Àgbàyanu Àgbáálá Ayé
Ohun Tí Ìbúgbàù Ńlá Náà Ṣàlàyé—Ohun Tí Kò Ṣàlàyé
ÌYANU ni gbogbo òwúrọ̀. Lọ́hùn-ún nínú oòrùn òwúrọ̀, èròjà hydrogen ń wọnú helium ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù. Ìtànṣán X ray àti gamma ray tí ó kún fún ìrọ́gììrì lílé kenkà ń tú jáde láti àárín gbùngbùn oòrùn sí àyíká rẹ̀. Bí oòrùn náà bá ń fòdì kejì hàn, àwọn ìtànṣán gbígbóná bí ajere wọ̀nyí yóò fipá kọjá ní ìwọ̀nba ìṣẹ́jú àáyá. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ta bọ́n-ún láti ara àwọn átọ́ọ̀mù fífún pọ̀ mọ́ra “adáàbò bo” oòrùn kan sí òmíràn, wọ́n sì ń pàdánù agbára wọn díẹ̀díẹ̀. Ọjọ́, ọ̀sẹ̀, ọ̀rúndún, ń kọjá lọ. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, ìrànyòò aṣèpalára nígbà kan rí náà wá yọjú níkẹyìn láti ara oòrùn gẹ́gẹ́ bí ìtànṣán ìmọ́lẹ̀ aláwọ̀ ìyeyè fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́—kì í ṣe ewu mọ́ ṣùgbọ́n, ó jẹ́ èyí tí ó bá a mu rẹ́gí fún fífi ìlọ́wọ́ọ́wọ́ rẹ̀ pèsè ìmóoru fún ayé.
Ìyanu ni gbogbo alẹ́ pẹ̀lú. Àwọn oòrùn míràn ń la ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ńláǹlà kọjá láti tàn yanranyanran sí wa. Àwọn àwọ̀ wọn, ìwọ̀n ìtóbi wọn, ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù wọn àti àwọn ìdíwọ̀n ìkìmọ́ra wọn kò bára dọ́gba. Àwọn kan tóbi gbàràmùgbaramu gan-an débi pé bí ọ̀kan lára wọ́n bá wà ní ibi tí oòrùn wa wà, yóò gbé pílánẹ́ẹ̀tì wa mì pátápátá. Àwọn oòrùn míràn jẹ́ láróńdó funfun, jáńjálá—wọ́n kéré ju ilẹ̀ ayé wa lọ, síbẹ̀ wọ́n wúwo bí oòrùn wa. Àwọn kan máa ń wà fún ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún. Àwọn mìíràn máa ń fọ́ yángá nígbà ìbúgbàù ìràwọ̀ ńlá, tí wọn óò sì rọra yọrí ọlá ju gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ tí ó kù lọ.
Àwọn ènìyàn ìjímìjí sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹran ńlá inú òkun àti àwọn ọlọrun tí ń jìjàkadì, nípa àwọn dírágónì àti àwọn ìjàpá àti àwọn erin, nípa àwọn òdòdó inú omi àti àwọn ọlọrun tí ń lálàá láti ṣàpẹẹrẹ àgbáálá ayé. Nígbà tí ó yá, ní àkókò tí wọ́n pè ní Sànmánì Ìrònújinlẹ̀, wọ́n fi àwọn “idán” ìlànà ìṣèṣirò àti àwọn ìlànà òfin Newton tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí gbá àwọn ọlọrun náà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan. Nísinsìnyí, a ń gbé nínú sànmánì tí a fi àwọn ewì àti ìtàn àtijọ́ dù. Àwọn ọmọ sànmánì ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ọlá àṣẹ òde òní kò yan àwọn ẹran ńlá inú òkun ti ìjímìjí, wọn kò yan “ẹ̀rọ ìṣàpẹẹrẹ ètò ìgbékalẹ̀ oòrùn” ti Newton gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìṣẹ̀dá ní tiwọn, ṣùgbọ́n ohun ìṣàpẹẹrẹ ajọbaborí ti ọ̀rúndún ogún náà—bọ́m̀bù. Ìbúgbàù ni “ẹlẹ́dàá” wọn. Wọ́n pe ìbúgbàù àgbáálá ayé wọn ní ìbúgbàù ńlá.
