Sísin Kòkòrò Oyin—Ìtàn “Aládùn” Kan
Láti ọwọ́ aṣojúkọ̀ròyìn Jí! ní Gíríìsì
ILẸ̀ rọra ń mọ́ bọ̀. Láàárín òtútù àti ìrì òwúrọ̀ kùtùkùtù náà ni ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan rọra dúró sí ìsàlẹ̀ ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ńlá kan. Àwọn ẹni méjì tí a kò rí dáradára jáde—wọ́n wọ ìbọ̀wọ́, bàtà àwọ̀dórúkún, aṣọ àwọ̀lékè olówùú, àti àkẹtẹ̀ tí etí rẹ̀ gbòòrò, tí ó sì ní ìbòjú. Wọ́n yára kánkán tìṣọ́ratìṣọ́ra, wọ́n kó ọ̀pọ̀ àpótí onígi sínú ọkọ̀ akẹ́rù náà. Ṣé olè méjì tí ń fìrọ̀rùn jí ẹrù kó lọ ni wọ́n ni? Rárá, àwọn tọkọtaya tí ń sin kòkòrò oyin, tí ń bójú tó ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ kòkòrò oyin wọn ṣíṣeyebíye dáradára—tí wọ́n múra tán láti rìnrìn àjò, tí wọ́n forí lé ibòmíràn tí àwọn ewéko tí ń mú omiídùn òdòdó jáde gbé wà.
Àwọn ènìyàn tí ń sin kòkòrò oyin jẹ́ oríṣi ènìyàn àrà ọ̀tọ̀ kan, tí wọ́n ń yangàn ní ti pé wọ́n ní àjọṣe pẹ̀lú oríṣi kòkòrò àrà ọ̀tọ̀ kan. Lọ́nà kan, oyin ìgàn wà, bóyá tí ó jẹ́ èyí tí ó níye lórí jù lọ ní ti ọrọ̀ ajé láàárín àwọn kòkòrò, tí o máa ń ṣèmújáde oyin àti àtè oyin, tí ó sì ń ṣèrànwọ́ fún ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ onírúurú irè oko láti gbakọ. Lọ́nà míràn, àwọn ènìyàn kan wà tí ń wọ́nà láti gbọ́ bùkátà ìgbésí ayé lọ́nà ṣíṣòro nípa sísin àwọn kòkòrò oyin, tí wọ́n sì fẹ́ràn àwọn ẹ̀dá kéékèèké wọ̀nyí nígbà kan náà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára wọn sì ṣe sọ ọ́, “tí wọ́n ní ìmọ̀ nípa kòkòrò oyin.”
Olùṣàbójútó “Iṣẹ́ Ìyanu Ojoojúmọ́”
Dídi ẹni tí ń sin kòkòrò oyin lè dà bí ohun tó rọrùn: Kó ilé oyin mélòó kan tí àwùjọ kòkòrò oyin kún inú wọn jọ, kó wọn sí ibì kan tí omiídùn òdòdó wà lọ́pọ̀, kí o sì pa dà wá kórè lẹ́yìn oṣù mélòó kan. Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀. Kí a lè mọ ohun tí ó jẹ́ gan-an, a bá John àti Maria, àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí ń sin kòkòrò oyin, sọ̀rọ̀, wọ́n sì sọ fún wa nípa iṣẹ́ àyànláàyò wọn tayọ̀tayọ̀.
Bí John ti bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ lórí ilé oyin tí ó wà ní ṣíṣí sílẹ̀ kan, ó wí pé: “Iṣẹ́ sísin kòkòrò oyin jẹ́ ìgbòkègbodò kan nínú iṣẹ́ ìyanu ojoojúmọ́. Títí di báyìí, kò sí ẹni tí ó lóye ní kedere nípa ìṣètò ìgbésí ayé àjùmọ̀gbé, ọgbọ́n ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ gígalọ́lá, àti àwọn àṣà iṣẹ́ ṣíṣe onílàákàyè ti àwọn kòkòrò oyin.”
Ní títọpa ìtàn iṣẹ́ sísin kòkòrò oyin, John sọ pé, látijọ́, àwọn tí ń sin kòkòrò oyin máa ń rẹ́ oyin nípa pípa àwọn kòkòrò oyin tí ń gbé pọ̀, nínú fofò igi àti àwọn àhámọ́ oníhò míràn, náà run. Bí ó ti wù kí ó rí, ní 1851, Lorenzo Lorraine Langstroth, ará America kan, tí ń sin kòkòrò oyin, ṣàwárí pé àwọn kòkòrò oyin máa ń fi àlàfo nǹkan bíi mìlímítà mẹ́fà sí àárín àwọn afárá oyin. Nípa báyìí, a lè lo àwọn ilé oyin onípákó tí ènìyàn ṣàtọwọ́dá rẹ̀, nínú èyí tí a ti fi irú àlàfo kan náà sí àárín àwọn ìgbékalẹ̀ afárá. Mímú àwọn ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan kúrò nínú ilé oyin kan, kí a sì rẹ́ oyin àti àtè oyin náà, láìsí pé a ń pa àwọn kòkòrò oyin run, wá ṣeé ṣe.
John ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Láti ṣàṣeyọrí nínú iṣẹ́ sísin kòkòrò oyin, o gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ni lílágbára fún àwùjọ kòkòrò oyin rẹ. O dà bíi bàbá fún àwọn kòkòrò oyin rẹ, mo sì gbà gbọ́ pé wọ́n mọ èyí, wọ́n sì ń hùwà pa dà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. O tún di dókítà wọn, alábòójútó wọn, ẹni tí ń bọ́ wọn ní àwọn àkókò tí ó ṣòro nígbà òtútù.”
Maria ṣàfikún pé: “Ojúlówó ẹni tí ń sin kòkòrò oyin lè sọ ohun púpọ̀ nípa wíwulẹ̀ bojú wo ilé oyin kan, tí ó sábà máa ń ní ẹgbẹ̀rún 8 sí ẹgbẹ̀rún 80 àwọn kòkòrò oyin nínú. Bí o bá nírìírí, nígbà tí o bá ṣí ilé oyin kan, ìró àwọn kòkòrò oyin náà lásán yóò sọ fún ọ bóyá àwùjọ kòkòrò oyin náà ń gbèrú, wọ́n ń ṣe àmújáde, wọ́n sì ‘láyọ̀’; bóyá ebi ń pa wọ́n; bóyá ‘aláìníyàá’ ni wọ́n nítorí pé ìyá oyin tí ń pamọ láàárín wọn ti kú; bóyá nǹkan tí kò dùn mọ́ni kan ń ṣẹlẹ̀ sí wọn; àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.”
Àwọn Kókó Pàtàkì fún Iṣẹ́ Sísin Kòkòrò Oyin Lọ́nà Aláṣeyọrí
John ṣàlàyé pé: “Ó ṣe pàtàkì pé kí ẹni tí ń sin kòkòrò oyin fara balẹ̀ yan ibi tí yóò gbé ilé oyin rẹ̀ sí. A máa ń baralẹ̀ wá ibi tí àwọn ewéko ti ń tanná, tí àwọn kòkòrò oyin ti lè rí oúnjẹ.
“Ẹni tí ń sin kòkòrò oyin náà lè wá àwọn ibi tí ọsàn àti igi basswood ti ń tanná, kí àwọn àwùjọ kòkòrò oyin wọn lè máa ríṣẹ́ ṣe. Láàárín ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà ìwọ́wé, àgbègbè tí ó bá kún fún àwọn igi ahóyaya àti igi fir yóò ṣèrànwọ́ láti pèsè ojúlówó oyin, tí àwọ̀ pupa rẹ̀ mọ́ roro, tí ó sì ń tà dáradára lọ́jà. Àwọn igbó tí igi thyme, tí ó hù nígbó fúnra rẹ̀, bá ti ń tanná yóò dára fún oríṣi oyin dídára jù lọ—ògidì oyin, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń sin oyin ṣe ń pè é. Àwọn kòkòrò oyin náà tún máa ń wá ìjẹ níbi òdòdó clover funfun, òdòdó clover dídùn, aláwọ̀ ìyeyè, àti igi alfalfa.”
Ó ṣe pàtàkì gan-an láti ní làákàyè. Maria ṣàlàyé pé: “Nígbà tí a bá gbé àwọn ilé oyin náà sí àgbègbè olókè, ó ṣàǹfààní láti gbé wọn sí ìtòsí ẹsẹ̀ òkè ńlá náà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn kòkòrò oyin lè fò lọ sókè, kí wọ́n bà lé àwọn igi tí ó ní òdòdó, lẹ́yìn náà—tí wọ́n bá ti yó tán—kí wọ́n fò pa dà wálẹ̀, lọ́nà tí ó túbọ̀ rọrùn, sí ilé wọn. Bí a bá gbé àwọn ilé oyin náà síbi gíga ju àwọn igi lọ, yóò mú àárẹ̀ bá àwọn kòkòrò oyin náà, yóò sì ṣàkóbá fún bí àwùjọ kòkòrò oyin náà ṣe ń ṣèmújáde.”
