Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
“ÌDÚRÓṢINṢIN.” “Ìfọkànsìn ti a dá pinnu.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn sábà ń lò láti ṣàpèjúwe bí wọ́n ṣe sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí tó pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn wọn. Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ kan náà yí lè ṣàpèjúwe bí ẹnì kan ṣe sún mọ́ra pẹ́kípẹ́kí tó pẹ̀lú Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá àgbàyanu àgbáyé yìí—pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ lè jẹ́ ọ̀rẹ́ ara ẹni rẹ? Bẹ́ẹ̀ ni, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run, kì í sì í ṣe ṣíṣe ìgbọ́ràn nìkan ni ọ̀rọ̀ yẹn ní nínú, ṣùgbọ́n, ó tún kan sísúnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú Ọlọ́run fúnra ẹni, ìsúnmọ́ra tí ń wá láti inú ọkàn àyà onímọrírì.
Àwọn àpilẹ̀kọ ìṣáájú nínú ọ̀wọ́ yìí ti fi hàn pé irú ìsúnmọ́ra bẹ́ẹ̀ ṣeé ṣe, ó sì ṣàǹfààní.a Ṣùgbọ́n báwo gan-an ni ọwọ́ rẹ ṣe lè tẹ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ ti ara ẹni yìí pẹ̀lú Ọlọ́run? A kì í bíni bí i, a kì í sì í jogún rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí oníwà-bí-Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń wá nípasẹ̀ ojúlówó ìsapá nìkan. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún ọ̀dọ́kùnrin náà, Tímótì, pé kí ó ‘máa kọ́ ara rẹ̀ pẹ̀lú ìfọkànsìn Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ̀.’ Dájúdájú, ó ní láti lo irú ìsapá tí eléré ìdárayá kan ń lò nígbà ìdánilẹ́kọ̀ọ́! (Tímótì Kíní 4:7, 8, 10) Ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe bákan náà bí Ọlọ́run yóò bá di ọ̀rẹ́ rẹ. Ṣùgbọ́n báwo ni o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní ọ̀nà yí?
Ìmọ̀ Tí Ẹnì Kan Ní Nípa Ọlọ́run
Níwọ̀n bí ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọ́run ti máa ń ti inú ọkàn àyà wá, o gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ Ọlọ́run kún ọkàn àyà rẹ. Ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà tí a béèrè lọ́wọ́ 500 èwe pé, “Báwo ni o ṣe ń dá ka Bíbélì déédéé tó?” ìpín 87 nínú ọgọ́rùn-ún sọ pé, “lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan,” “kò dájú,” tàbí “kò ṣẹlẹ̀ rí.” Ní kedere, ọ̀pọ̀ jù lọ èwe rò pé kíka Bíbélì kì í mórí yáni, ó sì ń fi nǹkan súni. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí ó rí bẹ́ẹ̀! Gba èyí yẹ̀ wò: Èé ṣe tí àwọn èwe kan fi ń kọ́ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa eré ìdárayá sórí, tàbí tí wọ́n ń kọ́ àwọn ọ̀rọ̀ orin tí wọ́n yàn láàyò? Ó jẹ́ nítorí pé wọ́n ní ọkàn ìfẹ́ nínú àwọn nǹkan wọ̀nyẹn. Bákan náà ni kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò gbádùn mọ́ ọ bí o bá fi ara fún un pátápátá. (Tímótì Kíní 4:15) Àpọ́sítélì Pétérù gbani nímọ̀ràn pé: “Ẹ ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà.” (Pétérù Kíní 2:2) Bẹ́ẹ̀ ni, o gbọ́dọ̀ ní, tàbí kí o mú irú ọkàn ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà nínú Ìwé Mímọ́. Èyí lè gba ìsapá, ṣùgbọ́n àwọn àǹfààní rẹ̀ mú kí ó tóyeyẹ.b
Àǹfààní kan ni pé, kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde tí a gbé karí Bíbélì, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ wọn, yóò ṣí “ẹwà Olúwa” payá. (Orin Dáfídì 27:4) Kristẹni ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Amber fi kíka Bíbélì lódindi ṣe góńgó rẹ̀. Èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ gba ọdún kan tán. Amber ṣàlàyé pé: “Kò dá mi lójú pé àwọn ohun tí ó gba àkókò àti ìsapá, ṣùgbọ́n tí ó ṣàǹfààní púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ wà nínú ìgbésí ayé mi. Nígbà tí mo ń kà á, ńṣe ni ó dà bíi pé Jèhófà gbé mi lé ẹsẹ̀ bíi bàbá, tí ó sì ń kọ́ mi. Mo kọ́ ohun púpọ̀ nípa Jèhófà—àwọn ohun tí ó túbọ̀ fà mí sún mọ́ ọn, tí ó sì mú kí n fẹ́ láti bẹ̀rù rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ jálẹ̀ gbogbo ìyókù ìgbésí ayé mi.”
