Ibo Lọ̀ràn “Iṣẹ́ Àfìgbésí Ayé Ẹni Ṣe” Ń Lọ Báyìí?
GRAHAMa bá ilé iṣẹ́ ńlá kan ní Ọsirélíà ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́tàdínlógójì. Nígbà tó kù díẹ̀ kó di ẹni ọgọ́ta ọdún, wọ́n fi tó o létí pé lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, yóò fi ilé iṣẹ́ náà sílẹ̀ nítorí pé wọn kò nílò iṣẹ́ rẹ̀ mọ́. Àwa náà lè mọ bí yóò ṣe yà á lẹ́nu tó, kàyéfì ńlá gbáà ló máa jẹ́ fún un, kò sì sí àníàní pé yóò ṣàníyàn gidigidi nípa àtúbọ̀tán rẹ̀. Graham ṣe kàyéfì pé, ‘Ibo lọ̀ràn “iṣẹ́ àfìgbésí ayé ẹni ṣe,” èyí tí mo ronú pé kò lè bọ́ lọ́wọ́ mi títí tí màá fi fẹ̀yìn tì, wá ń lọ báyìí?’
Dájúdájú, pé èèyàn pàdánù iṣẹ́ kì í ṣe ohun tójú ò rí rí, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe tuntun. Ṣùgbọ́n, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ṣe wá ń pàdánù iṣẹ́ kárí ayé jẹ́ tuntun sí àwọn òṣìṣẹ́ òde òní. Kò sí tàbí ṣùgbọ́n pé ohun tó ń jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn pọ̀, ṣùgbọ́n ó dà bíi pé èyí tó wọ́pọ̀ jù lọ ni ti dídín òṣìṣẹ́ kù. Kí ni dídín òṣìṣẹ́ kù, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀?
Ibi Iṣẹ́ Tí Ń Yí Padà
Lóde òní, gbogbo ayé ló ń ṣúnwó ná. Ní pàtàkì, èyí fara hàn ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní apá ìparí ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1970, nígbà tí àwọn ilé iṣẹ́ ṣàkíyèsí pé àwọn èèyàn púpọ̀ sí i ló lọ ń ra ọkọ̀, àwọn ohun èlò abánáṣiṣẹ́, àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó jẹ́ pé òkè òkun ni wọ́n ti ń ṣe wọ́n.
Kí àwọn ilé iṣẹ́ tó wà ní Amẹ́ríkà pẹ̀lú lè ṣe dáadáa, kí wọ́n sì lè dín owó tí wọ́n fi ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe jáde kù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí dín iye àwọn òṣìṣẹ́ kù kó lè mọ níwọ̀nba, wọ́n sì mú kí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣe nǹkan àti irin iṣẹ́ tí wọ́n ń lò túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Àwọn ọ̀nà tí wọ́n ń gbà dín àwọn òṣìṣẹ́ kù ni, “lílé àwọn kan kúrò lẹ́nu iṣẹ́, rírọ àwọn kan pé kí wọ́n tètè fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, gbígbé wọn lọ síbòmíràn, tàbí kó ṣẹlẹ̀ pé àwọn kan kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀ tàbí bóyá wọ́n kú.”
Fún àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ wọn kì í ṣe ti onígègé ni dídín àwọn òṣìṣẹ́ kù máa ń kàn. Ṣùgbọ́n ní apá ìparí ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1980 àti ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀wádún tó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 1990, ọ̀ràn yìí bẹ̀rẹ̀ sí kan àwọn òṣìṣẹ́ onígègé, pàápàá àwọn tí wọn kò tíì di ọ̀gá. Kò pẹ́ tí ọ̀ràn yìí fi kan gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ń ṣe iṣẹ́ àfẹ̀rọṣe. Bí ipò ìṣúnná owó sì ṣe ń le koko sí i, ìjọba àti àwọn agbanisíṣẹ́ ń wá ọ̀nà láti dín ìnáwó kù nípa títúbọ̀ dín àwọn òṣìṣẹ́ kù.
