ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 3/8 ojú ìwé 12-15
  • Àwọn Oníṣẹ́ Mẹ́fà Láti Gbalasa Òfuurufú

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Oníṣẹ́ Mẹ́fà Láti Gbalasa Òfuurufú
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìgbì Ìtànṣán Aláwọ̀ Mèremère
  • Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Ṣeé Fojú Rí—Oníṣẹ́ Àkọ́kọ́
  • Ìgbì Rédíò—Oníṣẹ́ Kejì
  • X-Ray—Oníṣẹ́ Kẹta
  • Ìtànṣán Aláìlèṣeéfojúrí —Oníṣẹ́ Kẹrin
  • Ìtànṣán Ultraviolet —Oníṣẹ́ Karùn-ún
  • Ìtànṣán Gamma—Oníṣẹ́ Kẹfà
  • Ó Ṣàràmàǹdà Gan-an Síbẹ̀, Ó Lẹ́wà Púpọ̀
    Jí!—1996
  • Rédíò—Ìhùmọ̀ Tó Yí Ayé Padà
    Jí!—1996
Jí!—1996
g96 3/8 ojú ìwé 12-15

Àwọn Oníṣẹ́ Mẹ́fà Láti Gbalasa Òfuurufú

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ JAPAN

ÀWỌN oníṣẹ́ ṣáà ń dé léraléra láti gbalasa òfuurufú ni. Wọ́n ń kó àwọn ìsọfúnni yíyani lẹ́nu wá nípa àgbáálá ayé títóbi lọ́lá tí ó yí wa ká. Àwọn oníṣẹ́ wọ̀nyí, tí gbogbo wọ́n jẹ́ mẹ́fà, ń rìnrìn àjò pẹ̀lú ìyára ìmọ́lẹ̀, 300,000 kìlómítà ní ìṣẹ́jú àáyá kan. Ọ̀kan lára wọ́n ṣeé fojú rí fún ẹ̀dá ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn yòókù kò ṣeé fojú rí. Kí ni wọ́n jẹ́?

Ìgbì Ìtànṣán Aláwọ̀ Mèremère

A ti mọ̀ fún ohun tí ó lé ní 300 ọdún pé bí imọ́lẹ̀ bá gba àárín ìgò onígun tí ń fòdì kejì hàn kọjá, yóò jáde pẹ̀lú àwọn lájorí àwọ̀ méje ara òṣùmàrè. Èyí fi hàn pé ìmọ́lẹ̀ lásán ni gbogbo àwọ̀ méje ara òṣùmàrè, tí wọ́n jẹ́ ní ìtòtẹ̀léra àwọ̀ pupa, olómi ọsàn, ìyeyè, àwọ̀ ewé, búlúù, àwọ̀ aró, àti búlúù rẹ́súrẹ́sú.

A ka ìmọ́lẹ̀ sí ìgbì àwọn egunrìn tí kò lọ́rìn tí a ń pè ní photon, tí ó tún ní ànímọ́ ìgbì. Bí ìbẹ̀rẹ̀ ìgbì kan ṣe jìnnà sí ìbẹ̀rẹ̀ òmíràn ni a ń pè ní wavelength (ìwọ̀n gígùn ìgbì), a sì máa ń gbé e lórí òṣùwọ̀n kan tí a ń pè ní angstrom, tí ìkékúrú rẹ̀ ń jẹ́ Å. Ó dọ́gba pẹ̀lú ìdámẹ́wàá lára ìdá kan nínú ìdá bílíọ̀nù mítà kan. Ìmọ́lẹ̀ tí a lè fojú rí máa ń wọn nǹkan bí 4,000 sí 7,000 angstrom, ìmọ́lẹ̀ tí ó sì ní onírúurú ìwọ̀n gígùn ìgbì ń fara hàn bí àwọ̀ yíyàtọ̀.—Wo àwòrán àlàyé, ojú ewé 15.

Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn photon lè ní àwọn ìwọ̀n gígùn ìgbì míràn pẹ̀lú. Ọ̀wọ́ àwọn photon, tí a ń pè ní ìrànyòò ìgbì ìtànṣán, ni a fún ní oríṣiríṣi orúkọ tí ó sinmi lé bí ìwọ̀n gígùn ìgbì wọn bá ṣe tó. Bí kò bá tó 4,000 angstrom, bí àwọn ìwọ̀n gígùn ìgbì bá ṣe ń kúrú sí i ju àwọn ti ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí, àwọn ìgbì ìtànṣán máa ń fara hàn lọ gẹ́gẹ́ bí ìtànṣán ultraviolet (UV), X-ray àti ìtànṣán gamma. Nígbà tí ó bá gùn ju 7,000 angstrom lọ, a kì í rí àwọn ìgbì náà mọ́, ṣùgbọ́n wọ́n wà láàárín apá aláìlèṣeéfojúrí sí apá ìgbì rédíò nínú àwọn ìgbì ìtànṣán aláwọ̀ mèremère. “Àwọn oníṣẹ́ mẹ́fà” láti gbalasa òfuurufú náà nìyẹn. Wọn máa ń kó ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run wá. Jẹ́ kí a wá wo bí a ṣe ń ṣàyẹ̀wò wọn láti lè rí ìsọfúnni tí ó gbéṣẹ́.

Ìmọ́lẹ̀ Tí Ó Ṣeé Fojú Rí—Oníṣẹ́ Àkọ́kọ́

Láti ìgbà tí Galileo ti dojú awò awọ̀nàjíjìn rẹ̀ kọ òfuurufú ní 1610 títí wá di 1950, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ti bẹ̀rẹ̀ sí í lo awò awọ̀nàjíjìn àfiríran láti ṣèwádìí nípa àgbáálá ayé. Wọ́n mọ kìkì àwọn ìhà tí ó ṣeé fojú rí lára ìgbì ìtànṣán aláwọ̀ mèremère náà. Àwọn nǹkan tí ó wà lójú ọ̀run ni a wulẹ̀ lè rí fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́ nínú àwọn awò awọ̀nàjíjìn àfiríran, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà sì gba àwọn àwòrán náà sílẹ̀ sórí fíìmù fọ́tò láti ṣèwádìí nípa wọn. Nísinsìnyí, àwọn ohun atúǹkanfó abánáṣiṣẹ́ tí a mọ̀ sí ìhùmọ̀ agbáwòrányọ, tí ó fi ìgbà 10 si 70 lágbára ju fíìmù kámẹ́rà lọ, ti wá ń wọ́pọ̀ gan-an. Oníṣẹ́ tí ó ṣeé fojú rí yìí ń pèsè ìsọfúnni nípa bí ìràwọ̀ ṣe wúwo tó, ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù rẹ̀, àti àwọn èròjà oníkẹ́míkà tí ó wà nínú rẹ̀, ó sì ń sọ nípa bí ó ṣe jìnnà tó.

Láti lè rí ìmọ́lẹ̀, àwọn awò awọ̀nàjíjìn títóbi gan-an ni a ń ṣe. Láti 1976 ni awò awọ̀nàjíjìn onímítà márùn-ún, tí ó wà ní Ibi Ìwosánmà ní Zelenchukskaya, Rọ́ṣíà, ti jẹ́ awò awọ̀nàjíjìn títóbi jù lọ tí ń gbé àwòrán yọ tí ó wà lágbàáyé. Bí ó ti wù kí ó rí, ní April 1992, awò awọ̀nàjíjìn àfiríran agbáwòrányọ tuntun ti Kecka ni a ṣe parí ní Mauna Kea ní Hawaii. Dípò dígí kan ṣoṣo, awò awọ̀nàjíjìn Keck ní àkópọ̀ abala dígí 36 onígun mẹ́fà. Àwọn abala náà ní ìwọ̀n ìdábùú òbírí tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ mítà mẹ́wàá.

