ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 May ojú ìwé 26-31
  • Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ÌDÍ TÁWỌN ÈÈYÀN FI Ń FẸ́RA WỌN SỌ́NÀ
  • Ẹ RÍ I PÉ Ẹ MỌRA YÍN DÁADÁA
  • ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÓ YẸ KẸ́ Ẹ RONÚ NÍPA Ẹ̀
  • BÁWO LÀWỌN ARÁ ÌJỌ ṢE LÈ RAN ÀWỌN TÓ Ń FẸ́RA SỌ́NÀ LỌ́WỌ́?
  • Báwo Lo Ṣe Lè Rí Ẹni Tó O Máa Fẹ́?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Báwo Ni Èmi àti Ẹni Tí Ọ̀nà Rẹ̀ Jìn Ṣe Lè Máa Fẹ́ra Wa Sọ́nà?
    Jí!—1999
  • Mímúra Sílẹ̀ fún Ìgbéyàwó Aláṣeyọrí
    Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé
  • Máa Ṣe Àwọn Ìpinnu Tó Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 May ojú ìwé 26-31

ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 22

ORIN 127 Irú Èèyàn Tó Yẹ Kí N Jẹ́

Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ

“Ẹni ìkọ̀kọ̀ ti ọkàn . . . níye lórí gan-an.”—1 PÉT. 3:4.

OHUN TÁ A MÁA KỌ́

Ohun táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà lè ṣe kí wọ́n lè múnú Jèhófà dùn àti báwọn ará ìjọ ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

1-2. Báwo ló ṣe rí lára àwọn kan nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà?

TÁWỌN méjì bá ń fẹ́ra sọ́nà, inú wọn máa ń dùn gan-an, kódà tí wọ́n bá gẹṣin nínú wọn, kò lè kọsẹ̀. Tó o bá ti lẹ́ni tó ò ń fẹ́ sọ́nà báyìí, ó dájú pé o ò ní fẹ́ kí ohunkóhun da àárín yín rú. Bó sì ṣe rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn torí àsìkò yẹn máa ń fún wọn láyọ̀. Arábìnrin Tsiona tó wá láti Etiópíà sọ pé: “Ọ̀kan lára ìgbà tínú mi dùn jù ni ìgbà tí èmi àti ọkọ mi ń fẹ́ra wa sọ́nà. A jọ máa ń jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì, a sì tún máa ń sọ̀rọ̀ tó ń pa wá lẹ́rìn-ín. Inú mi dùn gan-an nígbà tí mo rí i pé mo ti rí ẹni tí mo nífẹ̀ẹ́, tóun náà sì nífẹ̀ẹ́ mi gan-an.”

2 Àmọ́, Arákùnrin Alessio láti orílẹ̀-èdè Netherland sọ pé: “Mo gbádùn ìgbà témi àtìyàwó mi ń fẹ́ra wa sọ́nà torí àsìkò yẹn jẹ́ ká túbọ̀ mọra wa, ṣùgbọ́n a tún láwọn ìṣòro kan.” Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ìṣòro táwọn tó ń fẹ́ra wọn sọ́nà máa ń ní àtàwọn ìlànà Bíbélì tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí ẹ̀. A tún máa sọ̀rọ̀ nípa báwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ́wọ́.

ÌDÍ TÁWỌN ÈÈYÀN FI Ń FẸ́RA WỌN SỌ́NÀ

3. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń fẹ́ra wọn sọ́nà? (Òwe 20:25)

3 Lóòótọ́, àsìkò alárinrin ni àsìkò táwọn méjì bá ń fẹ́ra sọ́nà, síbẹ̀ wọn ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú un torí pé ó ṣeé ṣe káwọn méjèèjì di tọkọtaya. Lọ́jọ́ ìgbéyàwó, tọkọtaya máa ń jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Jèhófà pé àwọn máa nífẹ̀ẹ́ ara àwọn, àwọn á sì máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn ní gbogbo àsìkò táwọn bá fi wà láàyè. Àmọ́ ká tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ èyíkéyìí, ó yẹ ká fara balẹ̀ ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa. (Ka Òwe 20:25.) Ohun tó sì yẹ ká ṣe náà nìyẹn tó bá kan ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Ó yẹ káwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà lo àsìkò yẹn láti mọ ara wọn dáadáa, kí wọ́n lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Nígbà míì, wọ́n lè pinnu pé àwọn máa ṣègbéyàwó, ìgbà míì sì rèé, wọ́n lè pinnu pé káwọn má fẹ́ra mọ́. Táwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà bá sọ pé àwọn ò fẹ́ra mọ́, ìyẹn ò sọ pé ohun tí wọ́n ṣe burú. Kàkà bẹ́ẹ̀, àsìkò tí wọ́n fi fẹ́ra wọn sọ́nà yẹn jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá àwọn máa lè ṣègbéyàwó àbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

4. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fojú tó tọ́ wo ìfẹ́sọ́nà?

4 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa fojú tó tọ́ wo ìfẹ́sọ́nà? Táwọn tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́ bá mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń fẹ́ra sọ́nà, wọn ò ní máa fẹ́ ẹni tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ò ní bá ṣègbéyàwó. Àmọ́ o, kì í ṣe àwọn tí ò tíì ṣègbéyàwó nìkan ló yẹ kó máa fojú tó tọ́ wo ìfẹ́sọ́nà. Gbogbo wa ló yẹ ká máa ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, èrò àwọn kan ni pé dandan ni káwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà ṣègbéyàwó. Àkóbá wo nirú èrò yìí máa ń ṣe fáwọn Kristẹni tí ò tíì lẹ́ni tí wọ́n ń fẹ́? Arábìnrin kan tí ò tíì lọ́kọ tó ń jẹ́ Melissa lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Táwọn ará bá mọ̀ pé arákùnrin àti arábìnrin kan ń fẹ́ra, ohun tí wọ́n máa ń retí ni pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣègbéyàwó. Torí náà, táwọn tó ń fẹ́ra bá rí i pé ìwà àwọn ò bára mu, nígbà míì wọn kì í fẹ́ fòpin sí ìfẹ́sọ́nà náà torí nǹkan táwọn èèyàn máa sọ. Kódà, àwọn kan ò tiẹ̀ fẹ́ ní àfẹ́sọ́nà torí ọ̀rọ̀ náà máa ń kó wọn lọ́kàn sókè.”

Ẹ RÍ I PÉ Ẹ MỌRA YÍN DÁADÁA

5-6. Kí ló yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà mọ̀ nípa ara wọn? (1 Pétérù 3:4)

5 Tó o bá lẹ́ni tó ò ń fẹ́ sọ́nà, kí ló máa jẹ́ kó o mọ̀ bóyá kó o fẹ́ ẹni náà àbí kó o má fẹ́ ẹ? Ohun tó o máa ṣe ni pé kó o mọ ẹni náà dáadáa. Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ àwọn nǹkan kan nípa ẹni náà kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín sọ́nà. Àmọ́ ní báyìí, o ti láǹfààní láti mọ irú ‘ẹni tó jẹ́ gan-an.’ (Ka 1 Pétérù 3:4.) Ìyẹn máa gba pé kó o mọ ìwà ẹ̀, bó ṣe ń ronú àti bí àjọṣe tó ní pẹ̀lú Jèhófà ṣe dáa tó. Tó bá yá, ó yẹ kó o lè dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: ‘Ṣé ẹni tó yẹ kí n fẹ́ nìyí lóòótọ́?’ (Òwe 31:26, 27, 30; Éfé. 5:33; 1 Tím. 5:8) ‘Ṣé á lè máa fìfẹ́ hàn sí mi tá á sì máa mára tù mí, ṣé èmi náà á sì lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ṣé màá lè gbójú fo àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní?’b (Róòmù 3:23) Bẹ́ ẹ ṣe ń mọra yín, máa rántí pé: Ohun tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ mọwọ́ ara yín ni bẹ́ ẹ ṣe ń gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ yín, kì í ṣe bí ìwà yín ṣe jọra tó.