Fún ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́, kò sí ìdánilójú mọ́ pé iṣẹ́ kò lè bọ́ lọ́wọ́ wọn. Aṣíwájú ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kan sọ pé: “Àwọn èèyàn tó fi tọkàntara ṣiṣẹ́ fún ọdún mẹ́wàá, ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, tàbí ogún ọdún ń rí i tí iṣẹ́ tí wọ́n ti gbà pé kò lè bọ́ ń bọ́ lọ́wọ́ wọn.” Nínú ìwé náà, Healing the Downsized Organization, tí Delorese Ambrose kọ, ó ṣàlàyé pé lọ́dún 1956, wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà, “afarajinṣẹ́” láti ṣàpèjúwe irú òṣìṣẹ́ tí a sọ yìí. Ó fi kún un pé: “Yálà lébìrà ni o, tàbí ọ̀gá iṣẹ́, gbogbo èrè owó tó jẹ́ tirẹ̀, ìgbésí ayé aláfẹ́, àti ìdúróṣinṣin rẹ̀ ló lò fún àjọ náà kí iṣẹ́ má bàa bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀—ìyẹn iṣẹ́ àfìgbésí ayé ẹni ṣe. Ó ṣe kedere pé, àdéhùn yìí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ mọ́ ní àwọn ilé iṣẹ́ òde òní.”
Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ òṣìṣẹ́ jákèjádò ayé ni iṣẹ́ ti bọ́ lọ́wọ́ wọn nígbà tí àwọn ilé iṣẹ́ ń dín òṣìṣẹ́ kù, kò sì sí irú àwùjọ òṣìṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ yìí kò kàn. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nìkan, iye àwọn òṣìṣẹ́ tí ọ̀rọ̀ yìí kàn kúrò ní kékeré, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ni iṣẹ́ tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu rẹ̀ ṣáà dédé bọ́ lọ́wọ́ wọn. Irú dídín àwọn òṣìṣẹ́ kù yìí tún wáyé ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn. Ṣùgbọ́n iye tí a sọ níhìn-ín tó jóòótọ́ yìí nìkan kò lè ròyìn ohun tójú àwọn tọ́ràn kàn ń rí.
Àwọn Ipa Búburú Tó Ń Ní
Graham, tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Wàá ní ìdààmú ọpọlọ díẹ̀ ní ti gidi.” Ó fi gbígbà tí wọ́n gbaṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ wé “àìsàn kan tàbí líluni ní àlùkì.”
Bí àwọn èèyàn bá fi tọkàntara ṣiṣẹ́, tí wọn kò sì san èrè rẹ̀ fún wọn, wọ́n máa ń ronú pé ṣe ni wọ́n dalẹ̀ àwọn nítorí pé ilé iṣẹ́ tí àwọn bá ṣiṣẹ́ kò mọrírì iṣẹ́ takuntakun tí àwọn ti ṣe. Kò ní sí ìgbẹ́kẹ̀lé mọ́, pàápàá bí àwọn ọ̀gá tí ń darí ilé iṣẹ́ bá rí owó ńlá gbà nítorí pé wọ́n bá àwọn tó ni ilé iṣẹ́ dín àwọn òṣìṣẹ́ kù. Láfikún sí i, bí owó kò ṣe ní máa wọlé déédéé mọ́ fún ẹni tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́ yìí yóò jẹ́ kó ṣòro fún un láti máa san àwọn owó èlé tó yẹ kó san, láti san àwọn gbèsè mìíràn tó jẹ, láti máa tọ́jú ìlera àwọn mẹ́ńbà ìdílé rẹ̀, láti máa san owó ilé ìwé àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó sì máa bá ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ nìṣó, ṣíṣe ìgbòkègbodò àfipawọ́ àti bí àwọn ohun ìní rẹ̀ kò ṣe ní di gbígbé tà yóò di ìṣòro pẹ̀lú. Èyí máa ń mú kí èèyàn sọ̀rètí nù, kí èèyàn sì ronú pé òun kò já mọ́ nǹkan kan.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé níní iṣẹ́ tó ní láárí, tó sì lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ti máa ń jẹ́ kí èèyàn gbà pé òun ṣe pàtàkì, ronú nípa ẹ̀dùn ọkàn tí àìríṣẹ́ṣe máa ń kó bá àwọn aláàbọ̀ ara ná, àwọn tí kò ní iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe, tàbí àwọn tí wọ́n ti ń darúgbó lọ. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní Ọsirélíà fi hàn pé àwọn èèyàn tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọdún márùndínláàádọ́ta sí mọ́kàndínlọ́gọ́ta ni àwọn ilé iṣẹ́ á fẹ́ máa lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́ jù lọ. Síbẹ̀, àwọn tó wà ní irú ọjọ́ orí yìí ló máa ń ṣòro fún jù lọ láti mú ara wọn bá ìyípadà tó bá ṣẹlẹ̀ mu.