Wọ́n sì ń ṣe awò awọ̀nàjíjìn Keck kejì, tí ó wà nítòsí ti tẹ́lẹ̀, tí wọ́n ń pè ní Keck Kíní báyìí, àwọn awò awọ̀nàjíjìn méjèèjì náà sì lè ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ohun èèlò àfiríran aṣàkójọ ìgbì láti mọ ìwọ̀n gígùn ìgbì. Èyí kan títa àtagbà àwọn awò awọ̀nàjíjìn onímítà mẹ́wàá méjèèjì nípasẹ̀ kọ̀m̀pútà, tí ń yọrí sí agbára àtigbé àwòrán kedere dígí jáde, èyí tí yóò dọ́gba pẹ̀lú dígí kan ṣoṣo tí ìwọ̀n ìdábùú òbírí rẹ̀ jẹ́ mítà 85. “Agbára àtigbé àwòrán kedere dígí jáde,” tàbí “agbára ìgbéǹkanyọ kedere,” tọ́ka sí agbára átifìyàtọ̀ àárín àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ hàn.

Wọ́n ṣì ń ṣe awò awọ̀nàjíjìn àfiríran àti onítànṣán aláìlèṣeéfojúrí, Subaru, (orúkọ ilẹ̀ Japan fún ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Pleiade), tí ó gùn ní ìwọ̀n 8.3 mítà lọ́wọ́, ní Ibi Ìdúrósíwosánmà Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Sánmà Ti Orílẹ̀-Èdè ní Tokyo, ní Mauna Kea. Yóò ní dígí tín-ínrín kan tí ń lo àwọn ìhùmọ̀ agbéǹkanṣiṣẹ́ 261, tí yóò ṣàtúnṣe ìrísí dígí náà lẹ́ẹ̀kan ní ìṣẹ́jú àáyá kọ̀ọ̀kan láti lè ṣàtúnṣe àbùkù èyíkéyìí tí ó bá wà lójú dígí náà. Ṣíṣe àwọn awò awọ̀nàjíjìn gìrìwò míràn ṣì ń lọ lọ́wọ́, nítorí náà, ó dá wa lójú pé a óò ṣì mọ púpọ̀ sí i láti ọ̀dọ̀ oníṣẹ́ àkọ́kọ́—ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí.

Ìgbì Rédíò—Oníṣẹ́ Kejì

Ìtújáde ìgbì rédíò láti Milky Way ni a kọ́kọ́ mọ̀ ní 1931, ṣùgbọ́n ó di àwọn ọdún 1950 kí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà nípa ìgbì rédíò tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí ń lo awò awọ̀nàjíjìn àfiríran. Pẹ̀lú àwárí ìtújáde ìgbì rédíò láti gbalasa òfuurufú, ohun tí àwọn awò awọ̀nàjíjìn àfiríran kò lè rí wá ṣeé rí. Ṣíṣàkíyèsí àwọn ìgbì rédíò mú kí ó ṣeé ṣe láti rí àárín ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wa.

Ìwọ̀n gígùn ìgbì rédíò pọ̀ ju ti ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí lọ, a sì nílò àwọn òpó wáyà gíga láti lè gba ìgbì wọlé. Wọ́n ti ṣe àwọn òpó wáyà tí ìwọ̀n ìdábùú òbírí wọn tó 90 mítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ fún lílò nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà nípa ìgbì rédíò. Níwọ̀n bí agbára ìgbéǹkanyọ kedere kò ti dára tó, kódà nínú ohun èèlò tí ó tóbi tó bẹ́ẹ̀ yẹn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà lo kọ̀m̀pútà láti tàtagbà àwọn awò awọ̀nàjíjìn rédíò pẹ̀lú ọgbọ́n ìṣe kan tí wọ́n pè ní aṣàkójọpọ̀ ìgbì láti mọ ìwọ̀n gígùn ìgbì. Bí àwọn awò awọ̀nàjíjìn náà bá ṣe jìnnà síra tó ni yóò ti ṣe kedere tó.

