn oṣù mẹ́wàá tí wọ́n ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nípa lẹ́tà kíkọ! Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí náà tún dùn láti rí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti àwọn olùfìfẹ́hàn mìíràn láti ọ̀pọ̀ abúlé àdádó ní Alaska tí wọ́n wà níbẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdàgbàsókè lè dà bí ẹní falẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn “irúgbìn” kan máa ń tètè gbèrú nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ bá tàn sí wọn. Ní ìpíndọ́gba, ó lé ní ọgọ́rùn ún àwọn ẹni tuntun tí wọ́n jẹ́ olùyin Jèhófà tí ń ṣe batisí ní Alaska lọ́dọọdún! A sọ pé, “A dúpẹ́ o, Jèhófà,” fún mímú kí ó dàgbà!