ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb14 ojú ìwé 139-145
  • 1991 sí 2001 ‘Ìléru Ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’—Aísá. 48:10 (Apá Kejì)

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 1991 sí 2001 ‘Ìléru Ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’—Aísá. 48:10 (Apá Kejì)
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
  • Ìsọ̀rí
  • Wọ́n Jálẹ̀kùn Wọ Bẹ́tẹ́lì!
  • Ẹ Run Wọ́n Pátápátá
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2014
yb14 ojú ìwé 139-145

SIERRA LEONE ÀTI GUINEA

1991 sí 2001 ‘Ìléru Ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’—Aísá. 48:10 (Apá Kejì)

Wọ́n Jálẹ̀kùn Wọ Bẹ́tẹ́lì!

Ní February 1998, àwọn sójà ìjọba àti àwọn ọmọ ogun apẹ̀tùsíjà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ìyẹn ECOMOG, dojú ìjà tó gbóná kọ àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ láti lé wọn kúrò ní ìlú Freetown. Ó dunni pé irin wẹ́wẹ́ tí bọ́ǹbù fọ́n ká ṣèèṣì pa arákùnrin kan nígbà ìjà tó gbóná janjan náà.

Nǹkan bí àádọ́jọ [150] akéde wá forí pa mọ́ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì ní ìlú Kissy àti Cockerill. Laddie Sandy tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin méjì tó ń ṣọ́ Bẹ́tẹ́lì lálẹ́ sọ pé: “Bí èmi àti Philip Turay ṣe wà lẹ́nu iṣẹ́ lóru ọjọ́ kan, méjì lára àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ RUF tó dìhámọ́ra, wá sí Bẹ́tẹ́lì, wọ́n sì pàṣẹ pé ká ṣí àwọn ilẹ̀kùn onígíláàsì tó wọ ọ̀dẹ̀dẹ̀ fún àwọn. Nígbà tí èmi àti Philip sá lọ, wọ́n yìnbọn lu kọ́kọ́rọ́ ilẹ̀kùn náà léraléra. Àmọ́ kò já, kò sì wá sí wọn lọ́kàn pé kí wọ́n fìbọn fọ́ àwọn gíláàsì ilẹ̀kùn náà. Nígbà tó sú wọn, wọ́n bá lọ.

“Lóru ọjọ́ kẹta, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ náà pa dà wá pẹ̀lú nǹkan bí ogún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn. Wọ́n dìídì dira wá ni. A ta àwọn yòókù ní Bẹ́tẹ́lì lólobó kíá, gbogbo wa sì sá lọ síbi tá a ti ṣètò pé a máa sá sí nísàlẹ̀ ilé náà. Àwa méje tó wà níbẹ̀ sá pa mọ́ sẹ́yìn àgbá ńlá méjì nínú òkùnkùn. Ẹ̀rù bà wá débi pé ṣe ni ara wa ń gbọ̀n. Wọ́n fìbọn jálẹ̀kùn wọlé, kódà ṣe ni kọ́kọ́rọ́ ilẹ̀kùn náà yọ́. Ọ̀kan lára wọn fi ohùn tó rinlẹ̀ kígbe pé: ‘Ẹ wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yẹn, kí ẹ dúńbú wọn.’ A ba mọ́lẹ̀ búrúbúrú láìmí pínkín bí wọ́n ṣe ń wá gbogbo ilé náà fún odidi wákàtí méje. Wọ́n kó gbogbo nǹkan tí wọ́n fẹ́, wọ́n ba àwọn nǹkan míì jẹ́ débi tó tẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n sì bá tiwọn lọ.

“A kó àwọn ohun ìní wa, a sì sá lọ sí ilé àwọn míṣọ́nnárì ní Cockerill, ìyẹn ibi tó jẹ́ Bẹ́tẹ́lì tẹ́lẹ̀, lápá òkè ibi tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wà. Bá a ṣe ń lọ lọ́nà, àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ míì tún jà wá lólè. Ṣe ni jìnnìjìnnì bò wá títí tá a fi dé ilé àwọn míṣọ́nnárì náà, àmọ́ a dúpẹ́ pé Jèhófà dá ẹ̀mí wa sí. A fi ọjọ́ mélòó kan sinmi, a wá pa dà lọ sí Bẹ́tẹ́lì láti lọ palẹ̀ gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe mọ́.”

Oṣù méjì lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ ogun ECOMOG gba ìlú Freetown lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí, àwọn míṣọ́nnárì bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà láti orílẹ̀-èdè Guinea. Àmọ́ wọn ò mọ̀ pé àwọn ò ní dúró pẹ́ níbẹ̀ rárá.