Ọ̀kan lára irú àwọn ìsokọ́ra bẹ́ẹ̀ ní òpó wáyà onímítà 45 ti Ibi Ìdúrósíwosánmà Ìgbì Rédíò Nobeyama ní Japan; òpó wáyà onímítà 100 ní Bonn, Germany; àti awò awọ̀nàjíjìn onímítà 37 ní United States nínú. Irú ìsokọ́ra yìí ni a ń pè ní ìṣàkójọ ìgbì láti mọ ìwọ̀n gígùn ìgbì jíjìnnà síra gan-an (VLBI), èyí sì yọrí sí agbára ìgbéǹkanyọ kedere ìdá kan nínú ìdá ẹgbẹ̀rún ìṣẹ́jú àáyá kíkéré jọjọ, tàbí agbára láti dá ohun kan tí ó jẹ́ mítà 1.8 lórí òṣùpà mọ̀.b Ìwọ̀n ìdábùú òbírí ilẹ̀ ayé mú kí irú VLBI bẹ́ẹ̀ láàlà.

Ibi Ìdúrósíwosánmà Ìgbì Rédíò Nobeyama ń tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbésẹ̀ kan láti gba oníṣẹ́ yìí nípa fífi òpó wáyà rédíò onímítà mẹ́wàá kan sí gbalasa òfuurufú. Yóò gbéra ní Japan ní 1996, a óò sì tàtagbà rẹ̀ mọ́ àwọn awò awọ̀nàjíjìn ìgbì rédíò ní Japan, Europe, United States, àti Australia, tí èyí yóò sì mú kí ó fi 30,000 kìlómítà jìnnà síra. Lédè míràn, ìsokọ́ra yìí yóò dà bí awò awọ̀nàjíjìn gbàràmù kan tí ó tó ìlọ́po mẹ́ta ilẹ̀ ayé fúnra rẹ̀! Yóò ní agbára àtigbé àwòrán kedere jáde tí ó jẹ́ 0.0004 ìṣẹ́jú àáyá kíkéré jọjọ, tí ó túmọ̀ sí pé yóò lè rí ohun kan tí ó gùn ní 70 sẹ̀ǹtímítà lórí òṣùpá. Bí a ti pè é ní Ìṣètò Ibi Ìdúrósíwosánmà Gbalasa Òfuurufú VLBI, tàbí kí a ké e kúrú sí VSOP, a óò máa lò ó láti ṣàdàkọ àti láti ṣèwádìí àwọn àárín mímọ́lẹ̀ rekete inú ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ àti àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run, níbi tí a ronú pé àwọn ihò dúdú títóbi jàn-ànràn wà. Gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ kejì láti àgbáálá ayé, ìgbì rédíò ń pitú, yóò sì máa bá a lọ ní pípèsè ìsọfúnni nípa àwọn orísun wọn.

X-Ray—Oníṣẹ́ Kẹta

Ọdún 1949 ni a kọ́kọ́ ṣàkíyèsí X-ray. Níwọ̀n bí àwọn ìtànṣán X-ray kò ti lè dé agbègbè ilẹ̀ ayé, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ní láti dúró de àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tuntun nípa rọ́kẹ́ẹ̀tì àti àwọn sátẹ́láìtì àtọwọ́dá láti lè rí ìṣọfúnni láti ọ̀dọ̀ oníṣẹ́ yìí. Àwọn ìtànṣán X-ray ni a máa ń gbé jáde ní ìwọ̀n ìgbóná tí ó ga ré kọjá àlà, tí ó sì máa ń tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìsọfúnni nípa àwọn agbègbè ìràwọ̀ gbígbóná, àwọn àfọ́kù ìbúgbàù ìràwọ̀ bàm̀bà, ìṣùjọ ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀, àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run, àti àwọn ihò dúdú alábàá-èrò-orí.—Wo Jí!, March 22, 1992, ojú ewé 5 sí 9 (Gẹ̀ẹ́sì).