Ohun Tí Ìbúgbàù Ńlá Náà “Ṣàlàyé”
Abala tí ó gbajúmọ̀ jù lọ nínú ojú ìwòye ìran yìí nípa ìṣẹ̀dá sọ pé, ní nǹkan bíi bílíọ̀nù 15 sí 20 ọdún sẹ́yìn, àgbáálá ayé kò sí, bẹ́ẹ̀ ni gbalasa òfuurufú tí ó ṣófo kò sí pẹ̀lú. Kò sí àkókò, kò sí ohun kankan—àyàfi ojúkò kan tí ó ṣù pọ̀ láìlópin, tí ó kéré jọjọ, tí a ń pè ní ìdádó gedegbe, tí ó wá bú gbàù di àgbáálá ayé tí ó wà nísinsìnyí. Ìbúgbàù yẹn ní nínú, àkókò ráńpẹ́ kan nígbà ìpín kékeré àkọ́kọ́ ti ìṣẹ́jú àáyá kan nígbà tí àgbáálá ayé kóńkóló náà wú dàgbà, tàbí fẹ̀ lára, lọ́nà tí ó túbọ̀ yára ju ìmọ́lẹ̀ lọ.
Láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀ àkọ́kọ́ tí ìbúgbàù ńlá náà ṣẹlẹ̀, ìsopọ̀ náà ṣẹlẹ̀ káàkiri àgbáálá ayé, ní ṣíṣokùnfà ìpọ̀rẹpẹtẹ hydrogen àti helium tí a wọ̀n wò láìpẹ́ yìí, àti, ó kéré tán, apá kan lithium inú gbalasa òfuurufú àárín àwọn ìràwọ̀. Bóyá lẹ́yìn nǹkan bí 300,000 ọdún, ìbúgbàù náà lọ sílẹ̀ díẹ̀ ré kọjá ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ara oòrùn, tí ó sì ń fàyè gba àwọn electron láti di òpó yíká àwọn átọ́ọ̀mù, tí ó sì ń gbé ìbùyẹ̀rì àwọn photon, tàbí ìmọ́lẹ̀ jáde. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a ti mú un tutù gan-an, a lè wọn ìbùyẹ̀rì tí a kọ́kọ́ ṣẹ̀dá yẹn lónìí gẹ́gẹ́ bí ìrànyòò àtilẹ̀wá gbogbogbòò ní ìwọ̀n iye àyídé ìgbì mànàmáná òun òòfà tí ó dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù 2.7 Kelvin.a Ní tòótọ́, àwárí ìrànyòò àtilẹ̀wá yìí ní 1964 sí 1965 ni ó mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ gbà gbọ́ pé ohun gidi kan wà nípa àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà. Àbá èrò orí náà tún ṣàlàyé ìdí tí ó fi jọ pé àgbáálá ayé ń fẹ̀ sí i láti ìhà gbogbo, pẹ̀lú bí ó ti hàn gbangba pé àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ń sá lọ fún wa àti fún ara wọn pẹ̀lú eré púpọ̀ jọjọ.
Níwọ̀n bí àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà ti jọ bí èyí tí ó ṣàlàyé ohun púpọ̀, kí ló wá dé tí a fi ń ṣe iyè méjì nípa rẹ̀? Nítorí pé, ohun púpọ̀ ṣì tún wà tí kò ṣàlàyé. Láti ṣàkàwé rẹ̀: Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ìgbàanì náà, Ptolemy, ní àbá èrò orí kan pé, oòrùn àti àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ń yí ayé po lọ́nà lílé kenkà, tí wọ́n sì ń fa àwọn ilà roboto kéékèèké, tí a ń pè ní epicycle, lákòókò kan náà. Ó jọ pé àbá èrò orí náà ṣàlàyé ìgbésẹ̀ àwọn pílánẹ́ẹ̀tì. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ṣe ń ṣàkójọ àwọn ìsọfúnni oníṣirò púpọ̀ sí i, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé pẹ̀lú àbá èrò orí ti Ptolemy lè máa fìgbà gbogbo fi àwọn epicycle púpọ̀ sí i kún àwọn epicycle wọn mìíràn, kí wọ́n sì “ṣàlàyé” ìsọfúnni oníṣirò tuntun náà. Ṣùgbọ́n, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé àbá èrò orí yẹn tọ̀nà. Níkẹyìn pátápátá, ìsọfúnni oníṣirò tí a ní láti ṣàlàyé wulẹ̀ ti pọ̀ jù, tí àwọn àbá èrò orí mìíràn, irú bí èrò ti Copernicus pé, ayé ń yí oòrùn po sì ṣàlàyé àwọn nǹkan lọ́nà tí ó túbọ̀ péye, tí ó sì túbọ̀ rọrùn. Lónìí, ó ṣòro láti rí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà pẹ̀lú àbá èrò orí ti Ptolemy!
