Ìtàn Ìgbésí Ayé
Àwọn Nǹkan Díẹ̀ Tá A Yááfì Jẹ́ Ká Rí Ọ̀pọ̀ Ìbùkún
GẸ́GẸ́ BÍ GEORGE ÀTI ANN ALJIAN ṢE SỌ Ọ́
Èmi àtìyàwó mi ò lálàá rẹ̀ rí pé lọ́jọ́ kan a óò ṣi ọ̀rọ̀ náà “olùkọ́” gbé fún “eku.” A ò tiẹ̀ fìgbà kan rò ó rí pé nígbà tá a bá lé ní ẹni ọgọ́ta ọdún la ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá máa kọ́ èdè kan tá ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ ká bàa lè bá àwọn ará Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn ayé sọ̀rọ̀. Síbẹ̀, ohun témi àti Ann ṣe nìyẹn ní apá ìparí àwọn ọdún 1980. Ẹ jẹ́ ká sọ fún yín bí àwọn nǹkan díẹ̀ tá a yááfì láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ṣe mú ká rí ìbùkún yàbùgà-yabuga.
INÚ ìdílé kan ní ilẹ̀ Àméníà ni wọ́n bí mi sí, Ṣọ́ọ̀ṣì Àméníà ni mo ṣì ń lọ. Ọmọ ìjọ Kátólíìkì ni Ann. Àwa méjèèjì gba àwọn nǹkan kan fúnra wa lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nígbà tá a fẹ́ra lọ́dún 1950. Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ni mí nígbà yẹn, Ann sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún. Orí òkè ilé tí mo ti ń ṣe iṣẹ́ àgbàfọ̀ là ń gbé ní Ìlú Jersey, ní ìpínlẹ̀ New Jersey lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọdún náà ló di ọdún kẹrin tí mo ti ń bá iṣẹ́ àgbàfọ̀ bọ̀.
Ní ọdún 1955, a ra ilé rèǹtèrente oníyàrá mẹ́ta kan ní ìlú Middletown, ní ìpínlẹ̀ New Jersey. Ilé yẹn jìnnà tó ọgọ́ta kìlómítà sí ibi iṣẹ́ mi, níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́fà lọ́sẹ̀. Ojoojúmọ́ ni ilẹ̀ máa ń ṣú kí n tó wọlé. Kìkì ìgbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wá sí ṣọ́ọ̀bù mi lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí wọ́n sì fún mi láwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìkan ni mo máa ń rí wọn. Tìfẹ́tìfẹ́ ni mo fi máa ń ka àwọn ìwé wọ̀nyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ mi máa ń gba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò mi, síbẹ̀ mo ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún Bíbélì.
Láìpẹ́, mo wá mọ̀ pé iléeṣẹ́ rédíò Watchtower, ìyẹn WBBR máa ń gbé àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì sáfẹ́fẹ́ lásìkò tí mo máa ń wa ọkọ̀ lọ sí ṣọ́ọ̀bù tàbí tí mo bá ń bọ̀. Mo máa ń fetí sílẹ̀ dáadáa sáwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyí, ìyẹn wá jẹ́ kí ìfẹ́ mi jinlẹ̀ débi pé mo ní káwọn Ẹlẹ́rìí máa wá mi wá. Ní oṣù November ọdún 1957, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ George Blanton wá mi wá sílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ìdílé Wa Di Ọ̀kan Nínú Ìjọsìn Mímọ́gaara
Kí lèrò Ann lórí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Ẹ jẹ́ kó fẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.
“Níbẹ̀rẹ̀, mo ṣàtakò gan-an. Mo máa ń dí George lọ́wọ́ gan-an tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débi tó fi yí ibi tó ti ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ padà, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún oṣù mẹ́jọ gbáko. Ní gbogbo ìgbà yẹn, George ti ń lọ sípàdé lọ́jọọjọ́ Sunday ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ìgbà yẹn ni mó wà mọ̀ pé kò fi ìkẹ́kọ̀ó Bíbélì rẹ̀ ṣeré rárá, nítorí pé ọjọ́ yẹn nìkan ni kì í lọ síbi iṣẹ́. Àmọ́ o, ńṣe ló túbọ̀ ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ àti bàbá, bí ìwà tèmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí yí padà nìyẹn. Ká sòótọ́, nígbà míì tí mo bá ń nu tábìlì tá a ti ń mu kọfí tí kò bá sì sẹ́ni tó ń wò mí, mo máa ń ka ìwé ìròyìn Jí! tí George máa ń fi síbẹ̀. Nígbà míì, George máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! tó sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá fún mi, kì í ka èyí tó sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ ní tààràtà.
“Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí George ti lọ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ Arákùnrin Blanton, mo mú ìwé kan tí ọmọ wa ọlọ́dún méjì tó ń jẹ́ George fi sí orí tábìlì lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn mi. Ìwé yẹn sọ̀rọ̀ lórí ìrètí tó wà fáwọn òkú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ mí, mo bẹ̀rẹ̀ sí kà á nítorí kò pẹ́ tí ìyá ìyá mi kú, inú ìbànújẹ́ yẹn ni mò ṣì wà. Ojú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí lóye òtítọ́ Bíbélì pé àwọn òkú kì í jìyà níbikíbi, àti pé wọ́n á padà wà láàyè nígbà àjíǹde lọ́jọ́ iwájú. Ni mo bá dìde jókòó lórí ibùsùn, mo ń fi ìháragàgà ka ìwé náà, mo sì ń fàlà sídìí àwọn kókó tí mo fẹ́ fi han ọkọ mi tó bá dé láti ibi tó ti lọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
“Ó ṣòro fún ọkọ mi láti gbà pé èmi náà ṣì ni. Kó tó kúrò nílé, ńṣe ni mo ń ṣàtakò, ṣùgbọ́n ní báyìí, inú mi ti wá ń dùn nítorí àwọn òtítọ́ Bíbélì tó ṣeyebíye tí mo ti kọ́! A jọ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì títí di ọ̀gànjọ́ òru. George ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí ilẹ̀ ayé yìí rí. Mo béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn bóyá ó lè máa ṣèkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ nílé kí èmi náà lè dara pọ̀ mọ́ wọn.
“Arákùnrin Blanton dábàá pé káwọn ọmọ wa náà máa jókòó tì wá nígbà tá a bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́. A rò pé wọ́n ti kéré jù nítorí pé ọ̀kan jẹ́ ọmọ ọdún méjì, èkejì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rin. Àmọ́ ṣá o, Arákùnrin Blanton fi Diutarónómì 31:12 hàn wá, tó sọ pé: ‘Pe àwọn ènìyàn náà jọpọ̀, àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ kéékèèké . . . , kí wọ́n bàa lè fetí sílẹ̀ àti kí wọ́n bàa lè kẹ́kọ̀ọ́.’ Inú wa dùn sí ìmọ̀ràn yẹn, kódà a ṣètò pé káwọn ọmọ lóhùn sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. A máa ń múra ìdáhùn wa sílẹ̀ pa pọ̀, ṣùgbọ́n a kì í sọ ohun tí wọ́n á sọ fún wọn. A gbà pé èyí ṣèrànwọ́ láti mú káwọn ọmọ wa sọ òtítọ́ di tiwọn. A ò ní ṣaláì máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Arákùnrin Blanton nítorí pé ó fún wa ní ìtọ́sọ́nà tó ran ìdílé wa lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí.”
Ìṣòro Tó Gba Pé Ká Yááfì Àwọn Nǹkan Kan
Ní báyìí tá a ti jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn ìṣòro kan ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yọjú tá a ní láti kojú. Nítorí pé ṣọ́ọ̀bù mi jìnnà gan-an, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń tó aago mẹ́sàn-án alẹ́ kí n tó wọlé. Nítorí èyí, kò ṣeé ṣe fún mi láti máa lọ sípàdé láàárín ọ̀sẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń lọ lọ́jọọjọ́ Sunday. Ní gbogbo ìgbà yẹn, Ann ti ń lọ sí gbogbo ìpàdé tí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí sì yá kánkán. Èmi náà fẹ́ máa lọ sí gbogbo ìpàdé kí n sì máa darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé tó ń lọ déédéé. Mo mọ̀ pé mo gbọ́dọ̀ yááfì àwọn nǹkan kan. Nítorí náà, mo pinnu láti dín àkókò tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù, kódà bí èyí tiẹ̀ máa mú kí n pàdánù díẹ̀ lára àwọn oníbàárà mi.
