ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 2/8 ojú ìwé 7-10
  • O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọrun
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọrun Kì Yóò Já Ọ Kulẹ̀ Láé
  • Àwọn Ìdí Tí O Fi Ní Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Bibeli
  • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Ni Bíbélì Ti Wá
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Fífọkàntánni Ló Ń Mú Kí Ìgbésí Ayé Èèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Fọkàn Tán Àwọn Arákùnrin Àtàwọn Arábìnrin Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Fi Gbogbo Ọkàn Rẹ Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 2/8 ojú ìwé 7-10

O Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọlọrun

O LÈ fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan, tí ó ti lé ní 100 ọdún, fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọrun, ó sọ ìdí tí ó fi ní irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ pé: “Ẹ̀yín kíyè sí i, ní òní, èmi ń lọ sí ọ̀nà gbogbo ayé: [ẹ̀yín] sì mọ̀ ní àyà yín gbogbo, àti ní ọkàn yín gbogbo pé, kò sí ohun kan tí ó tàsé nínú ohun rere gbogbo tí OLUWA Ọlọrun yín ti sọ ní ti yín; gbogbo rẹ̀ ni ó ṣẹ fún yín, kò sì sí ohun tí ó tàsé nínú rẹ̀.”—Joṣua 23:14, ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Ọkùnrin yìí, Joṣua, aṣíwájú kan fún Israeli ìgbàanì, nírìírí gbígbára lé Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pátápátá. Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣèlérí fún Israeli ni ó ṣẹ. Bí o bá di ẹni tí ó mọ púpọ̀ sí i nípa Ẹlẹ́dàá àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìwọ náà lè mú irú ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn dàgbà. Ẹlòmíràn tí ó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọrun lẹ́yìn tirẹ̀, Ọba Dafidi, sọ ọ́ lọ́nà yìí pé: “Àwọn tí ó sì mọ orúkọ rẹ óò gbẹ́kẹ̀ lé ọ: nítorí ìwọ, Oluwa, kò tí ì kọ àwọn tí ń ṣe àfẹ́rí rẹ sílẹ̀.”—Orin Dafidi 9:10.

Ọlọrun Kì Yóò Já Ọ Kulẹ̀ Láé

Bí o bá ṣe ń ‘mọ orúkọ Ọlọrun’ àti ohun tí orúkọ yẹn túmọ̀ sí—àwọn ète, iṣẹ́, àti ànímọ́ rẹ̀—sí i tó, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò ṣe gbẹ́kẹ̀ lé e tó. Òún jẹ́ Ọ̀rẹ́ tí ó ṣeé fẹ̀mí tẹ̀ kan, tí kò lè já ọ kulẹ̀ tàbí ṣaláìmú ìlérí rẹ̀ ṣẹ. Má sì jẹ́ kí àrékérekè àwọn tí wọ́n ń fẹnu jẹ́wọ́ pé àwọn jẹ́ aṣojú rẹ̀, tí wọ́n sì ń fi ẹ̀tàn bá àwọn ẹlòmíràn lò tí ó bá yá, lé ọ sá. Bibeli fi irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí aláìṣeégbẹ́kẹ̀lé. Àwọn alárèékérekè onísìn máa ń sọ ohun kan, ṣùgbọ́n wọ́n máa ń ṣe òdì kejì rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Peteru ṣe kìlọ̀, wọ́n ń kó àwọn agbo wọn nífà. Peteru kọ̀wé pé: “Nítìtorí awọn wọnyi ọ̀nà òtítọ́ yoo sì di èyí tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ tèébútèébú. Bákan naa, pẹlu ojúkòkòrò wọn yoo fi awọn ayédèrú ọ̀rọ̀ kó yín nífà.”—2 Peteru 2:2, 3.

Irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ kò ṣojú fún Ọlọrun. Wọn kò bọlá fún Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Èé ṣe tí o kò fúnra rẹ ṣàyẹ̀wò àkọsílẹ̀ àti ẹ̀rí tí ó jẹ́ ti Ọlọrun fúnra rẹ̀, tí a fi hàn nínú Bibeli? O lè béèrè pé, ‘Àmọ́, kí ló dé tí mo fi ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ?’ Òtítọ́ ni pé, àìlóǹkà àwọn èrú nínú ìsìn ni ó ti wà jálẹ̀ ìtàn, àmọ́ Bibeli yàtọ̀. Gbé àwọn ìdí tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò tí o fi ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli.

