ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 January ojú ìwé 32
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìrànlọ́wọ́ fún Àwọn Ìdílé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àwọn Àbá Tó Lè Wúlò fún Yín Nígbà Ìjọsìn Ìdílé àti Ìdákẹ́kọ̀ọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Báwo La Ṣe Lè Mọ Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Ìdílé, Ẹ Máa Yin Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Apá kan Ìjọ Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 January ojú ìwé 32

OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́

Nǹkan Tó O Lè Fi Dá Kẹ́kọ̀ọ́ Tàbí Ṣe Ìjọsìn Ìdílé

A máa ń jọ́sìn Jèhófà pa pọ̀ láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àyíká àti àpéjọ agbègbè. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ṣe ìjọsìn ìdílé. O lè lo àwọn àbá tó wà nísàlẹ̀ yìí láti fi dá kẹ́kọ̀ọ́ tàbí ṣe ìjọsìn ìdílé:

  • Múra ìpàdé sílẹ̀. O lè fi àwọn orin tá a máa kọ nípàdé dánra wò, kó o sì rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé yín pé kí wọ́n múra ìdáhùn kan sílẹ̀.

  • Ka ìtàn Bíbélì kan. Lẹ́yìn náà, ya àwòrán ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn yẹn tàbí kó o ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o kọ́.

  • Ka àdúrà tẹ́nì kan gbà nínú Bíbélì, kó o sì wo bíyẹn ṣe lè jẹ́ kí àdúrà ẹ sunwọ̀n sí i.

  • Wo fídíò kan tí ètò Ọlọ́run ṣe, lẹ́yìn náà kó o sọ ohun tó o kọ́ níbẹ̀ fáwọn ẹlòmíì tàbí kó o ṣàkọsílẹ̀ ohun tó o kọ́.

  • Múra ohun tó o fẹ́ sọ lóde ìwàásù sílẹ̀, o sì lè fi dánra wò.

  • Kíyè sí àwọn nǹkan tí Jèhófà dá, kó o sì ṣàṣàrò lórí wọn tàbí kó o sọ ohun táwọn nǹkan yẹn kọ́ ẹ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn.a

a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Túbọ̀ Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Nípa Jèhófà Lára Àwọn Nǹkan Tó Dá” nínú Ilé Ìṣọ́ March 2023.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́