Ǹjẹ́ àwọn ohun mìíràn wà tí wọ́n lè ṣe? Ó dájú pé kí èèyàn máa ṣe iṣẹ́ àbọ̀ṣẹ́ tàbí iṣẹ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ mú owó wọlé dára ju pé kí èèyàn máà ríṣẹ́ ṣe rárá. Ṣùgbọ́n, ìyẹn lè máà jẹ́ kí èèyàn ní àwọn ohun kò-ṣeé-mánìí ìgbésí ayé bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ìwádìí sì ti fi hàn pé nǹkan bí ìdá mẹ́ta péré nínú àwọn òṣìṣẹ́ tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn ló ń padà rí iṣẹ́ tó ń mówó wọlé bí èyí tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Èyí ń fi kún àìfararọ nínú ìgbésí ayé ìdílé.
Kódà iṣẹ́ tí èèyàn ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí pàápàá lè máà túmọ̀ sí pé ọkàn ẹni á balẹ̀. Ìdí ni pé ríronú pé iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ ẹni lọ́jọ́ iwájú máa ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni lọ́nà kan pẹ̀lú. Ìwé kan tí ń jẹ́ Parting Company, sọ pé: “Ńṣe ni fífojúsọ́nà pé iṣẹ́ á bọ́ lọ́wọ́ ẹni dà bí ìgbà tí èèyàn bá sọ pé bí ọkọ̀ bá tiẹ̀ fẹ́ gbá òun, ẹ̀gbẹ́ ibi tí òun á kọ sí i nìyí. Àmọ́, ó ṣòro láti ṣe gẹ́lẹ́ bí èèyàn ṣe ronú rẹ̀ nítorí pé ọkọ̀ á ti gbá ẹni ọ̀hún tán kó tó mọ̀, bó ṣe jẹ́ pé lójijì ni iṣẹ́ máa ń bọ́ lọ́wọ́ ẹni.”
Ipa wo ni àìríṣẹ́ṣe máa ń ní lórí àwọn ọ̀dọ́? Lẹ́yìn tí ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀kọ́ àti ti sáyẹ́ǹsì ṣe ìwádìí kan, wọ́n ṣe àlàyé pé: “Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí ṣíṣe kedere tó máa ń jẹ́ kí a mọ̀ pé ẹnì kan ti dàgbà ni bó bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ kan tó jẹ́ alákòókò kíkún, èyí tó ń fi hàn pé ìgbésí ayé àgbàlagbà ‘ní tòótọ́’ ti bẹ̀rẹ̀, nínú ayé kan tó jẹ́ ti àgbàlagbà, tó bá ọ̀pá ìdiwọ̀n àgbàlagbà mu, tí èèyàn sì lè dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀.” Nítorí náà, bí a bá ronú pé rírí iṣẹ́ ṣe ló ń sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé àgbàlagbà, àìríṣẹ́ṣe lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá àwọn ọ̀dọ́.
Kíkojú Àìríṣẹ́ṣe
Wọ́n sọ pé ńṣe ni kíkojú ìpàdánù iṣẹ́ dà bí ìgbà tí èèyàn bá ń rin inú pápá tí wọ́n ti ri àwọn ọta aṣọṣẹ́ sí. Ìwé tí ń jẹ́ Parting Company dárúkọ irú àwọn ìmọ̀lára tí èèyàn sábà máa ń ní, àwọn bíi ìbínú, ìtìjú, ìbẹ̀rù, ìbànújẹ́, àti kíkáàánú ara ẹni. Ó ṣòro láti kojú wọn. Òǹkọ̀wé náà sọ pé: “Iṣẹ́ tó le ni wọ́n gbé lé ọ lọ́wọ́—láti mọ bọ́jọ́ ọ̀la rẹ yóò ṣe rí. Kì í ṣe ìwọ lo béèrè fún irú iṣẹ́ yìí, ó ṣeé ṣe kí o má mọ bí wàá ṣe ṣe é, o sì lè wá rí i pé lójijì, ó ku ìwọ nìkan láìní olùrànlọ́wọ́ kankan.” Ọ̀kan nínú àwọn ohun tó ṣòro jù lọ fún àwọn tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn sì ni bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé fún ìdílé wọn nípa iṣẹ́ tó bọ́ lọ́wọ́ wọn lójijì.
