ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 27
ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà
Ní Ìgboyà Bíi Sádókù
“Sádókù [jẹ́] ọ̀dọ́kùnrin kan tó lágbára, tó sì nígboyà.”—1 KÍRÓ. 12:28.
OHUN TÁ A MÁA KỌ́
A máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Sádókù ṣe jẹ́ onígboyà àti bá a ṣe lè fara wé e.
1-2. Ta ni Sádókù? (1 Kíróníkà 12:22, 26-28)
FOJÚ inú wo àwọn ọkùnrin tó ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogójì (340,000) tí wọ́n pé jọ láti fi Dáfídì jọba Ísírẹ́lì. Odindi ọjọ́ mẹ́ta ni wọ́n fi wà níbi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè nítòsí Hébúrónì, wọ́n ń bára wọn sọ̀rọ̀, inú wọn ń dùn, wọ́n ń kọrin ìyìn sí Jèhófà, ohùn wọn sì gba gbogbo agbègbè náà kan. (1 Kíró. 12:39) Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Sádókù wà láàárín èrò rẹpẹtẹ yẹn, àmọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ̀ ọ́n. Síbẹ̀ Jèhófà rí Sádókù, ó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó wà níbẹ̀. (Ka 1 Kíróníkà 12:22, 26-28.) Ta wá ni Sádókù?
2 Àlùfáà ni Sádókù, òun àti Àlùfáà Àgbà Ábíátárì ló sì jọ ń ṣiṣẹ́. Sádókù tún jẹ́ aríran tó lè mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, Ọlọ́run sì fún un ní ọgbọ́n tó ṣàrà ọ̀tọ̀. (2 Sám. 15:27) Àwọn èèyàn máa ń lọ sọ́dọ̀ Sádókù tí wọ́n bá fẹ́ gba ìmọ̀ràn tó dáa. Yàtọ̀ síyẹn, ó jẹ́ onígboyà. Torí náà nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgboyà tí Sádókù ní.
3. (a) Kí nìdí tó fi yẹ káwa tá à ń jọ́sìn Jèhófà nígboyà? (b) Kí la máa sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Sátánì túbọ̀ ń gbógun ti àwa èèyàn Ọlọ́run. (1 Pét. 5:8) Ó yẹ ká nígboyà bá a ṣe ń dúró de ìgbà tí Jèhófà máa pa Sátánì àti ayé burúkú yìí run. (Sm. 31:24) Torí náà ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mẹ́ta tá a lè ṣe, ká lè nígboyà bíi Sádókù.
FARA MỌ́ ÌJỌBA ỌLỌ́RUN
4. Kí nìdí tó fi yẹ káwa èèyàn Jèhófà nígboyà ká lè fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
4 Àwa èèyàn Jèhófà fara mọ́ Ìjọba Ọlọ́run tọkàntọkàn, àmọ́ ó máa ń gba ìgboyà láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Mát. 6:33) Bí àpẹẹrẹ, nínú ayé burúkú yìí, ó gba ìgboyà ká tó lè máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà, ká sì máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (1 Tẹs. 2:2) Bákan náà, àwọn èèyàn túbọ̀ ń kórìíra ara wọn nínú ayé yìí, wọ́n sì ń bára wọn jà nítorí ọ̀rọ̀ òṣèlú, torí náà ó gba ìgboyà láti má ṣe dá sọ́rọ̀ òṣèlú. (Jòh. 18:36) Torí pé àwa èèyàn Jèhófà kọ̀ jálẹ̀ tá ò dá sọ́rọ̀ òṣèlú, tá ò sì ṣiṣẹ́ ológun, ọ̀pọ̀ lára wa ló ti pàdánù àwọn nǹkan tó ń mówó wọlé fún wa, ọ̀pọ̀ lára wa ni wọ́n fìyà jẹ, tí wọ́n sì jù sẹ́wọ̀n.
Táwọn èèyàn bá ń sọ̀rọ̀ òṣèlú, kí ni wàá ṣe? (Wo ìpínrọ̀ 4)
5. Kí nìdí tó fi yẹ kí Sádókù nígboyà kó lè ti Dáfídì lẹ́yìn?
5 Kì í ṣe torí kí Sádókù lè bá Dáfídì yọ̀ nígbà tí wọ́n fẹ́ fi jọba nìkan ló ṣe lọ sí Hébúrónì. Nígbà tó ń lọ, ó kó àwọn nǹkan ìjà dání, ó sì ṣe tán láti jà torí pé tọkàntọkàn ló fi ń ti Dáfídì lẹ́yìn. (1 Kíró. 12:38) Ó ti gbára dì láti tẹ̀ lé Dáfídì lọ sójú ogun, kó sì gba Ísírẹ́lì lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá. Sádókù lè má mọ bí wọ́n ṣe ń jà dáadáa, síbẹ̀ ó nígboyà gan-an.