Ètò tí mo ṣe yìí dára gan-an ni. Ọwọ́ pàtàkì tá a fi mú àwọn ìpàdé márùn-ún tí à ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba náà la fi mú ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé. A pè é ní ìpàdé wa kẹfà. Nítorí náà, a ya ọjọ́ kan àti àkókò kan pàtó sọ́tọ̀, ìyẹn láago mẹ́jọ alẹ́ lọ́jọọjọ́ Wednesday. Nígbà mìíràn tá a bá jẹun alẹ́ tán, tá a si ti fọ abọ́ tán, ọ̀kan nínú wa yóò sọ pé, “Àkókò ‘ìpàdé’ tí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó o!” Bí mo bá pẹ́ kí n tó dé, Ann á ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, gbàrà tí mo bá sì ti dé ni máa gbà á lọ́wọ́ rẹ̀.
Ohun mìíràn tó mú ká lókun ká sì wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ìdílé ni kíkà tá a máa ń ka ẹsẹ ojoojúmọ́ pa pọ̀ lárààárọ̀. Ṣùgbọ́n, ìṣòro kan wà nínú ìṣètò yìí. Gbogbo wa kì í jí nígbà kan náà. A jọ jíròrò èyí, a sì fohùn ṣọ̀kan pé ká máa jí nígbà kan náà, ká jẹun àárọ̀ láago mẹ́fà ààbọ̀, ká sì jùmọ̀ ka ẹsẹ ojoojúmọ́. Ìṣètò yìí ṣàǹfààní fún wa gan-an. Nígbà táwọn ọmọkùnrin wa dàgbà, wọ́n yàn láti lọ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. A gbà pé àwọn ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wa ojoojúmọ́ yìí wà lára ohun tó mú kí wọ́n dẹni tẹ̀mí.
Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Lẹ́yìn Ìrìbọmi Gba Pé Ká Yááfì Ọ̀pọ̀ Nǹkan
Ọdún 1962 ni mo ṣèrìbọmi, mo wá ta ilé iṣẹ́ àgbàfọ̀ yẹn lẹ́yìn tí mo ti ṣe iṣẹ́ yẹn fún ọdún mọ́kànlélógún, mo sì wáṣẹ́ kan nítòsí kí n lè túbọ̀ sún mọ́ ìdílé mi ká bàa lè máa sin Jèhófà pa pọ̀. Èyí mú ká rí ọ̀pọ̀ ìbùkún. Gbogbo wa fi ṣe àfojúsùn wa láti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. A bẹ̀rẹ̀ èyí ní apá ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1970 nígbà tí Edward tó jẹ́ dáódù wa di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tàbí aṣáájú ọ̀nà déédéé ní gbàrà tó jáde ilé ìwé gíga. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni ọmọkùnrin wa tó ń jẹ́ George náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, kò sì tún pẹ́ tí Ann náà fi di aṣáájú ọ̀nà. Bí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣe máa ń sọ ìrírí tí wọ́n ní nínú iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ ìṣírí ńlá fún mi. Nínú ìdílé wa, a jíròrò lórí bí a ṣe lè mú àwọn nǹkan tí kò pọndandan nínú ìgbésí ayé wa kúrò kí gbogbo wa bàa lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nítorí náà, a ta ilé wa. Odindi ọdún méjìdínlógún la fi gbé inú ilé yẹn, ibẹ̀ sì la bí àwọn ọmọ wa sí. A fẹ́ràn ilé wa yẹn gan-an ni, ṣùgbọ́n Jèhófà bù kún wa nítorí ìpinnu tá a ṣe láti ta ilé náà.
