ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 44
Jẹ́ Kí Ìrètí Tó O Ní Dá Ẹ Lójú
“Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.”—SM. 27:14.
ORIN 144 Tẹjú Mọ́ Èrè Náà!
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Ìrètí wo ni Jèhófà jẹ́ ká ní?
JÈHÓFÀ jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu pé a máa wà láàyè títí láé. Àwọn kan nírètí láti di ẹni ẹ̀mí táá máa gbé títí láé lọ́run. (1 Kọ́r. 15:50, 53) Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wa ló nírètí àtigbé ayé níbi tí kò ti ní sí àìsàn mọ́, tá à sì máa láyọ̀ títí láé. (Ìfi. 21:3, 4) Torí náà, bóyá ọ̀run la máa gbé tàbí ayé, gbogbo wa la mọyì ìrètí tá a ní.
2. Kí ló ń mú ká nírètí, kí sì nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?
2 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé “ìrètí” ni kéèyàn “gbà pé ohun tó dáa ṣì máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.” Ìrètí tá a ní yìí dá wa lójú torí pé Jèhófà ló jẹ́ ká nírètí náà. (Róòmù 15:13) A mọ àwọn ìlérí tó ṣe fún wa, a sì mọ̀ pé kò sóhun tí Jèhófà sọ tí kò ní ṣẹ. (Nọ́ń. 23:19) Ó dá wa lójú pé ó wu Jèhófà kó ṣe àwọn ohun tó ṣèlérí fún wa, a sì mọ̀ pé ó lágbára láti ṣe àwọn nǹkan náà. A mọ̀ pé ohun tá à ń retí máa ṣẹlẹ̀, kì í ṣe ohun tí ò lè ṣẹlẹ̀ tàbí àsọdùn torí ẹ̀rí wà pé Ọlọ́run máa ṣe é.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí? (Sáàmù 27:14)
3 Bàbá wa ọ̀run nífẹ̀ẹ́ wa gan, ó sì fẹ́ ká fọkàn tán òun. (Ka Sáàmù 27:14.) Tí ìrètí tá a ní nínú Jèhófà bá dá wa lójú, àá lè fara da ìṣòro, àá sì máa láyọ̀, láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa bí ìrètí tá a ní ṣe ń dáàbò bò wá. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìrètí ṣe dà bí ìdákọ̀ró àti akoto. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa bí ìrètí tá a ní ṣe lè túbọ̀ dá wa lójú.
ÌRÈTÍ TÁ A NÍ DÀ BÍ ÌDÁKỌ̀RÓ
4. Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe dà bí ìdákọ̀ró? (Hébérù 6:19)
4 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn Hébérù, ó fi ìrètí tá a ní wé ìdákọ̀ró. (Ka Hébérù 6:19.) Torí pé ọkọ̀ ojú omi ni Pọ́ọ̀lù sábà máa ń wọ̀ tó bá ń rìnrìn àjò, ó mọ̀ pé ìdákọ̀ró ni wọ́n máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ kí ọkọ̀ náà dúró sójú kan. Nígbà kan tó ń rìnrìn àjò, ìjì kan tó lágbára jà lórí omi. Nígbà tí ìjì náà ń jà, ó rí báwọn awakọ̀ òkun náà ṣe ju ìdákọ̀ró wọn sínú omi kí ọkọ̀ náà má bàa kọ lu àpáta. (Ìṣe 27:29, 39-41) Bíi ti ìdákọ̀ró tí kì í jẹ́ kí ọkọ̀ kúrò lójú kan, ìrètí tá a ní kì í jẹ́ ká kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà tá a bá tiẹ̀ níṣòro tó le gan-an. Ìrètí tá a ní máa ń jẹ́ kọ́kàn wa balẹ̀ torí a mọ̀ pé nǹkan ṣì máa dáa. Ẹ rántí pé Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa ṣenúnibíni sí wa. (Jòh. 15:20) Torí náà, tá a bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà sọ pé òun máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú, á rọrùn fún wa láti máa jọ́sìn ẹ̀ nìṣó.
