Ìgbà Wo Ni Kòkòrò Oyin Kì Í Ṣe Kòkòrò Oyin?
Àwọn kòkòrò oyin kì í ṣàìrí nǹkan ṣe, wọ́n máa ń lọ láti orí òdòdó kan sí òmíràn lójoojúmọ́, wọ́n sì ń gbé omiídùn òdòdó pa dà lọ sí ilé wọn. Tí ìgbà ìrúwé bá dé, àwọn akọ oyin máa ń wá abo. Láti lè ṣe èyí, wọ́n máa ń gbẹ́kẹ̀ lé ìríran àti ìgbóòórùn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, alárédè míràn tí kò láyọ̀lé—òdòdó orchid—tún máa ń wá àtigbàfiyèsí oyin tí kò bá ṣọ́ra.
Ní ìhà gúúsù Yúróòpù, onírúurú òdòdó orchid ẹgàn ló wà tí gbígbakọ wọn sinmi lórí ṣíṣe bí àwọn abo oyin. Àwọn òdòdó orchid wọ̀nyí ní láti fi “àwọn ìdìpọ̀” lẹ́búlẹ́bú ránṣẹ́ sí àwọn òdòdó orchid ẹlẹgbẹ́ wọn. Àwọn oyin ló máa ń gbé e dáradára. Ṣùgbọ́n níwọ̀n bí àwọn òdòdó orchid kò ti ní omiídùn òdòdó tí ó lè pe ojú àwọn oyin mọ́ra, àwọn òdòdó orchid náà gbọ́dọ̀ lo ẹ̀tàn. Ẹ̀tàn náà sì ni pé òdòdó náà yóò rí bí abo oyin, yóò sì ní òórùn tí ó jọ ọ́ gan-an débi pé akọ oyin náà yóò gbìyànjú láti gùn ún! Ọ̀kọ̀ọ̀kan irú ọ̀wọ́ àwọn òdòdó orchid wọ̀nyí ní bí ó ṣe máa ń tàn wọ́n àti irú òórùn tirẹ̀.
Nígbà tí oyin náà bá fi máa fura pé òun ń ṣàṣìṣe, òdòdó orchid náà yóò ti da ìdìpọ̀ lẹ́búlẹ́bú fífà tìkọ̀ sára rẹ̀. Oyin náà yóò wá fò lọ, òdòdó orchid míràn tí yóò gba lẹ́búlẹ́bú náà yóò sì tún kó o nígàn-án. Lẹ́yìn irú ìtànjẹ bẹ́ẹ̀ bíi mélòó kan, oyin náà yóò wá mọ̀ pé àwọn òdòdó orchid wọ̀nyí kò ṣeé fọkàn tẹ̀. Nígbà yẹn, ó ṣeé ṣe kí ó ti fún díẹ̀ lára àwọn òdòdó náà ní lẹ́búlẹ́bú.
Báwo ni àwọn òdòdó orchid tí kì í ronú wọ̀nyí ṣe ń rí òórùn àti ìrísí yíyẹ tí wọ́n fi ń kó àwọn oyin nígàn-án? Irú ọ̀nà ìṣe kíkàmàmà bẹ́ẹ̀ jẹ́rìí sí Olùṣàgbékalẹ̀ onílàákàyè kan, tí ìṣẹ̀dá rẹ̀ kò kùnà ṣíṣeni-níkàyéfì àti fífanimọ́ra rí.