Ọdún 1972 ni wọ́n pe Edward sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì pe George ní ọdún 1974. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò wọn sọ wá gan-an, a kò rò pé ì bá dáa kí wọ́n dúró nítòsí wa, kí wọ́n gbéyàwó kí wọ́n sì bímọ. Dípò ìyẹn, ńṣe ni inú wa ń dùn ṣìnkìn pé àwọn ọmọkùnrin wa ń sin Jèhófà ní Bẹ́tẹ́lì.a A fara mọ́ ohun tó wà nínú Òwe 23:15, tó sọ pé: “Ọmọ mi, bí ọkàn-àyà rẹ bá gbọ́n, ọkàn-àyà mi yóò yọ̀, àní tèmi.”
A Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà Àkànṣe
Bí àwọn ọmọ wa ṣe wà ní Bẹ́tẹ́lì, àwa ń bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ ní pẹrẹu. Lọ́jọ́ kan ní ọdún 1975, a rí lẹ́tà kan gbà tí wọ́n fi sọ fún wa pé ká lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní ìpínlẹ̀ kan tí a kò pín fúnni tó wà ní ìlú Clinton County, ní ìpínlẹ̀ Illinois. Ohun ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún wa! Èyí fi hàn pé a ní láti fi ìpínlẹ̀ New Jersey sílẹ̀, níbi tá ò ti jìnnà sáwọn ọmọ wa ní New York àti ibi táwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí wa wà. Àmọ́ ṣá o, a gbà á bí ìṣẹ́ tí Jèhófà yàn fún wa, a fi àwọn nǹkan wọ̀nyẹn sílẹ̀, èyí sì jẹ́ ká rí àwọn ìbùkún mìíràn.
Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan tá a ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni yìí, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣèpàdé ní ilé èrò tó wà nílùú Carlyle, ní ìpínlẹ̀ Illinois. Ṣùgbọ́n ibi tá a ó ti máa ṣèpàdé lọ títí là ń fẹ́. Arákùnrin kan àti ìyàwó rẹ̀ ní ìlú yẹn rí ilé kékeré kan tá a yá lò. A fọ ilé náà mọ́ tónítóní, títí kan ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tó wà níta ilé náà, a sì sọ ọ́ di ilé ìpàdé kékeré. Ẹṣin kan wà tó máa ń fẹ́ mọ ohun tí à ń ṣe. Ó sábà máa ń yọjú lójú fèrèsé, kó lè máa rí ohun tó ń lọ nínú ìpàdé!
Kò pẹ́ tá a fìdí Ìjọ Carlyle múlẹ̀, inú wa sì dùn láti kópa nínú iṣẹ́ yìí. Tọkọtaya aṣáájú ọ̀nà kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ tórúkọ wọ́n ń jẹ́ Steve àti Karil Thompson ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Ńṣe làwọn náà wá wàásù ní ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni yìí. Arákùnrin àti arábìnrin Thompson wà níbẹ̀ fún ọdún bíi mélòó kan kí wọ́n tó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Lẹ́yìn ìyẹn ni wọ́n lọ sí ibi tí a yàn fún wọn gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà níbi tí wọ́n ti sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó arìnrìn-àjò.
Láìpẹ́, ibi kótópó tá a ti ń ṣèpàdé kò gba èrò mọ́, èyí sì mú ká nílò gbọ̀ngàn tó tóbi. Tọkọtaya tó ṣèrànwọ́ lákọ̀ọ́kọ́ yẹn náà ló tún ṣèrànwọ́ lọ́tẹ̀ yìí, wọ́n ra ilẹ̀ kan tó lè gba Gbọ̀ngàn Ìjọba. Inú wa dùn gan-an lẹ́yìn ọdún bíi mélòó kan tí wọ́n pè wá sí ibi ìyàsímímọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan ní ìlú Carlyle! Mo láǹfààní láti sọ ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ náà. Iṣẹ́ àyànfúnni wa ní ìlú yẹn jẹ́ ká ní àwọn ìrírí alárinrin, àní ó jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà.
