ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g02 3/8 ojú ìwé 31
  • Oyin—Ohun Aládùn Tó Ń Wo Ọgbẹ́ Sàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Oyin—Ohun Aládùn Tó Ń Wo Ọgbẹ́ Sàn
  • Jí!—2002
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Oyin Ẹ̀bùn Iyebíye Fáwa Ẹ̀dá
    Jí!—2005
  • “Ilẹ̀ Kan Tí Ń Ṣàn Fún Wàrà àti Oyin”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Sísin Kòkòrò Oyin—Ìtàn “Aládùn” Kan
    Jí!—1997
  • Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Àwọn Míì
Jí!—2002
g02 3/8 ojú ìwé 31

Oyin—Ohun Aládùn Tó Ń Wo Ọgbẹ́ Sàn

ÀWỌN èròjà apakòkòrò àtàwọn èròjà tí kì í jẹ́ kí ara wú tó wà nínú oyin ti mú kí inú àwọn olùwádìí kan dùn púpọ̀. Ìwé ìròyìn The Globe and Mail ti Kánádà sọ pé: “Oyin kò dà bí òbítíbitì àwọn oògùn apakòkòrò tí kò lè rí àwọn kòkòrò gbé ṣe, òun ní tirẹ̀ máa ń pa, ó kéré tán díẹ̀ nínú àwọn kòkòrò tó bá wà lójú ọgbẹ́.”

Kí ló wà nínú oyin tó fi lágbára tó bẹ́ẹ̀ láti wo ọgbẹ́? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí kò ṣẹ̀yìn kòkòrò oyin tó ń kó àwọn omiídùn jọ látinú òdòdó. Itọ́ ẹnu kòkòrò oyin ní èròjà kan tó máa ń fọ́ èròjà glucose tó wà nínú omiídùn yìí sí wẹ́wẹ́. Ibi ìfọ́síwẹ́wẹ́ yìí ni èròjà hydrogen peroxide tí wọ́n fi ń wẹ ọgbẹ́ tí wọ́n sì tún fi ń pa kòkòrò ti jáde. Èròjà hydrogen peroxide yìí kì í sábàá ṣiṣẹ́ lọ títí béèyàn bá fi í sí ojú egbò; àmọ́ tó bá jẹ́ oyin ni, ajẹ́bíidán ni. Ìwé ìròyìn Globe sọ pé: “Béèyàn bá fi oyin sójú egbò, ó máa dà pọ̀ mọ́ omi ara, èyí á sì dín èròjà ásíìdì tó wà nínú oyin kù.” Á wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu níbi tí kò ti sí èròjà ásíìdì púpọ̀ yìí. Èròjà ṣúgà tó wà nínú oyin á máa lọ sílẹ̀ díẹ̀díẹ̀, èyí sì máa ń ṣẹlẹ̀ látìgbàdégbà. Ìgbésẹ̀ yìí ló máa ń pèsè èròjà hydrogen peroxide díẹ̀díẹ̀ àmọ́ á pọ̀ débi tá á fi lè pa àwọn bakitéríà ojú ọgbẹ́ náà tí kò sì ní lè ṣèpalára fún ẹran ara tí ohunkóhun kò ṣe, tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọgbẹ́ náà.

Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn Globe ṣe sọ, onírúurú èròjà ló wà nínú oyin tó fi máa ń wo ọgbẹ́. “Oyin díẹ̀ téèyàn fi pa ojú ọgbẹ́ á dáàbò bò ó lọ́wọ́ kòkòrò, kò sì ní jẹ́ kí ojú egbò náà séèépá. Oyin tún máa ń jẹ́ kí àwọn òpójẹ̀ wẹ́wẹ́ dàgbà ó sì ń mú kí àwọn ohun tín-tìn-tín tó máa ń mú kí ọgbẹ́ san dàgbà.” Bákan náà, àwọn èròjà kan tún wà nínú oyin tó máa ń “dín ara wíwú kù, ó máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn káàkiri ara bó ṣe yẹ, kò sì ní jẹ́ kí egbò máa ‘wami.’”

Ìròyìn náà wá sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, gbogbo èèyàn kọ́ ni oyin máa ń ṣiṣẹ́ fún o.” Wọ́n fojú bù ú pé ìdá márùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún oyin ló ní àwọn kòkòrò botulin nínú. Àwọn ìwé bí èyí tí wọ́n fi ń ṣe Ìwádìí Nípa Kòkòrò Botulin tí àjọ Health Canada gbé jáde, àti àwọn ẹgbẹ́ tó ń tọ́jú àrùn ọmọdé sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ lo oyin fún àwọn ọmọ tí ò tíì pé ọmọ ọdún kan nítorí pé “àwọn ọmọ kéékèèké kò tíì ní àwọn èròjà tín-tìn-tín tó pọ̀ tó lára, èyí tó máa ń wà nínú èèyàn tó sì máa ń gbógun ti bakitéríà.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́