5. Báwo ni ìrètí tí Jésù ní ṣe fi í lọ́kàn balẹ̀ bó tiẹ̀ mọ̀ pé òun máa kú?
5 Ẹ jẹ́ ká wo bí ìrètí tí Jésù ní ṣe jẹ́ kó dúró gbọin-in bó tiẹ̀ mọ̀ pé ikú oró lòun máa kú. Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì 33 S.K., àpọ́sítélì Pétérù sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú ìwé Sáàmù tó jẹ́ ká mọ bí ọkàn Jésù ṣe balẹ̀ tó, ó ní: “Màá sì máa fi ìrètí gbé ayé; torí o ò ní fi mí sílẹ̀ nínú Isà Òkú, bẹ́ẹ̀ ni o ò ní jẹ́ kí ẹni ìdúróṣinṣin rẹ rí ìdíbàjẹ́. . . . Wàá mú kí ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.” (Ìṣe 2:25-28; Sm. 16:8-11) Bí Jésù tiẹ̀ mọ̀ pé òun máa kú, ó nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa jí òun dìde àti pé òun máa láǹfààní láti tún pa dà wà pẹ̀lú Bàbá òun lọ́run.—Héb. 12:2, 3.
6. Kí ni arákùnrin kan sọ pé ìrètí tá a ní máa ń jẹ́ ká ṣe?
6 Ìrètí tá a ní ti ran ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lọ́wọ́ láti máa fara da ìṣòro wọn. Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Leonard Chinn tó ń gbé nílẹ̀ England. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, wọ́n fi í sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Oṣù méjì ló fi wà nínú àhámọ́, lẹ́yìn náà wọ́n mú un lọ síbi tá á ti máa ṣiṣẹ́ àṣekára. Nígbà tó yá ó sọ pé: “Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí mi ti jẹ́ kí n rí i pé ìrètí ló máa ń jẹ́ ká fara da ìṣòro. Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà nínú Bíbélì tó ń jẹ́ ká fara dà á. Ó yẹ ká máa wo àpẹẹrẹ Jésù, tàwọn àpọ́sítélì àti tàwọn wòlíì, ó sì yẹ ká máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa. Gbogbo àwọn nǹkan yìí ló ń jẹ́ ká nírètí, tó sì ń fún wa lókun láti máa fara dà á.” Torí náà, bí ìrètí ṣe jẹ́ ìdákọ̀ró fún Arákùnrin Leonard, ó lè jẹ́ ìdákọ̀ró fún àwa náà.
7. Báwo ni ìṣòro ṣe máa ń jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú? (Róòmù 5:3-5; Jémíìsì 1:12)
7 Tá a bá fara da ìṣòro, tá a sì rí i pé Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, ìrètí tá a ní á túbọ̀ dá wa lójú, inú Jèhófà sì máa dùn sí wa. (Ka Róòmù 5:3-5; Jémíìsì 1:12.) Àwọn nǹkan tá a ti fara dà yẹn á jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú ju ti ìgbà tá a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lọ. Ohun tí Sátánì fẹ́ ni pé káwọn ìṣòro tá a ní bò wá mọ́lẹ̀, àmọ́ Jèhófà máa jẹ́ ká lè fara dà á báwọn ìṣòro náà ṣe ń yọjú.
ÌRÈTÍ TÁ A NÍ DÀ BÍ AKOTO
8. Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe dà bí akoto? (1 Tẹsalóníkà 5:8)
8 Bíbélì tún fi ìrètí tá a ní wé akoto. (Ka 1 Tẹsalóníkà 5:8.) Àwọn sójà máa ń wọ akoto kó lè dáàbò bo orí wọn káwọn ọ̀tá má bàa fọ́ orí wọn. Lọ́nà kan náà, bá a ṣe ń bá Sátánì jà, a gbọ́dọ̀ dáàbò bo ọkàn wa ká má bàa ro èròkerò. Ó máa ń fi oríṣiríṣi nǹkan dán wa wò, ká lè máa ro èròkerò. Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí sójà kan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní máa ń dáàbò bo ọkàn wa ká má bàa ro èròkerò, ká sì lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.
9. Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn tí ò nírètí?
9 Ìrètí tá a ní pé a máa wà láàyè títí láé máa ń jẹ́ ká ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àmọ́ tí ìrètí tá a ní ò bá dá wa lójú mọ́, tá a wá jẹ́ kí èròkerò gbà wá lọ́kàn, ó lè má jẹ́ ká nírètí mọ́ pé a máa wà láàyè títí láé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni kan nílùú Kọ́ríńtì àtijọ́. Ìgbà kan wà tí wọn ò nígbàgbọ́ mọ́ nínú ìlérí tí Jèhófà ṣe pé àwọn òkú máa jíǹde. (1 Kọ́r. 15:12) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tí ò gbà pé àjíǹde wà máa ń ṣe ohun tó wù wọ́n torí wọn ò nírètí kankan pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa. (1 Kọ́r. 15:32) Bákan náà lónìí, àwọn tí ò gba ìlérí tí Ọlọ́run ṣe gbọ́ ń ṣe ohun tó wù wọ́n, wọ́n ń jayé òní torí wọ́n gbà pé àwọn ò mẹ̀yìn ọ̀la. Àmọ́ àwa yàtọ̀ sí wọn torí a nígbàgbọ́ nínú àwọn ìlérí tí Ọlọ́run ṣe. Ìrètí tá a ní dà bí akoto tó ń dáàbò bo èrò wa, kì í jẹ́ ká mọ tara wa nìkan kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́.—1 Kọ́r. 15:33, 34.
10. Báwo ni ìrètí tá a ní ṣe ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ èrò tí ò tọ́?
10 Ìrètí tá a ní kì í jẹ́ ká ronú pé kò sí àǹfààní kankan nínú bá a ṣe ń sapá láti ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè sọ pé: ‘Mi ò lè sí lára àwọn tó máa ní ìyè àìnípẹ̀kun láéláé. Kì í ṣe irú mi ni Jèhófà ń wá torí mi ò rò pé màá lè ṣe ohun tí Jèhófà fẹ́ láé.’ Ṣẹ́ ẹ rántí pé Élífásì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó pe ara wọn lọ́ọ̀rẹ́ Jóòbù sọ nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀. Élífásì sọ pé: “Kí ni ẹni kíkú jẹ́ tó fi máa mọ́?” Ó tún sọ nípa Ọlọ́run pé: “Wò ó! Kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àwọn ọ̀run pàápàá kò mọ́ ní ojú rẹ̀.” (Jóòbù 15:14, 15) Ẹ ò rí i pé irọ́ ńlá nìyẹn! Má gbàgbé pé Sátánì ló máa ń fẹ́ ká nírú èrò yẹn. Ó mọ̀ pé tó o bá ti ń nírú èrò bẹ́ẹ̀, ìrètí tó o ní ò ní dá ẹ lójú mọ́. Torí náà, má gba èròkerò yẹn láyè, ṣe ni kó o máa ronú nípa àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún wa. Má ṣiyèméjì rárá torí Jèhófà fẹ́ kó o wà láàyè títí láé àti pé ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kọ́wọ́ ẹ lè tẹ̀ ẹ́.—1 Tím. 2:3, 4.
