Àwọn Ohun Tó Wà Lórí JW Library àti Ìkànnì JW.ORG
ÀKÓJỌ ÀPILẸ̀KỌ ÀTI FÍDÍÒ
Ìgbà Wo La Máa Bọ́ Lọ́wọ́ Àwọn Afẹ̀míṣòfò?
Bíbélì jẹ́ ká mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń hùwà ipá, tí wọ́n sì ń fẹ̀mí àwọn èèyàn ṣòfò. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé inú Ọlọ́run ò dùn sí ìwà burúkú yìí. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa fòpin sí ìwà ipá àti ìbẹ̀rù.
ÌRÍRÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
Wọ́n Fi Pẹ̀lẹ́tù Dá Àlùfáà Kan Tínú Ń Bí Lóhùn
Bíbélì rọ̀ wá pé ká jẹ́ oníwà tútù, kódà táwọn èèyàn bá múnú bí wa. Ṣé ìmọ̀ràn yìí ṣì lè ṣe wá láǹfààní?
BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ
Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tá A Ṣe Kí Àrùn Corona Tó Bẹ̀rẹ̀
Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, àwọn ilé ìjọsìn wa tá a ṣètò pé a máa kọ́ tá a sì máa tún ṣe ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje (2,700) lọ. Báwo ni àjàkálẹ̀ àrùn kòrónà (COVID-19) ṣe dí iṣẹ́ náà lọ́wọ́?