A Lọ sí Pápá Tuntun Mìíràn
Lọ́dún 1979, wọ́n gbé wa lọ sí ìpínlẹ̀ tuntun ní ìlú Harrison, ní ìpínlẹ̀ New Jersey. Nǹkan bí ọdún méjìlá la fi sìn níbẹ̀. Láàárín àkókò yẹn, a bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ obìnrin ará Ṣáínà kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí sì mú ká rí ọ̀pọ̀ àwọn ará Ṣáínà kọ́ lẹ́kọ̀ọ́. Kò pẹ́ tá a fi mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ iléèwé àtàwọn ìdílé tó jẹ́ ará Ṣáínà ń gbé ládùúgbò wa yẹn. Èyí ló wú wa lórí tá a fi ń kọ́ èdè Ṣáínà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kíkọ́ èdè yẹn ń gba ọ̀pọ̀ àkókò lọ́wọ́ wa lójoojúmọ́, ó yọrí sí rere, nítorí pé ó yọrí sí bíbá ọ̀pọ̀ àwọn ará Ṣáínà tó wà ládùúgbò wa yẹn ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tó sì mú wa láyọ̀.
Láwọn ọdún wọ̀nyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn ohun tó ń dẹ́rìn-ín pani ló ṣẹlẹ̀, pàápàá nígbà tá à ń kọ́ èdè Ṣáínà. Lọ́jọ́ kan, Ann fẹ́ sọ irú ẹni tó jẹ́, ló bá pe ara rẹ̀ ní “eku” Bíbélì dípò “olùkọ́” Bíbélì. Àwọn ọ̀rọ̀ méjèèjì yìí jọra. Ẹni tó ń bá sọ̀rọ̀ yẹn rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì sọ pé: “Ẹ wọlé. Ṣùgbọ́n mi ò tíì bá eku Bíbélì sọ̀rọ̀ rí o.” A ò tíì mọ èdè yẹn sọ dáadáa.
Nígbà tó yá, wọ́n gbé wa lọ síbòmíràn ní ìpínlẹ̀ New Jersey níbi tá a ti ń bá a lọ láti máa ṣiṣẹ́ níbi táwọn ará Ṣáínà wà. Lẹ́yìn náà, wọ́n ní ká lọ sí ìlú Boston, ní ìpínlẹ̀ Massachusetts, níbi tí àwùjọ kan tó ń sọ èdè Ṣáínà ti wà fún nǹkan bí ọdún mẹ́ta. Àǹfààní ló jẹ́ fún wa láti máa ran àwùjọ yìí lọ́wọ́ láti nǹkan bí ọdún méje sẹ́yìn, ṣùgbọ́n ó dùn mọ́ wa gan-an nígbà tí àwùjọ yìí di ìjọ ní January 1, 2003.
Ìbùkún Tá A Rí Nínú Gbígbé Ìgbésí Ayé Onífara-Ẹni-Rúbọ
Nínú Málákì 3:10, a kà nípa bí Jèhófà ṣe ní kí àwọn èèyàn òun mú ọrẹ àti ẹbọ wá kí òun bàa lè rọ̀jò ìbùkún rẹ̀ jáde títí dìgbà tí kò fi ní sí àìní mọ́. A fi iṣẹ́ tí mo gbádùn gan-an sílẹ̀. A ta ilé wa tá a fẹ́ràn lọ́pọ̀lọpọ̀. A sì tún yááfì ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan mìíràn. Síbẹ̀, tá a bá fi wé àwọn nǹkan tá a yááfì yìí wé ìbùkún ta a rí gbà, ó kéré jọjọ.
Ká sòótọ́, ìbùkún ńlá gbáà ni Jèhófà fi jíǹkí wa! A ní ìtẹ́lọ́rùn nítorí pé àwọn ọmọ wa wà nínú òtítọ́, ayọ̀ wa kún nítorí pé a kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó ń gbẹ̀mí là, a sì ti rí i pé Jèhófà ń pèsè àwọn ohun tá a nílò. Ká sòótọ́, nǹkan díẹ̀ tá a yááfì ti jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Títí di báyìí, wọ́n ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì—Edward àti Connie ìyàwó rẹ̀ wà ní Patterson nígbà tí George àti Grace ìyàwó rẹ̀ wà ní Brooklyn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Louise òun George Blanton àti Ann rèé, ní 1991
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Carlyle, a yà á sí mímọ́ ní June 4, 1983
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Èmi, ìyàwó mi àti ìjọ Boston tó ń sọ èdè Ṣáínà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ fìdí rẹ̀ múlẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi, ìyàwó mi, Edward, Connie, George àti Grace rèé