Ṣé O Ti Béèrè Àwọn Ìbéèrè Yìí Rí?
Tó bá jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ àlàáfíà, kí nìdí táwọn èèyàn fi ń bára wọn jagun?
Ṣé ọkàn èèyàn lè balẹ̀ nínú ayé tí rògbòdìyàn kún inú ẹ̀ yìí?
Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí kò ní sí ogun mọ́?
Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, àwọn ìdáhùn náà lè yà ẹ́ lẹ́nu. Àmọ́ ó dájú pé ó máa tù ẹ́ nínú.
Torí náà, á dáa kó o ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ìbéèrè pàtàkì yìí. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka Ilé Ìṣọ́ yìí kó o lè mọ̀ sí i.