JẸ́ KÍ ÌRÈTÍ TÓ O NÍ DÁ Ẹ LÓJÚ
11. Kí nìdí tó fi yẹ ká mú sùúrù dìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ?
11 A gbọ́dọ̀ sapá gan-an kí ìrètí tá a ní lè dá wa lójú. Torí náà, ó lè máa ṣe wá bíi pé àkókò tí Jèhófà sọ pé òun máa mú ìlérí òun ṣẹ ti ń pẹ́ jù. Àmọ́ torí pé Jèhófà ti wà tipẹ́, kò sì lè kú láéláé, nǹkan tó dà bíi pé ó ń pẹ́ lójú wa ò pẹ́ rárá lójú tiẹ̀. (2 Pét. 3:8, 9) Gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe ló máa ṣe, àmọ́ ó lè má jẹ́ lásìkò tá a retí pé ó máa ṣe é. Torí náà, kí ló máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú bá a ṣe ń retí ìgbà tí Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ?—Jém. 5:7, 8.
12. Bó ṣe wà nínú Hébérù 11:1, 6, báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe máa ń jẹ́ ká nírètí?
12 Ìrètí tá a ní máa dá wa lójú tá a bá dúró sọ́dọ̀ Jèhófà torí òun ló máa jẹ́ ká rí ohun tá à ń retí gbà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ká tó lè nírètí, a gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà wà àti pé “òun ló ń san èrè fún àwọn tó ń wá a tọkàntọkàn.” (Ka Hébérù 11:1, 6.) Tó bá dá wa lójú hán-ún hán-ún pé Jèhófà wà, ọkàn wa á túbọ̀ balẹ̀ pé ó máa mú gbogbo ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tá a lè ṣe táá jẹ́ kí àjọṣe àwa àti Jèhófà túbọ̀ lágbára, ìyẹn lá sì jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú.
Tá a bá ń gbàdúrà, tá a sì ń ronú lórí ohun tá a kà nínú Bíbélì, ìrètí tá a ní á dá wa lójú (Wo ìpínrọ̀ 13-15)b
13. Báwo la ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?
13 Máa gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì máa ka Bíbélì. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Jèhófà, a ṣì lè jẹ́ ọ̀rẹ́ ẹ̀. A lè bá a sọ̀rọ̀ tá a bá ń gbàdúrà, ó sì dá wa lójú pé ó máa gbọ́ wa. (Jer. 29:11, 12) Ọ̀nà kan tá a lè gbà tẹ́tí sí Ọlọ́run ni pé ká máa ka Bíbélì, ká sì máa ronú lórí ohun tá a kà. Tá a bá ń ronú lórí bí Jèhófà ṣe bójú tó àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ nígbà àtijọ́, ó máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú. Gbogbo nǹkan tó wà nínú Bíbélì “ni a kọ fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.”—Róòmù 15:4.
14. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa ohun tí Jèhófà ti ṣe fáwọn èèyàn kan?
14 Máa ronú nípa bí Jèhófà ṣe mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tí Ọlọ́run ṣe fún Ábúráhámù àti Sérà. Wọ́n ti dàgbà kọjá ẹni tó lè bímọ, síbẹ̀ Jèhófà ṣèlérí fún wọn pé wọ́n máa rọ́mọ bí. (Jẹ́n. 18:10) Kí ni Ábúráhámù wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Ó ní ìgbàgbọ́ pé òun máa di bàbá ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè.” (Róòmù 4:18) Lójú èèyàn, ó lè dà bíi pé kò ṣeé ṣe, àmọ́ ó dá Ábúráhámù lójú pé Jèhófà máa mú ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Jèhófà náà ò sì já a kulẹ̀. (Róòmù 4:19-21) Irú àwọn ìtàn Bíbélì bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ, bó ti wù kí ìṣòro náà le tó lójú wa.
15. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún wa?
