ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lff ẹ̀kọ́ 7
  • Irú Ẹni Wo Ni Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Irú Ẹni Wo Ni Jèhófà?
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • Irú Ẹni Wo Ni Jésù?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Máa Fi “Ìwà Tuntun” Wọ Ara Rẹ Láṣọ Lẹ́yìn Tó O Ti Ṣèrìbọmi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Ẹbun Ẹmi Mímọ́ Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Jẹ́ Kí Ẹ̀mí Ọlọ́run Máa Darí Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
lff ẹ̀kọ́ 7
Ẹ̀kọ́ 7. Ọkùnrin kan dúró lórí òkúta tó wà létí òkun lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́, ó ń wo omi tó lọ salalu.

Ẹ̀KỌ́ 07

Irú Ẹni Wo Ni Jèhófà?

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Irú ẹni wo lo rò pé Jèhófà jẹ́? Ṣó o gbà pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba, àmọ́ ó jìnnà sí wa gan-an bí ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run? Àbí ńṣe lo rò pé ó jẹ́ alágbára ńlá kan, àmọ́ tó dà bí ìjì àti ààrá tí kò ṣeé tù lójú? Irú ẹni wo ni Jèhófà jẹ́ gangan? Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.

1. Kí nìdí tá ò fi lè rí Ọlọ́run?

“Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.” (Jòhánù 4:24) Jèhófà ò dà bí àwa èèyàn ẹlẹ́ran ara. Ẹ̀mí ni Jèhófà, ọ̀run ló sì ń gbé, ìdí nìyẹn tá ò fi lè rí i.

2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí Jèhófà, Ẹni gidi tó wà lóòótọ́ ni, ó sì láwọn ìwà àti ìṣe tó dáa gan-an, tó máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo, kò sì ní kọ àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀.” (Sáàmù 37:28) Ó tún ní “ìfẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́, ó sì jẹ́ aláàánú.” Àwọn tó sì máa ń fi ìfẹ́ àti àánú hàn sí jù ni àwọn tí ìyà ń jẹ. (Jémíìsì 5:11) “Jèhófà wà nítòsí àwọn tó ní ọgbẹ́ ọkàn; ó ń gba àwọn tí àárẹ̀ bá ẹ̀mí wọn là.” (Sáàmù 34:18) Ṣó o tiẹ̀ mọ̀ pé ohun tó o bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó o bà á lọ́kàn jẹ́? Tẹ́nì kan bá ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tí kò dáa, inú Jèhófà ò ní dùn sí onítọ̀hún. (Sáàmù 78:40, 41) Ṣùgbọ́n tẹ́nì kan bá ń ṣe ohun tó dáa, ńṣe ló ń múnú Jèhófà dùn.​—Ka Òwe 27:11.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ wa?

Nínú gbogbo ìwà àti ìṣe Jèhófà, ìfẹ́ rẹ̀ ló ṣàrà ọ̀tọ̀. Kódà, “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Kì í ṣe inú Bíbélì nìkan ni Jèhófà ti jẹ́ ká mọ̀ pé òun nífẹ̀ẹ́ wa, a tún ń rí ẹ̀rí pé ó nífẹ̀ẹ́ wa nínú àwọn ohun tó dá. (Ka Ìṣe 14:17.) Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká wo ọ̀nà tó gbà dá wa. Ó dá wa lọ́nà tá a fi lè rí oríṣiríṣi àwọ̀, a lè gbọ́ orin aládùn, a sì lè mọ oúnjẹ aládùn lẹ́nu. Ńṣe ló fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa agbára tí Jèhófà fi ń ṣe àwọn ohun ìyanu àti bó ṣe jẹ́ ká mọ àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ tó fani mọ́ra gan-an.

4. Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́

Àwòrán: Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. 1. Àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí po. 2. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ń kọ ohun tí Ọlọ́run sọ fún un nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sínú àkájọ ìwé.

Bó ṣe jẹ́ pé àwa èèyàn máa ń fi ọwọ́ wa ṣiṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ agbára tí Jèhófà máa ń fi ṣe àwọn nǹkan tó bá fẹ́ ṣe. Ka Lúùkù 11:13 àti Ìṣe 2:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ọlọ́run máa ‘tú ẹ̀mí mímọ́’ rẹ̀ sára àwọn tó bá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣó o rò pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan àbí ó jẹ́ agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Jèhófà máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe àwọn ohun ìyanu. Ka Sáàmù 33:6 àti 2 Pétérù 1:20, 21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀?