6. Báwo ni ìgboyà tí Dáfídì ní ṣe jẹ́ kí Sádókù náà nígboyà? (Sáàmù 138:3)
6 Ibo ni àlùfáà Sádókù ti kọ́ ìgboyà? Àwọn ọkùnrin alágbára tí wọ́n nígboyà ló ń bá rìn. Ó dájú pé ó ti kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, torí pé Dáfídì nígboyà tó sì máa “ń kó Ísírẹ́lì jáde ogun,” gbogbo Ísírẹ́lì fẹ́ kó di ọba. (1 Kíró. 11:1, 2) Gbogbo ìgbà ni Dáfídì máa ń gbára lé Jèhófà tó bá fẹ́ lọ bá àwọn ọ̀tá jà. (Sm. 28:7; ka Sáàmù 138:3.) Àwọn èèyàn míì wà tí Sádókù kọ́ ìgboyà lára wọn, irú bíi Jèhóádà pẹ̀lú Bẹnáyà ọmọ ẹ̀ tó jẹ́ akíkanjú jagunjagun àtàwọn ọkùnrin méjìlélógún (22) tí wọ́n jẹ́ olórí ẹ̀yà Ísírẹ́lì tí wọ́n rọ̀gbà yí Dáfídì ká. (1 Kíró. 11:22-25; 12:26-28) Gbogbo àwọn ọkùnrin yìí ló fara mọ́ ọn pé kí Dáfídì jọba.
7. (a) Àwọn wo ló nígboyà lóde òní tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn? (b) Kí lo kọ́ lára Arákùnrin Nsilu nínú fídíò yẹn?
7 Tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn èèyàn Jèhófà tó nígboyà tí wọ́n sì fara mọ́ àkóso ẹ̀, a máa nígboyà, ìgbàgbọ́ wa á sì lágbára. Jésù Kristi Ọba wa ò gbà nígbà tí wọ́n fúngun mọ́ ọn pé kó lọ́wọ́ nínú òṣèlú ayé tí Sátánì ń darí yìí. (Mát. 4:8-11; Jòh. 6:14, 15) Gbogbo ìgbà ló gbára lé Jèhófà, tó sì máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó fún òun lókun láti ṣe ohun tó tọ́. Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì ti pinnu pé àwọn ò ní dá sọ́rọ̀ òṣèlú. Tó o bá lọ sórí ìkànnì jw.org, wàá rí àwọn ìrírí wọn níbẹ̀, o sì lè ka díẹ̀ lára wọn.a
MÁA RAN ÀWỌN ARÁ LỌ́WỌ́
8. Ìgbà wo ló yẹ káwọn alàgbà nígboyà kí wọ́n lè ran àwọn ará lọ́wọ́?
8 Ó máa ń wu àwa èèyàn Jèhófà láti ran ara wa lọ́wọ́. (2 Kọ́r. 8:4) Àmọ́ nígbà míì, ó gba ìgboyà ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ogun kan bẹ́ sílẹ̀, àwọn alàgbà tó wà lágbègbè yẹn rí i pé ó yẹ kí wọ́n fún àwọn ará níṣìírí, kí wọ́n fún wọn ní Bíbélì àtàwọn ìwé ètò Ọlọ́run, kí wọ́n sì pèsè oúnjẹ, aṣọ àti ibùgbé fún wọn. Torí pé àwọn alàgbà nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, wọ́n fẹ̀mí ara wọn wewu kí wọ́n lè pèsè gbogbo ohun tí wọ́n nílò. (Jòh. 15:12, 13) Ohun tí wọ́n ṣe yìí fi hàn pé wọ́n nígboyà bíi Sádókù.
9. Bí 2 Sámúẹ́lì 15:27-29 ṣe sọ, kí ni Dáfídì sọ fún Sádókù pé kó ṣe? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
9 Dáfídì wà nínú ewu. Ábúsálómù ọmọ ẹ̀ fẹ́ pa á kó lè gbàjọba. (2 Sám. 15:12, 13) Torí náà, ó máa gba pé kí Dáfídì fi Jerúsálẹ́mù sílẹ̀ kíákíá! Ló bá pe àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ dìde, ẹ sì jẹ́ kí a sá lọ, nítorí kò sí ìkankan lára wa tó máa bọ́ lọ́wọ́ Ábúsálómù!” (2 Sám. 15:14) Nígbà tí Dáfídì àtàwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ ń sá lọ, ó rí i pé ó yẹ kí ẹnì kan dúró sí Jerúsálẹ́mù kó lè máa sọ nǹkan tí Ábúsálómù fẹ́ ṣe fún òun. Torí náà, ó ní kí Sádókù àtàwọn àlùfáà yòókù dúró sílùú, kí wọ́n lè máa sọ ohun tó ń lọ fóun. (Ka 2 Sámúẹ́lì 15:27-29.) Èyí gba pé kí wọ́n ṣọ́ra gan-an. Ohun tí Dáfídì ní kí àwọn àlùfáà yẹn ṣe léwu, kódà ẹ̀mí wọn lè lọ sí i. Ábúsálómù máa ń gbéra ga, ó máa ń gbẹ̀san, ẹlẹ́tàn sì ni. Torí náà, ẹ wo ohun tó máa ṣe fún Sádókù àtàwọn àlùfáà tó kù ká ní ó mọ̀ pé wọ́n ń ṣe amí fún Dáfídì, tí wọ́n sì ń dáàbò bò ó!
Iṣẹ́ tí Dáfídì rán Sádókù léwu gan-an (Wo ìpínrọ̀ 9)
10. Kí ni Sádókù àtàwọn àlùfáà tó kù ṣe láti dáàbò bo Dáfídì?
10 Dáfídì àti Sádókù pẹ̀lú Húṣáì ọ̀rẹ́ ẹ̀ tó fọkàn tán forí korí kí wọ́n lè mọ ohun tí wọ́n máa ṣe. (2 Sám. 15:32-37) Lẹ́yìn náà, Húṣáì ṣe ohun tí wọ́n sọ. Ó díbọ́n bíi pé Ábúsálómù lòun fara mọ́, Ábúsálómù sì fọkàn tán an, lẹ́yìn náà Húṣáì fún un nímọ̀ràn nípa bó ṣe máa bá Dáfídì jà, ìyẹn ló jẹ́ kí Dáfídì láǹfààní láti múra sílẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn náà, Húṣáì sọ ohun tí Ábúsálómù fẹ́ ṣe fún Sádókù àti Ábíátárì. (2 Sám. 17:8-16) Àwọn ọkùnrin méjì yìí wá ránṣẹ́ sí Dáfídì. (2 Sám. 17:17) Jèhófà ran Sádókù àtàwọn àlùfáà tó kù lọ́wọ́ láti dáàbò bo Dáfídì.—2 Sám. 17:21, 22.
11. Báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi Sádókù nígbà tá a bá fẹ́ ran àwọn ará lọ́wọ́?
11 Táwọn ará wa bá níṣòro tó sì gba pé ká ràn wọ́n lọ́wọ́, báwo la ṣe lè jẹ́ onígboyà bíi Sádókù? (1) Máa ṣe ohun tí ètò Ọlọ́run sọ. Nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ onígbọràn, ká lè wà níṣọ̀kan. Máa ṣe ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì sọ. (Héb. 13:17) Látìgbàdégbà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ máa ṣàyẹ̀wò ètò tí wọ́n ṣe láti múra sílẹ̀ de àjálù, kí wọ́n sì máa ṣàyẹ̀wò ìtọ́sọ́nà ètò Ọlọ́run nípa ohun tí wọ́n máa ṣe tí àjálù bá ṣẹlẹ̀. (1 Kọ́r. 14:33, 40) (2) Jẹ́ onígboyà, àmọ́ máa ṣọ́ra. (Òwe 22:3) Ronú dáadáa kó o tó ṣe ohunkóhun. Má ṣe ohun tó máa kó ẹ sínú ewu. (3) Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Rántí pé Jèhófà ò fẹ́ kí ohunkóhun ṣe ìwọ àtàwọn ará. Torí náà, Jèhófà máa dáàbò bò ẹ́ kó o lè ran àwọn ará lọ́wọ́.
12-13. Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Viktor àti Vitalii? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
12 Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Arákùnrin Viktor àti Arákùnrin Vitalii tí wọ́n jẹ́ alàgbà. Wọ́n máa ń gbé oúnjẹ àti omi lọ fáwọn ará ní Ukraine nígbà tí wọ́n níṣòro. Viktor sọ pé: “Kò síbi tá ò wá oúnjẹ dé. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń dé ibi tí wọ́n ti ń yìnbọn. Arákùnrin kan kó àwọn oúnjẹ tó tọ́jú pa mọ́ sínú ilé ẹ̀ fún wa. Ohun tó fún wa yìí jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àwọn ará rí oúnjẹ jẹ fúngbà díẹ̀. Lọ́jọ́ tá à ń kó oúnjẹ náà sínú ọkọ̀ wa, wọ́n ju àdó olóró kan sílẹ̀, ibẹ̀ sì jẹ́ nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) síbi tá a wà. Jálẹ̀ ọjọ́ yẹn, ńṣe ni mò ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n nígboyà láti ran àwọn ará lọ́wọ́.”
13 Vitalii sọ pé: “Ó gba ìgboyà gan-an ká tó lè ṣe ohun tá a ṣe yẹn. Wákàtí méjìlá (12) gbáko ni mo fi rìnrìn àjò mi àkọ́kọ́. Mo gbàdúrà sí Jèhófà jálẹ̀ ìrìn àjò náà.” Vitalii nígboyà, àmọ́ ó tún ń ṣọ́ra ẹ̀. Ó sọ pé: “Léraléra ni mò ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún mi lọ́gbọ́n, kí n sì tún mọ̀wọ̀n ara mi. Àwọn ọ̀nà tí ìjọba fọwọ́ sí pé èèyàn lè wakọ̀ gbà nìkan ni mò ń gbà. Ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára nígbà tí mo rí báwọn ará ṣe ń ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan. Wọ́n ń bá wa kó àwọn nǹkan tó lè dí wa lọ́wọ́ kúrò lójú ọ̀nà. Wọ́n máa ń bá wa já ẹrù tá a kó wá fún wọn, wọ́n máa ń bá wa kó ẹrù sínú ọkọ̀, wọ́n máa ń fún wa lóúnjẹ, wọ́n sì máa ń ṣètò ibi tá a máa sùn.”
Ní ìgboyà kó o lè ran àwọn ará lọ́wọ́ lásìkò ewu, síbẹ̀ ó yẹ kó o ṣọ́ra (Wo ìpínrọ̀ 12-13)
JẸ́ OLÓÒÓTỌ́ SÍ JÈHÓFÀ
14. Báwo ló ṣe máa ń rí lára wa tí ẹni tá a nífẹ̀ẹ́ bá fi Jèhófà sílẹ̀?
14 Ọ̀kan lára ìṣòro tó le jù tó lè dé bá wa ni kí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wa tímọ́tímọ́ fi Jèhófà sílẹ̀. (Sm. 78:40; Òwe 24:10) Bí ẹni náà bá ṣe sún mọ́ wa tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa nira fún wa tó láti fara da ìṣòro náà. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí tó sì dùn ẹ́ gan-an, mọ̀ dájú pé àpẹẹrẹ Sádókù máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ torí ó ti fara da irú ìṣòro yẹn rí.
15. Kí nìdí tí Sádókù fi gbọ́dọ̀ nígboyà kó lè jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà? (1 Àwọn Ọba 1:5-8)
15 Sádókù jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà tí Ábíátárì ọ̀rẹ́ ẹ̀ tímọ́tímọ́ di ọ̀dàlẹ̀. Ìgbà tá à ń sọ yìí jẹ́ àsìkò tí ìjọba Dáfídì ń parí lọ. Nígbà tí Dáfídì wà lórí ibùsùn, tí ò sì ní pẹ́ kú, Ádóníjà ọmọ ẹ̀ fẹ́ fipá gbàjọba, bẹ́ẹ̀ sì rèé Jèhófà ti sọ pé Sólómọ́nì ló máa di ọba. (1 Kíró. 22:9, 10) Bí Ábíátárì àti Ádóníjà ṣe lẹ̀dí àpò pọ̀ nìyẹn. (Ka 1 Àwọn Ọba 1:5-8.) Ohun tí Ábíátárì ṣe yìí fi hàn pé ó dalẹ̀ Dáfídì, kò sì tún jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ó máa dun Sádókù gan-an. Ó ti ju ogójì (40) ọdún lọ tóun àti Ábíátárì ti jọ ń ṣiṣẹ́ àlùfáà. (2 Sám. 8:17) Wọ́n ti jọ bójú tó “Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.” (2 Sám. 15:29) Bákan náà, látìgbà tí Dáfídì ti di ọba ni Sádókù àti Ábíátárì ti ń ràn án lọ́wọ́, wọ́n sì jọ ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan míì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.—2 Sám. 19:11-14.