Bí John ṣe fìsọ́ra gbé ọ̀kan lára àwọn ìgbékalẹ̀ ilé oyin náà, tí ọ̀dọ́ ìyá oyin tí ń pamọ kan bà sí igun rẹ̀, sókè, ó wí pé: “Gbogbo ẹni tí ń sin kòkòrò oyin ló mọ ipa pàtàkì tí ìyá oyin tí ń pamọ ń kó nínú ire àti ìṣèmújáde àwùjọ kòkòrò oyin kan. Nínú àwọn ilé oyin tí ń mú irú ọmọ àti oyin tí kò tó nǹkan jáde, a gbọ́dọ̀ pa ìyá oyin tí ń pamọ náà, kí a sì fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Àwùjọ kòkòrò oyin tí ó ní àwọn ọ̀dọ́ ìyá oyin tí ń pamọ ní ń ṣe oyin púpọ̀ jù. Pẹ̀lúpẹ̀lù, nígbà tí a bá fẹ́ dá àwùjọ tuntun sílẹ̀, a óò mú ilé oyin oníbejì tí ó jí pépé kan tí ó ní ọ̀pọ̀ kòkòrò oyin nínú, a óò sì yọ àwọn àpótí ìsàlẹ̀ àti tòkè sọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Ìdajì kan ní ìyá oyin tí ń pamọ náà nínú, nítorí náà, a óò fi ọ̀dọ́ ìyá oyin tí ń pamọ kan, tí ó ti gùn sínú ìdajì kejì. Nígbà tí àwọn òdòdó bá fi ń tanná, ìyá oyin tí ń pamọ tuntun náà yóò máa yé ẹyin, yóò sì fi àwọn ọ̀dọ́ kòkòrò oyin òṣìṣẹ́ kún inú ilé oyin náà.”
Báwo ni kòkòrò oyin kan ṣe ń pẹ́ láyé tó? A gbọ́ pé gígùn ìgbésí ayé òṣìṣẹ́ oyin kan sinmi lórí bí ó bá ṣe ń ṣiṣẹ́ tó. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, tí kòkòrò oyin kan ń wá ìjẹ lára àwọn òdòdó fún nǹkan bíi wákàtí 15 lóòjọ́, tí ó sì ń fò ní ìwọ̀n ìyára nǹkan bíi kìlómítà 21 ní wákàtí kan, ó ń wà láàyè fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà péré. Ìgbà òtútù kì í tán àwọn kòkòrò oyin lókun tó bẹ́ẹ̀, nítorí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ fún wákàtí méjì sí mẹ́ta péré lóòjọ́, nítorí náà, wọ́n ń lè wà láàyè fún oṣù mélòó kan.
Onírúurú Ohun Àṣejáde
Dájúdájú, ohun àkọ́kọ́ tí ń wá sọ́kàn nígbà tí a bá sọ̀rọ̀ nípa sísin kòkòrò oyin ni oyin. Ohun olómi dídùn, tí ń ṣe mẹ̀yẹ̀nmẹ̀yẹ̀n yí ni omiídùn òdòdó tí kòkòrò oyin òṣìṣẹ́ yí pa dà. Ní ìpíndọ́gba, ilé oyin tí a fi ń ṣòwò kan lè ṣe kìlógíráàmù 29 jáde lọ́dún kan. Ohun àṣejáde mìíràn tí ń ti inú ìgbòkègbodò kòkòrò oyin wá ni àtè oyin. Afárá oyin kan wúlò fún nǹkan bí ọdún márùn-ún sí mẹ́fà. Nígbà yẹn, àwọ̀ rẹ̀ yóò ti dúdú sí i nítorí onírúurú kòkòrò tíntìntín àti àwọn kòkòrò àfòmọ́ tí ń gbé inú rẹ̀, ó sì yẹ kí a pààrọ̀ rẹ̀. A máa ń fún àwọn afárá oyin tí a kò lò mọ́ náà, kí a lè yọ àtè oyin tí ó wà lára wọn. Ìpíndọ́gba àṣejáde fún ìṣòwò jẹ́ kìlógíráàmù 9 sí 18 fún tọ́ọ̀nù oyin kọ̀ọ̀kan tí a bá rẹ́.
Lẹ́búlẹ́bú òdòdó—tí ó jẹ́ olórí orísun èròjà protein, fítámì, mineral, àti fat fún ìdàgbàsókè ìyá oyin tí ń pamọ, òṣìṣẹ́, àti akọ oyin—tún ti gboríyìn lọ́dọ̀ àwọn kan fún pé ó jẹ́ egbòogi àdánidá dáradára kan fún àwọn àìlera ara mélòó kan. Ilé oyin kan lè ṣèmújáde kìlógíráàmù márùn-ún rẹ̀ lọ́dún kan. Ìda propolis ni èròjà kan tí àwọn kòkòrò oyin ń lò láti mú ilé wọn móoru àti láti fi sé ayọjúràn èyíkéyìí tí ó bá tóbi jù fún wọn láti mú kúrò mọ́.
