ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb16 ojú ìwé 158-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 1
  • Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Bọ́ sí Ojútáyé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Bọ́ sí Ojútáyé
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
  • Ìsọ̀rí
  • “Oyinmọmọ Niṣẹ́ Ìwàásù Níbí!”
  • Àwọn Pápá Tó Funfun fún Ìkórè
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
yb16 ojú ìwé 158-ojú ìwé 167 ìpínrọ̀ 1

INDONÉṢÍÀ

Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa Bọ́ sí Ojútáyé

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àjà kọkànlélọ́gbọ̀n [31] nínú ilé alájà méjìlélógójì [42] kan tó wà ní ìgboro Jakarta

Àwọn ọ́fíìsì tó wà ní àjà kọkànlélọ́gbọ̀n [31]

Lọ́dún 2008, iye àwọn akéde tó wà lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà ti di ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún, ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún [21,699]. Àyè kò sì mọ́ nínú ẹ̀ka ọ́fíìsì àti pé ibi tó wọnú la kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wa sí torí pé ìgbà ìfòfindè la kọ́ ọ. Kò sì àní-àní nígbà náà pé a nílò ẹ̀ka ọ́fíìsì tó tóbi dáadáa, tó sì sún mọ́ ìlú Jakarta.

Nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn náà, àwọn ará ra ibì kan tó yàtọ̀ síbi tá à ń lò tẹ́lẹ̀. A rí ọ́fíìsì kan tó jẹ́ ilé alájà méjìlélógójì [42] lára àwọn ilé ìgbàlódé nínú ìgboro Jakarta. La bá ra àjà kọkànlélọ́gbọ̀n [31] láti fi ṣe ẹ̀ka ọ́fíìsì. Ó wá kú ibi tí ìdílé Bẹ́tẹ́lì á máa gbé. Làwọn ará bá tún ra àjà méjìlá nínú ilé gogoró tó wà nítòsí ibẹ̀, èyí tó máa gba ọgọ́rin [80] èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, a tún ra odindi ilé alájà márùn-ún kan láti fi ṣe ọ́fíìsì fún ẹ̀ká tó ń bójú tó ìgbòkègbodó Bẹ́tẹ́lì.

Àjà méjìlá nínú ilé gogoro yìí ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń gbé

Àjà méjìlá nínú ilé gogoro yìí ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì ń gbé

Àwọn ará tó jẹ́ ìránṣẹ́ ìkọ́lé látilẹ̀ òkèèrè wá láti onírúurú ilẹ̀, wọ́n sì ṣiṣẹ́ pẹ̀lú agbaṣẹ́ṣe tí wọ́n gbéṣẹ́ náà fún. Wọ́n jọ tún àwọn ọ́fíìsì àtàwọn ilé gbígbé náà ṣe. Arákùnrin Darren Berg tó jẹ́ alábòójútó iṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ pé: “Léraléra ni Jèhófà bá wa mú àwọn ìṣòro tó dà bí òkè balẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a sọ pé a fẹ́ ṣe ẹ̀rọ ìgbàlódé kan sínú ilé náà tí yóò máa gbé omi ìdọ̀tí jáde, àwọn aláṣẹ sọ pé àwọn kò rí irú ẹ̀rọ bẹ́ẹ̀ rí, àwọn kò sì mọ bó ṣe máa ṣiṣẹ́, torí náà àwọn kò fọwọ́ sí i. Àmọ́ wẹ́rẹ́ ni Jèhófà bá wa ṣe é. Arákùnrin kan tó jẹ́ ẹnjiníà gbé ọ̀rọ̀ náà lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá ilé iṣẹ́ ìjọba kan. Bí ọ̀gá yẹn ṣe fọwọ́ sí i nìyẹn pé ká lọ ṣe ohun tá a fẹ́ ṣe, pé òun gbà gbọ́ pé a mọ ohun tá à ń sọ.”

“A ò sí ní kọ̀rọ̀ mọ́. Gbogbo ayé ló ń gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tí wá mọ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá mọ́”

February 14, 2015 la ya àwọn ibi tá à ń lò yìí sí mímọ́. Arákùnrin Anthony Morris III tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé ìyàsímímọ́ náà. Arákùnrin Vincent Witanto Ipikkusuma tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka sọ pé: “Ọ́fíìsì wa ti wá wà ní ojútáyé báyìí, níbi táwọn iléeṣẹ́ ńláńlá fìdí kalẹ̀ sí lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, a ò sí ní kọ̀rọ̀ mọ́. Gbogbo ayé ló ń gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n tí wá mọ̀ pé mìmì kan ò lè mì wá mọ́.”

