ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 68
  • Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kí ló burú níbẹ̀?
  • Ṣé nǹkan wà tó o lè ṣe?
  • Kí Ló Máa Ń Mú Mi Ronú Pé Kò Yẹ Kí N Ṣe Àṣìṣe Kankan?
    Jí!—2003
  • Kí Ló Mú Kí N Máa Rò Pé Mi Ò Gbọ́dọ̀ Ṣàṣìṣe?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Ká Borí Ẹ̀mí Ìṣefínnífínní Dóríi Bíńtín?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ṣíṣàì Fẹ́ Ṣe Àṣìṣe Kankan?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 68
Ọ̀dọ́kùnrin kan ń yàwòrán ẹṣin, ó ti yà á sínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ bébà tẹ́lẹ̀ àmọ́ ó ti rún un torí kò rí bó ṣe fẹ́ kó rí

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Gbogbo Nǹkan Ni Mo Máa Ń Fẹ́ Ṣe Láìṣe Àṣìṣe Kankan?

Tí o bá máa ń

  • fẹ́ gba gbogbo máàkì tán nínú ìdánwò ẹ níléèwé

  • fẹ́ sá fún ṣíṣe ohun tó ò ṣe rí torí pé o ò fẹ́ ṣàṣìṣe rárá

  • wo gbogbo àwọn tó ń fi ibi tó o kù sí hàn ẹ́ bí ẹni pé wọ́n ń bà ẹ́ lórúkọ jẹ́

. . . , a jẹ́ pé ìdáhùn ẹ sí ìbéèrè tó wà lókè yìí lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni. Àmọ́ kí ló burú níbẹ̀?

  • Kí ló burú níbẹ̀?

  • Ṣé nǹkan wà tó o lè ṣe?

  • Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Kí ló burú níbẹ̀?

Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa gbìyànjú láti ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe kí nǹkan lè dáa. Àmọ́, ìwé Perfectionism​—What’s Bad About Being Too Good? sọ pé, “Kéèyàn máa ṣe ìwọ̀n tó lè ṣe káwọn ohun tó ń ṣe lè yọrí sí rere yàtọ̀ pátápátá sí kéèyàn máa fi taratara lé ohun tí ọwọ́ ẹ̀ ò lè tó.” Ìwé náà fi kún un pé: “Téèyàn bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe rárá, onítọ̀hún a kàn para ẹ̀ ni, torí ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó pé.”

Ohun tí Bíbélì náà sọ nìyẹn. Ó ní: “Kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé [tó máa] ń ṣe rere.” (Oníwàásù 7:​20) Torí pé aláìpé ni ẹ́, àwọn ohun tó o bá ṣe lè má dáa tán nígbà míì.

Ṣó nira fún ẹ láti gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn? Tó bá nira fún ẹ, wo ọ̀nà mẹ́rin tó lè gbà ṣàkóbá fún ẹ tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan.

  1. Ojú tó o fi ń wo ara ẹ. Ohun tí ọwọ́ wọn ò lè tó làwọn tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe máa ń lé, ìjákulẹ̀ ló sì máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Alicia sọ pé, “Ká sòótọ́, kì í ṣe gbogbo nǹkan náà la lè mọ̀ ọ́n ṣe dáadáa, tá a bá sì wá ń fojú kéré ara wa torí pé gbogbo nǹkan kọ́ la mọ̀ ọ́n ṣe, a ò ní lè fi ìdánilójú ṣe nǹkan kan mọ́. Ṣe nìyẹn sì máa ń múni rẹ̀wẹ̀sì.”​—Alicia

  2. Ojú tó o fi ń wo ìmọ̀ràn rere táwọn míì gbà ẹ́. Lójú àwọn tó máa ń fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan, ṣe ló máa ń dà bí ẹni fẹ́ bà wọ́n lórúkọ jẹ́ téèyàn bá fi ibi tí wọ́n kù sí hàn wọ́n, tó sì gbà wọ́n nímọ̀ràn. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Jeremy sọ pé: “Kì í dùn mọ́ mi nínú rárá tí wọ́n bá bá mi wí.” Ó wá sọ pé, “Téèyàn bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe rárá, kò ní jẹ́ kéèyàn rántí pé ó níbi tágbára èèyàn mọ, èèyàn ò sì ní máa gbàmọ̀ràn àwọn míì.”

  3. Ojú tó o fi ń wo àwọn míì. Àwọn tó máa ń fẹ́ ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan máa ń rí sí àwọn míì, ìdí tí wọ́n sì fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ rèé. Anna tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún [18] sọ pé, “Tó o bá ń retí pé kó o ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe, ohun tí wàá máa retí káwọn míì ṣe náà nìyẹn. Tí wọ́n bá wá ń ṣàṣìṣe, inú ẹ ò ní máa dùn sí wọn.”

