ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp22 No. 1 ojú ìwé 14-15
  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ò Ní Sí Ìkórìíra Mọ́!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ò Ní Sí Ìkórìíra Mọ́!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ỌLỌ́RUN MÁA MÚ OHUN TÓ Ń FA ÌKÓRÌÍRA KÚRÒ PÁTÁPÁTÁ
  • BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ÌGBÀ KAN Ń BỌ̀ TÍ Ò NÍ SÍ ÌKÓRÌÍRA MỌ́
  • Kí Nìdí Tí Ìkórìíra Fi Pọ̀ Láyé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • A Lè Borí Ìkórìíra!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
  • Ìkórìíra Yóò Ha Dópin Láé Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2022
wp22 No. 1 ojú ìwé 14-15

Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ò Ní Sí Ìkórìíra Mọ́!

Tá a bá tiẹ̀ mú ìkórìíra kúrò lọ́kàn wa, kò sí bá a ṣe lè fipá mú àwọn èèyàn tó wà láyìíká wa láti yí ìwà wọn padà. Torí náà, wọ́n á ṣì máa fìyà jẹ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀. Báwo wá ni ìkórìíra ṣe máa dópin?

Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè fòpin sí ìkórìíra, tó bá sì fòpin sí i, a ò ní gbúròó ẹ̀ mọ́ láé. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run máa ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn.​—Òwe 20:22.

ỌLỌ́RUN MÁA MÚ OHUN TÓ Ń FA ÌKÓRÌÍRA KÚRÒ PÁTÁPÁTÁ

  1. 1. SÁTÁNÌ ÈṢÙ. Ọlọ̀tẹ̀ ni Sátánì, òun ló sì wà nídìí báwọn èèyàn ṣe ń kórìíra ara wọn lónìí. Ọlọ́run máa pa Sátánì run, títí kan gbogbo àwọn tó lẹ́mìí ìkórìíra bíi tiẹ̀.​—Sáàmù 37:38; Róòmù 16:20.

  2. 2. AYÉ TÍ ÈṢÙ Ń DARÍ. Ọlọ́run máa mú ìwà ibi kúrò, á sì pa gbogbo àwọn ẹni ibi run, irú bí àwọn olóṣèlú jẹgúdújẹrá àtàwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe ohun tó mú káwọn èèyàn kórìíra ara wọn. Ọlọ́run tún máa fòpin sí gbogbo ètò ìṣòwò táwọn èèyàn dá sílẹ̀ kí wọ́n lè gba tọwọ́ àwọn aráàlú.​—2 Pétérù 3:13.

  3. 3. ÀÌPÉ WA. Bíbélì sọ pé gbogbo àwa èèyàn la ti jogún àìpé, ìdí nìyẹn tá a fi ń hùwà tí ò dáa, tá a sì ń ronú lọ́nà tí kò tọ́ nígbà míì. (Róòmù 5:12) Àìpé yìí ló tún ń mú ká di àwọn èèyàn sínú, ká sì kórìíra wọn. Ọlọ́run máa bá wa mú gbogbo ohun tí àìpé ti fà kúrò, ìyẹn á sì mú ká borí ẹ̀mí ìkórìíra títí láé.​—Àìsáyà 54:13.

BÍBÉLÌ JẸ́ KÁ MỌ̀ PÉ ÌGBÀ KAN Ń BỌ̀ TÍ Ò NÍ SÍ ÌKÓRÌÍRA MỌ́

  1. 1. KÒ NÍ SÍ ÌWÀ ÌRẸ́JẸ MỌ́. Ìjọba Ọlọ́run láá máa ṣàkóso ayé. Ọ̀run ni Ìjọba náà á ti máa ṣàkóso, á sì fòpin sí ìwà ìrẹ́jẹ títí láé. (Dáníẹ́lì 2:44) Kò ní sí ẹ̀tanú mọ́, ṣe ni gbogbo àwọn tó wà láyé máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ọlọ́run á sì ṣàtúnṣe gbogbo ohun tí ìwà ìrẹ́jẹ ti fà.​—Lúùkù 18:7.

  2. 2. GBOGBO ÈÈYÀN MÁA WÀ NÍ ÀLÀÁFÍÀ. Ogun tàbí ìwà ipá ò ní máa fa ìyà fáwọn èèyàn mọ́. (Sáàmù 46:9) Ayé á tura nígbà yẹn, torí gbogbo èèyàn ló máa jẹ́ èèyàn àlàáfíà.​—Sáàmù 72:7.

  3. 3. ÀWỌN ÈÈYÀN Á MÁA GBÉ AYÈ TÍTÍ LÁE PẸ̀LÚ ÌFỌ̀KÀNBALẸ̀. Gbogbo àwọn tó bá ń gbé ayé máa nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú. (Mátíù 22:39) Àwọn èèyàn ò ní máa ní èrò òdì síra wọn, kò sì ní sẹ́ni táá máa rẹ̀wẹ̀sì torí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá. (Àìsáyà 65:17) Gbogbo èèyàn á ti bọ́ lọ́wọ́ ìkórìíra nígbà yẹn, inú wọn á sì “máa dùn jọjọ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”​—Sáàmù 37:11.

Ṣó wù ẹ́ kó o wà níbẹ̀ nígbà tí gbogbo nǹkan yìí bá ṣẹlẹ̀? Ká sòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ló ti jẹ́ káwọn ìlànà Bíbélì ran àwọn lọ́wọ́ láti borí ìkórìíra. (Sáàmù 37:8) Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé ń ṣe nìyẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àṣà wọn àti ibi tí wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà yàtọ̀ síra, wọ́n wà níṣọ̀kan, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn bí ọmọ ìyá.​—Àìsáyà 2:​2-4.

Àwòrán kan tó jẹ́ ká rí àwọn ìwà rere, ìyẹn ìfẹ́, àlàáfíà, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu, pẹ̀lú ìwà tí ò dáa, ìyẹn ìkórìíra.

Ó máa wu àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tí wọ́n ti kọ́ nípa béèyàn ṣe lè fara dà á tí wọ́n bá ṣàìdáa sí i. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ohun tó o kọ́ á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa borí ìkórìíra, wàá sì máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Wàá tún kọ́ bó o ṣe lè máa hùwà tó dáa sáwọn èèyàn, títí kan àwọn tó kórìíra ẹ àtàwọn tó dà bíi pé wọn ò mọyì ẹ. Èyí á jẹ́ kó o máa láyọ̀, ìwọ àtàwọn èèyàn á sì túbọ̀ máa mọwọ́ ara yín. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, wàá mọ ohun tó o lè ṣe kó o lè wà nínú Ìjọba Ọlọ́run níbi tí kò ti ní sí ìkórìíra mọ́ títí láé.​—Sáàmù 37:29.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, lọ sí apá téèyàn ti lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ lórí ìkànnì jw.org tàbí kó o lọ wo ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! lórí ìkànnì náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́