ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 10-11
  • 3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ:
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
  • Sítéfánù “Kún fún Oore Ọlọ́run àti Agbára”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Wọ́n Sọ Sítéfánù Lókùúta Pa
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ohun Tó Lè Fòpin Sí Ìkórìíra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • A Lè Borí Ìkórìíra!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 10-11
Ọkùnrin kan ń fọkàn yàwòrán bó ṣe ń kí ọkùnrin míì tó wá látinú ẹ̀yà míì. Nínú òjìji àwọn méjèèjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbé pákó tí wọ́n fi ń fẹ̀hónú hàn dání, wọ́n sì ń bára wọn jiyàn.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

3 | Mú Ìkórìíra Kúrò Lọ́kàn Rẹ

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín pa dà, kí ẹ lè fúnra yín ṣàwárí ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.”​—RÓÒMÙ 12:2.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Èrò wa ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run. (Jeremáyà 17:10) Torí náà, yàtọ̀ sí pé ká yẹra fáwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìwà tó máa fi hàn pé a kórìíra àwọn èèyàn, a tún gbọ́dọ̀ mú gbogbo ohun tó lè mú ká kórìíra àwọn èèyàn kúrò lọ́kàn wa, torí pé inú ọkàn ni ìkórìíra ti ń bẹ̀rẹ̀. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àá fi hàn pé à ń “para dà,” ìyẹn á sì mú ká borí ìkórìíra.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

Fara balẹ̀ ronú nípa èrò tó o ní nípa àwọn èèyàn, ní pàtàkì àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì tàbí àwọn tí ẹ̀yà wọn yàtọ̀ sí tìẹ. Bi ara ẹ pé: ‘Èrò wo ni mo ní nípa wọn? Ṣé ohun tí mo mọ̀ nípa wọn ló jẹ́ kí n nírú èrò yẹn? Àbí torí ibi tí wọ́n ti wá tàbí ẹ̀yà wọn ló jẹ́ kí n nírú èrò náà?’ Á dáa kó o yẹra fáwọn fíìmù àtàwọn eré ìnàjú tí wọ́n ti ń hùwà ipá, kó o sì yẹra fàwọn ìkànnì tó ń kọ́ni nípa ìkórìíra àti ìwà ipá.

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra tó wà lọ́kàn wa

Kì í sábà rọrùn láti ṣàyẹ̀wò èrò wa láìtan ara wa jẹ. Àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ‘mọ ìrònú wa àti ohun tí ọkàn wa ń gbèrò.’ (Hébérù 4:12) Torí náà, máa ka Bíbélì déédéé, máa fi èrò rẹ wéra pẹ̀lú ohun tí Bíbélì sọ, kó o sì máa gbìyànjú láti mú kí èrò rẹ bá ohun tí Bíbélì sọ mu. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra tó ti “fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” nínú ọkàn wa.​—2 Kọ́ríńtì 10:​4, 5.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ẹnì Kan—STEPHEN

Yí Bó Ṣe Ń Ronú Padà

Stephen.

Àwọn aláwọ̀ funfun kórìíra Stephen àti ìdílé rẹ̀ gan-an, wọ́n sì fìyà jẹ wọ́n. Torí náà, Stephen dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kan tí wọ́n máa ń hùwà ipá láti jà fẹ́tọ̀ọ́ àwọn èèyàn. Nígbà tó yá, òun fúnra rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà ipá sáwọn aláwọ̀ funfun. Stephen sọ pé: “Lọ́jọ́ kan èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi lọ wo fíìmù kan tó dá lórí bí àwọn ará Amẹ́ríkà ṣe fìyà jẹ àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n kó lẹ́rú. Ìwà ìrẹ́jẹ yìí múnú bí wa gan-an débi pé a bẹ̀rẹ̀ sí í lu àwọn ọmọ òyìnbó tó wá wo fíìmù lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn náà, a lọ sí àdúgbò táwọn òyìnbó ń gbé láti lọ wá àwọn èèyàn tá a tún máa lù lálùbolẹ̀.”

Èrò Stephen yí padà pátápátá nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Torí pé mo ti rí bí àwọn èèyàn ṣe ń hùwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà síra wọn, ọ̀rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jọ mí lójú gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun fẹ́ rìnrìn àjò, ọ̀dọ̀ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú ló fi àwọn ọmọ rẹ̀ sí. Bákan náà, ìdílé Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ aláwọ̀ funfun gba ọmọ kan tó jẹ́ aláwọ̀ dúdú sílé, torí ọmọ náà ò ní ibi tó máa gbé.” Èyí jẹ́ kí Stephen rí i pé ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe bí ọmọ ìyá, ó sì jẹ́ kó gbà pé àwọn gan-an ló ń ṣe ohun tí Jésù sọ pé ìfẹ́ ni wọ́n máa fi dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀.​—Jòhánù 13:35.

Kí ló ran Stephen lọ́wọ́ tí ò fi hùwà ipá sáwọn èèyàn mọ́, tó sì borí ìkórìíra? Ohun tó wà ní Róòmù 12:2 ló ràn án lọ́wọ́. Stephen sọ pé: “Mo rí i pé ó yẹ kí n yí bí mo ṣe ń ronú pa dà. Mo wá gbìyànjú láti borí ìwà ipá, mo sì ti rí i pé kéèyàn wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn lohun tó dáa jù lọ.” Ó ti tó ogójì (40) ọdún báyìí tí Stephen ti borí ìkórìíra, tó sì ń wà lálàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn.

O lè ka apá tó kù nínú ìtàn Stephen nínú Ilé Ìṣọ́ July 1, 2015, ojú ìwé 10 sí 11.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́