ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • hdu àpilẹ̀kọ 6
  • Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tá A Ṣe Kí Àrùn Corona Tó Bẹ̀rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tá A Ṣe Kí Àrùn Corona Tó Bẹ̀rẹ̀
  • Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Iṣẹ́ Tá A Fẹ́ Ṣe Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn 2021
  • Eka To N Yaworan To si N Kole Kari Aye
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tó Ń Jẹ́ Ká Lè Túbọ̀ Wàásù
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Ṣé O Lè Lo Àkókò àti Okun Rẹ?
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Lọ́nà Tó Túbọ̀ Yára
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
Àwọn Míì
Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
hdu àpilẹ̀kọ 6
Àwọn òṣìṣẹ́ ìkọ́lé ń lẹ orúkọ mọ́ ara ògiri ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Cameroon.

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àwọn Iṣẹ́ Ìkọ́lé Tá A Ṣe Kí Àrùn Corona Tó Bẹ̀rẹ̀

NOVEMBER 1, 2020

Ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń ṣèrìbọmi lọ́dọọdún, torí náà a túbọ̀ ń nílò àwọn ibi ìjọsìn tó pọ̀ sí i. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ kárí ayé pinnu láti kọ́ tàbí ṣàtúnṣe sáwọn ibi ìjọsìn tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún méje (2,700) láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn 2020.a

Ó ṣeni láàánú pé àrùn Corona (COVID-19) ò jẹ́ ká lè ṣe gbogbo iṣẹ́ ìkọ́lé yìí. Ká lè dáàbò bo àwọn ará wa, ká sì pa àṣẹ Ìjọba mọ́, Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí pinnu láti dá èyí tó pọ̀ jù lára àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tá a fẹ́ ṣe kárí ayé dúró. Láìka ìyẹn sí, lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, àwọn ilé tó ju ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún méje (1,700) la ti kọ́ tàbí ṣàtúnṣe sí kí àrùn Corona tó bẹ̀rẹ̀. Bákan náà, àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tó ṣe pàtàkì tá a parí láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì kárí ayé lé ní ọgọ́rùn-ún kan (100). Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa méjì lára àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé náà, ká sì wo bí wọ́n ṣe ṣe àwọn ará wa láǹfààní.

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Cameroon. Ìlú Douala ni ẹ̀ka ọ́fíìsì yìí wà tẹ́lẹ̀, àmọ́ ibi tí wọ́n ń lò kéré gan-an, torí náà wọ́n nílò ibi tó tóbi sí i. Ìgbìmọ̀ Ìṣèwéjáde kọ́kọ́ ronú pé àwọn máa tún ilé náà ṣe, àmọ́ wọ́n wá rí i pé iye tí wọ́n fi máa tún un ṣe á pọ̀ ju iye tí wọ́n máa ná tí wọ́n bá fẹ́ kọ́ irú ẹ̀. Wọ́n tún wò ó bóyá káwọn kọ́ ilé tuntun síbòmíì àbí káwọn ra ilé kan, kí wọ́n wá ṣàtúnṣe sí i, àmọ́ pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí.

Nígbà tó yá, a gbọ́ pé ìjọba ìbílẹ̀ pinnu láti ṣe ọ̀nà tó gba iwájú Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà lápá àríwá ìlú Douala. Ọ̀nà yẹn á mú kó rọrùn láti dé ibi tílẹ̀ náà wà, á sì jẹ́ ká lè tètè rí àwọn nǹkan tá a nílò níbẹ̀. Irú ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì nílò gẹ́lẹ́ nìyẹn. Torí náà, Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun sí apá kan lára ilẹ̀ Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà.

Àwòrán: 1. Àwọn arákùnrin méjì ń ya fọ́tò níbi tí wọ́n ti ń to búlọ́ọ̀kù. 2. Àwọn arákùnrin mẹ́ta ń ṣètò ibi tí wọ́n máa da kọnkéré sí.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin yọ̀ǹda ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Cameroon

Àwọn ará tó yọ̀ǹda ara wọn àtàwọn òṣìṣẹ́ tá a sanwó fún ló pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ náà, ìyẹn sì mú kí àkókò àtowó tá a ná dín kù. Kódà, ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje ó lé ọgọ́ta mílíọ̀nù (760,000,000) náírà niye tá a ná fi dín kù! Inú wa dùn pé ìdílé Bẹ́tẹ́lì láǹfààní láti kó lọ sí ọ́fíìsì tuntun yìí kí àrùn Corona tó bẹ̀rẹ̀.

Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Cameroon ṣe rí tá a bá wò ó látòkè.

A parí iṣẹ́ ìkọ́lé ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Cameroon kí àrùn Corona tó bẹ̀rẹ̀

Ilé tuntun yìí ti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn fún ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Cameroon, ara tù wọ́n níbẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gbádùn iṣẹ́ wọn, torí náà wọ́n gbà pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà nilé náà. Tọkọtaya kan sọ pé, “Gbogbo ìgbà ló máa ń yá wa lára láti ṣiṣẹ́, ká lè fi hàn pé a mọyì ẹ̀bùn yìí.”

