Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀, kí làwọn àlùfáà máa ń ṣe sí ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n fi rúbọ ní tẹ́ńpìlì?
LỌ́DỌỌDÚN, àwọn àlùfáà Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń fi ẹgbẹgbẹ̀ẹ̀rún ẹran rúbọ lórí pẹpẹ nínú tẹ́ńpìlì. Òpìtàn àwọn Júù kan nígbà ayé àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó ń jẹ́ Josephus sọ pé, lọ́jọ́ àjọyọ̀ Ìrékọjá, iye àgùntàn tí wọ́n fi ń rúbọ ju ọ̀kẹ́ méjìlá ààbọ̀ (250,000) lọ, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ẹran tí wọ́n ro dà nù pọ̀ gan-an. (Léf. 1:10, 11; Nọ́ń. 28:16, 19) Ibo ni gbogbo ẹ̀jẹ̀ náà ń lọ?
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí gọ́tà kan tó gùn gan-an nínú tẹ́ńpìlì Hẹ́rọ́dù táwọn àlùfáà máa ń lò títí dìgbà tí wọ́n pa tẹ́ńpìlì náà run lọ́dún 70 S.K. Ó hàn gbangba pé tí wọ́n bá ń fọ ẹ̀jẹ̀ ẹran kúrò nínú tẹ́ńpìlì tó wà lórí òkè, inú gọ́tà yẹn ni ẹ̀jẹ̀ náà máa ń gbà lọ.
Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa nǹkan méjì tó máa ń jẹ́ kí pẹpẹ náà mọ́:
Àwọn ihò kan wà nísàlẹ̀ pẹpẹ náà: Ìwé Mishnah, ìyẹn òfin àwọn Júù tí wọ́n kọ sílẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹta S.K. ṣàlàyé bí gọ́tà tó wà níbi pẹpẹ náà ṣe rí. Ìwé náà sọ pé: “Ihò méjì wà ní ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà . . . inú wọn ni ẹ̀jẹ̀ àti omi tí wọ́n fi fọ pẹpẹ máa ń gbà lọ sínú gọ́tà kan táá sì ṣàn lọ sí àfonífojì Kídírónì.”
Àwọn awalẹ̀pìtàn gbà pé “àwọn ihò” tó máa ń gbé ẹ̀jẹ̀ lọ síta wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ náà. Ìwé The Cambridge History of Judaism sọ pé “gọ́tà tó gùn gan-an” wà nítòsí tẹ́ńpìlì náà. Ó ní: “Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé gọ́tà yẹn ni wọ́n fi ń gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran àti omi jáde nínú Tẹ́ńpìlì tó wà lórí Òkè.”
Wọ́n ní omi tó pọ̀: Àwọn àlùfáà nílò omi tó pọ̀ kí wọ́n lè fọ ẹ̀jẹ̀ orí pẹpẹ náà kúrò, kí pẹpẹ àti gọ́tà náà lè mọ́ tónítóní. Kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ pàtàkì náà dáadáa, wọ́n máa ń gbé omi tí wọ́n ń lò wá látinú ìlú. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é? Wọ́n gbẹ́ àwọn gọ́tà ńlá àti kékeré láti fi gbé omi látinú ìlú wá sínú tẹ́ńpìlì, wọ́n sì tún gbẹ́ àwọn kòtò ńlá àti kékeré sínú tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè tọ́jú omi pa mọ́ síbẹ̀. Awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Joseph Patrich sọ pé: “Kò sí tẹ́ńpìlì míì nígbà yẹn tó nírú ètò tí wọ́n ṣe láti máa gbé omi wá sínú tẹ́ńpìlì, láti fọ ìdọ̀tí kúrò, tó sì tún ní gọ́tà táá máa gbé omi ìdọ̀tí lọ.”