Àwọn Eṣinṣin Akóninírìíra Wọ̀nyẹn—Wọ́n Ha Wúlò Ju Bí O Ti Lérò Lọ Bí?
Ọ̀PỌ̀ jù lọ lára wa lérò pé àwọn eṣinṣin jẹ́ ayọnilẹ́nu tàbí ewu gan-an fún àwùjọ ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nipa ohun alààyè ti ń ṣàwárí pé àwọn eṣinṣin wúlò ju bí a ti lè lérò lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń dani láàmú.
Irú ẹ̀yà púpọ̀ máa ń lo àkókò tí ó pọ̀ jù lọ lóòjọ́ ní lílọ sórí àwọn òdòdó, tí ó dà bí ilé àrójẹ tí ń pèsè omiídùn òdòdó àti lẹ́búlẹ́bú fún àwọn kòkòrò tí wọ́n gbára lé wọn. Àwọn eṣinṣin kan tí wọ́n lè fa èròjà láti inú lẹ́búlẹ́bú—tí ó jẹ́ àṣeyọrí kan nínú ara rẹ̀—gbẹ́kẹ̀ lé oúnjẹ tí ń pèsè agbára púpọ̀ yìí láti mú àwọn ẹyin wọn dàgbà.
Bí wọ́n ti ń lọ láti orí òdòdó kan sí òmíràn, àwọn eṣinṣin náà kò lè ṣàìfi ara kó àwọn ẹ̀gbọ̀n lẹ́búlẹ́bú tí ń lẹ̀ mọ́ wọn lára. Eṣinṣin kan tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ohun alààyè fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ní 1,200 ẹ̀gbọ̀n lẹ́búlẹ́bú lára! Bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń ṣe ọ̀pọ̀ ìwádìí púpọ̀ sí i lórí ipa tí àwọn eṣinṣin ń kó ní ti gbígbọn lẹ́búlẹ́bú, wọ́n ṣàwárí pé àwọn òdòdó kan gbára lé wọn láti lè máa wà nìṣó.
Ìwé ìròyìn Natural History ṣàpèjúwe ọ̀wọ́ àwọn àṣeyẹ̀wò tí a ṣe ní Colorado, Àríwá America. Irú ẹ̀yà muscoid wíwọ́pọ̀, tí ó jọ eṣinṣin ilé, ni a fi àwọ̀ títàn pa lára kí a baà lè tètè tọpa wọn. Lẹ́yìn ṣíṣọ́ ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́, ó ya àwọn olùṣèwádìí náà lẹ́nu láti rí i pé àwọn eṣinṣin náà jẹ́ agbọn-lẹ́búlẹ́bú pàtàkì fún àwọn òdòdó ẹgàn kan ju àwọn oyin lọ àti pé wọ́n wà ní ipò tí ó wúlò ju ti àwọn oyin lọ.
Báwo ni iṣẹ́ eṣinṣin ti ṣe pàtàkì tó? Àwọn òdòdó kan máa ń da ohun fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan borí kí àwọn kòkòrò má baà ya ọ̀dọ̀ wọn. Àwọn òdòdó yìí kì í mú èso jáde rárá—ní ìyàtọ̀ ìfiwéra pẹ̀lú àwọn tí wọ́n wà nítòsí tí wọ́n ń mú èso jáde, tí àwọn eṣinṣin gbọn lẹ́búlẹ́bú sí lára. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn òdòdó kan ní àwọn oyin máa ń gbọn lẹ́búlẹ́bú sí lára, ní ti àwọn irú ẹ̀yà míràn bíi flax ẹgàn tàbí geranium ẹgàn, ní àwọn ibì kan tí ó ga ju ìtẹ́jú òkun lọ, àwọn eṣinṣin náà máa ń ṣe ohun tí ó lé ní ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára iṣẹ́ yìí.
Ibo ni Carol Kearns àti David Inouye, àwọn méjì lára àwọn olùṣèwádìí náà, fi ọ̀rọ̀ tì sí? “Nígbà náà, fún ọ̀pọ̀ àwọn òdòdó ẹgàn láàárín àwọn Òkè Colorado, àwọn eṣinṣin ta àwọn oyin, labalábá, àti àwọn ẹyẹ akùnyùnmù yọ . . . Bí kì í bá ṣe ti àwọn kòkòrò wọ̀nyí, tí ń kó ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn nírìíra, púpọ̀ lára àwọn òdòdó ẹgàn tí ń mú kí ṣíṣèbẹ̀wò sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ eléwéko tútù àárín àwọn òkè ńláńlá gbádùn mọ́ni ni kò ní hu hóró èso rárá.” Kò sí iyè méjì nípa rẹ̀, àwọn eṣinṣin wúlò láàyè tiwọn!