A Ń wu Òdòdó Orchid Léwu bí?
Àwọn òdòdó orchid lè mú ara bá ipò èyíkéyìí mu. Wọ́n lè hù lórí ilẹ̀, lára igi, kódà lórí àpáta pàápàá. Ṣùgbọ́n Àjọ Alágbàwí Ààbò Ìṣẹ̀dá àti Ohun Àmúṣọrọ̀ Lágbàáyé (IUCN) kìlọ̀ pé ọ̀pọ̀ lára onírúurú irúgbìn títayọ yìí lè run nínú igbó bí a kò bá jáwọ́ dída àyíká tí wọ́n wà láàmú. Wendi Strahm, láti àjọ IUCN, sọ pé: “Yíyí ibùgbé àdánidá wọn padà túmọ̀ sí pé àwọn kòkòrò tí ń lọ́wọ́ nínú ìgbakọ rẹ̀ yóò kú tán tàbí kí wọ́n ṣí lọ sí ibòmíràn.” Ó fi kún un pé: “Bí ìyẹn bá sì ṣẹlẹ̀, òdòdó orchid náà kò ní lè mú irú jáde mọ́.”
A fojú díwọ̀n pé ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún lára mílíọ̀nù márùn-ún òdòdó orchid tí a ń tà jákèjádò ayé lọ́dọọdún la lọ kó nínú igbó. Àjọ IUCN sọ pé, èyí ń ṣèdíwọ́ fún dídáàbò bo irúgbìn lílẹ́wà yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, àjọ IUCN dámọ̀ràn pé kí àwọn tí wọ́n fẹ́ òdòdó orchid máa lọ rà àwọn tí a gbìn sí àwọn ilé ewéko dípò kí wọ́n máa fà wọ́n tu ní àgbègbè àdánidá wọn.
Ó kéré tán, 20,000 irú ọ̀wọ́ òdòdó orchid ni ènìyàn mọ̀. Àwọn kan jẹ́ irúgbìn tí kò ga ju 0.6 sẹ̀ǹtímítà péré lọ; àwọn mìíràn ti gbilẹ̀ di igi tí gíga rẹ̀ jẹ́ 30 mítà. Púpọ̀ lára irú ọ̀wọ́ òdòdó orchid máa ń ṣe dáadáa ní àwọn àgbègbè ilẹ̀ olóoru, tí ó lọ́ wọ́ọ́wọ́ọ́ tí òjò ti máa ń rọ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n ìwàdéédéé ṣíṣẹlẹgẹ́ ti ìṣẹ̀dá ni wọ́n ń gbára lé láti máa wà nìṣó.
Ó bani nínú jẹ́ pé àìmọ̀kan àti àìbìkítà ẹ̀dá ń bá a lọ láti máa ba àyíká jẹ́, ó sì ń wu àwọn irúgbìn púpọ̀ sí i léwu, títí kan òdòdó orchid. Ṣùgbọ́n yóò dópin láìpẹ́. Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí, ènìyàn kò ní da ìṣẹ̀dá láàmú mọ́. Ní ìgbà yẹn, àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà yóò ṣẹ pé: “Kí pápá gbalasa yọ ayọ̀ ńláǹlà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀. Ní àkókò kan náà, kí gbogbo igi igbó fi ìdùnnú bú jáde.”—Sáàmù 96:12.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]
Jardinería Juan Bourguignon
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 27]
Jardinería Juan Bourguignon