ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 6-7
  • 1 | Yẹra fún Ojúsàájú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1 | Yẹra fún Ojúsàájú
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ:
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
  • Títù—“Alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún Ire Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • 3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Tó Lè Fòpin Sí Ìkórìíra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 6-7
Ọkùnrin aláwọ̀ dúdú kan mú fọ́tò ọkùnrin aláwọ̀ funfun kan tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ dání, bákan náà ọkùnrin aláwọ̀ funfun kan mú fọ́tò ọkùnrin aláwọ̀ dúdú kan tó ń rẹ́rìn-ín músẹ́ dání. Fọ́tò àwọn èèyàn tínú ń bí wà lẹ́yìn fọ́tò méjèèjì.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

1 | Yẹra Fún Ojúsàájú

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, àmọ́ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń ṣe ohun tí ó tọ́ ni ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.”​—ÌṢE 10:34, 35.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Kì í ṣe orílẹ̀-èdè wa, ẹ̀yà wa, àwọ̀ wa tàbí àṣà ìbílẹ̀ wa ni Jèhófàa fi ń dá wa lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ló máa ń wò, ìyẹn ohun tó wà lọ́kàn wa. Bíbélì sọ pé: “Ohun tí ó bá hàn síta ni èèyàn ń rí, ṣùgbọ́n Jèhófà ń rí ohun tó wà nínú ọkàn.”​—1 Sámúẹ́lì 16:7.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, ó yẹ ká rí i pé a kì í ṣe ojúsàájú bíi ti Ọlọ́run. Kò yẹ kó o kórìíra ẹnì kan torí ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ nípa ẹni náà, torí ibi tó ti wá, èdè tó ń sọ tàbí àwọn nǹkan míì. Tó o bá rí i pé o ti ń ní èrò tí ò dáa nípa àwọn èèyàn, gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè borí irú èrò bẹ́ẹ̀. (Sáàmù 139:​23, 24) Tó o bá fi tọkàntọkàn bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ lókun kó o má bàa máa ṣe ojúsàájú, jẹ́ kó dá ẹ lọ́jú pé ó máa gbọ́ àdúrà rẹ, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.​—1 Pétérù 3:12.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.​—Sáàmù 83:18.

“Èmi àti aláwọ̀ funfun kankan ò jọ jókòó pa pọ̀ lálàáfíà rí . . . Ní báyìí, mo ti wà lára ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé.”​—TITUS

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ẹnì Kan—TITUS

Borí Ìkórìíra

Titus.

Inú ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Titus ò dùn sáwọn òfin tó máa ń gbé àwọn aláwọ̀ funfun ga ju àwọn aláwọ̀ dúdú. Torí náà, ó dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tó máa ń dá wàhálà sílẹ̀ kí wọ́n lè kọ ìyà fáwọn aláwọ̀ dúdú. Titus sọ pé: “A sábà máa ń lọ sáwọn ibi tí wọn ò fẹ́ káwọn èèyàn dúdú máa wọ̀ nígboro, irú bí òtẹ́ẹ̀lì àtàwọn ilé ọtí, ká lè lọ dá ìjà sílẹ̀.” Titus gbà pé ìkórìíra mú kóun máa hùwà tí ò dáa sáwọn èèyàn. Ó ní: “Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín èmi àtẹnì kan, ì báà jẹ́ ọkùnrin tàbí obìnrin, èmi ni mo máa ń kọ́kọ́ gbá onítọ̀hún lẹ́ṣẹ̀ẹ́.”

Titus bẹ̀rẹ̀ sí í yíwà padà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àwọn ohun tó kà nínú Bíbélì ràn án lọ́wọ́ gan-an. Ọ̀kan pàtàkì lára ohun tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn jù lohun tí Ọlọ́run sọ pé òun máa ṣe fáwa èèyàn lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ni pé “ikú ò ní sí mọ́, kò ní sí ọ̀fọ̀ tàbí ẹkún tàbí ìrora mọ́.”​—Ìfihàn 21:​3, 4.

Kò kọ́kọ́ rọrùn fún Titus láti borí ìkórìíra tó wà lọ́kàn rẹ̀. Ó sọ pé: “Kò rọrùn rárá láti yí ìwà àti ìrònú mi pa dà.” Àmọ́ ohun tó kọ́ nínú Ìṣe 10:​34, 35 ràn án lọ́wọ́ gan-an, níbi tí Bíbélì ti sọ pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.

Kí nìyẹn yọrí sí? Titus sọ pé: “Nígbà tí mo rí bí ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe jinlẹ̀ tó láìka ẹ̀yà tàbí àwọ̀ wọn sí, ó dá mi lójú pé àwọn ni wọ́n ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́. Kódà, kó tó di pé mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹnì kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun nínú ìjọ wa pè mí pé kí n wá jẹun nílé òun. Ṣe ló dà bí àlá lójú mi. Èmi àti aláwọ̀ funfun kankan ò jọ jókòó pa pọ̀ lálàáfíà rí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti pé ká jọ jẹun nínú ilé wọn. Ní báyìí, mo ti wà lára ojúlówó ẹgbẹ́ ará kárí ayé.”

O lè ka apá tó kù nínú ìtàn Titus nínú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2009, ojú ìwé 28 àti 29.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́