Kánádà: Awọn ẹ̀yà Inuit ló ń gbé abúlé Kangirsuk tó wà ní àríwá Quebec
ÀWỌN OHUN PÀTÀKÌ TÓ ṢẸLẸ̀ LỌ́DÚN TÓ KỌJÁ
Ìròyìn—Nípa Àwọn Ará Wa
Kí Gbogbo Àwọn Tó Wà Ní Kánádà Lè Gbọ́ Ìhìn Rere
Ká lè mú ìhìn rere náà dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní orílẹ̀-èdè Kánádà ń bójú tó, a ti tú fídíò náà Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? sí èdè mẹ́jọ tí wọ́n ń sọ níbẹ̀. Nígbà táwọn ará lọ ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìwáásù ọlọ́jọ́ mẹ́wàá ní àgbègbè Nunavik Arctic ní October 2014, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ má sí ilé tí wọn ò ti fi fídíò náà hàn lédè Inuktitut ní gbogbo abúlé mẹ́wàá tí wọ́n ṣe. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn èèyàn tó ń gbé ní àwọn abúlé yìí ju ẹgbẹ̀rún méjìlá [12,000] lọ.
Inú Ọ̀gá Náà Dùn Gan-an
Pápá ìṣeré tí wọ́n ń pè ní Sangam World Cup Stadium la ti ṣe àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú Seoul ní orílẹ̀-èdè South Korea. September 2014 la ṣe é, àwọn tó sì gbádùn àpéjọ náà lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlọ́gọ́ta [56,000]. Ọ̀gá tó ń bójú tó pápá ìṣeré náà dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ará fún bí wọ́n ṣe hùwà ọmọlúwàbí àti bí wọ́n ṣe fọwọ́sowọ́pọ̀ nígbà àpéjọ náà. Ó sọ pé: “Ìwà tó bójú mu ni gbogbo wọn ń hù. Àní, bí wọ́n ṣe tún pápá ìṣeré náà ṣe dáa ju bí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tá a gbà ṣe máa ń tún un ṣe lọ. Kò bá wù mí pé káwọn òṣìṣẹ́ wa máa fi tọkàn tara ṣiṣẹ́ bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó ṣe yẹ kí gbogbo wa máa ṣẹ̀sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe é yìí.”
South Korea: Àpéjọ àgbáyé tá a ṣe nílùú Seoul lọ́dún 2014
Jèhófà Kọ́ Wọn Ní Ohun Tí Wọ́n Máa Sọ
Nígbà táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀wé sí ìjọba orílẹ̀-èdè Sweden pé kí wọ́n fún wa ní ẹ̀dínwò tí ìjọba ń fún àwọn ẹlẹ́sìn tó kù lábẹ́ òfin, ìjọba kọ̀ jálẹ̀. Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ gíga ti orílẹ̀-èdè náà.
Ilé ẹjọ́ gíga sọ pé àwọn fẹ́ gbọ́rọ̀ lẹ́nu wa kí wọ́n tó dájọ́. Káwọn ará wa lè múra sílẹ̀, àwọn ará láti oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè kóra jọ láti múra bí wọ́n á ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣeé ṣe kí wọ́n béèrè nílé ẹjọ́. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìlú Stockholm ni wọ́n lò fún ìmúrasílẹ̀ yìí.
Bí wọ́n ṣe ń ṣèyẹn lọ́wọ́ ni aago ilẹ̀kùn Gbọ̀ngàn Ìjọba dún. Nígbà tí arákùnrin kan lọ ṣílẹ̀kùn, àwọn ọmọbìnrin méjì ló bá níbẹ̀, ọ̀kan ọmọ ọdún mẹ́tàlá àti ìkejì ọmọ ọdún mẹ́rìnlà. Wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ béèrè àwọn ìbéèrè kan nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Arákùnrin yẹn rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Mo fẹ́ sọ fún wọn pé kí wọ́n pa dà wá lọ́jọ́ míì, torí a ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pàkúta sí ìmúrasílẹ̀ tá à ń ṣe.”
Síbẹ̀, arákùnrin náà gbà láti bá wọn sọ̀rọ̀. Àwọn ọmọbìnrin náà béèrè ọ̀pọ̀ ìbéèrè títi kan ìbéèrè nípa rògbòdìyàn ìlú àti bóyá ó yẹ kéèyàn máa dìbò. Nígbà tí arákùnrin náà pa dà sọ́dọ̀ àwọn tó kù, ó sọ fún wọn nípa àwọn ìbéèrè tí wọ́n béèrè àti bí òun ṣe dá wọn lóhùn.
Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ará náà pé nígbà tí wọ́n dé ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ kéjì, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè tí àwọn ọmọbìnrin yẹn béèrè ni wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ wọn. Àrákùnrin tó gbẹnusọ fún wa sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iwájú àwọn amòfin tó gbajúmọ̀ ni mo wà, mi ò gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ṣe lọkàn mi balẹ̀. Mo nímọ̀lára pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa torí pé ní ọjọ́ tó ṣáájú ló ti kọ́ wa ní ohun tá a máa sọ.”
Ilé ẹjọ́ kéde pé lóòótọ́ la lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin, wọ́n sì ní kí ìjọba tún èrò wọn pa lórí ọ̀rọ̀ náà.