15 Máa ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún ẹ. Ronú nípa àǹfààní tó o ti rí nígbà tó o kà nípa àwọn ìlérí Jèhófà tó wà nínú Bíbélì tó ti ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, Jésù ṣèlérí pé Bàbá òun máa pèsè àwọn nǹkan tó o nílò fún ẹ. (Mát. 6:32, 33) Ó tún fi dá ẹ lójú pé tó o bá béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ ẹ̀, á fún ẹ. (Lúùkù 11:13) Ó sì dájú pé Jèhófà ti ṣe àwọn nǹkan yìí fún ẹ. Ó ṣeé ṣe kó o rántí àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún ẹ tó sì mú ṣẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣèlérí pé òun máa dárí jì ẹ́, òun máa tù ẹ́ nínú, òun á sì máa fi ọ̀rọ̀ òun bọ́ ẹ. (Mát. 6:14; 24:45; 2 Kọ́r. 1:3) Torí náà, tó o bá ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe fún ẹ, á túbọ̀ dá ẹ lójú pé ó máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ lọ́jọ́ iwájú.
JẸ́ KÍ ÌRÈTÍ TÓ O NÍ MÁA FÚN Ẹ LÁYỌ̀
16. Kí ló mú kí ìrètí tá a ní jẹ́ ẹ̀bùn pàtàkì?
16 Ẹ̀bùn pàtàkì ni ìyè àìnípẹ̀kun tá à ń retí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gbogbo wa là ń retí ọjọ́ iwájú aláyọ̀ yẹn, ó sì dájú pé a máa rí i. Ìrètí yẹn dà bí ìdákọ̀ró, ó ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro, ó tún ń jẹ́ ká lè fara da inúnibíni, kì í sì í jẹ́ ká bẹ̀rù ikú. Ó dà bí akoto tó máa ń dáàbò bo èrò wa ká má bàa ṣe ohun tí kò tọ́, ká sì máa ṣe ohun rere. Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣèlérí nínú Bíbélì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn, ó sì ń jẹ́ ká mọ bó ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Torí náà, tá a bá jẹ́ kí ìrètí tá a ní túbọ̀ dá wa lójú, a máa jàǹfààní gan-an.
17. Kí ló ń mú kí ìrètí tá a ní máa fún wa láyọ̀?
17 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí ìrètí tí ẹ ní máa fún yín láyọ̀.” (Róòmù 12:12) Pọ́ọ̀lù ń láyọ̀ torí ó dá a lójú pé tóun bá jẹ́ olóòótọ́, òun máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lọ́run. Ó yẹ káwa náà jẹ́ kí ìrètí tá a ní máa fún wa láyọ̀ torí ó dá wa lójú pé Jèhófà máa mú àwọn ìlérí ẹ̀ ṣẹ. Onísáàmù kan sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni . . . tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, . . . Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ nígbà gbogbo.”—Sm. 146:5, 6.
ORIN 139 Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Máa Di Tuntun
a Jèhófà jẹ́ ká ní ìrètí àgbàyanu pé ọjọ́ iwájú máa dáa. Ìrètí yẹn máa ń fún wa lókun, kì í sì í jẹ́ ká ronú nípa àwọn ìṣòro wa ju bó ṣe yẹ lọ. Yàtọ̀ síyẹn, ó ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí. Bákan náà, kì í jẹ́ ká ro èròkerò tó máa kó bá ẹ̀rí ọkàn wa. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa rí bí àwọn nǹkan tá a sọ yìí ṣe máa jẹ́ kí ìrètí tá a ní dá wa lójú.
b ÀWÒRÁN: Bí akoto ṣe máa ń dáàbò bo orí sójà kan àti bí ìdákọ̀ró ṣe máa ń jẹ́ kí ọkọ̀ dúró sójú kan, bẹ́ẹ̀ náà ni ìrètí tá a ní máa ń dáàbò bo ọkàn wa ká má bàa ro èròkerò, ó sì máa ń mú ká jẹ́ olóòótọ́ nígbà ìṣòro. Arábìnrin kan ń gbàdúrà tọkàntọkàn sí Jèhófà. Arákùnrin kan ń ronú nípa bí Jèhófà ṣe mú àwọn ìlérí tó ṣe fún Ábúráhámù ṣẹ. Arákùnrin kejì ń ronú nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ti ṣe fún un.