Ẹnì Kankan Ha Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé Bí?
“Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn díẹ̀ lóde agbo ìdílé wa tí àwọn òbí mi ní ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá nínú wọn. . . . Ó fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ènìyàn dáradára, tí ó sì bìkítà, tí kò lè ṣe ohunkóhun láti pa wá lára láéláé. . . . Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn díẹ̀ tí wọ́n di ẹni tí mo gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá nínú ìgbésí ayé mi.”
BÍ Ọ̀DỌ́BÌNRIN kan ṣe ṣàpèjúwe ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó ní nínú dókítà ìdílé wọn nìyẹn. Ó bani nínú jẹ́ pé ibi tí kò tọ́ gbáà ló gbé ẹkẹ̀ rẹ̀ lé. Láti ìgbà tí ó ti wà ní ọmọ ọdún 16 ni dókítà yìí tí ń bá a ṣe ìṣekúṣe. Ọ̀dọ́bìnrin náà sọ fún àwọn aláṣẹ ilé ẹjọ́, tí wọ́n wá dá ẹjọ́ náà, pé: “Ó parọ́ fún mi, ó sì tàn mí jẹ.”—The Toronto Star.
Ibi Gbogbo Ni Wọ́n Ti Ń Ba Ìgbẹ́kẹ̀lé Jẹ́
Ìgbẹ́kẹ̀lé, tí ó dà bí òdòdó tí ó lẹ́wà, àmọ́ tí ó fẹ́lẹ́, ni a lè tètè fà tu, kí a sì fẹsẹ̀ gbo ó mọ́lẹ̀. Ibi gbogbo ni wọ́n ti ń gbo ó mọ́lẹ̀! Michael Gaine, tí ó jẹ́ akọ̀wé fún àwọn méjì tí ọ̀kan jẹ́ kádínà tí ọ̀kan sì jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù àgbà, ní England, sọ pé: “Ìgbà kan ti wà rí, tí gbogbo ènìyàn gbẹ́kẹ̀ lé àlùfáà. Ìgbà kan tí àwọn ìdílé yóò fi àwọn ọmọ wọn sábẹ́ àbójútó rẹ̀. N kò rò pé àwọn ènìyàn lè ṣe bẹ́ẹ̀ báyìí. Ìgbẹ́kẹ̀lé ìgbà yẹn tí lọ ráúráú.”—The Guardian Weekend.
Àwọn oníṣòwò ń rẹ́ àwọn tí ń bá wọn díje jẹ. Àwọn olùpolówó ọjà ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ń ṣi àwọn oníbàárà lọ́nà, wọ́n sì ń kó wọn nífà. Ìjòyè òṣìṣẹ́ kan tí ọkàn rẹ̀ ti yigbì jí owó ìfẹ̀yìntì ilé iṣẹ́ òun fúnra rẹ̀, ó sì jí àkójọ owó àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀. Àwọn tí a gbà síṣẹ́ máa ń ja àwọn agbanisíṣẹ́ wọn lólè déédéé. Fún àpẹẹrẹ, ìròyìn kan sọ pé, “okòwò Kánádà ń ṣòfò ohun tí a ṣírò sí nǹkan bí 20 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún nítorí àwọn tí ń jalè láàárín wọn.”—Canadian Business.
Kì í ṣe gbogbo àwọn òṣèlú ló ṣeé fọkàn tẹ̀. Àmọ́ àwọn ìròyìn bí èyí tí ó tẹ̀ lé e yìí máa ń ṣe àwọn ènìyàn díẹ̀ ní kàyéfì: “Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn tí wọ́n ti ṣekú pa ọ̀kan lára àwọn obìnrin olóṣèlú ilẹ̀ Faransé tí à ń sọ̀rọ̀ nípa wọn jù lọ, àwọn ọlọ́pàá ti ń tú gbogbo rẹ̀ yẹ́lẹ́yẹ́lẹ́ láti túdìí àṣírí ẹ̀tàn òṣèlú àti tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun ìwà ọ̀daràn tí ó ti bojú ètò ìjọba ni etíkun Mẹditaréníà.”—The Sunday Times, London.
Lọ́pọ̀ ìgbà, ìgbẹ́kẹ̀lé máa ń fọ́ yángá nínú ìbátan tímọ́tímọ́. Àwọn ìyàwó àti ọkọ kì í ṣe olóòótọ́ sí ẹnì kejì wọn nínú ìgbeyàwó. Àwọn òbí máa ń ṣe ọmọ wọn níṣekúṣe. Àwọn ọmọ máa ń tan àwọn òbí wọn. Nígbà tí a ṣí ibi ìkósọfúnnisí Àjọ Aláàbò Ìlú, àwọn ọlọ́pàá inú ní Ìlà Oòrùn Germany tẹ́lẹ̀ rí, wọ́n fi “ọ̀nà ìgbàṣẹ̀tàn tí ó ti gbilẹ̀” hàn láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ka ara wọn sí ọ̀rẹ́. Ìròyìn kan sọ pé, nínú ìsokọ́ra ọ̀ràn ìwà ọ̀dàlẹ̀ kan, “amúga Àjọ Aláàbò Ìlú ti nà dé yàrá ìkàwé, pèpéle ìwàásù, inú yàrá, àti dé ibi tí àwọn ènìyàn ti ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ fún àlùfáà pàápàá.”—Time.
Ní Ireland, òǹkọ̀wé ìròyìn kan kọ ọ́ pé: “Àwọn tí a fi síbi agbára ti purọ́ fún wa, wọ́n ti ṣì wá lọ́nà, wọ́n ti lò wá, wọ́n sì ti lò wá nílòkulò, wọ́n sì ti gàn wá.” (The Kerryman) Nítorí pé a ti da ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́pọ̀ ìgbà, wọn kò gbẹ́kẹ̀ lé ẹnikẹ́ni mọ́. Kí ni a lè ṣe láti rí i dájú pé a kò gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa lórí asán? Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ méjì tí ó kàn yóò gbé ìbéèrè yìí yẹ̀ wò.