Àìríṣẹ́ṣe—Kí Ló ń fà á?
NÍ ÀWỌN orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan, a ń fipá mú àwọn ènìyàn láti máa gbọ́ bùkátà ara wọn nípa ṣíṣiṣẹ́ àṣelàágùn fún ọ̀pọ̀ wákàtí ní àṣefẹ́rẹ̀ẹ́-kú, bóyá kí wọ́n tilẹ̀ máa ṣe iṣẹ́ líléwu kan fún iye owó tí kò tó nǹkan. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ní àwọn ilẹ̀ míràn, ó ti dá ọ̀pọ̀ ènìyàn lójú pé àwọn yóò ní iṣẹ́ kan tí ó gbámúṣé títí di ìgbà tí àwọn bá fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ bí ilé iṣẹ́ ńlá kan tàbí ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọba ìpínlẹ̀ bá gba àwọn síṣẹ́. Ṣùgbọ́n ó jọ pé kò tún sí iṣẹ́ òwò tàbí àwọn ilé iṣẹ́ tí wọ́n lè fúnni ní iṣẹ́ àti ààbò tí ń fani lọ́kàn mọ́ra ní ipò èyíkéyìí lẹ́nu iṣẹ́ mọ́. Kí ló fà á?
Àwọn Okùnfà Ìṣòro Náà
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ kò tilẹ̀ lè rí iṣẹ́ tí wọ́n yàn láàyò jù lọ—yálà wọ́n gba oyè ní kọ́lẹ́ẹ̀jì ni tàbí wọn kò gbà á. Fún àpẹẹrẹ, ní Itali, ohun tí ó lé ní ìdá mẹ́ta àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ni àwọn ènìyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún 15 sí ọdún 24. Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí àwọn tí wọ́n ti rí iṣẹ́ tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti máa bá iṣẹ́ wọn lọ ń pọ̀ sí i, nítorí èyí ni ó sì fi ṣòro púpọ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ láti wọ agbo àwọn òṣìṣẹ́. Kódà, láàárín àwọn obìnrin—tí ó jẹ́ pé wọ́n sáà ń wọ agbo àwọn òṣìṣẹ́ síwájú sí i ni—ọ̀pọ̀ lára wọn ni kò ríṣẹ́ ṣe. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ yamùrá àwọn òṣìṣẹ́ tuntun ló ń tiraka nísinsìnyí pé kí àwọ́n lè wọ agbo àwọn òṣìṣẹ́.
Láti ìgbà tí a ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ẹ̀rọ ṣiṣẹ́, ìlànà ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ ti dín àìní fún àwọn òṣìṣẹ́ kù. Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti ní láti gbaṣẹ́ lẹ́yìn ẹlòmíràn, àwọn lébìrà retí pé àwọn ẹ̀rọ náà yóò dín iṣẹ́ kù tàbí kí wọ́n tilẹ̀ fi òpin sí i. Ìlànà lílo ẹ̀rọ tí ń dá ṣiṣẹ́ ti mú kí ohun tí a ń ṣe jáde pọ̀ sí i, ó sì ti mú ọ̀pọ̀ ewu kúrò, ṣùgbọ́n ó tún ti dín iṣẹ́ kù. Àwọn tí wọn kò bá kúrò lójú kan ń kó ara wọn sínú ewu àìríṣẹ́ṣe fún àkókò gígùn àyàfi bí wọ́n bá kọ́ àwọn iṣẹ́ tuntun.
A ń kó ara wa sínu ewu dídi ẹni tí àpọ̀jù àwọn ohun àmújáde ọrọ̀ ajé bò mọ́lẹ̀ ṣíbáṣíbá. Àwọn kan lérò pé a ti dé òtéńté ìdàgbàsókè. Ní àfikún sí i, pẹ̀lú ìwọ̀nba ènìyàn kéréje tí wọ́n ríṣẹ́ ṣe, àwọn olùrajà kò tó nǹkan. Àwọn ohun tí a ń ṣe jáde wá ń tipa bẹ́ẹ̀ pọ̀ jú iye tí a lè rà lọ. Níwọ̀n bí àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ kò ti tóótun ní ti ọrọ̀ ajé mọ́, wọ́n ti àwọn tí a gbé dìde láti kájú àwọn ìlọsókè tí a retí nínú ìmújáde pa, tàbí kí a yí wọn padà sí ìlò ohun mìíràn. Àwọn ìtẹ̀sí irú èyí ń fi àwọn ènìyàn ṣèjẹ—àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe. Lákòókò ìlọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ajé, wíwá àwọn òṣìṣẹ́ ń dín kù, àwọn iṣẹ́ tí a sì pàdánù ní àwọn àkókò ìlọsílẹ̀ sábà máa ń ṣòro láti tún gbé dìde lákòókò ìmúgbòòrò ìgbòkègbodò iṣẹ́ òwò. Ní kedere, ohun tí ń ṣokùnfà àìríṣẹ́ṣe ju ẹyọ kan lọ.