Ọ̀jọ̀gbọ́n Fred Hoyle fi ìsapá àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé tí wọ́n ní àbá èrò orí ti Ptolemy, tí wọ́n gbìyànjú láti tún gbé àbá èrò orí wọn tí ó já kulẹ̀ kalẹ̀ bí wọ́n ti ń dojú kọ àwọn àwárí tuntun, wé ìgbìyànjú àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ nínú ìbúgbàù ńlá náà lónìí kí àbá èrò orí wọn ba lè ní ìtẹ́wọ́gbà. Ó kọ nínú ìwé rẹ̀, The Intelligent Universe, pé: “Lájorí ìsapá tí àwọn olùṣèwádìí ṣe ti wà nínú ìtakora fífara sin nínú àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà, láti gbé èrò kan tí ó lọ́jú pọ̀, tí ó sì ń fa ìnira, kalẹ̀.” Lẹ́yìn títọ́ka sí àwọn epicycle ti Ptolemy lò láti gba àbá èrò orí rẹ̀ sílẹ̀ ṣùgbọ́n tí kò ṣiṣẹ́, Hoyle ń bá a lọ pé: “Ó dá mi lójú pé, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, ìbòjú kékeré aláìlágbára kan ń fì dirodiro lórí àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà. Bí mo ti sọ níṣàájú, nígbà tí a bá gbé ìlànà òkodoro kan dìde láti kọjú ìjà sí àbá èrò orí kan, ìrírí fi hàn pé, kì í sábà kọ́fẹ padà.”—Ojú ìwé 186.
Ìwé ìròyìn New Scientist, December 22 àti 29, 1990, ké atótó èrò kan náà pé: “A ti lo ìlànà àbá èrò orí ti Ptolemy nílòkulò gan-an . . . irú ẹ̀yà ìbúgbàù ńlá ti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé.” Ó wá béèrè lẹ́yìn náà pé: “Báwo ni a ṣe lè ṣàṣeyọrí ìtẹ̀síwájú gidi nínú ìmọ̀ physics nípa agbára gíga àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé? . . . A gbọ́dọ̀ túbọ̀ lótìítọ́ ọkàn, kí a sì má ṣe fọ̀rọ̀ bọpo-bọyọ̀ nípa bí díẹ̀ lára àwọn ìgbèrò wa tí a nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ ṣe jẹ́ ìméfò pátápátá tó.” Àwọn àkíyèsí tuntun ń ya wọlé nísinsìnyí.
Àwọn Ìbéèrè Tí Ìbúgbàù Ńlá Náà Kò Dáhùn
Lájorí ìpèníjà kan tí ìbúgbàù ńlá náà ní wá láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí tí ń lo àwọn àgbá ìríran Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble láti wọn bí àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ míràn ṣe jìnnà tó. Ìsọfúnni oníṣirò tuntun náà ń rú àwọn alábàá èrò orí náà lójú!
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà Wendy Freedman àti àwọn yòókù lo Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble láìpẹ́ yìí láti wọn bí ọ̀nà ti jìn tó sí ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ kan nínú ìdìpọ̀ ìràwọ̀ Virgo, ohun tí ó wọ̀n sì dábàá pé àgbáálá ayé ń yára fẹ̀ sí i, nípa bẹ́ẹ̀, ọjọ́ orí rẹ̀ kéré sí bí a ti ronú tẹ́lẹ̀. Ní tòótọ́, ìwé ìròyìn Scientific American ròyìn ní June tí ó kọjá yìí pé, ó “dábàá pé, àgbáálá ayé kò dàgbà ju bílíọ̀nù mẹ́jọ ọdún lọ.” Nígbà tí bílíọ̀nù mẹ́jọ ọdún ti dà bí àkókò gígùn gan-an, ó wulẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ìdajì iye ọdún tí a ṣírò pé àgbáálá ayé ti fi wà. Èyí dá ìṣòro pàtàkì kan sílẹ̀, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti ń sọ lọ, “àwọn ìsọfúnni oníṣirò míràn tọ́ka pé àwọn ìràwọ̀ kan ti wà fún, ó kéré tán, bílíọ̀nù 14 ọdún.” Bí ó bá jẹ́ òtítọ́ ni iye tí Freedman sọ, àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ti dàgbà gan-an wọ̀nyẹn yóò wá dàgbà ju ìbúgbàù ńlá náà lọ!