Àwọn Ìdí Tí O Fi Ní Láti Gbẹ́kẹ̀ Lé Bibeli

O lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli nítorí pé, àwọn ìlérí àti àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ máa ń ṣẹ. Àpẹẹrẹ kan ṣoṣo péré ni èyí. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ó lè dà bí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ létí àwọn ọmọ Israeli tí wọ́n wà nígbèkùn, Jehofa Ọlọrun, olùṣẹ̀dá Bibeli, ti ṣèlérí pé òun yóò sọ wọ́n dí òmìnira kúrò nínú ìgbèkùn Babiloni alágbára, òun yóò sì mú wọn padà sí Jerusalemu. Ó dà bí ìrètí tí kò ní ṣeé ṣe, nítorí pé Babiloni ni àgbára ayé lílágbára jù lọ nígbà yẹn, ó sì ti sọ Jerusalemu dahoro pátápátá. Àmọ́ ní nǹkan bí igba ọdún ṣaájú ìyẹn, Jehofa tilẹ̀ ti dárúkọ Kirusi, olùṣàkóso ara Persia, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí yóò bi Babiloni ṣubú, tí yóò sì dá àwọn ènìyàn Òun sílẹ̀, Ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí odò tí ó jẹ́ ààbò Babiloni yóò ṣe já wọn kulẹ̀. O lè kà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà nínú Isaiah 44:24–45:4.

Ìwé Reasoning From the Scriptures ṣàlàyé bí ìlérí yìí ṣe ní ìmúṣẹ pé: “A kò tí ì bí Kirusi nígbà tí a ṣàkọsílẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ náà. . . . Àsọtẹ́lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìmúṣẹ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ ní ọdún 539 ṣaájú Sànmánì Tiwa. Kirusi darí omi Odò Euferate gba ibi adágún àtọwọ́dá kan, wọ́n fi àìbìkítà ṣí ẹnubodè odò Babiloni sílẹ̀ nígbà àjọ̀dún tí wọn ń ṣe ní ìlú náà, Babiloni sì ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Media àti Persia nígbà ìṣàkóso Kirusi. Lẹ́yìn ìyẹn, Kirusi sọ àwọn Júù tí wọ́n wà ní ìgbèkùn di òmìnira, ó sì dá wọn padà sí Jerusalemu, ó sì fún wọn ní ìtọ́ni láti tún tẹ́ḿpìlì Jehofa kọ́.”a Gbogbo irú àwọn ìlérí báwọ̀nyí tí Ọlọrun ṣe, gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó wà nínú Bibeli, ni ó ti já sí òtítọ́ láìtàsé.

Àpẹẹrẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí a mú ṣẹ mìíràn ni ti òtítọ́ náà pé ìgbẹ́kẹ̀lé ti pòórá ní ọ̀rúndún wa yìí. Bibeli sàsọtẹ́lẹ̀ pé èyí yóò jẹ́ àmì àkókò tí à ń gbé, nítorí pé ó pe sànmánì tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ogun Àgbáyé Kìíní ní 1914 ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ó sì sọ pé wọn yóò fa “àkókò lílekoko tí ó nira lati bálò.” Ó mú kí á mọ̀ pé ní ọjọ́ wa, àwọn ènìyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, . . . ajọra-ẹni-lójú, onírera, . . . aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, . . . afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹlu ìgbéraga.” Ó sì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Awọn ènìyàn burúkú ati awọn afàwọ̀rajà yoo máa tẹ̀síwájú lati inú búburú sínú búburú jù.” (2 Timoteu 3:1-4, 13) Ohun náà gẹ́lẹ́ tí à ń rí ní àkókò wa nìyẹn.

O lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli nítorí pé ó ṣeé fọkàn tẹ̀. Kò sí ẹni tí ó tí ì fi àṣeyọrí ta ko ìṣeéfọkàntẹ̀ Bibeli rí. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ náà, Alàgbà Isaac Newton, sọ pé: “Mo ṣàwárí àwọn àpẹẹrẹ ìṣeéfọkàntẹ̀ tí ó dájú nínú Bibeli ju nínú ọ̀rọ̀ ìtàn tí kò la ti ìsìn lọ èyíkéyìí, bí ó ti wù kí ó rí.” Kò sí màgòmágó bíi ti “àkọsílẹ̀” Hitler nínú eléyìí! Báwo ni Bibeli sì ṣe rí bí a bá fi wé àwọn ìwé ìgbàanì yókù? Ìwé The Bible From the Beginning sọ pé: “Tí a bá sọ ti iye àwọn ìwé MSS. [àwọn ìwé àfọwọ́kọ] ìgbàanì tí ó máa ń jẹ́rìí kín ìwé kan lẹ́yìn, tí a sì tún sọ ti iye ọdún tí ó wà láàárín ìwé ti àkọ́kọ́ àti MSS. tí ń jẹ́rìí kín in lẹ́yìn, láìṣe iyè méjì, Bibeli ta àwọn ìwé àtijọ́ [bíi ti Homer, Plato, àti àwọn mìíràn] yọ. . . . Lápapọ̀, díẹ̀ lásán ni ìwé MSS. tí a fi wéra pẹ̀lú àwọn ìwé àfọwọ́kọ Bibeli jẹ́. Kò sí ìwé ìgbàanì mìíràn tí a jẹ́rìí kín lẹ́yìn tó Bibeli.” Gbogbo ohun tí ó ní í ṣe pẹ̀lú Bibeli ni ó tọ́ka sí i pé ó jẹ́ ojúlówó látòkèdélẹ̀.

O lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli nítorí pé gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni ó péye délẹ̀délẹ̀. Bibeli sọ pé Ọlọrun “na ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfuurufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.” (Jobu 26:7) Dípò tí Bibeli ì bá fi sọ àsọtúnsọ àwọn àbá èrò orí alálàá asán tí ó gbalẹ̀ nígbà yẹn, irú bíi ti pé, ilẹ̀ ayé wà lórí àwọn erin, ó sọ ohun tí àwọn ènìyàn ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ tí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tì lẹ́yìn—pé ilẹ̀ ayé “rọ̀” sójú òfuurufú. Ní àfikún sí ìyẹn, ní ohun tí ó ju ẹgbàá ọdún ṣaájú àkókò Columbus, Bibeli sọ ọ́ ní kedere pé ilẹ̀ ayé rí roboto.—Isaiah 40:22.

O lè gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli nítorí ìṣòtítọ́ àti àìfọ̀rọ̀sábẹ́-ahọ́n-sọ rẹ̀. Àwọn òǹkọ̀wé Bibeli kò purọ́ ohunkóhun. Nígbà tí ohun tí wọ́n sọ bá tilẹ̀ fi àwọn fúnra wọn, àwọn ènìyàn wọn, àti àwọn alákòóso wọn hàn láìdáa, wọ́n fi ìṣòtítọ́ sọ òkodoro ọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìhìn rere rẹ̀, aposteli Matteu jẹ́wọ́ gbangba-gbàǹgbà pé, àwọn aposteli Jesu Kristi máa ń fi àìnì ìgbàgbọ́ hàn nígbà míràn, pé wọ́n máa ń jà láàárín ara wọn fún ipò ìyọrí ọlá, tí wọ́n sì tilẹ̀ pa Jesu tì nígbà tí wọ́n mú un.—Matteu 17:18-20; 20:20-28; 26:56.

Ìdí pàtàkì míràn tí a fi ní láti gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli ni pé, gbogbo ìgbà ni ìmọ̀ràn Bibeli máa ń gbéṣẹ́, tí ó sì máa ń ṣàǹfààní nígbà yòówù tí àwọn ènìyàn bá gbẹ́kẹ̀ lé e débi pé wọ́n fi í sílò. (Owe 2:1-9) Ìmọ̀ràn Bibeli jẹ́ òdì kejì pátápátá sí ìmọ̀ràn aláìdúrósójúkan tí “àwọn ògbógi” ń fúnni láti lè kojú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Nígbà tí ìwé agbéròyìnjáde The Sunday Times ti London ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn akọ̀ròyìn tí wọ́n máa ń fúnni ní irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìwé agbéròyìnjáde orílẹ̀-èdè, ó béèrè pé: “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ha ń tú gbogbo inú wọn fún àwọn aláìmọ̀kan tí wọ́n kàn ń fìkan mọ́kan lọ ní tiwọn lọ́dọọdún bí?” Kì í ṣe pé àwọn òǹkọ̀wé Bibeli ń fìkan mọ́kan lọ. Wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìmọ̀ràn tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ jálẹ̀jálẹ̀ ìtàn, tí Ọlọrun mí sí.—2 Timoteu 3:16, 17.

