SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
1991 sí 2001 ‘Ìléru Ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’—Aísá. 48:10 (Apá Kìíní)
Ogun Abẹ́lé
Ní ọdún 1980 sí 1989, ìṣòro tó wà láwùjọ, wàhálà lágbo òṣèlú àti ọrọ̀ ajé tí kò dáa fa rògbòdìyàn ní gbogbo Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Nígbà tí ogun ba orílẹ̀-èdè Làìbéríà jẹ́ gan-an, ọ̀pọ̀ àwọn ará ibẹ̀ sá wá sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Sierra Leone ṣètò ilé àwọn ará àti àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí àwọn Ẹlẹ́rìí tí ogun lé kúrò nílùú á máa dé sí, àwọn ará sì ń tọ́jú wọn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ò rọrùn fún àwọn ará tí ogun lé kúrò ní ìlú yẹn, àwọn nǹkan tó ń pa wọ́n lẹ́rìn-ín máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, Arábìnrin Isolde Lorenz, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì sọ pé: “Bàbá kan rán ọmọkùnrin rẹ̀ kékeré lọ síbì kan lẹ́yìn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, pé kó lọ gbé oúnjẹ kaná níbi ààrò kan tí wọ́n ṣe síbẹ̀. Nígbà tí ọmọ yìí pa dà dé, ó sọ fún bàbá rẹ̀ pé àwọn kò ní rí oúnjẹ jẹ lónìí o. Bàbá rẹ̀ wá béèrè pé kí ló dé? Ọmọ náà dáhùn pé: ‘Jèhófà ló gbà mí lẹ́nu kìnnìún lónìí!’ Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an? Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé bí ọmọ náà ṣe ń gbé oúnjẹ yẹn bọ̀, ó pàdé ajá ńlá kan tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Ajá náà bani lẹ́rù àmọ́ kì í pani lára. Lobo ni wọ́n ń pè é. Àyà ọmọ yìí já gan-an. Ló bá na ọwọ́ méjèèjì tó fi gbé oúnjẹ dání síwájú láti fi lé ajá náà sẹ́yìn. Ajá yìí rò pé ńṣe ló na oúnjẹ sóun. Bí Lobo ṣe parí oúnjẹ wọn nìyẹn o!”
Ní March 23, 1991, ogun ilẹ̀ Làìbéríà ya wọ orílẹ̀-èdè Sierra Leone, ó sì wá di ogun abẹ́lé tó jà fún ọdún mọ́kànlá níbẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní Revolutionary United Front (RUF) gbé ogun ja ìlú Kailahun àti Koindu. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èèyàn ibẹ̀ bá sá lọ sí ilẹ̀ Guinea. Nǹkan bí ọgọ́fà [120] àwọn ará ló wà lára àwọn tí ogun lé kúrò nílùú yìí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí míì tí ogun lé kúrò ní ìlú wọn ní Làìbéríà sá wá sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone kí àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tó kàn wọ́n lára.
Billie Cowan tó jẹ́ olùṣekòkáárí Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ibẹ̀ nígbà yẹn sọ pé: “Ó tó oṣù bíi mélòó kan tí àwọn ará tébi ti hàn léèmọ̀, tí wọ́n rù hangogo, tí ojú wọn ti jìn sínú, fi ń dé sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìlú Freetown. Ojú ọ̀pọ̀ nínú wọn ti rí ìwà ìkà tó kọjá àfẹnusọ, ewébẹ̀ àti egbò inú igbó ni wọ́n ń jẹ kí ebi má bàa pa wọ́n kú. A tètè fún wọn ní oúnjẹ àti aṣọ, a sì tọ́jú àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bá wọn wá. Àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà níbí gbà wọ́n sílé tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n sì tọ́jú wọn. Kíá ni àwọn Ẹlẹ́rìí tí ogun lé kúrò nílùú yìí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní pẹrẹu, wọ́n ń ran àwọn ìjọ tó wà níbí lọ́wọ́. Nígbà tó yá, èyí tó pọ̀ jù nínú wọn kó lọ síbòmíì, àmọ́ wọ́n gbé wa ró gan-an nígbà tí wọ́n wà níbí!”
Ọdún mọ́kànlá logun fi jà lórílẹ̀-èdè Sierra Leone
A Fún Wọn Ní Ìtùnú àti Ìrètí
Ẹ̀ka ọ́fíìsì kó oúnjẹ, oògùn, àwọn ohun èlò ìkọ́lé, irinṣẹ́ lóríṣiríṣi àti àwọn nǹkan èlò míì ránṣẹ́ sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú àgọ́ àwọn tógun lé kúrò nílùú, èyí tó wà ní gúúsù ilẹ̀ Guinea. Àwọn aṣọ rẹpẹtẹ tí wọ́n kó wá láti ilẹ̀ Faransé wà lára rẹ̀. Bàbá kan sọ pé: “Àwọn ọmọ mi mújó jó, wọ́n ń kọrin, wọ́n sì ń yin Jèhófà. Inú wọn dùn pé wọ́n ní aṣọ tuntun tí wọ́n lè máa wọ̀ lọ sí ìpàdé báyìí!” Àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan tiẹ̀ sọ pé àwọn kò tíì wọ aṣọ tó dáa tó bẹ́ẹ̀ rí!