6 Àwọn nǹkan míì wo ló yẹ kó o mọ̀ nípa ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà? Kí ìfẹ́ ẹni náà tó kó sí ẹ lórí, àwọn nǹkan kan wà tó yẹ kẹ́ ẹ jọ sọ irú bí àwọn nǹkan tẹ́ ẹ fẹ́ fayé yín ṣe. Àmọ́ àwọn nǹkan míì ńkọ́, irú bí ọ̀rọ̀ ìlera, ọ̀rọ̀ owó tàbí àwọn nǹkan tí ò dáa tó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí? Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo nǹkan lẹ lè bára yín sọ tẹ́ ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín. (Fi wé Jòhánù 16:12.) Tó o bá rí i pé o ò tíì fẹ́ dáhùn àwọn ìbéèrè kan báyìí, á dáa kó o jẹ́ kó mọ̀. Àmọ́ bópẹ́bóyá, ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà gbọ́dọ̀ mọ àwọn nǹkan yẹn, kó lè ṣèpinnu tó tọ́. Torí náà tó bá yá, á dáa kó o jẹ́ kó mọ̀.

7. Báwo làwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ṣe lè mọ ara wọn dáadáa? (Tún wo àpótí náà “Táwọn Tó Ń Fẹ́ra Sọ́nà Bá Ń Gbé Níbi Tó Jìnnà Síra.”) (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

7 Báwo lo ṣe lè mọ ẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà dáadáa? Ọ̀kan lára ohun tó dáa jù tó o lè ṣe ni pé kó o máa bá a sọ̀rọ̀, máa béèrè ìbéèrè, máa fetí sílẹ̀ dáadáa, má sì fi ohunkóhun pa mọ́ fún un. (Òwe 20:5; Jém. 1:19) Torí náà, á dáa kẹ́ ẹ máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó rọrùn fún yín láti jọ máa sọ̀rọ̀, irú bíi kẹ́ ẹ jọ máa jẹun, kẹ́ ẹ jọ máa rìn níbi táwọn èèyàn wà, kẹ́ ẹ sì jọ máa wàásù. Ẹ tún lè mọ ara yín sí i tẹ́ ẹ bá jọ ń wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àti ìdílé yín. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ ṣètò àwọn nǹkan tẹ́ ẹ lè máa ṣe táá jẹ́ kó o mọ bí ẹni tó ò ń fẹ́ ṣe máa hùwà sí oríṣiríṣi èèyàn láwọn ipò tó yàtọ̀ síra. Ẹ jẹ́ ká gbọ́ ohun tí Aschwin tó wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands sọ nípa ìgbà tó ń fẹ́ Alicia ìyàwó ẹ̀ sọ́nà, ó ní: “A jọ máa ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ ká túbọ̀ mọra wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn nǹkan kéékèèké la sábà máa ń ṣe pa pọ̀, bíi ká jọ se oúnjẹ tàbí ká jọ ṣiṣẹ́ ilé. Àsìkò yẹn la mọ ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa lè ṣe àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tá a ní.”

Fọ́tò: 1. Arákùnrin àti arábìnrin kan tó ń fẹ́ra sọ́nà wà nílé oúnjẹ, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀, inú wọn sì ń dùn. 2. Arákùnrin àti arábìnrin míì tó ń fẹ́ra sọ́nà ń se oúnjẹ níbi àpèjẹ kan. 3. Arákùnrin àti arábìnrin kan ń ba ara wọn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Mo Lè Máa Retí Tá A Bá Di Tọkọtaya?​— Apá Kìíní” lórí jw.org. Bíbélì wà níwájú arákùnrin yẹn, ó sì ṣí i sílẹ̀.

Táwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà bá ń ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kí wọ́n jọ máa sọ̀rọ̀, wọ́n á túbọ̀ mọ ara wọn dáadáa (Wo ìpínrọ̀ 7-8)


Táwọn Tó Ń Fẹ́ra Sọ́nà Bá Ń Gbé Níbi Tó Jìnnà Síra

Tẹ́yin méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà bá ń gbé níbi tó jìnnà síra, ẹ lè lo àwọn àbá tá a sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè máa bára yín sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí fóònù. Síbẹ̀, ẹ rí i dájú pé ẹ ò fi nǹkan kan pa mọ́ fún ara yín, kẹ́ ẹ sì máa fetí sílẹ̀ dáadáa tí ẹnì kejì bá ń sọ̀rọ̀. Àmọ́, má gbàgbé pé ó lè ṣòro láti mọ àwọn nǹkan kan nípa ẹni náà torí pé ẹ̀ ń gbé níbi tó jìnnà síra. Torí náà, ẹ lọ máa wo ara yín tẹ́ ẹ bá rí i pé ó yẹ kẹ́ ẹ ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn nǹkan míì tún wà tó o lè ronú nípa ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ: Ṣé o ṣe tán láti lọ gbé ìlú míì, kó o sì kọ́ èdè àti àṣà wọn? Ṣé o lówó tí wàá fi máa rìnrìn àjò lọ rí ẹni náà nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra sọ́nà àti owó tí wàá fí máa rìnrìn àjò lọ wo àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ ẹ̀ lẹ́yìn ìgbéyàwó?—Lúùkù 14:28.

