MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI | OHUN TÓ O LÈ FI ṢE ÀFOJÚSÙN NÍ ỌDÚN IṢẸ́ ÌSÌN TÓ Ń BỌ̀
Máa Ṣèrànwọ́ Níbi Iṣẹ́ Ìkọ́lé Ètò Ọlọ́run
Ọ̀nà kan tá a lè gbà kọ́wọ́ ti ìjọsìn Jèhófà ni pé ká máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìkọ́lé ètò Ọlọ́run. (Ẹk 36:1) Ṣé o lè máa ṣèrànwọ́ látìgbàdégbà láwọn iṣẹ́ ìkọ́lé tó ń lọ ládùúgbò ẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, jọ̀wọ́ kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù Local Design/Construction Volunteer Application (DC-50). Tó bá sì jẹ́ pé o lè ṣèrànwọ́ láwọn ibi tó jìnnà sádùúgbò ẹ fún ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ tàbí oṣù pàápàá, jọ̀wọ́ kọ̀rọ̀ sí fọ́ọ̀mù Application for Volunteer Program (A-19). Kò pọn dandan kó o mọ̀ nípa iṣẹ́ ìkọ́lé kó o tó lè yọ̀ǹda ara ẹ.—Ne 2:1, 4, 5.
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JẸ́ KÍ ÌGBÀGBỌ́ MÚ KÓ O ṢE PÚPỌ̀ SÍ I—MÁA ṢÈRÀNWỌ́ NÍBI IṢẸ́ ÌKỌ́LÉ ÈTÒ ỌLỌ́RUN, KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Àwọn nǹkan wo ló ba Arábìnrin Sarah lẹ́rù, kí ló sì ràn án lọ́wọ́?