Ṣùgbọ́n ohun táwọn tí ogun lé kúrò nílùú yìí nílò ju ìrànlọ́wọ́ nípa tara lọ. Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo [ọ̀rọ̀] tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Torí náà, ẹ̀ka ọ́fíìsì kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ránṣẹ́ sí àgbègbè yẹn, wọ́n sì ṣètò bí wọ́n á ṣe máa ṣe àwọn àpéjọ àkànṣe, àyíká àti àgbègbè déédéé. Wọ́n tún rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àti àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò lọ síbẹ̀.
Nígbà tí alábòójútó àyíká kan tó ń jẹ́ André Baart lọ bẹ ìlú Koundou wò ní ilẹ̀ Guinea, ó pàdé ọ̀kan lára àwọn tó ń bójú tó àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò nílùú. Ẹni náà sì ní kó wá sọ àsọyé Bíbélì fún àwọn èèyàn àdúgbò ibẹ̀ tó wà ní àgọ́ wọn. Nǹkan bí àádọ́ta [50] èèyàn ló gbọ́ àsọyé tí Arákùnrin André sọ. Àkòrí rẹ̀ ni “Sá Di Jèhófà.” Ó gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ka Sáàmù kejìdínlógún [18]. Nígbà tó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, obìnrin àgbàlagbà kan dìde láti sọ̀rọ̀. Ó ní: “O ti mú kínú wa dùn gan-an ni. Ìrẹsì tí wọ́n ń fún wa ò yanjú àwọn ìṣòro wa, Bíbélì ló jẹ́ ká mọ bí a ṣe lè ní ìrètí nínú Ọlọ́run. A dúpẹ́ gan-an pé o tù wá nínú, o sì jẹ́ ká ní ìrètí.”
Nígbà tí wọ́n rán William àti Claudia Slaughter tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì lọ sí ìlú Guékédou ní ilẹ̀ Guinea, ńṣe ni iná ẹ̀mí ń jó lala nínú ìjọ kan tí àwọn tó ju ọgọ́rùn-ún [100] lọ tí ogun lé kúrò nílùú wà. (Róòmù 12:11) Arákùnrin William sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́kùnrin ló ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè kúnjú ìwọ̀n fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Tí ẹni tó níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run kò bá lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n fún un, arákùnrin mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó jẹ́ ọ̀dọ́ á yọ̀ǹda láti ṣe iṣẹ́ náà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló máa ń jáde òde ẹ̀rí tí wọ́n sì ń fi ìtara wàásù. Àwọn kan lára àwọn ọ̀dọ́ onítara yìí di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe àti alábòójútó arìnrìn-àjò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”
Iṣẹ́ Ìkọ́lé Nígbà Ogun
Láìpẹ́ lẹ́yìn tí ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀, àwọn ará tó wà ní ìlú Freetown ra ilẹ̀ éékà kan àtààbọ̀ sí ojúlé 133 Wilkinson Road, tí kò jìnnà sí apá ìsàlẹ̀ ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wà. Arákùnrin Alfred Gunn sọ pé: “A fẹ́ kọ́ Bẹ́tẹ́lì tuntun sórí ilẹ̀ yìí, àmọ́ a tún ń ro ti ọ̀rọ̀ ogun yẹn. Arákùnrin Lloyd Barry tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí sì wá bẹ̀ wá wò lásìkò yẹn, la bá sọ ohun tó ń jẹ wá lọ́kàn yìí fún un. Ó fèsì pé, ‘Tá a bá ń jẹ́ kí ogun dá wa dúró, a ò ní lè gbé nǹkan kan ṣe rárá!’ Ọ̀rọ̀ tó tani jí tó sọ yìí mú ká fìgboyà dáwọ́ lé iṣẹ́ náà.”
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará ló ṣiṣẹ́ kára níbi ìkọ́lé náà, títí kan àwọn tó lé ní àádọ́ta [50] tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti orílẹ̀-èdè méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn ará tó wá ṣèrànwọ́ látinú àwọn ìjọ wa níbí. Iṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ lóṣù May 1991. Arákùnrin Tom Ball tó jẹ́ alábòójútó iṣẹ́ ìkọ́lé sọ pé: “Ó jọ àwọn aráàlú lójú gan-an bí wọ́n ṣe ń rí irú àwọn búlọ́ọ̀kù tó lágbára tí à ń yọ níbẹ̀. Ilé wa tó ní àwọn òpó irin yìí yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ilé tí wọ́n máa ń kọ́ níbẹ̀. Àmọ́ ohun tó ya àwọn èèyàn lẹ́nu jù ni bí wọ́n ṣe ń rí àwọn òyìnbó àti àwọn aráàlú wọn aláwọ̀ dúdú tí wọ́n ń fayọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ níṣọ̀kan níbi ìkọ́lé náà.”
