Ìtànkálẹ̀ Àwọn Kòkòrò Àrùn Gbẹ̀mígbẹ̀mí
Eloise àti àwọn tí ó bá wọ ọkọ̀ pọ̀ ni a fún ní káàdì Ìsọfúnni Ìkìlọ̀ Nípa Ìlera lẹ́yìn tí wọ́n wọ ọkọ̀ òfuurufú kan tí ń lọ sí New York láti London. May 1995 ni. Ohun tí wọ́n kọ sí iwájú káàdì náà kà pé:
“SÍ Arìnrìn Àjò: Tọ́jú káàdì yìí sínú àpamọ́wọ́ tàbí àpò owó rẹ fún ọ̀sẹ̀ 6. Bí o bá ṣàìsàn láàárín àkókò yìí, fún oníṣègùn rẹ ní káàdì yìí, kí o sì wí fún un nípa àjò tí o lọ kúrò ní United States lẹ́nu àìpẹ́.
“Ó ṣeé ṣe kí o ti kó àrùn kan tí ó ṣeé tàn kálẹ̀ kí o tó darí sí United States, mímọ èyí sì lè ṣèrànwọ́ fún oníṣègùn rẹ láti mọ ohun tí ń ṣe ọ́.”
Àwọn olùtọ́jú èrò inú ọkọ̀ òfuurufú pẹ̀lú fúnni ní àwọn ìwé agbéròyìnjáde tí ń ṣàpèjúwe ìbẹ́sílẹ̀ àrùn Ebola, àrùn onífáírọ́ọ̀sì tí ń pa ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn ní Zaire.
Eloise kà nípa Ebola—àrùn líle koko kan tí ń ṣekú pani. Àwọn olùgbàtọ́jú tí ó bá ràn kọ́kọ́ máa ń ní ibà, ọ̀fun dídùn, àti ẹ̀fọ́rí, tí èébì, inú rírun, àti àrunṣu yóò sì yára tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà ni ẹ̀jẹ̀ púpọ̀, tí kò ṣeé dá dúró, yóò máa ya nínú àti lóde ara. Àwọn 9 nínú 10 lára àwọn tí ń ṣe ni wọ́n máa ń yára kú.
Ní oṣù díẹ̀ ṣáájú ìyẹn, ó ti gbọ́ròyìn àwọn àrùn ṣíṣàjèjì, tí ó sì jẹ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí mìíràn: fún àpẹẹrẹ, àjàkálẹ̀ àrùn ní India. Ní ibòmíràn, ohun tí àwọn ilé iṣẹ́ agbéròyìnjáde pè ní “kòkòrò àrùn ajẹran-ara” ti ṣekú pa àwọn ènìyàn láàárín wákàtí díẹ̀.
Eloise yí káàdì náà padà. Ojú kejì kà pé:
“Sí Oníṣègùn: Olùgbàtọ́jú tí ó fún ọ ní káàdì yìí ti rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè láìpẹ́ yìí, ó sì lè ṣeé ṣe kí ó ti kó àrùn kan tí ó ṣeé tàn kálẹ̀, tí a kì í sábà rí ní United States. Bí o bá fura sí àkóràn àrùn ṣíṣàjèjì kan nínú ọ̀ràn yìí (àrùn onígbá méjì, ibà tí ó mú ìsun ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ibà, ibà pọ́njú, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ), jọ̀wọ́ fi tó Alábòójútó Ìlera Ìpínlẹ̀, ìlú ńlá, tàbí ti ìgbèríko rẹ létí, bákan náà (nípasẹ̀ tẹlifóònù—tí a óò san owó rẹ̀ fún ọ) fi tó Ẹ̀ka Ìsénimọ́, Àwọn Ibùdó fún Ìkáwọ́ Òkùnrùn, Atlanta, Georgia . . . létí.”
Káàdì náà fi àníyàn tí àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé ń ní hàn nípa ìtànkálẹ̀ àwọn kòkòrò àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí—àwọn kòkòrò àfòmọ́, bakitéríà, àti àwọn fáírọ́ọ̀sì—èyí tí ó jẹ́ pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá tanná ran àjàkálẹ̀ àrùn ní ibì kan lórí ilẹ̀ ayé, wọ́n lè yára tàn kálẹ̀ bí iná ọyẹ́. Láìdà bí Eloise àti àwọn tí ó bá wọ ọkọ̀ pọ̀, àwọn kòkòrò àrùn kì í mú ìwé àṣẹ ìrìnnà lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní ọ̀wọ̀ fún ààlà orílẹ̀-èdè. Láìmọ̀ àti pẹ̀lú ìrọ̀rùn yíyani lẹ́nu ni wọ́n máa ń rìn kiri lára ẹni tí ó bá ní àkóràn.
Bí Eloise ti ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ki káàdì Ìsọfúnni Ìkìlọ̀ Nípa Ìlera náà bọ inú àpò owó rẹ̀, ó ṣe kàyéfì pé, ‘Ibo ni àwọn àrùn panipani wọ̀nyí ti ń wá? Kí ló dé tí ó fi jọ pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ìṣègùn ìgbàlódé kò lè borí wọn?’ Bóyá ìwọ pẹ̀lú ti ṣe kàyéfì nípa èyí.