Ẹ Run Wọ́n Pátápátá

Ní December 1998, ìyẹn oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ará wà ní pápá ìṣeré tí wọ́n ń pè ní Freetown’s National Stadium, wọ́n ń gbádùn Àpéjọ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́.” Àfi bí wọ́n ṣe dédé gbọ́ ìró kan tó kù rìrì, èéfín ńlá sì rú túú láti orí òkè kan nítòsí ibẹ̀. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ọlọ̀tẹ̀ tún ti dé!

Láàárín ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn èyí, ìlú Freetown túbọ̀ dà rú. Ni Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka bá háyà ọkọ̀ òfuurufú kékeré kan láti fi kó míṣọ́nnárì méjìlá, àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mẹ́jọ tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àtàwọn márùn-ún kan tó yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ ìkọ́lé lọ sí ìlú Conakry. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, ní January 6, 1999, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í pààyàn nípakúpa, wọ́n pe ogun náà ní Ẹ Run Wọ́n Pátápátá. Wọ́n fi ìwà ìkà tó burú jáì ba gbogbo ìgboro ìlú Freetown jẹ́, wọ́n sì pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] aráàlú. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí ń gé apá àti ẹsẹ̀ àwọn ẹni ẹlẹ́ni dà nù bó ṣe wù wọ́n, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọmọdé ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì ba ẹgbẹẹgbẹ̀rún ilé jẹ́.

Wọ́n pa arákùnrin wa Edward Toby, táwọn èèyàn fẹ́ràn gan-an, ní ìpa ìkà. Inú Bẹ́tẹ́lì àti ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Cockerill ni àwọn akéde tó ju igba [200] tí ìpayà bá forí pa mọ́ sí. Àwọn míì sì sá pa mọ́ sínú ilé wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wá forí pa mọ́ sí ilé àwọn míṣọ́nárì ní ìlú Kissy, tó wà ní ìpẹ̀kun ìlú lápá ìlà oòrùn, nílò egbòogi ní kánmọ́kánmọ́. Ṣùgbọ́n ó léwu gan-an láti kọjá láti ibì kan síbòmíì láàárín ìlú. Ta ló máa wá torí bọ̀ ọ́ báyìí? Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Laddie Sandy àti Philip Turay, àwọn onígboyà tí wọ́n ń ṣọ́ Bẹ́tẹ́lì lóru yọ̀ǹda ara wọn.

Arákùnrin Philip sọ pé: “Gbogbo ìlú ti dà rú gan-an. Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ wà ní gbogbo ojú ọ̀nà káàkiri, wọ́n ń dá àwọn èèyàn dúró, wọ́n sì ń han aráàlú léèmọ̀ bó ṣe wù wọ́n. Òfin kónílé-gbélé wà láti nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán títí di aago mẹ́sàn-án àárọ̀, tó fi jẹ́ pé a ò lè rìn bí a ṣe fẹ́. Nígbà tí a fi máa dé ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Kissy lọ́jọ́ kẹta tá a kúrò nílé, a rí i pé àwọn jàǹdùkú ti jí gbogbo ohun tó wà níbẹ̀ kó lọ, wọ́n sì ti dáná sun ún.

“Bá a ṣe ń wá àyíká ibẹ̀, a rí arákùnrin wa kan tó ń jẹ́ Andrew Caulker tí wọ́n ṣá lọ́gbẹ́ lórí yánnayànna. Ṣe ni àwọn ọlọ̀tẹ̀ dè é lókùn, tí wọ́n sì fi àáké ṣá a yánnayànna. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ó yè é, ó sì ráyè sá lọ. A sáré gbé e lọ ilé ìwòsàn, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ara rẹ̀ yá. Ó sì di aṣáájú-ọ̀nà déédéé nígbà tó yá.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 143]

(Láti apá òsì sí apá ọ̀tún) Laddie Sandy, Andrew Caulker àti Philip Turay

Ohun tó kó àwọn Ẹlẹ́rìí míì yọ tí wọn kò fi pa wọ́n tàbí kí wọ́n ṣe wọ́n léṣe ni mímọ̀ tí àwọn èèyàn ti mọ̀ wọ́n pé wọn kì í dá sí òṣèlú tàbí ogun jíjà. Arákùnrin kan sọ pé: “Àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ ní ká fi ọ̀já funfun wérí ká jó kiri ìgboro láti fi hàn pé a wà lẹ́yìn wọn. Wọ́n ní: ‘Tẹ́ ẹ bá kọ̀, a ó gé apá tàbí ẹsẹ̀ yín sọ nù tàbí kí a pa yín.’ Àyà èmi àti ìyàwó mi já gan-an, la bá bọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, a rọra ń gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́. Bí ọmọkùnrin kan ní àdúgbò wa tó bá àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà lẹ̀dí àpò pọ̀ ṣe rí ohun tó dé bá wa, ó sọ fún ọ̀gá àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà pé: ‘“Búrọ́dà” wa ni ẹni yìí ńtiẹ̀. Kì í lọ́wọ́ sí òṣèlú, a máa bá a jó ijó tiẹ̀.’ Ọ̀gá àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà gbà bẹ́ẹ̀, ó sì fi wá sílẹ̀, la bá sá pa dà sílé.”