8. Àǹfààní wo làwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà máa rí tí wọ́n bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

8 Ẹ máa túbọ̀ mọ ara yín tẹ́ ẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó, ó ṣe pàtàkì pé kẹ́ ẹ máa ṣe ìjọsìn ìdílé déédéé torí ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ fi Jèhófà ṣáájú nínú ìdílé yín. (Oníw. 4:12) Torí náà, ẹ ò ṣe ṣètò àkókò tí ẹ̀ẹ́ jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀ ní báyìí tẹ́ ẹ ṣì ń fẹ́ra sọ́nà? Lóòótọ́, àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ò tíì di ìdílé, arákùnrin yẹn ò sì tíì di orí arábìnrin náà. Síbẹ̀, tẹ́ ẹ bá jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ̀ bóyá ẹni tó ò ń fẹ́ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya ni Max àti Laysa, orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n sì ti wá. Wọ́n rí àǹfààní míì tó wà nínú káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà jọ máa kẹ́kọ̀ọ́. Max sọ pé: “Gbàrà tá a bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra sọ́nà la ti jọ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìfẹ́sọ́nà, ìgbéyàwó àti ọ̀rọ̀ ìdílé nínú àwọn ìwé ètò Ọlọ́run. Àwọn nǹkan tá à ń kọ́ yẹn jẹ́ ká lè máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó nira fún wa láti sọ.”

ÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÓ YẸ KẸ́ Ẹ RONÚ NÍPA Ẹ̀

9. Táwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà bá fẹ́ pinnu àwọn tí wọ́n máa sọ fún, kí ló yẹ kí wọ́n ronú nípa ẹ̀?

9 Ta ló yẹ kó o sọ fún pé o ti ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà? Ìwọ àtẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà lẹ máa pinnu ìyẹn. Tẹ́ ẹ bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, á dáa kó jẹ́ àwọn díẹ̀ lẹ máa sọ fún. (Òwe 17:27) Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn èèyàn ò ní máa béèrè àwọn ìbéèrè tí ò pọn dandan lọ́wọ́ yín, kò sì ní jẹ́ kẹ́ ẹ ṣe ìpinnu tí ò wù yín. Àmọ́, tẹ́ ò bá sọ fún ẹnikẹ́ni, ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé ní kọ̀rọ̀ káwọn èèyàn má bàa mọ̀ sọ́rọ̀ náà. Ìyẹn sì léwu gan-an torí ó lè mú kẹ́ ẹ ṣohun tí kò tọ́. Torí náà, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kẹ́ ẹ jẹ́ káwọn tó lè fún yín nímọ̀ràn tó dáa, tó sì lè ràn yín lọ́wọ́ mọ̀ nípa ẹ̀. (Òwe 15:22) Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè sọ fáwọn kan nínú ìdílé yín, àwọn ọ̀rẹ́ yín tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn tàbí àwọn alàgbà.

10. Báwo làwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà ṣe lè múnú Jèhófà dùn? (Òwe 22:3)

10 Báwo nìwọ àtẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà ṣe lè múnú Jèhófà dùn? Bẹ́ ẹ ṣe túbọ̀ ń mọra yín, bẹ́ẹ̀ lẹ̀ ẹ́ túbọ̀ máa nífẹ̀ẹ́ ara yín. Kí ni ò ní jẹ́ kẹ́yin méjèèjì ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí? (1 Kọ́r. 6:18) Ẹ má ṣe bára yín sọ̀sọkúsọ, ẹ má ṣe dá wà, ẹ má sì mutí yó. (Éfé. 5:3) Tẹ́ ò bá ṣọ́ra, àwọn nǹkan yìí lè mú kó ṣòro fún yín láti ṣe ohun tó tọ́, ó sì lè mú kẹ́ ẹ ṣèṣekúṣe. Torí náà, á dáa kẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ẹ̀ẹ́ máa ṣe àtohun tẹ́ ò ní ṣe. (Ka Òwe 22:3.) Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ran Dawit àti Almaz tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Etiópíà lọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà. Wọ́n sọ pé: “A máa ń wà pa pọ̀ níbi tí ọ̀pọ̀ èèyàn tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá wà. A máa ń rí i pé a kì í dá wà nínú mọ́tò tàbí nínú ilé. Ìyẹn ni ò jẹ́ ká ṣohun tí ò dáa.”