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣiṣẹ́ nínú ọ́fíìsì wọn tuntun kí àrùn Corona tó bẹ̀rẹ̀

Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Tojolabal Lórílẹ̀-èdè Mexico. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé ẹ̀ka ọ́fíìsì Central America tó wà nítòsí Mexico City làwọn atúmọ̀ èdè Tojolabal ti ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, agbègbè Altamirano àti Las Margaritas làwọn tó ń sọ èdè yìí pọ̀ sí jù, ibẹ̀ sì tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ogún (620) máìlì síbi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wà! Torí náà, àwọn atúmọ̀ èdè kì í rí àwọn tó ń sọ èdè yẹn déédéé, ìyẹn sì jẹ́ kó nira fún wọn láti mọ̀ táwọn ọ̀rọ̀ kan bá yí padà nínú èdè náà. Yàtọ̀ síyẹn, kì í rọrùn láti ráwọn arákùnrin àti arábìnrin tó tóótun láti ṣiṣẹ́ atúmọ̀ èdè tàbí láti gbohùn sílẹ̀ nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣiṣẹ́ níwájú ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè, kó lè rẹwà.

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin yọ̀ǹda ara wọn lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́lé Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè

Torí náà, Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí wò ó pé á dáa káwọn atúmọ̀ èdè yẹn kó lọ síbi táwọn tó ń sọ èdè Tojolabal pọ̀ sí. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, ẹ̀ka ọ́fíìsì pinnu láti ra ilé kan, kí wọ́n sì tún un ṣe. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n ṣọ́wó ná, torí iye tí wọ́n máa ná máa pọ̀ ju iye tí wọ́n máa fi kọ́ ilé tuntun tàbí háyà ibì kan.

Bí Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Tojolabal tó wà lórílẹ̀-èdè Mexico ṣe rí lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ ọ tán.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè yẹn sọ bí àyípadà yìí ṣe ṣe òun láǹfààní, ó ní: “Odindi ọdún mẹ́wàá ni mo fi ṣe iṣẹ́ atúmọ̀ èdè, àmọ́ ní gbogbo ọdún yẹn, kò sígbà tí mo pàdé ìdílé kankan tó ń sọ èdè mi nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ní báyìí tá a ti wà níbi táwọn tó ń sọ èdè Tojolabal pọ̀ sí, ó ti ṣeé ṣe fún mi láti máa rí àwọn tó ń sọ èdè yẹn lójoojúmọ́. Ìyẹn ti jẹ́ kí n kọ́ àwọn nǹkan tuntun nípa èdè náà, ó sì ti jẹ́ kí iṣẹ́ wa túbọ̀ sunwọ̀n sí i.”

Bí ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè Tojolabal ṣe rí kí wọ́n tó kọ́ ọ àti lẹ́yìn tí wọ́n kọ́ ọ tán

Àwọn Iṣẹ́ Tá A Fẹ́ Ṣe Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn 2021

Tó bá ṣeé ṣe, lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn 2021 a pinnu láti ṣiṣẹ́ lórí Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè àtàwọn ilé tá a máa lò fún ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run tó tó márùndínlọ́gọ́rin (75). Àá máa báṣẹ́ lọ lórí àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé pàtàkì mẹ́jọ tá à ń ṣe láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, títí kan iṣẹ́ tá a fẹ́ ṣe lóríléeṣẹ́ wa tuntun ní Ramapo tó wà ní New York. Àá sì kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun lórílẹ̀-èdè Argentina àti Italy. Yàtọ̀ síyẹn, a nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó ju ẹgbẹ̀rún kan (1,000) lọ, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) Gbọ̀ngàn Ìjọba tá à ń lò báyìí ni ò bójú mu mọ́, a sì máa nílò láti tún wọn kọ́. A tún máa ṣàtúnṣe sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000).

Àwòrán: Àtẹ tó jẹ́ ká mọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a nílò báyìí àtàwọn tá a máa nílò lọ́jọ́ iwájú bá a ṣe ń rí i tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. 1. Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun tá a nílò: 1,179; Àwọn ilé ìpàdé tá a fẹ́ tún kọ́: 1,367; Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a fẹ́ tún kọ́: 4,672; Àròpọ̀: 7,218. 2. Iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tá a máa nílò lọ́dún kan: 699; Iye Gbọ̀ngàn Ìjọba tá a fẹ́ tún ṣe lọ́dún kan: 2,028.

Ibo la ti ń rówó tá a fi ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé yìí? Arákùnrin Lázaro González, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Central America dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé Ọ́fíìsì Àwọn Atúmọ̀ Èdè Tojolabal. Ó sọ pé: “Àwọn ará tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ń bójú tó ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ. Torí náà, a ò ní lè kọ́ ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè yìí láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn ará wa kárí ayé. Owó táwọn ará wa fi ń ṣètìlẹyìn ló mú kó ṣeé ṣe fáwọn atúmọ̀ èdè yìí láti máa gbé láàárín àwọn tó ń sọ èdè wọn. A dúpẹ́, a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ ẹ̀yin ará wa kárí ayé fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín.” Ká sòótọ́, owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé ló mú káwọn iṣẹ́ ìkọ́lé yìí ṣeé ṣe, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì jẹ́ pé orí ìkànnì donate.jw.org lẹ ti ń fi ránṣẹ́.

a Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ ló ń ṣètò bí wọ́n ṣe máa kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kan ń bójú tó. Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Kárí Ayé tó wà lóríléeṣẹ́ wa, ló máa ń pinnu iṣẹ́ tó gba kánjúkánjú kárí ayé, tí wọ́n á sì ṣe kòkáárí bí wọ́n á ṣe kọ́ ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́