Nígbà tí o bá ń ka Bíbélì, o ń mọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láìyẹsẹ̀. (Orin Dáfídì 18:25; 27:10) O ń rí i pé àwọn ìlànà rẹ̀ ni ó dára jù lọ nígbà gbogbo, wọ́n sì wà fún ire wa pípẹ́ títí. (Aísáyà 48:17) Kíkà nípa àwọn ànímọ́ aláìlẹ́gbẹ́ ti Ọlọ́run, bí ìfẹ́ àti ọgbọ́n rẹ̀, ń mú kí o fẹ́ láti fara wé e. (Éfésù 5:1) Ṣùgbọ́n kí irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ lè ru ọkàn àyà rẹ sókè, o gbọ́dọ̀ ṣàṣàrò pẹ̀lú. Bí o ti ń kà á, bi ara rẹ pé: ‘Kí ni èyí ń sọ fún mi nípa Jèhófà? Báwo ni mo ṣe lè lo èyí nínú ìrònú àti ìhùwà mi? Báwo ni èyí ṣe ń fi hàn pé Ọlọ́run ni ọ̀rẹ́ dídára jù lọ tí mo lè ní?’
Ìmọ̀ tí o jèrè nípa Ọlọ́run nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti ìkẹ́kọ̀ọ́ ìjọ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ ọn ní ọ̀nà míràn. Òwe Faransé kan sọ pé: “Àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń ronú lọ́nà kan náà.” Ṣùgbọ́n báwo ni ìwọ àti Ọlọ́run ṣe lè máa “ronú lọ́nà kan náà”? Denise ọ̀dọ́ ṣàlàyé pé: “Bí o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa kókó kan, tí o sì ń wádìí lórí rẹ̀ tó ni ìwọ yóò máa ṣàwárí ojú ìwòye Jèhófà nípa rẹ̀ tó. Mímọ èrò rẹ̀ nípa ohun kan ń ṣàǹfààní.”
Ìwà Ìdúróṣinṣin Ṣe Kókó
Àwọn ènìyàn tí ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ìlànà ìwà híhù rẹ̀ nìkan ni Ọlọ́run ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Òwe 3:32 sọ pé: “Àṣírí rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn olódodo.” Èwe kan tí ń tiraka láti dúró ṣinṣin yóò “ṣe àkíyèsí láti máa . . . rìn nínú òfin Olúwa.” (Àwọn Ọba Kejì 10:31) Báwo ni irú ìwà onígbọ̀ọ́ràn bẹ́ẹ̀ yóò ṣe mú kí ẹnì kan sún mọ́ Ọlọ́run tó? Jésù Kristi wí pé: “Baba mi yóò . . . nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àwa yóò sì wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwa yóò sì fi ọ̀dọ̀ rẹ̀ ṣe ibùjókòó wa.” (Jòhánù 14:21-24) Ẹ wo bí ipò náà ti jẹ́ amọ́kànyọ̀ tó! Rò ó wò ná, kí àwọn ẹni títóbilọ́lá jù lọ méjèèjì lágbàáyé darí èrò àti àbójútó déédéé wọn sọ́dọ̀ ẹ̀dá ènìyàn kan! Ìyẹn yóò ṣẹlẹ̀ sí ọ bí o bá ṣe àkíyèsí láti máa rìn nínú òfin Jèhófà.
