OHUN TÓ O LÈ KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍPA Ẹ̀
Máa Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀ Kó O Lè Wà Lójúfò
Ka Dáníẹ́lì 9:1-19 kó o lè mọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀.
Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè kan nípa ohun tó ò ń kà. Àwọn nǹkan wo ló ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹlẹ̀, báwo ló sì ṣe kan Dáníẹ́lì? (Dán. 5:29–6:5) Ká sọ pé ìwọ ni Dáníẹ́lì, báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe máa rí lára ẹ?
Kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀. “Àwọn ìwé mímọ́” wo ló ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì kà? (Dán. 9:2, àlàyé ìsàlẹ̀; w11 1/1 22 ¶2) Kí nìdí tí Dáníẹ́lì fi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ àti tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì? (Léf. 26:39-42; 1 Ọba 8:46-50; dp 182-184) Kí la rí nínú àdúrà Dáníẹ́lì tó jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa?—Dán. 9:11-13.
Wá àwọn ẹ̀kọ́ inú ẹ̀. Bi ara ẹ pé:
‘Báwo ni mi ò ṣe ní jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ń lọ nínú ayé pín ọkàn mi níyà?’ (Míkà 7:7)
‘Àǹfààní wo ni mo máa rí tí mo bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jinlẹ̀ bíi ti Dáníẹ́lì?’ (w04 8/1 12 ¶17)
‘Àwọn nǹkan wo ni mo lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀ tó máa jẹ́ kí n lè “máa ṣọ́nà”?’ (Mát. 24:42, 44; w12 8/15 5 ¶7-8)