Àpò Ráìsì Kan Látọ̀dọ̀ Ken
Orílẹ̀-èdè Haiti ni Ken tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà ń gbé. Ayọ̀ rẹ̀ kọjá àfẹnusọ nígbà tó gbọ́ pé wọn ò ní pẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọ̀ba fún ìjọ wọn. Ló bá ṣe àpótí ọrẹ kan, ó sì gbé e pamọ́ sí yàrá rẹ̀ láìsọ fún ẹnì kankan. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó tí àwọn òbí rẹ̀ máa ń fún un pé kó ná ní ilé-ìwé pa mọ́ síbẹ̀. Bó ṣe ń ṣe lójoojúmọ́ nìyẹn títí tí àwọn tó máa bá wọn kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọ̀ba náà fi dé láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́. Ìgbà tí wọ́n dé ló gbé àpótí náà jáde, ó sì gbé e fún wọn. Nígbà tí wọ́n ṣí àpótí náà, ǹjẹ́ ẹ mọ iye tí Ken ti tù jọ? Owó náà tó ra àpò ráìsì ńlá kan. Àìmọye ọjọ́ ló fi jẹ́ pé ráìsì Ken yìí ni wọ́n jẹ lọ́sàn níbi ìkọ́lé náà.
Àṣẹ Látọ̀dọ̀ Ọ̀ga Ológun
Lọ́dún tó kọjá, ó pọn dandan kéèyàn gbàwé àṣẹ tó bá fẹ́ wọ àwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Siria Lóònù nítorí àrùn Ebola tó gbòde kan làwọn àgbègbè yẹn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn alábòójútó àyíká gbọ́dọ̀ gba báàjì àyà àti ìwé ọkọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ kí wọ́n tó wọ àwọn àgbègbè yìí. Bẹ́ẹ̀ náà làwọn iléeṣẹ́ tó ń bá wa kó àwọn ìwé àti lẹ́tà lọ fáwọn ará. Àwọn ará tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Tó Ń Pèsè Ìrànwọ́ náà gbọ́dọ̀ gbàwé àṣẹ kí wọ́n lè kó àwọn nǹkan táwọn ara tó ń gbé lágbègbè yìí nílò lọ fún wọn, ìyẹn àwọn nǹkan bí oúnjẹ, ọṣẹ àti irinṣẹ́ tí wọ́n fi ń mọ bí ara èèyàn ṣe gbóná tó. Síbẹ̀, ó yà wá lẹ́nu pé gbogbo ìgbà tá a bá béèrè fún àwọn ìwé àṣẹ yìí la máa ń rí i gbà.
Lọ́jọ́ kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an. Àwọn ará kọ̀wé béèrè fún báàjì àyà mẹ́rìnlélọ́gbọ́n [34] àti ìwé ọkọ̀ mọ́kànlá [11], àmọ́ wọ́n ní kí wọ́n lọ rí ọ̀gá àgbà ológun kan kó lè fọwọ́ sí i. Àwọn arákùnrin méjì láti ẹ̀ka ọ́fíìsí lọ rí ọ̀gá àgbà ológun yìí pẹ̀lú ète pé wọ́n á rí àwọn báàjì àyà àti ìwé ọkọ̀ náà gbá lọ́jọ́ yẹn. Àmọ, wọn ò rí ìwé tí àwọn ará ti mú wá látọjọ́ yìí. Wọ́n ní káwọn ará wá ìwé náà láàárín òkìtì ìwé tó wà ní ọ́fíìsì náà, àmọ́ wọn ò rí ohun tó jọ ọ́. Ìgbà yẹn ní ọ̀gá ológun yẹn wá sọ fún akọ̀wé rẹ́ pé òun ti ń lọ, àti pé ó di ẹ̀yìn ọ̀sẹ̀ méjì kí òun tún tó fọwọ́ sí àwọn ìwé tó kù. Kí làwọn arákùnrin yìí gbọ́ èyí sí, ṣe ni wọ́n sáré fi ọkàn gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ran àwọn lọ́wọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí wọ́n ṣe gbàdúrà yìí tan ni ọ̀gá náà wò wọ́n lójú, tó ní: “Báàjì àyà àti ìwé ọkọ̀ mélòó lẹ ni ẹ fẹ́?” Nígbà tí wọ́n sọ iye rẹ̀ fún un, ó fò dìde lórí àga rẹ̀, ò fìbínú pariwo pé: “Kí ló dé? Ìyẹn ti pọ̀ jù!”
Àwọn arákùnrin náà fara balẹ̀ ṣàlàyé iṣẹ́ wa àti bí àwọn ohun ìrànwọ́ tá a ń kó ránṣẹ́ ṣe ń mú nǹkan rọrùn pẹ̀lú àrùn Ebola tó gbòde kan. Ni ọ̀gá náà bá wò lọ suu, ó yíjú sí akọ̀wé rẹ̀, ó sì sọ pé: “Fún wọn ní gbogbo ohun tí wọ́n béèrè.”
Gínì àti Siria Lóònù: Gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba la ti ṣètò bí àwọn èèyàn á ṣe máa fọwọ́ wọn