Àwọn Mẹ́rin Tó Jẹ́ Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka ní Indonéṣíà

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka, láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Budi Sentosa Lim, Vincent Witanto Ipikkusuma, Lothar Mihank, Hideyuki Motoi

“Oyinmọmọ Niṣẹ́ Ìwàásù Níbí!”

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń wá láti orílẹ̀-èdè míì sí Indónéṣíà láti wá wàásù. Arákùnrin Lothar Mihank tó wà níbẹ̀ sọ pé: “Orílẹ̀-èdè wa náà wà lára àwọn tó ń jadùn iṣẹ́ ribiribi tí àwọn tó ń sìn níbi tí àìní pọ̀ sí ń ṣe. Àwọn ìjọ tí wọ́n ti ń sìn ń jàǹfààní látinú ìrírí wọn, ìdàgbàdénú wọn àti ìtara wọn. Ńṣe ni wọ́n mú káwọn ará túbọ̀ mọyì pé àwọn wà nínú ẹgbẹ́ ará kárí ayé.” Kí ló tiẹ̀ mú kí wọ́n wá sílẹ̀ yìí láti wá sìn? Báwo ni nǹkan ṣe rí fún wọn? Ẹ gbọ́ ohun tí díẹ̀ lára wọn sọ.

Janine àti Dan Moore; Mandy àti Stuart Williams; Casey àti Jason Gibbs; Mari àti Takahiro Akiyama

Àwọn Tó Ń Sìn Níbi Tí Àìní Pọ̀ Sí

1. Janine àti Dan Moore

2. Mandy àti Stuart Williams

3. Casey àti Jason Gibbs

4. Mari (lápá ọ̀tún ní iwájú) àti Takahiro Akiyama (lápá ọ̀tún lẹ́yìn)

Jason àti Casey Gibbs láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Nígbà tá à ń ka Ìwé Ọdọọdún, a rí i pé tá a bá fi wé àwọn orílẹ̀-èdè tó kù láyé, Indonéṣíà ló ní iye èèyàn tó pọ̀ jù tó yẹ kí akéde kọ̀ọ̀kan wàásù fún. Àwọn ọ̀rẹ́ wa tó ń sìn níbi tí àìní pọ̀ sí wá sọ fún wa pé àá gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Torí bẹ́ẹ̀, a fóònù ẹ̀ka ọ́fíìsì nílẹ̀ náà, wọ́n sì sọ fún wa pé ká lọ sí ìlú Bali. Ìhìn rere náà ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń sọ Gẹ̀ẹ́sì nílùú yẹn ni, ó ṣe kedere pé àá rí iṣẹ́ púpọ̀ ṣe. Ọdún kan péré la sọ pé a máa lò níbẹ̀, àmọ́ ọdún kẹta là ń lò yìí. Àwọn kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé ìgbà tá a wàásù fún wọn nìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n máa gbọ́ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wòó, a gbádùn iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀ gan-an ni!”

Stuart àti Mandy Williams, tọkọtaya kan tó ti dàgbà díẹ̀ tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà sọ ìrírí tiwọn, wọ́n ní: “Ọjọ́ pẹ́ tá a ti ń wá bá a ṣe máa wàásù fáwọn tí òùngbẹ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń gbẹ, ohun tó gbé wa dé orílè-èdè Indonéṣíà nìyẹn. Ìlú Malang ní àgbègbè East Java la kó lọ. Níbẹ̀, a bá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ Yunifásítì tí wọ́n ń sọ Gẹ̀ẹ́sì pàdé. Inú wọn dùn láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àní wọ́n tún jẹ dòdò ìkànnì jw.org! Iṣẹ́ ìwàásù níbí yìí ti lọ wà jù.”

Takahiro àti Mari Akiyama tí wọ́n ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà ní ìlú Yogyakarta tó wà ní erékùṣù Java sọ ní tiwọn pé: “Ọkàn wa balẹ̀ níbí, kò sí pákáǹleke bíi ti ìlú wa ní Japan. Àwọn èèyàn ibí nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnni. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ mọ̀ nípa àwọn ẹ̀sìn míì, pàápàá jù lọ, àwọn ọ̀dọ́. Lọ́jọ́ kan tá a pàtẹ àwọn ìwé wa sorí tábìlì, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [2,600] ìwé ìròyìn làwọn èèyàn gbà, láàárín wákàtí márùn-ún péré.”

