OHUN TÓ O LÈ FI KẸ́KỌ̀Ọ́
Máa Dá Kẹ́kọ̀ọ́ Kó O sì Máa Sọ Ohun Tó O Kọ́ Fáwọn Èèyàn
Tá a bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó máa ń jẹ́ kára tù wá. Àmọ́ ara túbọ̀ máa ń tù wá tá a bá sọ ẹ̀kọ́ iyebíye tá a kọ́ fáwọn èèyàn. Òwe 11:25 sọ pé: ‘Ẹni tó bá ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà.’
Tá a bá ń sọ ohun tá a kọ́ fáwọn èèyàn, ó máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wa láti rántí àwọn kókó pàtàkì tá a ti kọ́, á sì jẹ́ ká túbọ̀ mọ Jèhófà. Yàtọ̀ síyẹn, a mọ̀ pé ohun tá a kọ́ máa ṣe àwọn èèyàn láǹfààní, torí náà a máa láyọ̀ tá a bá sọ fún wọn.—Ìṣe 20:35.
Gbìyànjú ẹ̀ wò: Lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, wá bó o ṣe máa sọ ohun tó o kọ́ fún ẹnì kan. O lè sọ fún ará ilé ẹ, ẹni tẹ́ ẹ jọ wà níjọ, ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, ọmọ ilé ìwé ẹ, ẹni tẹ́ ẹ jọ ń gbé ládùúgbò àtẹni tó o fẹ́ wàásù fún. Sọ ohun tó o kọ́ fún ẹni náà lọ́rọ̀ ara ẹ, má sọ̀rọ̀ jù, kó o sì jẹ́ kó yé e.
Ohun tó yẹ kó o rántí: Sọ ohun tó o kọ́ fáwọn èèyàn kí wọ́n lè jàǹfààní nínú ẹ̀, kì í ṣe kó o lè fi gbayì.—1 Kọ́r. 8:1.