ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 12-13
  • 4 | Ọlọ́run Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìkórìíra

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 4 | Ọlọ́run Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìkórìíra
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ:
  • Ohun Tó Túmọ̀ Sí:
  • Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:
  • Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Ohun Tó Lè Fòpin Sí Ìkórìíra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • A Lè Borí Ìkórìíra!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Kí Nìdí Tí Ìkórìíra Fi Pọ̀ Láyé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 12-13
Bíbélì ńlá kan tí ìmọ́lẹ̀ ń jáde lára ẹ̀ wà ní ṣíṣí sílẹ̀, ìmọ́lẹ̀ tó tàn látara ẹ̀ sì tàn sára àwọn èèyàn tó ń rìn sún mọ́ ọn. Òjìji àwọn èèyàn náà jẹ́ ká mọ̀ pé wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹni tó lẹ́mìí ìkórìíra.

OHUN TÓ LÈ FÒPIN SÍ ÌKÓRÌÍRA

4 | Ọlọ́run Lè Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìkórìíra

Ohun Tí Bíbélì Sọ:

“Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”​—GÁLÁTÍÀ 5:​22, 23.

Ohun Tó Túmọ̀ Sí:

Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra. Òótọ́ ni pé àwọn ìwà rere kan wà tó lè má rọrùn fún wa láti ní, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní wọn. Torí náà, dípò ká máa gbìyànjú láti borí ìkórìíra fúnra wa, ṣe ló yẹ ká jẹ́ kí Ọlọ́run ràn wá lọ́wọ́. Tá a bá jẹ́ kó ràn wá lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ tiwa náà máa dà bíi ti Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílípì 4:13) Àwa náà á lè sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti ń wá.”​—Sáàmù 121:2.

Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe:

“Ní báyìí, mi ò hùwà ipá mọ́ torí Jèhófà ti sọ mí di èèyàn àlááfíà.”​—WALDO

Fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa hùwà tó dáa. Kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìwà tó jẹ́ òdìkejì ìkórìíra, irú bí ìfẹ́, àlàáfíà, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu. Jẹ́ káwọn ìwà yìí máa hàn nínú gbogbo ohun tó ò ń ṣe lójoojúmọ́. Kó o sì máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó ń gbìyànjú láti máa hu irú ìwà bẹ́ẹ̀, torí wọ́n “máa mú kó wù [ẹ́] láti ní ìfẹ́ àti láti ṣe àwọn iṣẹ́ rere.”​—Hébérù 10:24; àlàyé ìsàlẹ̀.

Ohun Tó Ṣẹlẹ̀ sí Ẹnì Kan—WALDO

Borí Ìkórìíra Tó Ń Mú Kó Hùwà Ipá

Waldo.

Nǹkan nira gan-an fún Waldo nígbà tó wà ní kékeré, ìyẹn sì mú kó kórìíra àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo máa ń bá àwọn tó ń ta oògùn olóró ja ìjà ìgboro . . . Nígbà tó yá, àwọn ẹgbẹ́ ọmọọ̀ta míì rán alágbára kan tó jẹ́ oníwà ipá pé kó wá pa mí, mo sá lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ àmọ́ ó dọ́gbẹ́ sí mi lára.”

Inú Waldo ò dùn rárá nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìyàwó rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Waldo sọ pé: “Mo kórìíra àwọn Ajẹ́rìí yẹn, lọ́pọ̀ ìgbà ńṣe ni mo máa ń sọ̀rọ̀ burúkú sí wọn. Àmọ́ . . . ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ ni wọ́n fi máa ń dá mi lóhùn.”

Nígbà tó yá, Waldo náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Kò rọrùn fún mi láti fi ohun tí mò ń kọ́ ṣèwà hù. Mo ti ro ara mi pin pé mi ò ní lè kápá ìbínú mi láéláé.” Àmọ́, ó kọ́ ohun kan látinú Bíbélì tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an, ìyẹn sì mú kó yí padà.

Waldo sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, Alejandro tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ pé kí n ka Gálátíà 5:​22, 23. . . . Alejandro wá ṣàlàyé pé mi ò lè dá ní àwọn ìwà yìí láyè ara mi, àmọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló máa ràn mí lọ́wọ́. Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ fún mi lọ́jọ́ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì yí èrò mi pa dà pátápátá!”

Waldo borí ìkórìíra torí pé ó gbà kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́. Ó sọ pé: “Ní báyìí, mi ò hùwà ipá mọ́ torí Jèhófà ti sọ mí di èèyàn àlááfíà. . . . Ìyàlẹ́nu ni ọ̀rọ̀ mi jẹ́ fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́, wọn ò mọ̀ pé mo lè yí pa dà báyìí.”

O lè ka apá tó kù nínú ìtàn Waldo nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2013, ojú ìwé 12 sí 13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́