ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ 33
Kẹ́kọ̀ọ́ Lára Dáníẹ́lì
“O ṣeyebíye gan-an.”—DÁN. 9:23.
ORIN 73 Fún Wa Ní Ìgboyà
OHUN TÁ A MÁA JÍRÒRÒa
1. Kí làwọn ará Bábílónì rí lára wòlíì Dáníẹ́lì tó wú wọn lórí?
Ọ̀DỌ́ ni wòlíì Dáníẹ́lì nígbà táwọn ará Bábílónì mú un nígbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sílùú Bábílónì. Àmọ́, ohun táwọn ìjòyè Bábílónì rí lára Dáníẹ́lì wú wọn lórí. Wọ́n rí i pé Dáníẹ́lì ‘kò ní àbùkù kankan, ìrísí ẹ̀ dáa,’ ilé ọlá ló sì ti wá. (1 Sám. 16:7) Àwọn nǹkan tí wọ́n rí lára Dáníẹ́lì yìí ló jẹ́ káwọn ará Bábílónì dá a lẹ́kọ̀ọ́ kó lè máa ṣiṣẹ́ láàfin.—Dán. 1:3, 4, 6.
2. Irú ojú wo ni Jèhófà fi wo Dáníẹ́lì? (Ìsíkíẹ́lì 14:14)
2 Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì, kì í ṣe torí pé ó rẹwà tàbí torí ipò tó wà láàfin, àmọ́ torí pé ó níwà ọmọlúàbí. Kódà, ó ṣeé ṣe kó ku díẹ̀ kí Dáníẹ́lì pé ọmọ ogún (20) ọdún tàbí kó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lógún ọdún nígbà tí Jèhófà dárúkọ ẹ̀ pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ ẹ̀, irú bíi Nóà àti Jóòbù tí wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ ọdún bá Ọlọ́run rìn, tí wọ́n sì lórúkọ rere lọ́dọ̀ ẹ̀. (Jẹ́n. 5:32; 6:9, 10; Jóòbù 42:16, 17; ka Ìsíkíẹ́lì 14:14.) Jèhófà ò yéé nífẹ̀ẹ́ Dáníẹ́lì, kódà ó ṣe bẹ́ẹ̀ jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀.—Dán. 10:11, 19.
3. Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ méjì tí Dáníẹ́lì ní tó jẹ́ kó ṣeyebíye lójú Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a máa sọ̀rọ̀ nípa ànímọ́ kọ̀ọ̀kan àtìgbà tó fi àwọn ànímọ́ náà hàn. Lẹ́yìn náà, a máa sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ kí Dáníẹ́lì ní àwọn ànímọ́ yẹn. Paríparí ẹ̀, a máa sọ̀rọ̀ nípa báwa náà ṣe lè fara wé e. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀dọ́ la dìídì kọ àpilẹ̀kọ yìí fún, gbogbo wa la lè kẹ́kọ̀ọ́ lára Dáníẹ́lì.
NÍGBOYÀ BÍI TI DÁNÍẸ́LÌ
4. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun nígboyà? Sọ àpẹẹrẹ kan.
4 Ẹ̀rù lè ba ẹni tó nígboyà, àmọ́ ìyẹn ò ní kó má ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀dọ́kùnrin tó nígboyà gan-an ni Dáníẹ́lì. Ẹ jẹ́ ká wo ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí Dáníẹ́lì fi hàn pé òun nígboyà. Ìgbà àkọ́kọ́ ṣeé ṣe kó jẹ́ nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run. Nebukadinésárì ọba Bábílónì lá àlá kan tó bani lẹ́rù. Nínú àlá náà, ó rí ère ńlá kan. Ó sọ pé òun máa pa gbogbo àwọn amòye òun títí kan Dáníẹ́lì tí wọn ò bá lè sọ àlá náà, kí wọ́n sì túmọ̀ ẹ̀. (Dán. 2:3-5) Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ gbé ìgbésẹ̀ kíákíá, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa kú. Torí náà ó “wọlé, ó sì ní kí ọba yọ̀ǹda àkókò fún òun kóun lè sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.” (Dán. 2:16) Ẹ ò rí i pé ohun tó ṣe yìí gba ìgboyà àti ìgbàgbọ́! Kò sí àkọsílẹ̀ kankan nínú Bíbélì tó fi hàn pé Dáníẹ́lì ti túmọ̀ àlá rí. Torí náà, ó sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ tórúkọ wọn ń jẹ́ Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígòb pé “kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run fún àánú nípa àṣírí yìí.” (Dán. 2:18) Jèhófà sì dáhùn àdúrà wọn. Ó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ láti túmọ̀ àlá Nebukadinésárì, ìyẹn ni ò sì jẹ́ kí Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ kú.