Ìṣòro Ẹgbẹ́ Òun Ọ̀gbà
Níwọ̀n bí kò tí sí ẹni tí àìríṣẹ́ṣe kò lè ṣẹlẹ̀ sí, ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ni. Àwọn orílẹ̀-èdè kan ń pèsè onírúurú ìgbésẹ̀ láti dáàbò bo àwọn tí wọ́n ṣì ń rí iṣẹ́ ṣe—fún àpẹẹrẹ, dídín iye àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lọ́sẹ̀ kù pẹ̀lú owó tí ó dín kù. Bí ó ti wù kí ó rí, èyí lè ba ìfojúsọ́nà àwọn ẹlòmíràn tí ń wá iṣẹ́ jẹ́.
Àwọn tí wọ́n ríṣẹ́ ṣe àti àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ń fi ẹ̀hónú hàn síwájú àti síwájú sí i nípa àwọn ìṣòro tí ó jẹ mọ́ ọ̀ràn iṣẹ́. Ṣùgbọ́n bí àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ti ń wá iṣẹ́ tuntun, àwọn tí wọ́n rí iṣẹ́ ṣe ń gbìyànjú láti dáàbò bo èyí tí wọ́n ní—àwọn ète ìlépa méjì tí wọn kì í fìgbà gbogbo bára dọ́gba. Ìwé ìròyìn Itali náà, Panorama, sọ pé: “A sábà máa ń ké sí àwọn tí wọ́n rí iṣẹ́ láti ṣe àṣekún iṣẹ́. Àwọn tí wọn kò rí iṣẹ́ ṣe sì wà bẹ́ẹ̀. Ewu pé àwùjọ lè pín sí méjì wà . . . àwọn tí wọ́n ń ṣe àṣekún iṣẹ́ lápá kan, àti lápá kejì, àwọn aláìríṣẹ́ṣe tí a ṣá tì, tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé wọ́n gbára lé ìfẹ́ inú rere àwọn ẹlòmíràn pátápátá.” Àwọn ògbógi sọ pé, ní ilẹ̀ Europe, àwọn tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ ni wọ́n ń gbádùn àbájáde ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé, dípò kí ó jẹ́ àwọn tí wọn kò níṣẹ́ lọ́wọ́.
Síwájú sí i, àìríṣẹ́ṣe ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ipò tí ètò ọrọ̀ ajé àdúgbò wà, tí ó mú kí ìyàtọ̀ ńláǹlà wà láàárín àìní agbègbè kan sí ti òmíràn ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi Germany, Itali, àti Spain. Ǹjẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ múra tán láti kọ́ nípa àwọn iṣẹ́ tuntun tàbí kí wọ́n tilẹ̀ kó lọ sí agbègbè míràn tàbí orílẹ̀-èdè míràn bí? Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí lè jẹ́ kókó kan tí ó lè mú kí ènìyàn ríṣẹ́.
Ojútùú Kankan Ha Wà Lọ́nà Bí?
Fún apá tí ó pọ̀ jù lọ, a ti gbé ìrètí karí ìmúsunwọ̀n ètò ọrọ̀ ajé. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kan ń ṣiyè méjì, wọ́n sì lérò pé irú ìmúsunwọ̀n bẹ́ẹ̀ kò ní ṣẹlẹ̀ títí di nǹkan bí ọdún 2000. Lójú àwọn mìíràn, ìkọ́fẹpadà ti bẹ̀rẹ̀ ná, ṣùgbọ́n àwọn àbájáde rẹ̀ kò yá kánkán, bí ó ti hàn nínú ìlọsílẹ̀ tí ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú àwọn tí wọ́n ríṣẹ́ ṣe ní Itali. Ìkọ́fẹpadà ètò ọrọ̀ ajé kò fi dandan túmọ̀ sí ìjórẹ̀yìn nínú àìríṣẹ́ṣe. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdàgbàsókè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, àwọn ilé ìdókòwò ń yàn láti lo àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n ní dáradára dípò gbígba àwọn mìíràn—ìyẹn ni pé, “ìdàgbàsókè ọrọ̀ ajé tí kò pèsè àǹfààní iṣẹ́” wà. Síwájú sí i, iye àwọn aláìríṣẹ́ṣe sábà máa ń yára pọ̀ ju iye àwọn iṣẹ́ tuntun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ ń dá sílẹ̀ lọ.