Ní June 1990, sátẹ́láìtì Roentgen gbéra, ó sì ṣàṣeyọrí ní yíyàwòrán X-ray gbogbo àgbáálá ayé. Ìsọfúnni tí a ṣàkọsílẹ̀ fi mílíọ̀nù mẹ́rin orísun X-ray, tí a pín ká gbogbo òfuurufú hàn. Bí ó ti wù kí ó rí, ìrànyòò ṣíṣàjèjì kan wà lọ́wọ́ ẹ̀yìn láàárín àwọn orísun wọ̀nyẹn. Ó lè jẹ́ pé, ó ń wá láti inú ìṣùjọ àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run, tí a gbà gbọ́ pé wọ́n jẹ́ àárín alágbára àwọn ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ nítòsí ohun tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kan pè ní “ẹbátí àgbáálá ayé tí ó ṣeé fojú rí.” Bí àkókò ti ń lọ, a lè fojú sọ́nà láti jàǹfààní ìsọfúnni síwájú sí i láti ọ̀dọ̀ oníṣẹ́ náà, X-ray.

Ìtànṣán Aláìlèṣeéfojúrí —Oníṣẹ́ Kẹrin

Àkíyèsí àkọ́kọ́ tí ó jẹ́ nípa ohun tí a kò lè fojú rí ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọdún 1920. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ooru gbígbóná máa ń fa ìtànṣán aláìlèṣeéfojúrí mọ́ra, fún àbájáde dídára jù lọ, a lò àwọn sátẹ́láìtì ayíbírí láti ṣèwádìí nípa oníṣẹ́ yìí. Ní 1983, wọ́n lo Sátẹ́láìtì Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Sánmà Tí Kò Ṣeé Fojú Rí (IRAS) láti yàwòrán gbogbo òfuurufú tí a kò lè fojú rí pátápátá, wọ́n sì ṣàwárí 245,389 orísun ohun aláìlèṣeéfojúrí. Nǹkan bí ìpín 9 nínú ọgọ́rùn-ún (22,000) lára àwọn ohun náà ni ó hàn kedere pé ó jẹ́ ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ jíjìnnà réré.

Àwọn awò awọ̀nàjíjìn àfiríran kò lè ríran láàárín gbogbo àwọn agbègbè ibi tí gáàsì àti eruku wà ní gbalasa òfuurufú. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, oníṣẹ́ kẹrin yìí mú kí ó rọrùn láti “ríran” jìnnà láàárín eruku, ó sì ṣe pàtàkì ní ti gidi ní wíwo àárín ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ wa. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ wéwèé láti mú awò awọ̀nàjíjìn kan tí a ń pè ní Ìpèsè Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Tí Kò Ṣeé Fojú Rí, tí agbára ìgbésọfúnni rẹ̀ fi 1,000 ìgbà ju ti IRAS lọ, yí po.

Ìtànṣán Ultraviolet —Oníṣẹ́ Karùn-ún

Àkíyèsí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà àkọ́kọ́ tí a ṣe nípa ìtànṣán ultraviolet (UV) ṣẹlẹ̀ ní 1968. Ipele ozone kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára ìtànṣán yìí dé agbègbè ilẹ̀ ayé. Awò Awọ̀nàjíjìn Gbalasa Òfuurufú Hubble, tí ó gbéra ní April 1990, wà ní ìgbaradì láti ṣàyẹ̀wò àwọn ìtànṣán ultraviolet àti àwọn ìtànṣán tí ó ṣeé fojú rí, yóò sì dojú kọ 30 ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run tí àwọn kan lára wọ́n jìnnà tó bílíọ̀nù mẹ́wàá ọdún ìmọ́lẹ̀.c Ní èdè míràn, ṣíṣàyẹ̀wò oníṣẹ́ ultraviolet náà mú kí ó ṣeé ṣe láti rí bí àgbáálá ayé ṣe rí ní nǹkan bíi bílíọ̀nù mẹ́wàá ọdún sẹ́yìn. A lérò pé oníṣẹ́ yìí yóò fi àwọn ohun àràmàǹdà púpọ̀ sí i nípa àgbáálá ayé hàn.