Ellen, tí ó ti lé ní ọmọ 30 ọdún nísinsìnyí, tí ó sì ti ń bá ìgbeyàwó lọ tayọ̀tayọ̀, sọ pé: “Ìmọ̀ràn Bibeli dáàbò bò mí kúrò lọ́nà tí ì bá ti run ìgbésí ayé mi. Àwọn òbí mi, tí wọ́n ti kọra sílẹ̀, kò fi ìdúróṣinṣin tí ó tó hàn nínú ìṣètò ìgbeyàwó, wọ́n sì tilẹ̀ fún mi níṣìírí pé kí ń kàn máa gbé pẹ̀lú ẹnì kan dípò kí n ṣègbeyàwó pẹ̀lú rẹ̀. Tí mo bá ronú nípa ìwàdéédéé tí títẹ̀ lé àwọn ìlànà Bibeli ti fún ìgbésí ayé mi, inú mi máa ń dùn pé mo gbẹ́kẹ̀ lé Bibeli, àní ju ìmọ̀ràn àwọn òbí mi gan-an lọ pàápàá.”—Wo Efesu 5:22-31; Heberu 13:4.

Florence sọ pé: “N kò ju ọmọ ọdún 14 lọ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Bibeli sọ. Nísinsìnyí, tí mo bá ronú sẹ́yìn sí àwọn ọdún 1960 àti wàhálà tí àwọn ojúgbà mi kó ara wọn sí nítorí títẹ̀ lé àwọn ìlànà ìhùwà àti ìwà ìgbà yẹn, mo máa ń ṣọpẹ́ fún ààbò tí ìmọ̀ràn Bibeli pèsè fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́bìnrin, aláìnírìírí.”—Wo 1 Korinti 6:9-11.

James sọ pé: “Nínú ọ̀ràn tèmi, odò tẹ́tẹ́ títa, sìgá mímu àti ọtí mímu ló gbé mi lọ.” Ó tẹ̀ síwájú ní sísọ pé: “Mo mọ ìṣòro tí ó ti fà fún ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn àti fún àwọn ìdílé wọn. Lákọ̀ọ́kọ́, n kò lè rí bí Bibeli ṣe tan mọ́ àwọn ìṣòro mi. Àmọ́ nísinsìnyí, mo rí i kedere bí ó ṣe nípa lórí ìrònú mi lọ́nà rere, tí ó sì ràn mí lọ́wọ́ láti pa ọ̀nà ìgbésí ayé tí ó sunwọ̀n sí i mọ́.”—Wo 2 Korinti 7:1.

Mary Anne gbìdánwò láti pa ara rẹ̀ nítorí àwọn wàhálà ìgbésí ayé àti àwọn ìṣòro ti ìmọ̀lára tí ó ní nítorí ìgbésí ayé oníhílàhílo tí ó ní látẹ̀yìnwá. Ó sọ pé: “Ìṣekúpara-ẹni dà bí ojútùú kan ṣoṣo tí ó wà ní àkókò yẹn. Ṣùgbọ́n Bibeli tún ojú ìwòye mi ṣe. Nítorí kìkì ohun tí mo kà nínú Bibeli ni n kò ṣe pa ara mi.”—Wo Filippi 4:4-8.

Kí ni ohun náà gan-an tí ó ran gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí lọ́wọ́? Wọ́n mú ìgbẹ́kẹ̀lé pátápátá dàgbà nínú Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli. Ọlọrun wá dà bí ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí ń sọ ìmọ̀ràn sí wọn létí wúyẹ́wúyẹ́ ní àkókò ìṣòro. (Fi wé Isaiah 30:21.) Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìlànà Bibeli tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn wàhálà àti ìṣòro ìgbésí ayé. Wọ́n sì kọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí àgbàyanu, tí Ọlọrun tí kò lè purọ́ ṣe—irú bí ìlérí “ilẹ̀-ayé titun” ẹlẹ́wà kan tí kò ní ẹ̀tàn, irọ́ àti ìrẹ́nijẹ, tí kò sì ní ìbànújẹ́, àìsàn àti ikú pàápàá!—2 Peteru 3:13; Orin Dafidi 37:11, 29; Ìṣípayá 21:4, 5.

Ìwọ náà lè mú irú ìgbẹ́kẹ̀lé kan náà dàgbà. Ayé òde òní lè da ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ, àmọ́, o lè jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ nínú Ọlọrun àti nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a kò ní bà jẹ́. Inú àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde yóò dùn láti ṣètò kí ẹnì kan ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ Ọlọrun àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, dáradára sí i.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Ní nǹkan bí 200 ọdún ṣaájú, wòlíì Ọlọrun sàsọtẹ́lẹ̀ nípa bí a óò ṣe bi Babiloni ṣubú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Alàgbà Isaac Newton rí i pé Bibeli ṣeé fọkàn tẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́