MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Lè Lo Àkókò àti Okun Rẹ?
Bí wòlíì Àìsáyà ṣe sọ, à ń rí bí ètò Jèhófà tó wà láyé ṣe ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń gbòòrò sí i. (Ais 54:2) Torí náà, a túbọ̀ máa nílò àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, Gbọ̀ngàn Àpéjọ àtàwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì. Tá a bá sì ti kọ́ wọn tán, ó dájú pé a máa ní láti máa bójú tó wọn, àwọn míì sì lè nílò àtúnṣe. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà lo àkókò àti okun rẹ fún Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ yìí?
O lè rí i pé ìwọ náà wà níbẹ̀ tí wọ́n bá ní kẹ́ ẹ wá tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe
O lè yọ̀ǹda ara rẹ láti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe
O lè kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Local Design/Construction Volunteer Application (DC-50) kó o lè máa yọ̀ǹda ara rẹ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fún iṣẹ́ ìkọ́lé tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn àtúnṣe kan nítòsí ibi tó ò ń gbé
O lè kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù Application for Volunteer Program (A-19) kó o lè yọ̀ǹda ara rẹ fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní agbègbè rẹ̀ tàbí ní ilé míì tá a yà sí mímọ́ fún ìjọsìn Jèhófà
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ À Ń MÚRA SÍLẸ̀ LÁTI KỌ́ ILÉ TUNTUN—ÀYỌLÒ, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Látọdún 2014, báwo la ṣe túbọ̀ ń lo fídíò?
Ká lè túbọ̀ máa ṣe ọ̀pọ̀ fídíò jáde, kí làwọn nǹkan tá a fẹ́ ṣe, ìgbà wo la fẹ́ bẹ̀rẹ̀, ìgbà wo la sì fẹ́ parí ẹ̀?
Báwo la ṣe lè ti iṣẹ́ yìí lẹ́yìn?
Tó bá wù ẹ́ láti yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìkọ́lé ní Ramapo, kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù (DC-50) kó o sì yọ̀ǹda ara rẹ níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n bá ń ṣe ládùúgbò rẹ?
Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà ló ń darí iṣẹ́ yìí?
Kí la lè ṣe láti ṣèrànwọ́ tá ò bá tiẹ̀ lè lọ síbi ìkọ́lé yìí?