INDONÉṢÍÀ
Jèhófà Bù Kún Wa Ju Bá A Ṣe Rò Lọ!
Angeragō Hia
WỌ́N BÍ I NÍ 1957
Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1997
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ó pa dà sí abúlé wọn tó wà ládàádó ní erékùṣù Nias, ó sì dá ìjọ kan sílẹ̀.
LỌ́DÚN 2013, a rí ìròyìn amóríyá kan gbà ní ìjọ wa kékeré tó wà nílùú Tugala Oyo, pé wọ́n ń bọ̀ wá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun fún wa! Àwọn aláṣẹ àdúgbò fàyè gba iṣẹ́ náà, ọgọ́ta [60] àwọn aládùúgbò wa ló fọwọ́ sí i kí iṣẹ́ náà bàa lè di ṣíṣe. Ọ̀kan lára wọn tiẹ̀ sọ pé: “Bó bá jẹ́ igba [200] èèyàn lẹ̀ ń wá pé kó fọwọ́ sí i, ẹ máa rí.”
Àwọn méjì lára àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tó máa ń yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wà lárọ̀ọ́wọ́tó, àwọn ló sì bá wa mójú tó bí iṣẹ́ náà ṣe ń lọ. A dúpẹ́ pé ní November 2014, iṣẹ́ náà parí. A ò tiẹ̀ lálàá ẹ̀ rí pé ìjọ wa náà máa ní irú ibi ìjọsìn to dára báyìí. Ká sòótọ́, Jèhófà bù kún wa ju bá a ṣe rò lọ!