11. Kí ló yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ronú nípa ẹ̀ tí wọ́n bá fẹ́ pinnu bí wọ́n ṣe máa fìfẹ́ hàn síra wọn?

11 Ṣé àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lè fìfẹ́ hàn síra wọn? Bẹ́ ẹ bá ṣe túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ ara yín, kò sóhun tó burú níbẹ̀ tẹ́ ẹ bá ń fìfẹ́ hàn síra yín lọ́nà tó bójú mu. (Orin Sól. 1:2; 2:6) Àmọ́, tí ara yín bá lọ gbóná sódì, ó lè ṣòro láti kó ara yín níjàánu. Tẹ́ ò bá ṣọ́ra, ẹ lè ṣe ohun tínú Jèhófà ò dùn sí níbi tẹ́ ẹ ti ń fìfẹ́ hàn síra yín. (Òwe 6:27) Torí náà, gbàrà tẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà ló yẹ kẹ́ ẹ ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ́ ò ní máa ṣe tí Bíbélì sọ pé kò dáa.c (1 Tẹs. 4:3-7) Á dáa kẹ́yin méjèèjì bi ara yín pé: ‘Táwọn tó wà ládùúgbò wa bá rí i pé à ń fìfẹ́ hàn síra wa, ojú wo ni wọ́n á fi máa wò wá? Ṣé bá a ṣe ń fìfẹ́ hàn síra wa ò ní jẹ́ kó wu ọ̀kan nínú wa láti ṣèṣekúṣe?’

12. Tí èdèkòyédè bá wáyé láàárín ìwọ àtẹni tó ò ń fẹ́ sọ́nà, kí ló yẹ kẹ́ ẹ ṣe?

12 Báwo lẹ ṣe lè yanjú èdèkòyédè? Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín yín ńkọ́? Ṣé ẹ̀yin méjèèjì máa wá gbà pé ẹ ò ní lè fẹ́ra yín? Kò yẹ kẹ́ ẹ gbà bẹ́ẹ̀ torí pé kò sí tọkọtaya tí èdèkòyédè kì í wáyé láàárín wọn. Tí ìgbéyàwó kan bá máa yọrí sí rere, ó gba pé káwọn méjèèjì máa bọ̀wọ̀ fúnra wọn, kí wọ́n sì máa yááfì àwọn nǹkan kan torí ẹnì kejì wọn. Torí náà, bẹ́ ẹ bá ṣe ń sapá tó láti yanjú àwọn ìṣòro tẹ́ ẹ ní nígbà tẹ́ ẹ̀ ń fẹ́ra yín sọ́nà ló máa pinnu bóyá ìgbéyàwó yín máa yọrí sí rere. Ó yẹ kẹ́yin méjèèjì bi ara yín pé: ‘Tí èdèkòyédè bá wáyé, ṣé a máa ń fara balẹ̀ yanjú ẹ̀, tá a sì máa ń bọ̀wọ̀ fúnra wa? Ṣé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń gbà pé òun láwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, tó sì ń sapá láti ṣàtúnṣe? Ṣé a tètè máa ń gbà tá a bá ṣohun tí ò dáa, ṣé a tètè máa ń tọrọ àforíjì, ṣé a sì tètè máa ń dárí ji ara wa?’ (Éfé. 4:31, 32) Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà lẹ kì í gbọ́ra yín yé, tẹ́ ẹ sì máa ń bára yín jiyàn, ó lè jẹ́ pé bí ẹ̀ẹ́ ṣe máa bá a yí nìyẹn lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ṣègbéyàwó. Torí náà, tó o bá rí i pé kì í ṣe ẹni tó yẹ kó o fẹ́ nìyẹn, ohun tó máa dáa jù fẹ́yin méjèèjì ni pé kẹ́ ẹ má fẹ́ra yín mọ́.d