Síbẹ̀, ìṣòro mìíràn tí ìbúgbàù ńlá náà ní ti wá láti inú àwọn ẹ̀rí tí ń pọ̀ sí i látìgbàdégbà nípa “àwọn àlàfo” nínú àgbáálá ayé tí wọ́n tóbi tó 100 mílíọ̀nù ọdún ìmọ́lẹ̀, pẹ̀lú àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní gbangba àti àwọn àlàfo ní inú. Margaret Geller, John Huchra, àti àwọn yòókù ní Ibùdó Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Nípa Ìṣẹ̀dá Inú Sánmà ní Harvard òun Smithsonian ti ṣàwárí ohun tí wọ́n pè ní ògiri ńlá àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ní nǹkan bí 500 mílíọ̀nù ọdún ìmọ́lẹ̀ ní gígùn ní òfuurufú láti ìhà àríwá ìlàjì ayé. Agbo àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà míràn, tí a wá mọ̀ sí Seven Samurai, ti rí ẹ̀rí ìkójọpọ̀ àgbáálá ayé yíyàtọ̀, tí wọ́n pè ní Òòfà Ńlá, tí ó wà nítòsí ìhà gúúsù ìràwọ̀ Hydra àti Centaurus. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, Marc Postman àti Tod Lauer, gbà gbọ́ pé ohun kan tí ó tilẹ̀ tóbi gbọ́dọ̀ nà ré kọjá ìdìpọ̀ ìràwọ̀ Orion, tí ó sì ń mú kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, títí kan tiwa, dorí kọ ìhà yẹn bí àdìlù igi ojú omi lórí irú “odò ojú òfuurufú” bẹ́ẹ̀.
Gbogbo ìgbékalẹ̀ yìí ń ṣeni ní kàyééfì. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà sọ pé, gbẹ̀ẹ̀ tí ìbúgbàù ńlá náà bú dán mọ́rán gan-an, ó sì ṣọ̀kan délẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú ìrànyòò àtẹ̀yìnwá tí wọ́n sọ pé ó fi sílẹ̀. Báwo ni irú ìràwọ̀ dídán mọ́rán bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣamọ̀nà sí irú ìgbékalẹ̀ ràgàjì tí ó sì díjú bẹ́ẹ̀? Ìwé ìròyìn Scientific American gbà pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ògiri ńláńlá àti àwọn òòfà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí náà túbọ̀ mú kí àràmàǹdà nípa bí àwọn ìgbékalẹ̀ tí ó di nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣe lè pọ̀ tó láàárín bílíọ̀nù 15 tí àgbáálá ayé ti fi wà náà túbọ̀ le sí i”—ìṣòro kan tí ó jẹ́ pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í burú sí i, kìkì nígbà tí Freedman àti àwọn yòókù tún dín ọjọ́ orí àgbáálá ayé tí wọ́n ti fojú díwọ̀n tẹ́lẹ̀ kù sí i.
“A Ń Pàdánù Àwọn Ohun Pàtàkì Kan”
Àwọn àwòrán oníwọ̀n ìpele mẹ́ta tí Geller yà nípa ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òkìtì ìṣùjọ, ìfọ́nkiri àti àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ti yí ọ̀nà tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń gbà wo àgbáálá ayé padà. Kò díbọ́n bí ẹni tí ó lóye ohun tí ó ń rí. Kò dà bíi pé òòfàmọ́lẹ̀ nìkan ni ó lè ṣàlàyé nípa ògiri ńlá obìnrin náà. Ó sọ pé: “Mo sábà máa ń nímọ̀lára pé, a ń pàdánù àwọn ohun pàtàkì kan nínú ìgbìyànjú wa láti lóye ìgbékalẹ̀ yìí.”