Àwòrán: Àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. 1. Àwọn pílánẹ́ẹ̀tì tó ń yí po. 2. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì ń kọ ohun tí Ọlọ́run sọ fún un nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ sínú àkájọ ìwé.

5. Ìwà àti ìṣe Jèhófà dára gan-an

Mósè jẹ́ ọkàn lára àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́, àmọ́ ó wù ú kó túbọ̀ mọ Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Torí náà, ó sọ fún Jèhófà pé: “Jọ̀ọ́, tí mo bá rí ojúure rẹ, jẹ́ kí n mọ àwọn ọ̀nà rẹ, kí n lè mọ̀ ọ́.” (Ẹ́kísódù 33:13) Nígbà tí Jèhófà máa dá Mósè lóhùn, ńṣe ló jẹ́ kó mọ àwọn ìwà àti ìṣe òun. Ka Ẹ́kísódù 34:4-6, lẹ́yin náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà wo ni Jèhófà jẹ́ kí Mósè mọ̀?

  • Èwo lára ìwà àti ìṣe Jèhófà ló fà ẹ́ mọ́ra jù?

6. Jèhófà fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀

Obìnrin kan ń gbàdúrà.

Àwọn Hébérù tí wọ́n jẹ́ èèyàn Ọlọ́run di ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì. Báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ ń jìyà? Gbọ́ ÀTẸ́TÍSÍ yìí kó o sì máa fọkàn bá a lọ, tàbí kó o ka Ẹ́kísódù 3:1-10. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

ÀTẸ́TÍSÍ: Jèhófà Gba Àwọn Èèyàn Rẹ̀ Lọ́wọ́ Ìyà (2:45)

  • Nínú ìtàn yìí, kí lo rí kọ́ nípa bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ìyà bá ń jẹ wá?​—Wo ẹsẹ 7 àti 8.

  • Ṣó o rò pé ó máa ń wu Jèhófà pé kó ran àwa èèyàn lọ́wọ́, ṣé ó sì lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ lóòótọ́? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

7. Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ń jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́

Àwòrán: Ẹja àbùùbùtán kan àti ọmọ rẹ̀, òdòdó àti ẹyẹ akùnyùnmù.

Àwọn nǹkan tí Jèhófà dá ń jẹ́ ká mọ ìwà àti ìṣe rẹ̀. Wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà, ka Róòmù 1:20, kó o wá dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: Àwọn Ohun Tí Jèhófà Dá Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa​—Ara Èèyàn (1:57)

  • Àwọn ìwà àti ìṣe Jèhófà wo lo rí lára àwọn nǹkan tó dá?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ọlọ́run kì í ṣe ẹnì kan pàtó, ńṣe ló dà bí afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ kárí ayé.”

  • Kí lèrò tìẹ?

  • Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà wà lóòótọ́, ṣùgbọ́n a ò lè rí i. Gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀ ló fani mọ́ra, àmọ́ ìfẹ́ rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tá ò fi lè rí Jèhófà?

  • Kí ni ẹ̀mí mímọ́?

  • Àwọn ìwà àti ìṣe wo ni Jèhófà ní?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Kó o lè túbọ̀ mọ Jèhófà, kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìwà àti ìṣe rẹ̀ mẹ́rin tó gbawájú.

“Irú Ẹni Wo Ni Ọlọ́run?” (Ilé Ìṣọ́ No. 1 2019)

Wo àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé kì í ṣe ibi gbogbo ni Jèhófà wà.

“Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Wo ìdí tí Bíbélì fi pe ẹ̀mí mímọ́ ní ọwọ́ Ọlọ́run.

“Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Ọkùnrin afọ́jú kan ò kọ́kọ́ gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ òun. Wo ohun tó mú kó yí èrò rẹ̀ pa dà.

“Mo Ti Lè Ran Àwọn Míì Lọ́wọ́ Báyìí” (Ilé Ìṣọ́, October 1, 2015)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́