5. Nǹkan míì wo ló ṣẹlẹ̀ tó jẹ́ ká mọ̀ pé Dáníẹ́lì nígboyà?
5 Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì sọ ìtumọ̀ ère inú àlá yẹn, ohun míì tún ṣẹlẹ̀ tó gba pé kó nígboyà gan-an. Ọba Nebukadinésárì tún lá àlá míì tó bà á lẹ́rù. Nínú àlá yẹn, ó rí igi ńlá kan. Àmọ́ Dáníẹ́lì fìgboyà sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba. Yàtọ̀ síyẹn, ó sọ fún ọba pé ó máa ya wèrè, kò sì ní lè ṣàkóso fún àkókò kan. (Dán. 4:25) Ọ̀rọ̀ tí Dáníẹ́lì sọ yìí lè mú kí Ọba Nebukadinésárì gbà pé ọ̀tá òun ni Dáníẹ́lì, kó sì pa á. Àmọ́ Dáníẹ́lì fìgboyà sọ ìtumọ̀ àlá náà fún ọba.
6. Kí ló ṣeé ṣe kó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ tó fi nígboyà?
6 Kí ló ṣeé ṣe kó ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ tó fi nígboyà jálẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀? Ó dájú pé nígbà tó wà lọ́mọdé, ó kẹ́kọ̀ọ́ lára àpẹẹrẹ rere ìyá àti bàbá ẹ̀. Kò sí àní-àní pé àwọn òbí Dáníẹ́lì ṣègbọràn sí òfin tí Jèhófà fún àwọn òbí ní Ísírẹ́lì, ó sì dájú pé wọ́n fi kọ́ àwọn ọmọ wọn. (Diu. 6:6-9) Kì í ṣe pé Dáníẹ́lì mọ àwọn Òfin tí Jèhófà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ni, irú bí Òfin Mẹ́wàá, ó tún mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa òfin náà. Bí àpẹẹrẹ, ó mọ ohun tó yẹ kó jẹ àtohun tí ò yẹ kó jẹ.c (Léf. 11:4-8; Dán. 1:8, 11-13) Dáníẹ́lì tún mọ ìtàn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà àtohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn torí pé wọn ò tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. (Dán. 9:10, 11) Àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Dáníẹ́lì jẹ́ kó dá a lójú pé ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, Jèhófà àtàwọn áńgẹ́lì ẹ̀ alágbára máa ran òun lọ́wọ́.—Dán. 2:19-24; 10:12, 18, 19.
Ohun tó jẹ́ kí Dáníẹ́lì nígboyà ni pé ó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa ń gbàdúrà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà (Wo ìpínrọ̀ 7)
7. Nǹkan míì wo ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ tó fi nígboyà? (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.)
7 Dáníẹ́lì kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Ọlọ́run títí kan àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Jeremáyà. Àwọn ẹ̀kọ́ tí Dáníẹ́lì kọ́ yìí ló jẹ́ kó fòye mọ̀ pé àkókò táwọn Júù máa lò nígbèkùn Bábílónì máa tó pé. (Dán. 9:2) Bí Dáníẹ́lì ṣe ń rí i táwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń ṣẹ mú kó túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì jẹ́ kó rí i pé àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run máa ń nígboyà gan-an. (Fi wé Róòmù 8:31, 32, 37-39.) Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Dáníẹ́lì máa ń gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run déédéé. (Dán. 6:10) Ó jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀ fún Jèhófà, ó sọ bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀ fún un, ó sì ní kó ran òun lọ́wọ́. (Dán. 9:4, 5, 19) Èèyàn bíi tiwa ni Dáníẹ́lì, a ò bí ìgboyà mọ́ ọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló kọ́ béèyàn ṣe ń nígboyà. Ohun tó sì ràn án lọ́wọ́ ni pé ó máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń gbàdúrà, ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