Geller ṣàlàyé síwájú sí i nípa iyè méjì tí ó ní nípa ọjọ́ ọ̀la pé: “Dájúdájú, a kò mọ bí a ṣe lè ṣàlàyé ìgbékalẹ̀ ńlá nínú àyíká ọ̀rọ̀ Ìbúgbàù Ńlá náà.” Àwọn àpẹẹrẹ ìgbékalẹ̀ àgbáálá ayé lórí ìpìlẹ̀ àwọn àwòrán ọ̀run ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí kò ṣe pàtó rárá—a gbé àwọn àpẹẹrẹ náà karí ìsọfúnni oníṣirò tí kò tó nǹkan. Geller ń bá a lọ pé: “Lọ́jọ́ kan, a lè wá rí i pé a kò ṣàpẹẹrẹ àwọn ìsọfúnni oníṣirò náà lọ́nà tí ó tọ́, nígbà tí a bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, yóò jọ bí ohun tí ó hàn kedere pé a óò ṣe kàyééfì nípa ìdí tí a kò fi ronú nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀.”
Ìyẹn ṣamọ̀nà sí ìbéèrè títóbi jù lọ nínú gbogbo rẹ̀: Kí ni ì bá ti ṣokùnfa ìbúgbàù ńlá náà fúnra rẹ̀? Kò sé lẹ́yìn ọlá àṣẹ Andrei Linde, ọ̀kan lára àwọn olùdásílẹ̀ abala olókìkí nípa àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá tí a fẹnu pọ́n náà, tí ó gbà pẹ̀lú òtítọ́ aláìfarasin náà pé àbá èrò orí ìpilẹ̀ náà kò mẹ́nu kan ìbéèrè pàtàkì yìí. Ó wí pé: “Ìṣòro àkọ́kọ́, tí ó sì jẹ́ lájorí rẹ̀, ni wíwà tí ìbúgbàù ńlá náà wà gan-an. Ẹnì kan lè ṣe kàyééfì pé, Kí ló kọ́kọ́ wá sójútáyé? Bí ìjótìítọ́ ìṣẹ̀dá kò bá sí nígbà náà lọ́hùn-ún, báwo ni ohun gbogbo ṣe lè jáde wá láti inú ohun tí kò sí? . . . Ṣíṣàlàyé ìdádó gedegbe ti ìbẹ̀rẹ̀ yìí—ibi tí ó ti bẹ̀rẹ̀ àti ìgbà tí ó bẹ̀rẹ̀—ṣì jẹ́ ìṣòro nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé òde òní, tí ó ṣòro jù lọ láti yanjú.”
Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Discover sọ láìpẹ́ yìí pé, “kò sí aronújinlẹ̀ onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan tí yóò sọ pé Ìbúgbàù Ńlá náà ni àbá èrò orí tí ó kẹ́yìn.”
Ẹ jẹ́ kí a wá jáde síta báyìí, kí a sì ronú nípa àtẹ ẹwà àti àràmàǹdà inú gbalasa ìràwọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwọ̀n kelvin ni ẹyọ ìpín ara òṣùwọ̀n ìgbóná òun ìtutù tí ìwọ̀n rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú ìwọ̀n ara òṣùwọ̀n ìgbóná òun ìtutù ti Celsius, yàtọ̀ sí pé òṣùwọ̀n ti Kelvin bẹ̀rẹ̀ láti orí oódo, ìyẹn ni 0 K.—tí ó dọ́gba wẹ́kú pẹ̀lú ìwọn -273.16 Celsius sí ìsàlẹ̀ oódo. Omi máa ń di yìnyín lórí 273.16 K. ó sì máa ń hó lórí 373.16 K.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]
Ọdún Ìmọ́lẹ̀—Òṣùwọ̀n Àgbáyé
Àgbáyé tóbi gan-an débi pé gbígbé e lórí ìwọ̀n máìlì tàbí kìlómítà dà bíi fífi òṣùwọ̀n micrometer wọn bí London ṣe jìnnà sí Tokyo. Òṣùwọ̀n tí ó túbọ̀ bójú mu ni ọdún ìmọ́lẹ̀, bí ìmọ́lẹ̀ ṣe ń rìn tó lọ́dún, tàbí nǹkan bí 9,460,000,000,000 kìlómítà. Níwọ̀n bí ìmọ́lẹ̀ ti jẹ́ ohun tí ó yára jù lọ lágbàáyé, tí ó sì béèrè fún ìṣẹ́jú àáyá 1.3 péré láti rìn lọ sínú òṣùpá àti nǹkan bí ìṣẹ́jú 8 lọ sínú oòrùn, ó lè jọ pé, ọdún ìmọ́lẹ̀ ṣàràmàǹdà ní tòótọ́!