ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 October ojú ìwé 5
  • Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Ọgbọ́n Jẹ́ Fún Ìdáàbòbò”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Oyin Ẹ̀bùn Iyebíye Fáwa Ẹ̀dá
    Jí!—2005
  • Oyin—Ohun Aládùn Tó Ń Wo Ọgbẹ́ Sàn
    Jí!—2002
  • “Aláyọ̀ Ni Ènìyàn Tí Ó Ti Wá Ọgbọ́n Rí”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 October ojú ìwé 5

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÒWE 12-16

Ọgbọ́n Dára Ju Wúrà Lọ

Bíi Ti Orí Ìwé
Òṣùwọ̀n tó ní àkájọ ìwé tó tẹ̀wọ̀n ju owó onírin lọ

Kí nìdí tí ọgbọ́n tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fi wúlò gan-an? Ìdí ni pé kì í jẹ́ kí ẹni tó bá ní in hùwà búburú ó sì máa pa ẹni náà mọ́ láàyè. Ó tún máa ń ní ìpa rere lórí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ó máa jẹ́ kéèyàn lọ́rọ̀ rere lẹ́nu kó sì níwà ọmọlúwàbí.

Ọgbọ́n máa ń jẹ́ ká yẹra fún ìgbéraga

16:18, 19

  • Ọkùnrin agbéraga kan

    Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń mọ̀ pé Jèhófà ni orísun gbogbo ọgbọ́n

  • Ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ tẹ àfojúsùn rẹ̀ tàbí tó ní àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún ẹ̀mí ìgbéraga àti ìjọra-ẹni-lójú

Ọgbọ́n máa ń jẹ́ kéèyàn lọ́rọ̀ rere lẹ́nu

16:21-24

  • Ọkùnrin kan ń sọ̀rọ̀, èkejì sì ń tẹ́tí sílẹ̀

    Ọlọ́gbọ́n èèyàn máa ń fòye bá àwọn èèyàn lò, á máa wá dáadáa wọn, á sì sọ̀rọ̀ rere nípa wọn

  • Ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n máa ń dùn lẹ́nu bí oyin, ó lè yíni lọ́kàn pa dà, kì í tani bí agbọ́n tàbí gúnni bí idà

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Afárá oyin

Béèyàn bá lá oyin, ó máa ń tètè wọnú ara lọ á sì fúnni lágbára. Oyin dùn gan-an ó sì máa ń tún àgọ́ ara ṣe.

Ọ̀rọ̀ rere máa ń tuni lára nípa tẹ̀mí bí oyin ṣe máa tuni lára téèyàn bá lá a.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́