Lónìí, ètò ọrọ̀ ajé àwọn orílẹ̀-èdè ń la ìlọkáàkiri àgbáyé já. Àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé kan lérò pé ìdásílẹ̀ àwọn agbègbè ìṣòwò ńlá, tuntun tí ó naṣẹ̀ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè, bí àwọn ti Àdéhùn Òwò Àjùmọ̀ṣe ní Àríwá America (NAFTA) àti Àjọ Elétò Ọrọ̀ Ajé Asia Òun Pacific (APEC), lè kín ètò ọrọ̀ ajé àgbáyé lẹ́yìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìtẹ̀sí yìí ń sún àwọn àjọ ńláńlá láti fìdí sọlẹ̀ ní àwọn ibi tí àwọn òṣìṣẹ́ ti wà fàlàlà, pẹ̀lú ìyọrísí pé àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ yóò máa pàdánù iṣẹ́. Lákòókò kan náà, àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn kì í gba owó tí ó pọ̀ tó ń rí i tí ìwọ̀nbà owó tí ń wọlé fún wọn ń kéré sí i. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ èèṣì pé ní àwọn orílẹ̀-èdè díẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn ti fi àtakò hàn sí àwọn àdéhùn òwò wọ̀nyí, kódà pẹ̀lú ìwà ipá.
Àwọn ògbógi dábàá ọ̀pọ̀ ohun tí a lè lò láti bá àìríṣẹ́ṣe jà. Àwọn mìíràn tilẹ̀ ta kora, ó sinmi lórí bóyá àwọn onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé, àwọn òṣèlú, tàbí àwọn òṣìṣẹ́ fúnra wọn ló dábàá wọn. Àwọn kan wà tí wọ́n dábàá fífún àwọn ilé iṣẹ́ ní ìsúnniṣe láti mú kí àwọn òṣìṣẹ́ wọn pọ̀ sí i nípa dídín ẹrù owó orí tí a gbé lé wọn kù. Àwọn kan dámọ̀ràn pé kí ìjọba dá sí ọ̀ràn náà ní ìwọ̀n gíga. Àwọn mìíràn dámọ̀ràn pípín iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti dídín wákàtí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kù. Wọ́n ti ṣe èyí ní àwọn ilé iṣẹ́ ńláńlá kan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láàárín ọ̀rúndún tí ó kọjá, wọ́n ti dín àwọn ọ̀sẹ̀ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ kù pátápátá ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè onílé iṣẹ́ ẹ̀rọ tí èyí kò sì mú kí àìríṣẹ́ṣe dín kù. Onímọ̀ ètò ọrọ̀ ajé Renato Brunetta tẹnu mọ́ ọn pé: “Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ìlànà iṣẹ́ ló wá yọrí sí èyí tí kò gbéṣẹ́, nítorí pé owó tí ń náni ti pọ̀ ju àǹfààní tí ń ti inú rẹ̀ wá lọ.”
Ìwé ìròyìn L’Espresso parí ọ̀rọ̀ pé: “Ẹ máà jẹ́ kí a máa ṣi ara wa lọ́nà, ìṣòro náà le gan-an.” Ṣé ó le jù láti yanjú ní? Ojútùú kankan ha wà sí ìṣòro àìríṣẹ́ṣe bí?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìṣòro Àtọjọ́mọ́jọ́ Kan
Ìṣòro àìríṣẹ́ṣe ti wà tipẹ́tipẹ́. Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni àwọn ènìyàn máa ń rí i tí àwọn kì í níṣẹ́ lọ́wọ́ ti wọn kò sì fẹ́ bẹ́ẹ̀. Gbàrà tí iṣẹ́ bá ti parí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún mẹ́wàá-mẹ́wàá àwọn òṣìṣẹ́ tí a lò ní àwọn ibi ìdáwọ́lé iṣẹ́ ilé kíkọ́ ńlá kan yóò wá di aláìríṣẹ́ṣe pẹ̀lú—ó kéré tán títí di ìgbà tí a óò gbà wọ́n síṣẹ́ níbòmíràn. Kí ó tó di ìgbà náà, wọ́n ń gbé láìláàbò, kí a wulẹ̀ rọra sọ ọ́ bẹ́ẹ̀.