Ìtànṣán Gamma—Oníṣẹ́ Kẹfà

Àwọn ìtànṣán gamma jẹ́ alágbára gíga tí ó ní ìwọ̀n gígùn ìgbì kíkúrú jọjọ. Ó dùn mọ́ni pé, òfuurufú kì í jẹ́ kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtànṣán aṣèbàjẹ́ wọ̀nyí dé agbègbè ilẹ̀ ayé. Oníṣẹ́ yìí ń ṣiṣẹ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onípá nínú àgbáálá ayé. Ní April 5, 1991, Ẹ̀ka Ìfòlófuurufú àti Ìṣàkóso Gbalasa Òfuurufú ti Orílẹ̀-Èdè fi Ibi Ìdúrósíwosánmà Ìtànṣán Gamma ránṣẹ́ sínú gbalasa òfuurufú. Yóò ṣàkíyèsí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó kan àwọn ìṣẹ̀dá ojú ọ̀run, ìbúgbàù ìràwọ̀ bàm̀bà, àwọn orísun ìlùkìkì ìgbì rédíò, àwọn ihò dúdú alábàá-èrò-orí, àti àwọn ohun jíjìnnà míràn.

Pẹ̀lú sànmánì ìmọ̀ gbalasa òfuurufú tí ó dáyé, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà lè wo gbogbo ìgbì ìtànṣán aláwọ̀ mèremère pátápátá, láti orí ìgbì rédíò dé orí ìtànṣán gamma. Lótìítọ́, sànmánì aásìkí ni ó jẹ́ fún àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà. Tí a bá ‘gbé ojú wa sókè síbi gíga,’—pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ mẹ́fà tí wọ́n ṣẹ̀ láti inú ìràwọ̀—a lè “wo” àràmàǹdà ọgbọ́n Ẹlẹ́dàá gbogbo wọn. (Isaiah 40:26; Orin Dafidi 8:3, 4) Bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí ń bá a lọ láti túmọ̀ àwọn ìsọfúnni tí àwọn oníṣẹ́ wọ̀nyí kó wá, a óò máa bá a lọ láti nímọ̀lára gan-an gẹ́gẹ́ bí Jobu ti ní in ní ohun tí ó lé ní 3,000 ọdún sẹ́yìn pé: “Kíyè sí i, èyí ni òpin ọ̀nà rẹ̀, ohun èyí tí a gbọ́ ti kéré tó!”—Jobu 26:14.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tí a fi orúkọ ọlọ́rẹ kan tí ó lọ́rọ̀, W. M. Keck, sọ.

b Agbára ìgbéǹkanyọ kedere ojú ènìyàn jẹ́ ìpín ìṣẹ́jú àáyá kíkéré jọjọ kan. Agbára ìgbéǹkayọ kedere ìdá kan nínú ẹgbẹ̀rún ìṣẹ́jú àáyá kíkéré jọjọ kan fi ìgbà 60,000 ju ti ojú lọ.

c Ọdún ìmọ́lẹ̀ kan jẹ́ 9,460,000,000,000 kìlómítà.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

0.1Å Ìtànṣán gamma

1Å X-ray

10Å

100Å UV

1,000Å

4000Å sí 7000Å Ìmọ́lẹ̀ tí ó ṣeé fojú rí

10,000Å Ìtànṣán aláìlè- ṣeéfojúrí

10μ

100μ Ìgbì rédíò

1 mm

1 cm

10 cm

1m

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Pẹ̀lú awò awọ̀nàjíjìn ìgbì rédíò ní gbalasa òfuurufú VSOP, yóò ṣeé ṣe láti rí ohun tí ó jẹ́ 70 sẹ̀ǹtímítà lórí òṣùpá

[Credit Line]

VSOP: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure Nobeyama Radio Observatory, Japan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwòrán awò awọ̀nàjíjìn àfiríran àti ìtànṣán aláìlèṣeéfojúrí Subaru, tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́

[Credit Line]

Subaru: Pẹ̀lú ìyọ̀ọ̀da onínúure National Astronomical Observatory, Japan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́