ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 May ojú ìwé 32
  • Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Onídàájọ́ Ilẹ̀ Ayé’ Máa Ń Ṣe Ohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • ‘Èmi Kò Lè Hùwà Búburú Ńlá Yìí’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Jèhófà Máa Jẹ́ Kó O Ṣàṣeyọrí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ẹrú Tó Ṣègbọràn sí Ọlọ́run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 May ojú ìwé 32

OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀

Bó O Ṣe Lè Fara Dà Á Tí Wọ́n Bá Rẹ́ Ẹ Jẹ

Ka Jẹ́nẹ́sísì 37:23-28; 39:17-23 kó o lè rí bí Jósẹ́fù ṣe fara dà á nígbà tí wọ́n rẹ́ ẹ jẹ.

Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Kí ló mú káwọn èèyàn hùwà ìkà sí Jósẹ́fù? (Jẹ́n. 37:3-11; 39:1, 6-10) Ọdún mélòó ni Jósẹ́fù fi fara da ìwà ìrẹ́jẹ náà? (Jẹ́n. 37:2; 41:46) Lásìkò yẹn, kí ni Jèhófà ṣe fún Jósẹ́fù, kí ni ò sì ṣe fún un?—Jẹ́n. 39:2, 21; w23.01 17 ¶13.

Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì parọ́ mọ́ Jósẹ́fù, Bíbélì ò sọ pé Jósẹ́fù fẹ̀sùn kàn án pé ó parọ́ mọ́ òun. Báwo làwọn ẹsẹ Bíbélì tó tẹ̀ lé e yìí ṣe jẹ́ ká rídìí tí Jósẹ́fù ò fi sọ nǹkan kan tàbí ìdí tí ò fi yẹ ká retí pé kí Bíbélì sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà? (Òwe 20:2; Jòh. 21:25; Ìṣe 21:37) Àwọn ìwà wo ló ran Jósẹ́fù lọ́wọ́ láti fara dà á nígbà tí wọ́n rẹ́ ẹ jẹ?—Míkà 7:7; Lúùkù 14:11; Jém. 1:2, 3.

Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:

  • ‘Ìwà ìrẹ́jẹ wo ló ṣeé ṣe káwọn èèyàn hù sí mi torí pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù?’ (Lúùkù 21:12, 16, 17; Héb. 10:33, 34)

  • ‘Báwo ni mo ṣe lè múra sílẹ̀ láti fara dà á tí wọ́n bá rẹ́ mi jẹ?’ (Sm. 62:7, 8; 105:17-19; w19.07 2-7)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́