ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w23 August ojú ìwé 32
  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Nípa Jèhófà
  • Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Tó O Lè Fi Sílò
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Irú Ẹni Wo Ni Jèhófà?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Báwo Ni Ènìyàn Ṣe Lè Jẹ́ Ní Àwòrán Ọlọrun?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
w23 August ojú ìwé 32

Ohun Tó O Lè Fi Kẹ́kọ̀ọ́

Wá Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Nípa Jèhófà

Tá a bá ń ka Bíbélì, a lè lo àwọn ìwé àti fídíò wa láti ṣèwádìí, ká lè lóye ohun tá à ń kà. Àmọ́, kò yẹ ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ká lè ní ìmọ̀ nìkan, ó tún yẹ ká máa wá àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye nípa ìwà àti ìṣe Jèhófà táá jẹ́ ká túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ẹ̀. Ohun tó máa jẹ́ ká ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká bi ara wa ní ìbéèrè yìí, ‘Kí ni ìtàn Bíbélì yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?’

Bí àpẹẹrẹ, o lè ṣèwádìí sí i nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó gba iwájú, ìyẹn ìfẹ́, ọgbọ́n, ìdájọ́ òdodo àti agbára, kó o sì wo bó ṣe ń fi wọ́n hàn nínú ohun tó ń ṣe. Àmọ́, Jèhófà ṣì láwọn ànímọ́ míì tó dáa. Torí náà, ibo lo ti lè ṣèwádìí kó o lè mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ànímọ́ náà?

Lọ wo àwọn ànímọ́ míì tí Jèhófà ní tó ju àádọ́ta (50) lọ nínú Watch Tower Publications Index. Wàá rí àkòrí náà “Jehovah” àti ìsọ̀rí tó sọ pé “Qualities by Name.” Ṣèwádìí nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà tó wà nínú ìtàn Bíbélì tó ò ń kà. (Tó bá jẹ́ pé Ìwé Ìwádìí fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo fi máa ń ṣèwádìí, lọ wo “Jèhófà Ọlọ́run,” lẹ́yìn náà kó o wo ìsọ̀rí tó sọ pé “Àwọn Ànímọ́ Jèhófà.”)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́