8. Kí ló máa jẹ́ ká nígboyà?
8 Kí ló yẹ ká ṣe ká lè nígboyà? Àwọn òbí wa lè rọ̀ wá pé ká nígboyà, àmọ́ a ò lè jogún ìgboyà látọ̀dọ̀ wọn. Tẹ́nì kan bá fẹ́ nígboyà, ṣe ló máa kọ́ bó ṣe máa ní in. Bó o ṣe lè nígboyà ni pé kó o máa wo ohun tẹ́ni tó nígboyà ń ṣe, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ lára ẹ̀. Lọ́nà kan náà, tá a bá fẹ́ kọ́ ìgboyà, ó yẹ ká máa wo báwọn èèyàn ṣe ń fi ànímọ́ yìí hàn, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ lára wọn. Torí náà, kí la rí kọ́ lára Dáníẹ́lì? Ohun tá a rí kọ́ ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa. Ó yẹ ká máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, ká máa sọ bí nǹkan ṣe rí lára wa fún un kí àjọṣe wa lè túbọ̀ lágbára. Ó tún yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé e, kó sì dá wa lójú pé ó máa ràn wá lọ́wọ́. Tí nǹkan kan bá wá dán wa wò, àá lè fìgboyà kojú ẹ̀.
9. Tá a bá nígboyà, àǹfààní wo la máa rí?
9 Ọ̀pọ̀ àǹfààní la máa rí tá a bá nígboyà. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ben. Ilé ìwé kan lórílẹ̀-èdè Jámánì ló lọ. Yàtọ̀ sí Ben, gbogbo wọn ló gbà pé Ọlọ́run kọ́ ló dá àwọn nǹkan, wọ́n sì gbà pé ìtàn àròsọ lásán ni Bíbélì sọ nípa ẹ̀. Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní kí Ben dúró síwájú kíláàsì, kó sì ṣàlàyé ìdí tó fi gbà pé Ọlọ́run ló dá gbogbo nǹkan tó wà láyé. Ben fìgboyà ṣàlàyé ohun tó gbà gbọ́. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Ben sọ pé: “Olùkọ́ kíláàsì wa fara balẹ̀ gbọ́ mi, ó ṣe ẹ̀dà ìwé tí mo fi ṣàlàyé ohun tí mo sọ, ó sì pín in fún gbogbo ọmọ kíláàsì mi.” Kí làwọn ọmọ kíláàsì Ben wá ṣe? Ben sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára wọn ló fetí sí mi dáadáa, wọ́n sì sọ pé àwọn fẹ́ràn àlàyé tí mo ṣe.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ben jẹ́ ká rí i pé àwọn èèyàn máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn tó nígboyà. Wọ́n tún lè mú káwọn èèyàn wá mọ Jèhófà. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká nígboyà!
JẸ́ ADÚRÓṢINṢIN BÍI TI DÁNÍẸ́LÌ
10. Kí ni ìdúróṣinṣin?
10 Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ Hébérù náà “adúróṣinṣin” tàbí “ìfẹ́ tí kì í yẹ̀” tó bá ń sọ nípa bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ olóòótọ́ sáwọn ìránṣẹ́ ẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí kan náà la máa ń lò tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa báwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (2 Sám. 9:6, 7) Àmọ́, ká tó lè jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa gba àkókò. Ẹ jẹ́ ká wo bí Dáníẹ́lì ṣe túbọ̀ fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin.
Torí pé Dáníẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó rán áńgẹ́lì rẹ̀ kó wá gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún (Wo ìpínrọ̀ 11)
11. Báwo ni Dáníẹ́lì ṣe fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin nígbà tó ti darúgbó? (Wo àwòrán iwájú ìwé.)