Láàárín Sànmánì Ìtàn Europe, “bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìṣòro àìríṣẹ́ṣe nígbà náà bí ó ti rí lóde òní,” àwọn aláìríṣẹ́ṣe wà. (La disoccupazione nella storia [Àìríṣẹ́ṣe Nínú Ọ̀rọ̀ Ìtàn]) Bí ó ti wù kí ó rí, ní ayé ìgbàanì, ní pàtàkì, ẹnikẹ́ni tí kì í bá ṣiṣẹ́ ni a kà sí aláìdára fún nǹkankan tàbí alárìnkiri. Ọ̀jọ̀gbọ́n John Burnett ṣàlàyé pé, títí wá fi di ọ̀rúndún kọkàndínlógún, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain tí wọ́n jẹ́ olùṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ “so aláìríṣẹ́ṣe pọ̀, ní pàtàkì, mọ́ ‘àwọn ènìyàn játijàti’ àti àwọn alárìnká tí ń sùnta tàbí tí wọ́n máa ń fẹsẹ̀ palẹ̀ lópòópónà lóru.”—Idle Hands.
“Mímọ̀ pé àìríṣẹ́ṣe jẹ́ ìṣòro kan tí ó wà gedegbe” ṣẹlẹ̀ lápá ìparí ọ̀rúndún kọkàndínlógún tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Àwọn ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe pàtàkì ti ìjọba, bí Ìgbìmọ̀ Àṣàyàn Láti Ilé Ìgbìmọ̀ Àṣòfin Kékeré lórí “Ìrora Ọkàn Nítorí Àìríṣẹ́ṣe,” ni a gbé kalẹ̀ ní 1895 láti ṣèwádìí, kí wọ́n sì yanjú ìṣòro náà. Àìníṣẹ́lọ́wọ́ ti di ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.
Mímọ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ yìí ń lọ sókè díẹ̀díẹ̀, ní pàtàkì lẹ́yìn ogun àgbáyé kìíní. Ìforígbárí yẹn, pẹ̀lú gbogbo ìgbéjáde ohun ìdìhámọ́ra oníjàgídíjàgan rẹ̀, ti mú àìríṣẹ́ṣe kúrò pátápátá. Ṣùgbọ́n bẹ̀rẹ̀ láti àwọn ọdún 1920, àwọn orílẹ̀-èdè Ìwọ̀ Oòrùn ayé dojú kọ ọ̀wọ́ ìlọsílẹ̀ ọrọ̀ ajé tí ó jálẹ̀ sí Ìjórẹ̀yìn Ọrọ̀ Ajé Ńlá tí ó bẹ̀rẹ̀ ní 1929, tí ó sì kọ lu gbogbo ètò ọrọ̀ ajé àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ lágbàáyé. Lẹ́yìn ogun àgbáyé kejì, orílẹ̀-èdè púpọ̀ nírìírí ìbẹ́sílẹ̀ tuntun kan nínú ètò ọrọ̀ ajé, tí àìríṣẹ́ṣe sì ṣé pẹ́ẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n Ètò Àjọ Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti Ìdàgbàsókè Ètò Ọrọ̀ Ajé sọ pé, “a lè tọpa ìbẹ̀rẹ̀ ìṣòro àìríṣẹ́ṣe ti òde òní padà sí ìdajì àwọn ọdún 1960.” Agbo àwọn òṣìṣẹ́ jìyà lọ́wọ́ ìdìgbòlù kan tí rògbòdìyàn epo dá sílẹ̀ ní àwọn ọdún 1970 àti ìmúgbòòrò yíyára kánkán tí ó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú lílo kọ̀m̀pútà, pẹ̀lú àbájáde lílé àwọn òṣìṣẹ́ dà nù. Àìríṣẹ́ṣe ti bẹ̀rẹ̀ sí i ga sókè láìdábọ̀, ó wọlé sáàárín agbo àwọn òṣìṣẹ́ alákọ̀wé àti àwọn olùṣàbójútó tí a ti kà sí èyí tí ó láàbò nígbà kan rí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Wíwá iṣẹ́ púpọ̀ sí i kò lè yanjú ìṣòro àìríṣẹ́ṣe
[Credit Line]
Reuters/Bettmann