13. Kí ló máa jẹ́ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà mọ bó ṣe yẹ kó pẹ́ tó kí wọ́n tó ṣègbéyàwó?

13 Tó o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, báwo ló ṣe yẹ kó pẹ́ tó? Tá ò bá ronú dáadáa ká tó ṣèpinnu, lọ́pọ̀ ìgbà ìgbẹ̀yìn ẹ̀ kì í dáa. (Òwe 21:5) Torí náà, tẹ́ ẹ bá ń fẹ́ra yín sọ́nà, ó yẹ kẹ́ ẹ jẹ́ kó pẹ́ díẹ̀ kẹ́ ẹ lè túbọ̀ mọra yín dáadáa. Àmọ́ o, kò yẹ kẹ́ ẹ wá jẹ́ kó pẹ́ jù. Bíbélì tiẹ̀ sọ pé: “Ìrètí pípẹ́ máa ń mú ọkàn ṣàìsàn.” (Òwe 13:12) Bákan náà, bí ìfẹ́sọ́nà yín bá ṣe ń pẹ́ sí i, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa ṣòro fún yín láti yẹra fún ìṣekúṣe. (1 Kọ́r. 7:9) Dípò tí wàá fi máa ronú nípa bó ṣe pẹ́ tó tẹ́ ẹ ti ń fẹ́ra yín sọ́nà, á dáa kó o bi ara ẹ pé, ‘Kí ló kù tó yẹ kí n mọ̀ nípa ẹni yìí kí n lè pinnu ohun tí màá ṣe?’

BÁWO LÀWỌN ARÁ ÌJỌ ṢE LÈ RAN ÀWỌN TÓ Ń FẸ́RA SỌ́NÀ LỌ́WỌ́?

14. Kí làwọn ará ìjọ lè ṣe láti ran àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ́wọ́? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)

14 Tá a bá mọ àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà, báwo la ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́? A lè pè wọ́n wá jẹun nílé wa, ká ní kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wa nígbà ìjọsìn ìdílé tàbí ká jọ ṣeré jáde. (Róòmù 12:13) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, á jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ mọ ara wọn. Ṣé wọ́n fẹ́ kẹ́nì kan wà pẹ̀lú wọn tí wọ́n bá fẹ́ ríra tàbí ṣeré jáde? Ṣé o lè bá wọn ṣètò ọkọ̀ tí wọ́n bá fẹ́ jáde àbí kó o bá wọn ṣètò ibi tí wọ́n ti lè bára wọn sọ̀rọ̀ táwọn èèyàn á sì máa rí wọn? Tó o bá rí i pé wọ́n nílò àwọn nǹkan yìí, ṣé o lè ràn wọ́n lọ́wọ́? (Gál. 6:10) Arábìnrin Alicia tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ bí òun àti Aschwin ọkọ ẹ̀ ṣe mọyì ohun táwọn ará kan ṣe fún wọn. Ó sọ pé: “Inú wa dùn gan-an nígbà táwọn ará kan sọ fún wa pé a lè wá kí wọn tá a bá fẹ́ bára wa sọ̀rọ̀, àmọ́ kì í ṣe pé a máa dá wà o.” Táwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà bá ní kó o tẹ̀ lé àwọn lọ síbì kan, á dáa kó o ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ rí i pé o ò jìnnà sí wọn, kó o sì fòye mọ ìgbà tó yẹ kó o fún wọn láyè tí wọ́n bá fẹ́ bára wọn sọ̀rọ̀.—Fílí. 2:4.

Arákùnrin àti arábìnrin tó ń fẹ́ra sọ́nà wà níbi àpèjẹ kan. Wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀rọ̀.

Tó o bá mọ àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà, ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ (Wo ìpínrọ̀ 14-15)


15. Kí ni nǹkan míì táwọn ará ìjọ lè ṣe láti ran àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ́wọ́? (Òwe 12:18)

15 Ohun tá a bá sọ lè ran àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ́wọ́, ó sì lè ṣàkóbá fún wọn. Torí náà, nígbà míì á dáa ká má ṣe sọ nǹkan kan. (Ka Òwe 12:18.) Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ṣe wá bíi pé ká sọ fáwọn ẹlòmíì pé arákùnrin àti arábìnrin kan ti ń fẹ́ra, àmọ́ wọ́n lè fẹ́ kó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ló máa sọ fáwọn èèyàn. Kò yẹ ká máa sọ̀rọ̀ àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà káàkiri tàbí ká máa ṣàríwísí wọn lórí ọ̀rọ̀ tí ò kàn wá. (Òwe 20:19; Róòmù 14:10; 1 Tẹs. 4:11) Bákan náà, kò yẹ ká máa da ìbéèrè bo àwọn tó ń fẹ́ra, ká wá máa sọ pé ó yẹ kí wọ́n ti ṣègbéyàwó tàbí kí wọ́n má tíì ṣe é. Nígbà tí Arábìnrin Elise àti ọkọ ẹ̀ rántí nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra, wọ́n ní: “Inú wa kì í dùn táwọn kan bá ń bi wá nípa àwọn nǹkan tá a máa ṣe nígbà ìgbéyàwó wa tó sì jẹ́ pé a ò tíì sọ nǹkan kan fún wọn nípa ẹ̀.”

16. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbọ́ pé àwọn tó ń fẹ́ra wọn tẹ́lẹ̀ ò fẹ́ra mọ́?

16 Táwọn kan tó ń fẹ́ra sọ́nà bá sọ pé àwọn ò fẹ́ra mọ́ ńkọ́? Kò yẹ ká tojú bọ ọ̀rọ̀ náà tàbí ká gbè sẹ́yìn ẹnì kan. (1 Pét. 4:15) Bí àpẹẹrẹ, arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lea sọ pé: “Mo gbọ́ pé àwọn kan ti ń ṣòfófó nípa ìdí témi àti arákùnrin kan ò ṣe fẹ́ra mọ́, ọ̀rọ̀ yẹn sì dùn mí gan-an.” Bá a ṣe sọ lẹ́ẹ̀kan, táwọn tó ń fẹ́ra bá rí i pé àwọn ò ní lè fẹ́ra mọ́, ìyẹn ò sọ pé aláṣetì ni wọ́n. Ohun tíyẹn kàn fi hàn ni pé wọ́n mọra wọn dáadáa nígbà tí wọ́n ń fẹ́ra sọ́nà yẹn, ìyẹn sì jẹ́ kí wọ́n ṣe ìpinnu tó tọ́. Síbẹ̀, ìpinnu yẹn lè má jẹ́ kí inú wọn dùn, ó sì lè máa ṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bíi pé òun dá wà. Torí náà, ó yẹ ká wá bá a ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.—Òwe 17:17.

17. Kí ló yẹ káwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà máa ṣe?

17 Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ìgbà alárinrin làsìkò ìfẹ́sọ́nà, àmọ́ ó tún níṣòro tiẹ̀. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Kí n má parọ́, ó máa ń gba okun àti àkókò téèyàn bá ń fẹ́ra sọ́nà, àmọ́ ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.” Torí náà, tó o bá ń fẹ́ ẹnì kan sọ́nà, rí i pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti mọ ẹni náà dáadáa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá láyọ̀, ẹ̀yin méjèèjì á sì lè ṣèpinnu tó tọ́.

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń fẹ́ra sọ́nà?

  • Báwo làwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà ṣe lè mọ ara wọn dáadáa?

  • Báwo làwọn ará ìjọ ṣe lè ran àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ́wọ́?

ORIN 49 Bá A Ṣe Lè Mú Ọkàn Jèhófà Yọ̀

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

b Kó o lè mọ àwọn ìbéèrè míì tó yẹ kó o bi ara ẹ, wo ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, ojú ìwé 39-40.

c Kéèyàn máa fọwọ́ pa ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì wà lára ìṣekúṣe, ó sì máa gba pé káwọn alàgbà yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Kéèyàn máa fọwọ́ pa ọyàn ẹni tí kì í ṣe ìyàwó ẹ̀, kó máa sọ̀rọ̀ ìṣekúṣe lórí fóònù tàbí kó fi ránṣẹ́ sí ẹnì kan tún lè gba pé káwọn alàgbà yan ìgbìmọ̀ ìgbẹ́jọ́. Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ kan ló máa sọ bóyá wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀.

d Kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa ẹ̀, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ August 15, 1999.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́