16. Kí ló mú kí Sádókù jẹ́ olóòótọ́?
16 Sádókù jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bó tiẹ̀ jẹ́ pé Ábíátárì ò jẹ́ olóòótọ́, tó sì tún dalẹ̀ Dáfídì. Àmọ́, Dáfídì fọkàn tán Sádókù pé kò ní dalẹ̀ òun. Nígbà tí àṣírí Ádóníjà tú, Sádókù, Nátánì àti Bẹnáyà ni Dáfídì sọ fún pé kí wọ́n lọ fòróró yan Sólómọ́nì láti di ọba. (1 Ọba 1:32-34) Torí pé Sádókù ń wà pẹ̀lú Nátánì àtàwọn míì tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Dáfídì, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà, ìyẹn fún un níṣìírí, ó sì mú kó jẹ́ olóòótọ́. (1 Ọba 1:38, 39) Torí náà, nígbà tí Sólómọ́nì di ọba, ó “yan àlùfáà Sádókù sí ipò Ábíátárì.”—1 Ọba 2:35.
17. Báwo lo ṣe lè fara wé Sádókù tí ẹni tó o nífẹ̀ẹ́ bá fi Jèhófà sílẹ̀?
17 Báwo lo ṣe lè fara wé Sádókù? Tí ẹni tó o nífẹ̀ẹ́ bá fi Jèhófà sílẹ̀, pinnu pé wàá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Jóṣ. 24:15) Jèhófà máa fún ẹ lókun àti ìgboyà kó o lè ṣe ohun tó tọ́. Máa gbàdúrà sí i, má sì jìnnà sáwọn ará tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. Mọ̀ dájú pé Jèhófà mọyì bó o ṣe jẹ́ olóòótọ́, ó sì máa san èrè fún ẹ.—2 Sám. 22:26.
18. Kí lo kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Marco àti Sidse ìyàwó ẹ̀?
18 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Marco àti ìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Sidse. Àwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì tó ti dàgbà fi Jèhófà sílẹ̀. Marco sọ pé: “Àwa òbí máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wa gan-an látọjọ́ tá a ti bí wọn. Gbogbo ohun tó bá gbà làwa òbí máa ń ṣe láti dáàbò bò wọ́n. Pẹ̀lú gbogbo wàhálà yìí, táwọn ọmọ náà bá fi Jèhófà sílẹ̀, ó máa ń dùn wá gan-an.” Ó tún sọ pé: “Àmọ́ Jèhófà ò fi wá sílẹ̀. Bó ṣe ràn wá lọ́wọ́ ni pé tí mo bá rẹ̀wẹ̀sì, ìyàwó mi máa ń fún mi lókun, nígbà tí ìyàwó mi bá sì rẹ̀wẹ̀sì, èmi náà máa ń fún un lókun.” Sidse wá sọ pé: “Ká ní Jèhófà ò fún wa lókun ni, kò ní rọrùn fún wa láti fara dà á. Ńṣe ló ń ṣe mí bíi pé èmi ni mo fa ohun tó ṣẹlẹ̀, torí náà mo sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára mi fún Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni arábìnrin kan tá a ti ríra fún ọ̀pọ̀ ọdún wá mi wá sípàdé, ó fọwọ́ kọ́ mi lọ́rùn, ó ń wojú mi, ó sì sọ pé: ‘Sidse, ìwọ kọ́ lo fa ohun tó ṣẹlẹ̀!’ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ gan-an, ó sì jẹ́ kí n máa láyọ̀ bí mo ṣe ń sìn ín.”
19. Kí lo pinnu pé wàá máa ṣe?
19 Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwa tá à ń jọ́sìn ẹ̀ nígboyà bíi Sádókù. (2 Tím. 1:7) Àmọ́, kò fẹ́ ká gbára lé ara wa. Ó fẹ́ ká gbẹ́kẹ̀ lé òun. Torí náà, tó o bá níṣòro tó gba pé kó o nígboyà, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó máa fún ẹ nígboyà bíi ti Sádókù!—1 Pét. 5:10.
ORIN 126 Wà Lójúfò, Dúró Gbọn-in, Jẹ́ Alágbára
a Wo fídíò Ìdí Tí Àwa Kristẹni Tòótọ́ Fi Nílò Ìgboyà—Láti Má Ṣe Dá sí Ọ̀rọ̀ Òṣèlú lórí ìkànnì jw.org.