11 Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ sí Dáníẹ́lì tó gba pé kó jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àmọ́, ó ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún (90) ọdún nígbà tí àdánwò tó le jù dé bá a. Lásìkò yẹn, àwọn ará Mídíà àti Páṣíà ti ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, Ọba Dáríúsì ló sì ń ṣàkóso ìlú náà. Àwọn ìjòyè ọba kórìíra Dáníẹ́lì gan-an, wọn ò sì bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run tó ń sìn. Torí náà, wọ́n wá bí wọ́n ṣe máa fẹ̀sùn kan Dáníẹ́lì kí wọ́n lè pa á. Wọ́n ṣe òfin kan tí ọba fọwọ́ sí tó máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá Ọlọ́run tí Dáníẹ́lì ń sìn ló máa jẹ́ adúróṣinṣin sí àbí ọba. Ohun tí Dáníẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe kó lè fi hàn pé òun jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọba Dáríúsì bíi tàwọn yòókù ni pé kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí Jèhófà fún ọgbọ̀n (30) ọjọ́. Dípò kí Dáníẹ́lì ṣe ohun tí wọ́n sọ, Jèhófà ló jẹ́ adúróṣinṣin sí. Torí náà, wọ́n jù ú sínú ihò kìnnìún. Àmọ́ torí pé Dáníẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún. (Dán. 6:12-15, 20-22) Báwo làwa náà ṣe lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà bíi ti Dáníẹ́lì?
12. Kí ló ran Dáníẹ́lì lọ́wọ́ kó lè máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nìṣó?
12 Bá a ṣe sọ níṣàájú, ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà ló máa ń mú ká jẹ́ adúróṣinṣin. Dáníẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run gan-an. Ohun tó jẹ́ kí Dáníẹ́lì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ó máa ń ronú nípa àwọn ànímọ́ tí Jèhófà ní àti bó ṣe ń fi àwọn ànímọ́ yìí hàn. (Dán. 9:4) Dáníẹ́lì tún ronú nípa gbogbo nǹkan rere tí Jèhófà ti ṣe fún òun àtàwọn èèyàn ẹ̀, ó sì mọyì ẹ̀ gan-an.—Dán. 2:20-23; 9:15, 16.
Bíi ti Dáníẹ́lì, táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tọkàntọkàn, àá lè máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó (Wo ìpínrọ̀ 13)
13. (a) Kí ló lè mú kó ṣòro fáwọn ọ̀dọ́ wa láti jẹ́ adúróṣinṣin? Sọ àpẹẹrẹ kan. (Tún wo àwòrán tó wà fún ìpínrọ̀ yìí.) (b) Nínú fídíò yẹn, tí wọ́n bá bi ẹ́ pé kí nìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò fi fara mọ́ bíbá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀, kí lo máa sọ?
13 Bíi ti Dáníẹ́lì, àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ìlànà ẹ̀ làwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bá ṣe nǹkan pọ̀ lójoojúmọ́. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ máa ń kórìíra àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Àwọn míì máa ń halẹ̀ mọ́ àwọn ọ̀dọ́ wa kí wọ́n má bàa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Graeme ní Ọsirélíà. Àdánwò kan dé bá a nígbà tó wà nílé ẹ̀kọ́ girama. Olùkọ́ wọn bi gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì pé, kí ni wọ́n máa ṣe tí ọ̀rẹ́ wọn kan bá sọ fún wọn pé òun máa ń bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀? Olùkọ́ wọn wá sọ pé kí àwọn tó bá fara mọ́ ọn pé kí ọ̀rẹ́ wọn máa bá ẹ̀yà kan náà lò pọ̀ dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, káwọn tí ò sì fara mọ́ ọn dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ kejì. Graeme sọ pé: “Gbogbo àwọn ọmọ kíláàsì àti olùkọ́ wa ló fara mọ́ ọn. Èmi àti ọ̀dọ́kùnrin kan tá a jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ò fara mọ́ ọn.” Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ̀ bóyá Graeme máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Ó ní: “Ó lé ní wákàtí kan tí olùkọ́ wa fi kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ lọ́jọ́ yẹn, àmọ́ ńṣe ni gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń bú wa. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn. Mo sì fara balẹ̀ sọ ọ́, àmọ́ wọn ò fetí sí mi rárá.” Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rí lára Graeme? Ó sọ pé: “Kí n sòótọ́, inú mi ò dùn bí àwọn ọmọ kíláàsì mi ṣe fi mí ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ inú mi dùn gan-an torí pé mo jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, mo sì ṣàlàyé ohun tí mo gbà gbọ́ fún wọn.”d