Nígbà tí ìgboro ìlú wá pa rọ́rọ́, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í fọgbọ́n ṣèpàdé, wọ́n ń lọ sóde ẹ̀rí. Àwọn akéde ń fi báàjì àpéjọ àgbègbè sáyà láti fi ṣe ohun ìdánimọ̀ wọn láwọn ibi tí wọ́n ti ń dá àwọn èèyàn dúró lọ́nà. Àwọn ará sì wá di ọ̀jáfáfá lẹ́nu bíbẹ̀rẹ̀ ìfọ̀rọ̀wérọ̀ nípa Bíbélì nígbà tí wọ́n bá wà lórí ìlà gígùn láwọn ibi tí wọ́n ti máa ń dá àwọn èèyàn dúró lójú ọ̀nà.

Bó ṣe di pé àwọn èèyàn ò rí nǹkan rà mọ́ nílùú, ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì fi ọkọ̀ òfuurufú kó igba [200] páálí ẹrù oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ránṣẹ́ sí ìlú Freetown láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Arákùnrin Billie Cowan àti Alan Jones wá wọ ọkọ̀ òfuurufú wá sí ìlú Freetown láti ìlú Conakry kí wọ́n lè sin àwọn tó kó àwọn ẹrù náà kọjá onírúurú ibi táwọn ọmọ ogun dúró sí lójú ọ̀nà. Àwọn ẹrù náà sì dé Bẹ́tẹ́lì kó tó di ìrọ̀lẹ́ tí kónílé-gbélé máa bẹ̀rẹ̀. Arákùnrin James Koroma máa ń bá ètò Ọlọ́run kó lẹ́tà àtàwọn nǹkan míì lọ sí ìlú Conakry, á sì tún kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn ẹrù míì tó ṣe pàtàkì pa dà tó bá ń bọ̀. Wọ́n máa ń kó lára oúnjẹ tẹ̀mí tí wọ́n bá rí gbà yìí ránṣẹ́ sí àwọn akéde tí wọ́n dá wà ní ìlú Bo àti Kenema.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 145]

Àwọn ẹrù tí wọ́n fẹ́ fi ran àwọn ará lọ́wọ́ dé sí ìlú Freetown

Ní August 9, 1999, àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní ìlú Conakry bẹ̀rẹ̀ sí í pa dà sí ìlú Freetown. Lọ́dún 2000, ẹgbẹ́ ọmọ ogun ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó máa ń jagun nílẹ̀ òkèèrè wá lé àwọn ọmọ ogun ọlọ̀tẹ̀ jáde ní ìlú Freetown. Ogun ṣì ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan fúngbà díẹ̀, àmọ́ nígbà tó fi máa di January 2002, wọ́n kéde pé ogun ti parí. Nígbà ogun tí wọ́n fi ọdún mọ́kànlá jà yìí, ọ̀kẹ́ méjì àbọ̀ [50,000] èèyàn ni wọ́n pa, ọ̀kẹ́ kan [20,000] èèyàn ni wọ́n gé lápá tàbí lẹ́sẹ̀. Wọ́n ba ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [300,000] ibùgbé jẹ́, mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ mẹ́wàá [1,200,000] èèyàn ló sì di aláìrílégbé.

Báwo ni nǹkan ṣe wá rí fún ètò Jèhófà láwọn orílẹ̀-èdè yìí nígbà yẹn? Ó hàn kedere pé Jèhófà dáàbò bo ètò rẹ̀, ó sì bù kún un. Nígbà ogun yẹn, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] èèyàn ló ṣèrìbọmi. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló sá kúrò láwọn ibi tí ogun ti ń jà, síbẹ̀ iye akéde tó wà ní ilẹ̀ Sierra Leone tún fi àádọ́ta dín nírinwó àti mẹ́rin [354], ìyẹn ìlàjì iye tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀, lé sí i. Àwọn akéde tó wà ní ilẹ̀ Guinea fi ẹgbẹ̀ta dín mẹ́fà [594], ìyẹn ìlọ́po mẹ́ta iye tí wọ́n jẹ́ tẹ́lẹ̀, lé sí i! Pàtàkì jù lọ ni pé àwọn èèyàn Ọlọ́run pa ìwà títọ́ wọn mọ́. Lákòókò ‘ìléru ìṣẹ́ni-níṣẹ̀ẹ́’ náà, ẹ̀mí ìṣọ̀kan àti ìfẹ́ Kristẹni tí kò ṣeé já tó wà láàárín wọn túbọ̀ hàn gbangba, wọ́n sì “ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere.”—Aísá. 48:10; Ìṣe 5:42.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́