Dan àti Janine Moore, tọkọtaya tí wọ́n ti lé ní ẹni àádọ́ta [50] ọdún sọ pé: “Nígbà tá a bá lọ wàásù, ńṣe làwọn èèyàn máa ń rọ̀gbà yí wa ká. A máa ń rẹ́rìn-ín sí wọn, àwọn náà á sì bú sẹ́rìn-ín. Wọ́n máa ń fẹ́ mọ ẹni tá a jẹ́, nígbà tá a bá sọ fún wọn, wọ́n máa ń fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ìyẹn sì máa ń múnú wọn dùn gan-an. Nígbà tá a bá ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún wọn nínú Bíbélì, wọ́n á béèrè pé: Ṣé mo lè kọ ọ́ sílẹ̀? Àwọn ohun tó mọ́gbọ́n dání tí wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì ṣáà ń yà wọ́n lẹ́nu. Kò tíì ju ọdún kan tá a débí, tá a bá ti mọ̀ ni, à bá ti wá ibí tipẹ́. Nígbà tá a wà ní Amẹ́ríkà, a máa ń wá ibi táwọn èèyàn púpọ̀ á ti gbọ́ ìwàásù. Àmọ́ níbi tá a wà báyìí, àìmọye èèyàn ló fẹ́ gbọ́rọ̀ Ọlọ́run!”

Misja àti Kristina Beerens wá ṣe míṣọ́nnárì níbí lọ́dún 2009, àmọ́ ní báyìí, alábòójútó àyíká ni wọ́n. Wọ́n ní: “Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ àtimáa gbọ́ ìwàásù gan-an ní erékùṣù Madura tó wà ní East Java, níbi táwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù ní orílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Àwọn èèyàn á páàkì mọ́tò wọn, wọ́n á ní ká fún àwọn ní àwọn ìwé ìròyìn wa. Wọ́n á sọ pé: ‘Lóòótọ́ Mùsùlùmí ni mí, àmọ́ mo máa ń gbádùn àwọn ìwé ìròyìn yín gan-an ni. Ṣé ẹ lè fún mi sí i kí n lè fún àwọn ọ̀rẹ́ mi?’ Oyinmọmọ niṣẹ́ ìwàásù níbí!”

Àwọn Pápá Tó Funfun fún Ìkórè

Lọ́dún 1931 tí Arákùnrin Frank Rice dé sí ìlú Jakarta, nǹkan bí ọgọ́ta mílíọ̀nù [60,000,000] èèyàn ló ń gbé ní Indonéṣíà. Àmọ́ lónìí, wọ́n ti di mílíọ̀nù lọ́nà igba ó lé ọgọ́ta [260,000,000] èèyàn. Èyí ló sọ orílẹ̀-èdè Indonéṣíà di orílẹ̀-èdè kẹ́rin tí èèyàn pọ̀ sí jù láyé.

Ìbísí tó kàmàmà bá àwa èèyàn Jèhófà náà lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1946, akéde mẹ́wàá ló ṣẹ́ kú lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì. Àmọ́ lónìí, akéde tó wà lórílẹ̀-èdè náà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26,000]. Ẹ ò rí i pé Jèhófà ti bù kún wa gan-an! Tá a bá sì wo ẹgbẹ̀rún márùndínlọ́gọ́ta, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́rìnlélọ́gọ́ta [55,864] èèyàn tó wá sí Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2015, ó ṣe kedere pé ọ̀pọ̀ ṣì máa wá sin Jèhófà.

Èyí rán wa létí ọ̀rọ̀ Jésù tó sọ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mát. 9:​37, 38) Àwọn èèyàn Jèhófà ní Indonéṣíà ń ṣe ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn. Wọ́n ti pinnu pé àwọn á máa sapá láti máa ṣe ohun tó máa fi kún ìjẹ́mímọ́ orúkọ ńlá Ọlọ́run ní orílẹ̀-èdè yìí àti kárí gbogbo erékùṣù tó wà níbẹ̀.​—Aísá. 24:⁠15.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàású fún ọkùnrin kan ní abúlé kan ní Indonéṣíà
    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́