  4. Ojú tí àwọn míì fi ń wò ẹ́. Tó o bá ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì, má ṣe jẹ́ kó yà ẹ́ lẹ́nu tí àwọn èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í sá fún ẹ! Beth tó ti dàgbà díẹ̀ sọ pé, “Ó máa ń máyé súni téèyàn bá ń bá ẹni tí kì í fẹ́ ṣàṣìṣe kankan ṣiṣẹ́. Kò sẹ́ni tó máa ń fẹ́ dúró ní sàkáání irú ẹni bẹ́ẹ̀!”

Ṣé nǹkan wà tó o lè ṣe?

Bíbélì sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ìfòyebánilò yín di mímọ̀.” (Fílípì 4:5) Àwọn tó jẹ́ afòyebánilò kì í retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara wọn àti lọ́wọ́ àwọn ẹlòmíì.

“Ìṣòro tá à ń kojú láyé yìí tó lọ́tọ̀. Ṣó wá yẹ kéèyàn tún dì kún ìṣòro ara ẹ̀, kó fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan? Èèyàn á kàn ṣera ẹ̀ léṣe lásán ni!”​—Nyla.

Bíbélì sọ pé: “Jẹ́ ẹni tí ó mẹ̀tọ́mọ̀wà ní bíbá Ọlọ́run rẹ rìn!” (Míkà 6:8) Àwọn tó mẹ̀tọ́mọ̀wà máa ń mọ ibi tí agbára wọn mọ. Wọn kì í ṣe ohun tó ju agbára wọn lọ, wọn kì í sì í lò kọjá àkókò tí wọ́n bá mọ̀ pé agbára àwọn lè gbé nídìí iṣẹ́ kan.

“Tí mo bá fẹ́ kí inú mi máa dùn pé mò ń ṣiṣẹ́ mi dáadáa, iṣẹ́ tí mo bá mọ̀ pé agbára mi á gbé ni mo máa ń dáwọ́ lé. Mi kì í ṣe kọjá agbára mi.”​—Hailey.

Bíbélì sọ pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Oníwàásù 9:​10) Torí náà, kì í ṣe pe wàá wá di ọ̀lẹ torí pé o ò fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe. Kò yẹ kó o fiṣẹ́ ṣeré, síbẹ̀ ó yẹ kó o máa ṣe ohun méjì tá a sọ lókè yìí bó o ṣe ń ṣiṣẹ́ kára: Àkọ́kọ́, máa fòye báni lò, ìyẹn ni pé kó o má retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara ẹ. Èkejì, mẹ̀tọ́ mọ̀wà, ìyẹn ni pé kó o mọ ibi tí agbára ẹ mọ.

“Ọwọ́ tó ṣe pàtàkì gan-an ni mo fi máa ń mú iṣẹ́ mi, tọkàntọkàn sì ni mo máa ń ṣe é. Mo mọ̀ pé kò sí bí àṣìṣe ò ṣe ní wáyé, àmọ́ inú mi máa ń dùn pé gbogbo ọkàn mi ni mo fi ṣe é.”​—Joshua.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

Sierra

“Tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe, á mú kí nǹkan nira fún ẹ gan-an, inú ẹ ò sì ní dùn tẹ́nì kan bá rí i pé o kù síbì kan, tó sì gbà ẹ́ nímọ̀ràn. Ohun tí mo ti kọ́ ni pé téèyàn bá ṣàṣìṣe, kó má wo àṣìṣe yẹn bíi pé òun ò mọ nǹkan kan ṣe, ṣe ló yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀.”​—Sierra.

Bo

“Ṣe ni inú ẹ á kàn máa bà jẹ́ tó o bá fẹ́ máa ṣe gbogbo nǹkan láìṣe àṣìṣe kankan. Wàá tún máa fara ni àwọn ọ̀rẹ́ ẹ torí ṣe ló máa dà bíi pé ò ń rí sí wọn, ó sì tún lè dà bíi pé ò ń wò ó pé wọn ò mọ nǹkan ṣe.”​—Bo.

Sarina

“Wákàtí mẹ́rìnlélógún [24] péré la ní lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì wà tó yẹ kéèyàn ṣe. Téèyàn bá wá lọ ń ranrí mọ́ gbogbo nǹkan dórí bíńtín, àkókò tó yẹ kó fi ṣe àwọn nǹkan pàtàkì míì, bí àkókò oúnjẹ tàbí àkókò oorun, lè lọ sí i.”​—Sarina.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́