14. Sọ ohun tó o lè ṣe táá mú kó o máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nìṣó.
14 Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an bíi ti Dáníẹ́lì, àá máa jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà nìṣó. Ohun tó máa jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ànímọ́ tó ní. Bí àpẹẹrẹ, a lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tó dá, ká sì ṣàṣàrò lórí ẹ̀. (Róòmù 1:20) Tó o bá fẹ́ kí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tó o ní fún Jèhófà túbọ̀ pọ̀ sí i, o lè ka àwọn àpilẹ̀kọ tó wà ní abala “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tàbí kó o wo àwọn fídíò tó wà níbẹ̀. O sì tún lè ka àlàyé tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Was Life Created? àti The Origin of Life—Five Questions Worth Asking. Ẹ gbọ́ ohun tí Arábìnrin Esther tó wá láti orílẹ̀-èdè Denmark sọ nípa àwọn ìwé méjì yìí. Ó ní: “Àlàyé tó wà nínú àwọn ìwé yẹn wọni lọ́kàn gan-an. Wọn ò sọ ohun tó o máa gbà gbọ́, àmọ́ wọ́n ṣàlàyé àwọn òótọ́ pọ́ńbélé kan tó máa jẹ́ kó o pinnu ohun tó o máa ṣe.” Arákùnrin Ben tá a sọ̀rọ̀ ẹ̀ níṣàájú sọ pé: “Àwọn ìwé yẹn jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára. Ó jẹ́ kó dá mi lójú pé Ọlọ́run ló dá àwọn nǹkan eléèémí.” Lẹ́yìn tó o bá ka àwọn ìwé yìí, ìwọ náà máa gbà pé òótọ́ ni Bíbélì sọ pé: “Jèhófà, Ọlọ́run wa, ìwọ ló tọ́ sí láti gba ògo àti ọlá àti agbára, torí ìwọ lo dá ohun gbogbo.”—Ìfi. 4:11.e
15. Kí ni nǹkan míì táá jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
15 Ohun míì táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ni pé ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù Ọmọ ẹ̀. Ohun tí arábìnrin ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Samira lórílẹ̀-èdè Jámánì ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Ìgbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù ni mo túbọ̀ mọ Jèhófà sí i.” Nígbà tí Samira wà ní kékeré, ó ṣòro fún un láti gbà pé Jèhófà lè jẹ́ ọ̀rẹ́ òun, kó sì nífẹ̀ẹ́ òun. Àmọ́, ohun tó kọ́ jẹ́ kó rí i pé Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn. Ó sọ pé: “Ohun tó jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ Jésù ni pé ara ẹ̀ yá mọ́ọ̀yàn, ó sì fẹ́ràn àwọn ọmọdé.” Bó ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jésù, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà sí i. Kí nìdí? Ó ní: “Díẹ̀díẹ̀ ló wá yé mi pé Jèhófà ni Jésù fìwà jọ, ìwà wọn sì bára mu. Mo wá rí i pé ọ̀kan lára ìdí tí Jèhófà fi rán Jésù wá sáyé ni pé ó fẹ́ káwa èèyàn túbọ̀ mọ ẹni tóun jẹ́.” (Jòh. 14:9) Tíwọ náà bá fẹ́ túbọ̀ mọ Jèhófà, o ò ṣe wáyè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Jésù? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wàá sì máa jẹ́ adúróṣinṣin nìṣó.
16. Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà? (Sáàmù 18:25; Míkà 6:8)
16 Táwọn méjì bá jẹ́ adúróṣinṣin síra wọn, ọ̀rẹ́ wọn máa wà pẹ́ títí. (Rúùtù 1:14-17) Ohun míì ni pé tí ẹnì kan bá jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, ọkàn ẹ̀ máa balẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jèhófà ṣèlérí pé òun máa jẹ́ adúróṣinṣin sáwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí òun. (Ka Sáàmù 18:25; Míkà 6:8.) Àbí ẹ ò rí nǹkan! Ó wu Ẹlẹ́dàá wa tó lágbára jù láyé àti lọ́run pé kó sún mọ́ wa. Tá a bá sì ti di ọ̀rẹ́ ẹ̀, ìṣòro, àtakò tàbí ikú kò ní lè yà wá kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀. (Dán. 12:13; Lúùkù 20:37, 38; Róòmù 8:38, 39) Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fara wé Dáníẹ́lì, ká sì jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà!
TÚBỌ̀ MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁRA DÁNÍẸ́LÌ
17-18. Nǹkan míì wo la lè kọ́ lára Dáníẹ́lì?
17 Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ti sọ̀rọ̀ nípa méjì lára àwọn ànímọ́ tí Dáníẹ́lì ní. Àmọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan la ṣì lè kọ́ lára ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà jẹ́ kí Dáníẹ́lì rí àwọn ìran kan, kó lá àwọn àlá kan, kó sì túmọ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ kan. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì ti ṣẹ. Àwọn èyí tí ò tíì ṣẹ jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn lọ́jọ́ iwájú.
18 Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa kẹ́kọ̀ọ́ nípa àsọtẹ́lẹ̀ méjì kan tí Dáníẹ́lì sọ. Tá a bá lóye àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn, ó máa ran gbogbo wa lọ́wọ́ báyìí bóyá ọmọdé ni wá tàbí àgbàlagbà láti ṣe ìpinnu tó tọ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tún máa jẹ́ ká nígboyà, ó sì máa jẹ́ ká túbọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin bá a ṣe ń múra sílẹ̀ de àwọn àdánwò tó máa dé bá wa lọ́jọ́ iwájú.
ORIN 119 Ó Yẹ Ká Ní Ìgbàgbọ́
a Lónìí, àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń bá ìṣòro pàdé tó máa ń fi hàn bóyá wọ́n nígboyà tàbí wọ́n jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Àwọn ọmọ kíláàsì wọn lè máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ torí wọ́n gbà pé Ọlọ́run ló dá ohun gbogbo tàbí káwọn ojúgbà wọn máa sọ pé wọn ò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe torí pé wọ́n ń sin Ọlọ́run, wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà ẹ̀. Àmọ́ bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn tó bá ń fara wé wòlíì Dáníẹ́lì, tí wọ́n ń fìgboyà sin Jèhófà, tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ máa fi hàn pé àwọn gbọ́n.
b Àwọn ará Bábílónì ló sọ wọ́n ní orúkọ yẹn.
c Nǹkan mẹ́ta ló ṣeé ṣe kí Dáníẹ́lì wò tí ò fi jẹ oúnjẹ àwọn ará Bábílónì. Àkọ́kọ́, ó ṣeé ṣe kí ẹran tí wọ́n fẹ́ kó jẹ wà lára àwọn ẹran tí Òfin Mósè sọ pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ. (Diu. 14:7, 8) Ìkejì, ó ṣeé ṣe kí wọ́n má ro ẹ̀jẹ̀ ẹran náà dà nù dáadáa nígbà tí wọ́n pa á. (Léf. 17:10-12) Àti ìkẹta, ó ṣeé ṣe kó rò pé tóun bá jẹ oúnjẹ náà, wọ́n lè máa rò pé òun ti ń bá wọn jọ́sìn ọlọ́run èké wọn.—Fi wé Léfítíkù 7:15 àti 1 Kọ́ríńtì 10:18, 21, 22.
d Wo fídíò náà, “Àlàáfíà Ni Òdodo Tòótọ́ Máa Mú Wá” lórí ìkànnì jw.org.
e Kí ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lè túbọ̀ lágbára, o lè kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Sún Mọ́ Jèhófà. Ìwé yẹn ṣàlàyé gbogbo ìwà àti ìṣe tí Jèhófà ní táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn.