ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/8 ojú ìwé 9-11
  • Bíbọ́ lọ́wọ́ Àìríṣẹ́ṣe—Báwo àti Nígbà Wo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bíbọ́ lọ́wọ́ Àìríṣẹ́ṣe—Báwo àti Nígbà Wo?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wíwá Iṣẹ́ Kiri
  • Ìjẹ́pàtàkì Ìtìlẹ́yìn Èrò Ìmọ̀lára
  • Bíbọ́ Lọ́wọ́ Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ Àìríṣẹ́ṣe
  • Ìṣòro Àìríṣẹ́ṣe
    Jí!—1996
  • Àìríṣẹ́ṣe—Kí Ló ń fà á?
    Jí!—1996
  • Bá A Ṣe Lè Ní Èrò Tó Yẹ Nípa Iṣẹ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa
    Jí!—1996
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 3/8 ojú ìwé 9-11

Bíbọ́ lọ́wọ́ Àìríṣẹ́ṣe—Báwo àti Nígbà Wo?

BÍI ti Ẹlẹ́dàá rẹ̀, ènìyàn lè gbádùn iṣẹ́, tí a túmọ̀ lọ́nà títọ́ sí “ẹ̀bùn Ọlọrun.” (Oniwasu 3:12, 13; Johannu 5:17) Iṣẹ́ tí ó gbádùn mọ́ni lè fún wa láyọ̀, ó sì lè mú kí a nímọ̀lára bí ẹni tí ó wúlò tí a sì ń fẹ́. Kò dájú pé ẹnì kan yóò fẹ́ láti pàdánù iṣẹ́ rẹ̀, láìka bí ìgbádùn tí ó ń rí nínú rẹ̀ ṣe lè kéré tó sí. Yàtọ̀ sí pé iṣẹ́ tí a ń sanwó rẹ̀ fúnni pèsè ìdánilójú gbígba owó ọ̀yà, ó ń pèsè ìwàlétòlétò, ète, àti ìmọ̀lára pé a jẹ́ nǹkan nínú ìgbésí ayé ẹni. Kò yani lẹ́nu pé lọ́pọ̀ ìgbà, “àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe ń wá iṣẹ́ ju ohunkóhun mìíràn lọ.”

Wíwá Iṣẹ́ Kiri

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, bí ipò nǹkan ti rí nínú agbo àwọn òṣìṣẹ́ lọ́jú pọ̀ gan-an. Gẹ́gẹ́ bí àbáyọrí rẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà tí ó gbéṣẹ́ ló wà láti fi wáṣẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá lẹ́tọ̀ọ́ sí àwọ́n àǹfààní láti ọwọ́ ìjọba lè gbádùn wọn bí ó bá wà; níbi tí irú ìṣètò bẹ́ẹ̀ bá sì wà, wọ́n lè forúkọ sílẹ̀ ní àwọn ọ́fíìsì tí ń bójú tó ọ̀ràn àwọn aláìríṣẹ́ṣe, kí wọ́n sì gbádùn àwọn ìpèsè tí a fúnni. Àwọn mìíràn máa ń rí iṣẹ́ ṣe nípa dídá iṣẹ́ tiwọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n ènìyàn ní láti ṣọ́ra. Lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn tí wọ́n ní iṣẹ́ tiwọn fúnra wọn ní láti korí bọ ìnáwó rẹpẹtẹ, tí ó lè má rọrùn láti san padà, láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Ó tún pọn dandan láti mọ̀, kí a sì bọ̀wọ̀ fún àwọn òfin ètò ìlú àti owó orí—tí kì í ṣe kérémí ní àwọn orílẹ̀-èdè kan!—Romu 13:1-7; Efesu 4:28.

Láti rí iṣẹ́, àwọn kan ti sọ iṣẹ́ wíwá fúnra rẹ̀ di iṣẹ́, ní lílo gbogbo ara wọn fún un pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìtẹpẹlẹmọ́. Àwọn mìíràn ti kọ̀wé sí àwọn ilé iṣẹ́ tí ń wá àwọn òṣìṣẹ́, tàbí kí wọ́n ṣe ìkéde nínú àwọn ìwé agbéròyìnjáde ládùúgbò—tí àwọn kan lára wọn ń tẹ ìkéde iṣẹ́ wíwá jáde lọ́fẹ̀ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jí! tí pèsè àwọn ìmọ̀ràn wíwúlò, tí ó sì gbéṣẹ́ lórí kókó ọ̀ràn yìí—fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà pẹ̀lú.a—Wo àwọn àpótí, ojú ewé 11.

O gbọ́dọ̀ mọwọ́ọ́ yí padà—kí o múra tán láti ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́, títí kan àwọn iṣẹ́ tí o kò fi bẹ́ẹ̀ fẹ́ràn. Àwọn ògbógi sọ pé ọ̀kan lára àwọn ohun àkọ́kọ́ tí a máa ń béèrè níbi ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún iṣẹ́ ni ìrírí tí a ti ní lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí àti bí ó ti pẹ́ tó ti a ti kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Ẹni tí yóò gbani síṣẹ́ máa ń kà á sí ohun tí kò dára kí ẹni tí ń wá iṣẹ́ ti pàdánù iṣẹ́ fún àkókò pípẹ́.

Ẹni tí ó lo àkókò rẹ̀ lọ́nà ọgbọ́n láti kẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ní àǹfààní dídára jù láti rí iṣẹ́ tí o yàn láàyò jù lọ. Alberto Majocchi, olùkọ́ ìmọ̀ ìjinlẹ̀ ìṣúnná owó, sọ pé: “Àwọn òṣìṣẹ́ tí wọn kò ní iṣẹ́ àkọ́mọ̀ọ́ṣe ni àìríṣẹ́ṣe máa ń ṣẹlẹ̀ sí jù.”

Ìjẹ́pàtàkì Ìtìlẹ́yìn Èrò Ìmọ̀lára

Níní ojú ìwòye títọ̀nà jẹ́ kókó pàtàkì kan. Èyí lè mú kí ènìyàn rí iṣẹ́ tàbí kí ó máà rí iṣẹ́. Àwọn tí wọn kò ríṣẹ́ ṣe máa ń mọyì ìtìlẹ́yìn èrò ìmọ̀lára, èyí tí ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yẹra fún yíya ara wọn sọ́tọ̀ àti sísoríkọ́. Ó tún máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí pípàdánù ọ̀wọ̀ ara ẹni tí ó lè jẹ yọ láti inú fífi ara wọn wé àwọn ẹlòmíràn tí wọn kò pàdánù iṣẹ́ wọn.

Mímú kí awọ kájú ìlù lè má rọrùn. Stefano sọ pé: “Níwọ̀n bí mo ti wà nínú ìdààmú, ó ṣòro fún mi láti lo àkókò tí mo ní dáradára.” Francesco rántí pé: “Ipò ọ̀ràn náà mú kí pákáǹleke bá mi, débi pé mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí sí díẹ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n.” Ìhìn ni ìtìlẹ́yìn láti ọ̀dọ̀ ìdílé ti wúlò. Àìsí owó tí ń wọlé béèrè pé kí gbogbo àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yí ọwọ́ padà, láti lè dín àwọn ohun tí wọ́n fi ń ṣègbádùn ara kù. Franco, tí wọ́n lé dànù lẹ́nu iṣẹ́ nígbà tí ó jẹ́ ẹni ọdún 43 lẹ́yìn tí ó ti bá ilé iṣẹ́ náà ṣiṣẹ́ fún ọdún 23, sọ pé: “Láti ìgbà tí wọ́n ti lé mi dànù lẹ́nu iṣẹ́, aya mi ní ojú ìwòye títọ̀nà, ó sì jẹ́ orísun ìṣírí gígadabú fún mi.” Armando kún fún ìmoore ní pàtàkì sí aya rẹ̀ fún “òye ńláǹlà tí ó máa ń lò nígbà tí ó bá lọ rajà.”—Owe 31:10-31; Matteu 6:19-22; Johannu 6:12; 1 Timoteu 6:8-10.

Àwọn ìlànà Bibeli lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí títọ̀nà, kí a sì má ṣe gbàgbé àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù. Àwọn ènìyàn tí Jí! fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, tí a mẹ́nu kàn lókè yìí, rí ìfọ̀kànbalẹ̀ tí ń tuni nínú láti inú Bibeli. Èyí tí mu kí wọ́n nímọ̀lára sísún mọ́ Ọlọrun sí i. (Orin Dafidi 34:10; 37:25; 55:22; Filippi 4:6, 7) Níní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa Ọlọrun ṣe pàtàkì púpọ̀, nítorí ó ṣèlérí pé: “Emi kì yoo fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tabi ṣá ọ tì lọ́nàkọnà.”—Heberu 13:5.

Yálà ẹnì kan ríṣẹ́ ṣe tàbí kò rí ṣe, Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gba olúkúlùkù níyànjú láti mú àwọn ànímọ́ tí ó wúlò dàgbà fún ìgbésí ayé ojoojúmọ́. Kì í ṣe èèṣì pé a máa ń wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kiri, tí a sì máa ń mọyì wọn gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ aláìlábòsí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Wọ́n máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bibeli láti jẹ́ aláápọn, ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, tí kì í ṣe ọ̀lẹ.—Owe 13:4; 22:29; 1 Tessalonika 4:10-12; 2 Tessalonika 3:10-12.

Bíbọ́ Lọ́wọ́ Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ Àìríṣẹ́ṣe

Bí a bá wa gbòǹgbò àìníṣẹ́, okùnfà pàtàkì kan wà níbẹ̀—ìmọtara-ẹni-nìkan àti ìwọra ènìyàn. Gẹ́gẹ́ bí Bibeli ti sọ, “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnì kejì fún ìfarapa rẹ̀.”—Oniwasu 8:9.

Ìṣòro àìríṣẹ́ṣe—àti àwọn ìṣòro mìíràn pẹ̀lú—ni a óò yanjú nípa mímú ìjẹgàba ènìyàn, tí ó ti dé àwọn “ìkẹyìn ọjọ́” rẹ̀ nísinsìnyí, kúrò. (2 Timoteu 3:1-3) A nílò ayé kan tí ó tuntun ní ti gidi. Bẹ́ẹ̀ ni, ayé kan nínú èyí tí àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn olódodo lè gbé, kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ lábẹ́ ìṣàkóso òdodo tí ó dára, níbi tí ìwọra kì yóò sí mọ́. (1 Korinti 6:9, 10; 2 Peteru 3:13) Ìdí nìyẹn tí Jesu fi kọ́ àwọn ènìyàn láti gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọrun dé, àti pé kí ìfẹ́ Rẹ̀ di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé.—Matteu 6:10.

Nígbà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń ṣàpèjúwe bí a óò ṣe mú díẹ̀ lára àwọn lájorí ìṣòro aráyé kúrò lọ́nà alásọtẹ́lẹ̀, ó ṣàkàwé àwọn ipa tí Ìjọba yẹn yóò ní pé: “Wọn ó sì kọ́ ilé, wọn ó sì gbé inú wọn; wọn ó sì gbin ọgbà àjàrà, wọn ó sì jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn gbé, wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Àwọn àyànfẹ́ mi yóò jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọn kì yóò ṣiṣẹ́ lásán, wọn kì yóò bímọ fún wàhálà.” (Isaiah 65:21-23) Dúgbẹ̀dùgbẹ̀ àìríṣẹ́ṣe yìí yóò pòórá láìpẹ́ títí ayé. Bí ìwọ yóò bá fẹ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa ojútùú tí Ọlọrun ní, jọ̀wọ́ kàn sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lágbègbè rẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Jí!, October 22, 1994, ojú ewé 16 sí 18; January 8, 1992, ojú ewé 6 sí 10; October 8, 1984, ojú ewé 13 sí 15; àti ti January 22, 1985, ojú ewé 18 sí 23.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Dídá Iṣẹ́ Sílẹ̀ Nílé

• Wíwo ọmọ deni, àbójútó ọmọdé

• Títa ewébẹ̀ tàbí òdòdó tí a gbìn sí etílé

• Rírán aṣọ, títún aṣọ rán, àti títún aṣọ ṣe

• Ṣíṣe àwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ fún àwọn tí ń ṣe nǹkan jáde

• Yíyan nǹkan àti gbígbọ́ oúnjẹ

• Ṣíṣe aṣọ ìborí bẹ́ẹ̀dì, híhun nǹkan, híhunṣọ; ṣíṣe janwọnjanwọn sí etí aṣọ, mímọ̀kòkò; àwọn iṣẹ́ ọnà mìíràn

• Ṣíṣe àwọn ohun ìjókòó onítìmùtìmù

• Ṣíṣèṣirò ìnáwó, títẹ̀wé, fífi kọ̀m̀pútà ṣiṣẹ́ nílé

• Iṣẹ́ dídáhùn tẹlifóònù

• Ṣíṣe irun lọ́ṣọ̀ọ́

• Bíbóju tó àwọn ayálégbé

• Kíkọ orúkọ sí àpòòwé àti kíkọ ọ̀rọ̀ kún un fún àwọn olùpolówó ọjà

• Fífọ ọkọ̀ àti fífi kẹ́míkà dán an (àwọn oníbàárà yóò gbé ọkọ̀ wá sílé rẹ)

• Títún ara àwọn ohun ọ̀sìn ìṣiré ṣe àti mímú wọn ṣeré ìmárale

• Ṣíṣàtúnṣe àgádáǹgodo àti ṣíṣe kọ́kọ́rọ́ (ní ṣọ́ọ̀bù nílé)

• Ìpolówó ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí ni a lè fi sínú àwọn ìwé ìròyìn tí ń sọ nípa ìrajà òpin ọ̀sẹ̀ tàbí pátákò àfiyèsí àwọn ilé ìrajà lọ́fẹ̀ẹ́ tàbí lówó pọ́ọ́kú.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Dídá Iṣẹ́ Sílẹ̀ Níta

• Wíwolé deni (nígbà tí àwọn onílé bá lọ fún ìsinmi, tí wọ́n sì fẹ́ kí a máa bójú tó ibùgbé àwọn)

• Títúnléṣe: àwọn ilé ìtajà; ọ́fíìsì; ibùgbé àti ilé gbéetán lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìkọ́lé bá parí, lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ iná, lẹ́yìn tí àwọn ènìyàn bá kó jáde; iṣẹ́ ilé (nínú ilé àwọn ẹlòmíràn); àwọn fèrèsé (ti ibi iṣẹ́ àti ti ilé)

• Iṣẹ́ àtúnṣe: oríṣiríṣi àwọn ohun èèlò (àwọn ibi ìkówèésí ní àwọn ìwé tí wọ́n ṣàlàyé nípa ìṣàtúnṣe nǹkan lọ́nà rírọrùn)

• Àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́: lílẹ nǹkan mọ́ ara ilé; ṣíṣe àpótí ìkóǹkansí, ilẹ̀kùn, àkọ́yọ ilé; kíkunlé; ṣíṣọgbà yí ilé ká; kíkanlé

• Iṣẹ́ oko: irè oko, kíká èso

• Gbígbin òdòdó àti ṣíṣàbójútó òdòdó ní: àwọn ọ́fíìsì, báǹkì, àwọn gbàgede ìtajà àti àwọn gbọ̀ngàn ńláńlá, àwọn ọ̀dẹ̀dẹ̀

• Bíbójú tó ohun ìní: atilẹ̀kùn, alábòójútó ilé gbéetán (tí a máa ń fún ní ilé gbígbé lọ́fẹ̀ẹ́ nígbà míràn)

• Ìbánigbófò, ojúlówó dúkìá

• Títẹ́ kápẹ́ẹ̀tì, fífọ̀ ọ́

• Títa ìwé agbéròyìnjáde (àwọn àgbàlagbà àti ọmọdé), àwọn iṣẹ́ kíkó nǹkan kiri mìíràn: ìpolówó ọjà, ìwé ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjà fún àwọn agbègbè kan

• Kíkó nǹkan kúrò, kíkó nǹkan pa mọ́

• Gbígbin koríko, gígé ẹ̀ka igi, títún ojú ọ̀nà ṣe, gígé igi

• Awakọ̀ ilé ẹ̀kọ́

• Fọ́tò yíyà (èyí tí a dá yà àti níbi ìṣẹ̀lẹ̀ ládùúgbò)

• Ìjẹ̀ fún àwọn apẹja

• Gbígba pààrọ̀ iṣẹ́: fífi títún ọkọ̀ ṣe gba pààrọ̀ iṣẹ́ ohun èèlò abánáṣiṣẹ́, fífi aṣọ rírán gba pààrọ̀ títún pọ́m̀pù omi ṣe, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Àwọn àyànfẹ́ mi yóò jìfà iṣẹ́ ọwọ́ wọn.”—Isaiah 65:22

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́