Ǹjẹ́ jíjẹ́ adúróṣinṣin túmọ̀ sí pé o gbọ́dọ̀ jẹ́ pípé bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá! Ṣíṣe àṣìṣe kan nítorí àìlera kò túmọ̀ sí pé o ti pa ‘ipa àṣẹ Ọlọ́run’ tì. (Orin Dáfídì 119:35) Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa Ọba Dáfídì. Láìka ti pé ó jẹ́ olóòótọ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run sí, ó ṣe àwọn àṣìṣe wíwúwo mélòó kan nítorí àìlera. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà sọ pé ó ti rìn “ní òtítọ́ ọkàn, àti ní ìdúróṣinṣin.” (Àwọn Ọba Kìíní 9:4) Ọba Dáfídì sábà máa ń fi ìrònúpìwàdà tọkàntọkàn hàn fún ìwà àìtọ́ èyíkéyìí tí ó bá hù, ó sì ń gbìyànjú gidigidi láti ṣe ohun tí ó wu Ọlọ́run.—Orin Dáfídì 51:1-4.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì fẹ́ràn Ọlọ́run, ó mọ bí ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ti lè ṣòro tó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ìdí nìyẹn tí ó fi bẹ Ọlọ́run pé: “Sìn mí ní ọ̀nà òtítọ́ rẹ.” Dájúdájú, ó mú ìfòyà, tàbí ìbẹ̀rù àtọkànwá, láti má ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, dàgbà. Nípa bẹ́ẹ̀, Dáfídì lè sọ pé: “Àṣírí Olúwa wà pẹ̀lú àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Orin Dáfídì 25:5, 14) Èyí kì í ṣe ìbẹ̀rù oníjìnnìjìnnì, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ẹlẹ́dàá náà àti ìfòyà gbígbámúṣé láti má ṣe ohun tí kò wù ú. Orí ìbẹ̀rù Ọlọ́run yìí ni a gbé ìwà yíyẹ kà. Láti fi ṣàpẹẹrẹ, gbé àpẹẹrẹ Kristẹni ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Joshua yẹ̀ wò.
Joshua rí ìwé kan gbà láti ọ̀dọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan, tí ó jẹ́ obìnrin, pé òun fẹ́ràn rẹ̀, òun sì fẹ́ láti ní “ipò ìbátan” kan pẹ̀lú rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkàn Joshua fà mọ́ ọn, ó mọ̀ pé irú àjọṣepọ̀ bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú aláìgbàgbọ́ kan lè yọrí sí ìwà pálapàla, ó sì lè ba ìbádọ́rẹ̀ẹ́ òun pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Nítorí náà, ó sọ fún un ní tààràtà pé òun kò fẹ́! Nígbà tí ó sọ bí ó ṣe yanjú ọ̀ràn náà fún ìyá rẹ̀ lẹ́yìn náà, ìyá rẹ̀ jágbe mọ́ ọn, láìkọ́kọ́ ronú lórí ìhùwàsí rere rẹ̀, pé: “Joshua, ó ṣeé ṣe kí o ti bà á lọ́kàn jẹ́!” Joshua dáhùn pé: “Ṣùgbọ́n, Mọ́mì. Ó sàn kí n bà á lọ́kàn jẹ́ ju kí n ba Jèhófà lọ́kàn jẹ́ lọ.” Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ̀, ìfòyà rẹ̀ láti má ṣe ohun tí kò wu Ọ̀rẹ́ rẹ̀ ọ̀run, sún un láti pa ìwà ìdúróṣinṣin mọ́.