Ní April 19, 1997, àwọn èèyàn láti onírúurú orílẹ̀-èdè kóra jọ tayọ̀tayọ̀ láti ṣe ìyàsímímọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí. Oṣù kan lẹ́yìn náà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀, ìyẹn RUF, gbógun wọ ìlú Freetown, lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí wọ́n ti ń ja ogun oníwà ìkà káàkiri ìgbèríko.
Ìgbà tí wọ́n ń kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Freetown; ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ní báyìí
Ogun Ìlú Freetown
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ogun RUF ya wọ ìgboro, irun wọn rí játijàti, wọ́n fi aṣọ pupa wérí, wọ́n ń kó ẹrù àwọn èèyàn, wọ́n ń fipá bá àwọn obìnrin lò pọ̀, wọ́n sì ń pa àwọn èèyàn. Arákùnrin Alfred Gunn sọ pé: “Nǹkan ò fara rọ nílùú rárá. Torí náà, wọ́n kó èyí tó pọ̀ jù lára àwọn míṣọ́nnárì tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè kúrò níbẹ̀ kíákíá. Èmi àti Catherine, Billie àti Sandra Cowan pèlú Jimmie àti Joyce Holland la kúrò níbẹ̀ gbẹ̀yìn.
“Àwọn ará tó jẹ́ ọmọ ibẹ̀ tí wọ́n sì jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì yọ̀ǹda ara wọn láti dúró sí Bẹ́tẹ́lì. A gbàdúrà pẹ̀lú wọn, a sì yára lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ kó wa kúrò nílùú. Nǹkan bí ogún [20] ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ tó ti mutí yó, tójú wọn ranko dá wa dúró lójú ọ̀nà. Nígbà tá a fún wọn ní ìwé ìròyìn àti owó, wọ́n jẹ́ ká kọjá. Àwa àtàwọn míì tó ju ẹgbẹ̀rún tí wọ́n fẹ́ kó kúrò níbẹ̀ kóra jọ sí ibì kan lójú ọ̀nà, àwọn ọmọ ogun ojú omi Amẹ́ríkà tó dìhámọ́ra ló ń ṣọ́ ibẹ̀. Ní kíá, wọ́n fi ọkọ̀ òfuurufú hẹlikóbítà kó wa lọ sínú ọkọ̀ òkun àwọn ọmọ ogun náà tó wà láàárín agbami òkun. Ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ọkọ̀ òkun náà sọ fún wa pé, yàtọ̀ sí ìgbà ogun orílẹ̀-èdè Vietnam, kò sígbà tí àwọn ọmọ ogun ojú omi ilẹ̀ Amẹ́ríkà tún kó àwọn ará ìlú tó pọ̀ tó tiwa yìí kúrò níbi tí ogun ti ń jà. Lọ́jọ́ kejì, ọkọ̀ hẹlikóbítà gbé wa lọ sí ìlú Conakry ní ilẹ̀ Guinea. A sì ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì síbẹ̀ fúngbà díẹ̀.”
Alfred àti Catherine Gunn wà lára àwọn tí wọ́n kó kúrò ní Freetown
Àwọn míṣọ́nnárì yìí ń hára gàgà láti gbọ́ ìròyìn láti ìlú Freetown. Níkẹyìn, wọ́n gba lẹ́tà kan tó sọ pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ti dà rú, a ṣì ń pín Ìròyìn Ìjọba No. 35, ìyẹn Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí? Àwọn èèyàn ń tẹ́tí gbọ́ wa gan-an, kódà àwọn kan lára àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ pàápàá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa. Torí náà, a kúkú pinnu pé a ó túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù wa.”
Jonathan Mbomah tó jẹ́ alábòójútó àyíká nígbà yẹn sọ pé: “Kódà, a ṣe àpéjọ àkànṣe ní ìlú Freetown. Ọ̀rọ̀ tá a gbọ́ gbéni ró gan-an nípa tẹ̀mí débi pé mo tún gbéra lọ sí ìlú Bo àti Kenema láti tún lọ ṣe é níbẹ̀. Àwọn ará tó ń gbé ní àwọn ìlú tí ogun ti bà jẹ́ gan-an yẹn dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀ náà.
“Nígbà tí ọdún 1997 ń parí lọ, a ṣe àpéjọ àgbègbè kan ní pápá ìṣeré National Stadium ti ìlú Freetown. Lọ́jọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ wọnú pápá ìṣeré náà, wọ́n sì pàṣẹ pé ká kúrò níbẹ̀. A bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n jẹ́ ká parí àpéjọ náà. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àlàyé, wọ́n fi wá sílẹ̀, wọ́n sì jáde lọ. Àwọn èèyàn tó lé ní ẹgbẹ̀rún [1,000] ló wá sí àpéjọ àgbègbè náà, àwọn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] sì ṣèrìbọmi. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló rìnrìn àjò ọ̀nà eléwu lọ sí ìlú Bo láti tún lọ gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ yẹn níbẹ̀. Àwọn àpéjọ àgbègbè yẹn gbéni ró gan-an, wọ́n sì gbádùn mọ́ni!”