Àwọn Tí Wọ́n Ti Bá Ṣèṣekúṣe Lọ́mọdé
OBÌNRIN kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Eilenea sọ pé: “Mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ogójì (40) ọdún báyìí, ó sì ti lé lọ́gbọ̀n (30) ọdún tí ohun tó ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá mi ti ṣẹlẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń bà mí lọ́kàn jẹ́, inú kàn máa ń ṣàdédé bí mi, mo máa ń dá ara mi lẹ́bi, kódà ó máa ń fa ìṣòro láàárín èmi àti ọkọ mi. Àwọn èèyàn gbìyànjú kí wọ́n lè lóye ohun tó ń ṣe mí, àmọ́ kò yé wọn, kò sì lè yé wọn.” Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Eilene gan-an? Wọ́n bá a ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé, ìyẹn sì dá ọgbẹ́ sọ́kàn rẹ̀, kódà ọgbẹ́ ọ̀hún kò tíì jinná.
Kì í ṣe Eilene nìkan nirú nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ sí. Ìwádìí fi hàn pé àìmọye àwọn èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin làwọn ẹni ibi ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé.b Ọ̀rọ̀ yìí ti kúrò lóhun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ti di àìsàn tó ń jà ràn-ìn. Kódà, onírúurú èèyàn ló ń hùwà burúkú yìí, àtolówó àti tálákà, títí kan àwọn tó lẹ́nu láwùjọ àtàwọn onísìn.
Ohun kan tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ ni pé ojú burúkú lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe, wọn ò tiẹ̀ jẹ́ ronú ẹ̀ láé pé àwọn á ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀. Bó ti wù kó rí, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ohun tó máa ń wù wọ́n nìyẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe kò ní nǹkan míì tí wọ́n ń fi ọpọlọ wọn rò, àfi kí wọ́n bọ́mọdé lò pọ̀. Wọ́n gbà pé ìwà wèrè yìí ló máa ń darí wọn, òun ló sì máa ń mú kí wọ́n lúgọ kiri ibi táwọn ọmọdé ti ń ṣeré. Irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wà lóòótọ́, àmọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Lọ́wọ́ kejì, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn abọ́mọdé ṣèṣekúṣe lèèyàn kì í fura sí, bẹ́ẹ̀ lẹ ò sì ní mọ̀ pé wọ́n ń hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Kódà, èèyàn á rò pé èèyàn gidi ni wọ́n. Kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn, wọ́n máa ń ṣọ́ àwọn ọmọdé tí ò dákan mọ̀, tí wọn ò sì lè dáàbò bo ara wọn. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ọmọ tiwọn alára ni wọ́n máa ń bá ṣèṣekúṣe.c Tẹ́ ẹ bá rí wọn níta, wọ́n á máa fẹ́ àwọn ọmọ náà lójú àti nímú, wọ́n á sì máa ṣìkẹ́ wọn. Àmọ́ tó bá ku àwọn nìkan pẹ̀lú ọmọ náà, wọ́n á halẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n lè lù ú, lẹ́yìn náà wọ́n á bá a ṣèṣekúṣe.
Ká sòótọ́, ó ṣòro gbà gbọ́ pé irú ìwà abèṣe yìí lè máa ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ìdílé tó jọ pé gbogbo nǹkan ń lọ dáadáa. Kódà lásìkò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn òbí kan máa ń fi àwọn ọmọ wọn dúró ‘kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn.’ (The International Critical Commentary; fi wé Jóẹ́lì 3:3.) Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n mọ èyí, pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá . . . aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere.” Torí náà, kò yani lẹ́nu pé bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe ti gbòde kan lónìí.—2 Tímótì 3:1, 3, 13.
Èèyàn lè má rí ojú àpá kankan lára ọmọ tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe. Bákan náà, kì í ṣe gbogbo àgbàlagbà tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé ló máa ń hàn pé wọ́n ní ẹ̀dùn ọkàn. Àmọ́, òwe àtijọ́ kan sọ pé: “Nínú ẹ̀rín pàápàá, ọkàn-àyà lè wà nínú ìrora.” (Òwe 14:13) Bí ẹsẹ yìí ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé ló máa ń ní ọgbẹ́ ọkàn, ọgbẹ́ tó fara sin, tí kì í jinná bọ̀rọ̀. Kí nìdí tí ìwà ìkà yìí fi máa ń ṣàkóbá tó lágbára bẹ́ẹ̀ fáwọn tó ṣẹlẹ̀ sí? Kí nìdí tó fi jẹ́ pé bó ti wù kọ́rọ̀ náà pẹ́ tó, ọgbẹ́ náà kì í tètè jinná? Ó ṣe kedere pé ìwà ìkà tó burú jáì nìwà yìí, ó sì yẹ ká sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ká sòótọ́, díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a máa jíròrò báyìí lè má bára dé fún àwọn kan láti kà, pàápàá fún àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé. Àmọ́, fọkàn balẹ̀ torí pé ìrètí ṣì wà fún ẹ, bẹ́ẹ̀ ni, o lè borí ẹ̀dùn ọkàn rẹ.
a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.
b Torí pé ìtumọ̀ táwọn èèyàn fún bíbá ọmọdé ṣèṣekúṣe yàtọ̀ síra àti pé ẹnu ò kò nípa bó ṣe wọ́pọ̀ tó, ìdí nìyẹn tó fi ṣòro láti ṣírò iye àwọn tírú ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí.
c Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe lọ́mọdé ló jẹ́ pé bàbá wọn tàbí àwọn tó dà bíi bàbá fún wọn ló bá wọn lò pọ̀. Nígbà míì, ó lè jẹ́ ẹ̀gbọ́n wọn, ìbátan wọn, bàbá àgbà wọn, àgbàlagbà míì àtàwọn tí kò tan mọ́ wọn. Obìnrin ló pọ̀ jù lára àwọn ọmọ tí wọ́n ti bá ṣèṣekúṣe, àmọ́ ó máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn ọmọkùnrin náà. Torí náà, àtọkùnrin àti obìnrin làwọn àpilẹ̀kọ yìí máa ṣe láǹfààní.