Wá Àwọn Alábàákẹ́gbẹ́ Rere
Bí ó ti wù kí ó rí, ọ̀dọ́ kan tí ń jẹ́ Lynn máa ń kó sínú ìjọ̀ngbọ̀n ṣáá ni. Kí ni ìṣòro rẹ̀? Ó ń bá àwùjọ tí kò tọ́ kẹ́gbẹ́. (Ẹ́kísódù 23:2; Kọ́ríńtì Kíní 15:33) Kí ni ojútùú rẹ̀? Ó jẹ́ wíwá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun! Lynn parí ọ̀rọ̀ sí pé: “Bí àwọn ọ̀rẹ́ tí ó fẹ́ràn Jèhófà bá yí ọ ká, ó ń jẹ́ kí o lè pa ẹ̀rí ọkàn mímúná mọ́ kí o sì jìnnà sí ìjọ̀ngbọ̀n. Nígbà tí wọ́n bá fi ìkórìíra hàn fún ìwà àìtọ́, yóò mú kí o ní ìmọ̀lára bákan náà.”
Ní ti gidi, yíyàn tí o bá yan àwọn ọ̀rẹ́ búburú lè jẹ́ ìdènà títóbi jù lọ fún ọ láti bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. Ann, ọmọ ọdún 18, jẹ́wọ́ pé: “Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ ń ní ipa gidigidi. Bó pẹ́ bó yá, ìwọ yóò dà bíi wọn. Wọ́n yóò mú kí o ronú bíi tiwọn. Àwọn ìjíròrò púpọ̀ jù lè máa dá lórí ìbálòpọ̀. Ó lè mú kí o ní ìfẹ́ ìtọpinpin. O ń ṣe kàyéfì nípa ohun tí yóò jọ.” Ann kẹ́kọ̀ọ́ nípa èyí lọ́nà tí kò dùn mọ́ni. Ó wí pé: “Mo mọ̀ pé èyí jẹ́ òtítọ́. Mo lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla, mo sì lóyún lọ́mọ ọdún 15.”
Níkẹyìn, Ann wá mọyì ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì náà pé: “Nítorí náà, ẹni yòó wù tí ó bá fẹ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá Ọlọ́run.” (Jákọ́bù 4:4) Dájúdájú, Ann fẹ́—ó sì pinnu—láti jẹ́ ọ̀rẹ́ ayé. Ṣùgbọ́n èyí wulẹ̀ sún un láti inú ìbọkànjẹ́ kan sínú òmíràn ni. Ann rìnnà kore ní ti pé, ó ṣíwọ́ híhùwà àìlọ́gbọ́n-nínú. Ó kábàámọ̀ jinlẹ̀jinlẹ̀ nípa ọ̀nà rẹ̀, ó sì wá ìrànwọ́ àwọn òbí rẹ̀ àti ti àwọn alàgbà ìjọ tí ó wà. Ó tún wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun fún ara rẹ̀. (Orin Dáfídì 111:1) Nípa sísapá gidigidi, ó ṣeé ṣe fún Ann láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run lẹ́ẹ̀kan sí i. Nísinsìnyí, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Ipò ìbátan mi pẹ̀lú Jèhófà túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ sí i.”
Nípasẹ̀ ìdákẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àṣàrò, ìwà ìdúróṣinṣin, àti ìbákẹ́gbẹ́ gbígbámúṣé, ìwọ pẹ̀lú lè mú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run dàgbà. Bí ó ti wù kí ó rí, mímú kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ yẹn máa wà lọ jẹ́ ọ̀ràn míràn. Báwo ni ó ṣe lè ṣeé ṣe láti ṣe bẹ́ẹ̀ láìka àwọn ìṣòro àti àìlera ti ara ẹni sí? Àpilẹ̀kọ kan lọ́jọ́ iwájú nínú ọ̀wọ́ yìí yóò jíròrò ọ̀ràn yí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àwọn ìtẹ̀jáde Jí!, July 22 àti November 22, 1995.
b Wo “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Èé Ṣe Tí Ó Fi Yẹ Láti Ka Bíbélì?” nínú ìtẹ̀jáde wa ti August 8, 1985 (Gẹ̀ẹ́sì).
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi yóò ha ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run bí?