Lọ́nà tààràtà tàbí lọ́nà tí kò ṣe tààràtà, ìṣèmújáde nǹkan bí ìdá mẹ́rin oúnjẹ tí a ń jẹ sinmi lórí agbára àwọn kòkòrò oyin láti mú àwọn ire gbakọ. Àwọn ápù, álímọ́ńdì, bàrà olómi, plum, pear, apálá, àti onírúurú àgbáyun lápapọ̀ gbára lé àwọn kòkòrò oyin láti mú kí wọ́n gbakọ. Bákan náà ni onírúurú ohun ọ̀gbìn oníhóró, títí kan kárọ́ọ̀tì, àlùbọ́sà, àti abóòrùnyí pàápàá. Àwọn kòkòrò oyin tún ń nípa lórí ẹran àti àwọn ìpèsè tí ń wá láti ara ẹran, nítorí pé àwọn ní ń mú kí òdòdó alfalfa tí ń di oúnjẹ ẹran ọ̀sìn gbakọ.
“Wọ́n Ní Ọgbọ́n Àdámọ́ni”
Maria rán wa létí bí a kò ṣe lè ṣàlàyé ìdíjúpọ̀ ìgbékalẹ̀ àwùjọ àwọn kòkòrò oyin, bí wọ́n ṣe ń ṣàgbékalẹ̀ ìgbésí ayé ẹgbẹ́ àwùjọ dídíjú tí ń fani lọ́kan mọ́ra, àti agbára ìṣe kíkàmàmà tí wọ́n ní fún ìdarí onílàákàyè àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, ó wí pé: “Mo lérò pé ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tí ń sin kòkòrò oyin gba Ọlọ́run gbọ́.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa kòkòrò oyin, tí wọ́n sì ń sìn ín ni yóò ṣe tán láti gbóṣùbà gbogbo ìwọ̀nyí fún kókó náà pé àwọn kòkòrò oyin “ní ọgbọ́n àdámọ́ni,” irú ohun àdámọ́ni bẹ́ẹ̀ ni a ti fún wọn lọ́nà ọlọ́làwọ́ láti ọwọ́ Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run.—Fi wé Òwe 30:24.
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Láti Orí Òdòdó Dé Orí Tábìlì Rẹ
1 Àwọn kòkòrò oyin ajẹko ń bẹ òdòdó wò, wọ́n sì ń fa omiídùn òdòdó mu
Bí àwọn kòkòrò oyin náà ṣe ń bà lórí àwọn òdòdó, wọ́n ń fa omiídùn òdòdó sínú àpò oyin wọn, tí ó jẹ́ ìmútóbi ihò ọ̀fun wọn. Kí àpò yí lè kún, kòkòrò oyin náà gbọ́dọ̀ bà lórí 1,000 sí 1,500 ẹyọ ẹ̀ka òdòdó
2 Nínú ilé oyin, wọ́n ń fi omiídùn òdòdó pa mọ́ sínú afárá oyin
Bí kòkòrò oyin ajẹko náà ṣe ń pa dà wọ ilé oyin, ó ń pọ àwọn ohun tí ó ti kó jọ sínú àpò oyin rẹ̀ sẹ́nu ọ̀dọ́ oyin òṣìṣẹ́ kan. Oyin òṣìṣẹ́ náà yóò da omiídùn òdòdó náà sínú horo kékeré kan, yóò sì ṣe àwọn ìgbòkègbodò tí ó pọn dandan láti sọ omiídùn òdòdó náà di oyin
3 Ẹni tí ń sin kòkòrò oyin náà ń rẹ́ oyin
Yóò fi abẹ gbígbóná kan gé ìda tí ó bo àwọn horo kéékèèké tí ó wà nínú ìgbékalẹ̀ kọ̀ọ̀kan. Yóò wá fi àwọn ìgbékalẹ̀ náà sínú ẹ̀rọ kan tí yóò fi agbára fún oyin jáde
4 A ń di oyin sínú ìṣà tàbí àwọn ohun ìkóǹkansí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Àwọn àkọlé ìdáǹkanmọ̀ ara ìṣà oyin ń sọ àwọn ewéko tí àwọn kòkòrò oyin náà ti fa omiídùn òdòdó. Bí inú ìṣà náà bá ṣeé rí láti ìta, o lè ṣàyẹ̀wò ìjójúlówó oyin náà nípa wíwo àwọ̀ tí ó ní
5 Oyin dára fún ìlera rẹ!
Oyin tètè máa ń dà lára, ó sì máa ń yára yí dà di okunra. Àwọn ìròyìn fi hàn pé a lè fi ṣètọ́jú ibi tí iná bá ti jóni àti onírúurú egbò ara