Bó ti wù kó rí, àwọn ọ̀nà gbígbéṣẹ́ kan wà tí a lè fi kojú ipa tí dídín àwọn òṣìṣẹ́ kù máa ń ní. Ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé kí o wéwèé kí o sì máa gbé ìgbé ayé tí ó túbọ̀ jẹ́ ti ṣe-bóo-ti-mọ, tí kò dà bí èyí tó ti mọ́ ọ lára tẹ́lẹ̀.
Wo àwọn àbá kan tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ipò ọ̀hún, àní bí wọn kò bá tilẹ̀ lè yanjú rẹ̀ tán pátápátá. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mọ̀ pé lákòókò táa wà yìí, iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ rẹ lójijì. Nítorí náà, láìka ọjọ́ orí àti ìrírí rẹ sí, máa wéwèé fún ìyẹn nínú bí o ṣe ń gbé ìgbésí ayé rẹ.
Ìkejì, ṣọ́ra kí o má ṣe jẹ gbèsè tabua nítorí àwọn nǹkan tí kò ṣe kókó fún ìgbẹ́mìíró àti aṣọ. Má ṣe ná ju iye tí ń wọlé fún ọ, má sì ṣe ronú pé wàá lè san àwọn gbèsè kan nítorí o ń retí láti rí owó nígbà tí wọ́n bá fún ọ ní ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́ tàbí nígbà tí wọ́n bá fi kún owó iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n tí máa ń ṣe déédéé. Ohun tí ètò ọrọ̀ ajé tòní ń fi hàn ni pé, ó ṣeé ṣe kí ọjọ́ ọ̀la má fi bẹ́ẹ̀ ṣeé gbára lé mọ́.
Ìkẹta, wá àwọn ọ̀nà láti mú kí ìgbésí ayé rẹ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí o sì dín àwọn ohun tí o ń náwó sí kù. Èyí kan pípa jíjẹ gbèsè nítorí àwọn nǹkan tí kò ṣe kókó fún ọ̀nà ìgbésí ayé tó mọ níwọ̀n, tó sì gbámúṣé tì.
Ìkẹrin, ṣàyẹ̀wò àwọn góńgó tí o gbé kalẹ̀ ní ìgbésí ayé, ìyẹn góńgó tẹ̀mí àti ti ara, kí o sì mú kí wọ́n bá ìgbà mu. Lẹ́yìn náà, o lè fara balẹ̀ ronú nípa gbogbo ohun tí o pinnu lórí àwọn góńgó rẹ, kí o sì mọ ipa tí wọn yóò ní lórí rẹ.
Ní paríparí rẹ̀, má ṣe yán hànhàn fún ọ̀nà tí àwọn ẹlòmíràn ń gbà gbé ìgbésí ayé olówó gọbọi ní àgbègbè rẹ, kí ọkàn rẹ má bàa fà sí ohun tí wọ́n ní, kí ìwọ náà sì bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbé ayé bíi tiwọn.
Àbá mélòó kan nìwọ̀nyẹn, tó lè mú kí ìwọ àti ìdílé rẹ yẹra fún ìdẹkùn gbígbára lé ọrọ̀ tí kò dáni lójú, nínú ayé aláìdánilójú yìí, kí ẹ sì bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àníyàn tí ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn máa ń fà.
Wọ́n fa ọ̀rọ̀ olùfi owó ìdókòwò pamọ́ tẹ́lẹ̀ rí nì, Felix Rohatyn, yọ tí ó sọ pé: “Ohun kan wà tí kò tọ́ ní ti gidi láwùjọ wa, ìyẹn ni pé kí àìríṣẹ́ṣe ẹnì kan máa sọ ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀.” Ètò nǹkan ìsinsìnyí ṣàìtọ́ ní ti gidi débi pé láìpẹ́, a óò fi ayé kan dípò rẹ̀, níbi tí gbólóhùn náà pé “iṣẹ́ àfìgbésí ayé ẹni ṣe” yóò túbọ̀ ní ìtumọ̀ ju ohun tí a lè finú wòye rẹ̀ nísinsìnyí.—Aísáyà 65:17-24; 2 Pétérù 3:13.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ yìí padà.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]
‘Ohun kan wà tí kò tọ́ ní ti gidi láwùjọ wa, ìyẹn ni pé kí àìríṣẹ́ṣe ẹnì kan máa sọ ẹlòmíràn di ọlọ́rọ̀’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Wá àwọn ọ̀nà láti mú kí ìgbésí ayé rẹ wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì